ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 5/15 ojú ìwé 21-25
  • Ǹjẹ́ o Ti Múra Sílẹ̀ Kó o Lè Rí Ìgbàlà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ o Ti Múra Sílẹ̀ Kó o Lè Rí Ìgbàlà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipò Tí Ayé Wà Lónìí Bá Ti Ìgbà Ayé Nóà Mu
  • Ẹni Tó Bá Fẹ́ Rí Ìgbàlà Gbọ́dọ̀ Ní Ìgbàgbọ́
  • Àwọn Àyípadà Tó Ń Wáyé Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé Ń Múra Wa Sílẹ̀ fún Ìgbàlà
  • Múra Sílẹ̀ Kó O Lè Rí Ìgbàlà
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìgbàgbọ́ Nóà Dá Ayé Lẹ́bi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 5/15 ojú ìwé 21-25

Ǹjẹ́ o Ti Múra Sílẹ̀ Kó o Lè Rí Ìgbàlà?

“Lọ, ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ, sínú áàkì náà, nítorí ìwọ ni mo rí pé ó jẹ́ olódodo níwájú mi nínú ìran yìí.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 7:1.

1. Ètò wo ni Jèhófà ṣe fún ìgbàlà nígbà ayé Nóà?

JÈHÓFÀ “mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” nígbà ayé Nóà, àmọ́ ó tún ṣe ètò kan káwọn èèyàn lè rí ìgbàlà. (2 Pétérù 2:5) Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún Nóà olódodo pé kó kan ọkọ̀ áàkì láti dáàbò bo àwọn ẹ̀dá ẹlẹ́mìí nígbà tí omi bá bo gbogbo ayé, ó sì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bó ṣe máa kan ọkọ̀ náà fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 6:14-16) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa retí pé kí ìránṣẹ́ Jèhófà tó bá jẹ́ onígbọràn ṣe, “Nóà . . . ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un.” Àní “ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” Ìgbọràn Nóà wà lára ohun tó jẹ́ ká wà láàyè lónìí.—Jẹ́nẹ́sísì 6:22.

2, 3. (a) Ìhà wo làwọn tó ń gbé nígbà ayé Nóà kọ sí ohun tí Nóà ń ṣe? (b) Ìdánilójú wo ni Nóà ní tó fi wọnú áàkì?

2 Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni Nóà ṣe láti kan ọkọ̀ áàkì yẹn o. Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ bàǹtàbanta tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe yìí jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún púpọ̀ lára àwọn tó ń gbé láyé ìgbà yẹn. Àmọ́, gbogbo ìyẹn ò mú kí wọ́n gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ wọnú ọkọ̀ náà táwọn bá fẹ́ rí ìgbàlà. Níkẹyìn, sùúrù tí Ọlọ́run ní fún ayé burúkú yẹn dópin.—Jẹ́nẹ́sísì 6:3; 1 Pétérù 3:20.

3 Lẹ́yìn iṣẹ́ tó gba agbára tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Jèhófà sọ fún Nóà pé: “Lọ, ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ, sínú áàkì náà, nítorí ìwọ ni mo rí pé ó jẹ́ olódodo níwájú mi nínú ìran yìí.” Ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú tí Nóà ní nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà mú kí “Nóà wọlé, [òun] àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti aya rẹ̀ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Jèhófà sì ti ilẹ̀kùn ọkọ̀ náà kó bàa lè dáàbò bo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ yìí. Nígbà tí Ìkún Omi dé, ọkọ̀ áàkì tí Ọlọ́run ní kí Nóà kàn kò já wọn kulẹ̀, òun ló gbà wọ́n là.—Jẹ́nẹ́sísì 7:1, 7, 10, 16.

Ipò Tí Ayé Wà Lónìí Bá Ti Ìgbà Ayé Nóà Mu

4, 5. (a) Kí ni Jésù fi ìgbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ wé? (b) Kí ni ìgbà ayé Nóà àti àkókò tiwa yìí fi jọra?

4 Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:37) Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí láti jẹ́ ká mọ̀ pé irú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà máa ṣẹlẹ̀ nígbà wíwàníhìn-ín òun tí a kò lè fojú rí, bó sì ṣe rí nìyẹn lóòótọ́. Àgàgà láti ọdún 1919, àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ti gbọ́ irú ìkìlọ̀ tí Nóà kéde. Ìhà tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn sì kọ sí ìkìlọ̀ náà jọ tàwọn tó wà nígbà ayé Nóà.

5 Jèhófà fi Ìkún Omi pa ayé ìgbà yẹn tó “kún fún ìwà ipá” run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13) Gbogbo àwọn tó ń rí Nóà àti ìdílé rẹ̀ láyé ìgbà yẹn ló mọ̀ pé wọn ò sí lára àwọn tó ń hu ìwà ipá, pé ńṣe ni wọ́n ń bá iṣẹ́ kíkan ọkọ̀ áàkì lọ jẹ́jẹ́ ní tiwọn. Èyí náà bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí mu. Àwọn olóòótọ́ ọkàn ń “rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Málákì 3:18) Àwọn èèyàn tí kò ní ẹ̀tanú fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, onínúure, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, àtẹni tó ń tẹpá mọ́ṣẹ́. Ìwà táwọn èèyàn Ọlọ́run ní yìí mú kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn ayé. Àwọn Ẹlẹ́rìí kì í hu ìwà ipá èyíkéyìí, wọ́n sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà darí wọn. Ohun tó mú kí àlàáfíà jọba láàárín wọn, tó sì mú kí wọ́n máa gbé ìgbésí ayé òdodo nìyẹn.—Aísáyà 60:17.

6, 7. (a) Kí làwọn tó wà nígbà ayé Nóà kò róye rẹ̀, báwo lèyí sì ṣe bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí mu? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀?

6 Àwọn èèyàn tó wà nígbà ayé Nóà kò róye pé Ọlọ́run ló ń ti Nóà lẹ́yìn, àti pé òun ló ní kí Nóà máa ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìdí rèé tí wọn ò fi kọbi ara sí ìkìlọ̀ Nóà, tí wọn ò sì ṣe nǹkan kan nípa ìkìlọ̀ náà. Àwọn tòde òní ńkọ́? Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe dára, pé ọmọlúwàbí sì ni wá, síbẹ̀ èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ò ka ìkìlọ̀ Bíbélì àti ìhìn rere tá à ń wàásù sí. Àwọn aládùúgbò, àwọn agbanisíṣẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n ń kíyè sí àwọn Kristẹni tòótọ́ lè máa yìn wọ́n nítorí ìwà rere wọn àmọ́ wọ́n tún lè máa ṣàròyé pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ló bọ̀rọ̀ jẹ́!” Wọ́n ti gbàgbé pé ẹ̀mí Ọlọ́run tó ń darí àwọn Ẹlẹ́rìí ló jẹ́ kí wọ́n lè ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, àlàáfíà, inú rere, ìwà rere, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gálátíà 5:22-25) Ńṣe ló sì yẹ kí èyí túbọ̀ mú káwọn èèyàn máa kọbi ara sí ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí.

7 Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Ọkùnrin kan tó yà síbi iṣẹ́ náà láti bá ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà sọ̀rọ̀ sọ pé: “Kàyéfì gbáà ló jẹ́ fún mi láti rí i pé kò sẹ́nì kankan tó ń mu sìgá láàárín yín, kò sí pé ẹnì kan ń bú ẹnì kejì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tó mutí yó! Ẹ jọ̀ọ́, ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà niyín ni?” Òṣìṣẹ́ náà bi í pé: “Tí n bá sọ fún ẹ pé a kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣé wàá gbà mí gbọ́?” Ọkùnrin náà fèsì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Mi ò ní gbà ẹ́ gbọ́ o.” Ní ìlú mìíràn lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà yẹn kan náà, bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn látìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí wú olórí ìlú náà lórí gan-an. Ó sọ pé ojú kan náà lòun fi ń wo gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn tẹ́lẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn tóun ti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, òun ò fojú kan náà wò wọ́n mọ́. Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ méjì lára ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà yàtọ̀ sáwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì.

8. Ká tó lè la òpin ayé búburú yìí já, kí ló ṣe pàtàkì pé ká ṣe?

8 “Oníwàásù òdodo” ni Nóà ní gbogbo apá ìgbẹ̀yìn “ayé ìgbàanì” tó ṣègbé sínú Ìkún Omi. (2 Pétérù 2:5) Bákan náà, láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí, àwọn èèyàn Jèhófà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run, wọ́n sì ń wàásù ìhìn rere fún wọn nípa ohun tí wọ́n lè ṣe láti wọnú ayé tuntun. (2 Pétérù 3:9-13) Ọlọ́run lo ọkọ̀ áàkì láti dáàbò bo Nóà àti ìdílé rẹ̀ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Bákan náà, yóò dáàbò bo àwọn èèyàn lónìí nígbà ìparun ayé búburú yìí, àmọ́ wọ́n ní láti kọ́kọ́ ní ìgbàgbọ́ kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà.

Ẹni Tó Bá Fẹ́ Rí Ìgbàlà Gbọ́dọ̀ Ní Ìgbàgbọ́

9, 10. Kí nìdí tá a fi ní láti ní ìgbàgbọ́ tá a bá fẹ́ la ìparun ayé Sátánì já?

9 Kí lẹni tó bá fẹ́ rí ìgbàlà nígbà ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí gbọ́dọ̀ ṣe? (1 Jòhánù 5:19) Ẹni náà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ pé òun nílò ààbò. Lẹ́yìn náà, ó gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó máa fi rí ààbò náà. Nǹkan tara wọn làwọn tó wà nígbà ayé Nóà gbájú mọ́, wọn ò gbà pé àwọn nílò ààbò nígbà ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ohun mìíràn tó kó bá wọn ni pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.

10 Àmọ́, Nóà àti ìdílé rẹ̀ gbà pé àwọn nílò ààbò àti ìgbàlà. Wọ́n tún ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti [wu Jèhófà] dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀; àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí, ó dá ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́.”—Hébérù 11:6, 7.

11. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ nípa bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyé ìgbàanì?

11 Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dá wa sí nígbà ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, àwọn nǹkan míì wà tá a ní láti ṣe yàtọ̀ sí pé ká kàn gbà gbọ́ pé ètò àwọn nǹkan yìí máa pa run. A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́, ká sì máa lo àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè láti mú ká rí ìgbàlà. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣe pàtàkì pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. (Jòhánù 3:16, 36) Àmọ́ o, ká rántí pé àwọn tó wọnú ọkọ̀ áàkì tí Nóà kàn nìkan ló rí ìgbàlà nígbà Ìkún Omi. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì tó jẹ́ pé ohun kan ṣoṣo tó ń dáàbò bo ẹni tó bá ṣèèṣì pààyàn ni pé kó sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ìsádi tàbí ìlú ààbò, kò sì gbọ́dọ̀ kúrò níbẹ̀ títí àlùfáà àgbà yóò fi kú. (Númérì 35:11-32) Nígbà tí Jèhófà fi ìyọnu mẹ́wàá kọ lu Íjíbítì nígbà ayé Mósè, gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Íjíbítì ló kú, àmọ́ nǹkan kan ò ṣe àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà ti sọ fún Mósè ṣáájú pé: “Kí [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] mú lára ẹ̀jẹ̀ [ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n fi ṣe Ìrékọjá], kí wọ́n sì fi wọ́n ara òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn àwọn ilé tí wọn yóò ti jẹ ẹ́. . . . Kí ẹnikẹ́ni nínú [wọn] má sì ṣe jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ títí di òwúrọ̀.” (Ẹ́kísódù 12:7, 22) Àkọ́bí ọmọ Ísírẹ́lì wo ló máa jẹ́ ṣàìgbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run, kó wá jáde kúrò nínú ilé tí wọ́n ti wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí ara òpó méjèèjì ilẹ̀kùn rẹ̀ àti sí apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn?

12. Ìbéèrè wo ló yẹ kí kálukú bi ara rẹ̀, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

12 Nítorí náà, ó yẹ kí kálukú ronú dáadáa nípa ipò tóun wà. Ǹjẹ́ lóòótọ́ la wà nínú ibi tí Jèhófà ṣètò pé kó jẹ́ ibi ààbò fún wa nípa tẹ̀mí? Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá dé, omijé ayọ̀ yóò máa bọ́ lójú àwọn tí wọ́n wà nírú ibi ààbò yẹn, tí wọ́n á sì máa dúpẹ́. Àmọ́, ńṣe làwọn yòókù máa ki ìka àbámọ̀ bọnu tí wọ́n á sì máa sunkún kíkorò.

Àwọn Àyípadà Tó Ń Wáyé Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé Ń Múra Wa Sílẹ̀ fún Ìgbàlà

13. (a) Àǹfààní wo làwọn àyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run ti ṣe? (b) Ṣàlàyé díẹ̀ lára àyípadà tó ti wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

13 Jèhófà ti mú kí àwọn àyípadà kan wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nínú apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀. Àwọn àyípadà yìí ti mú kí ètò tí Jèhófà ṣe láti dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí dára sí i, ó ti mú kó dúró dáadáa, ó sì ti mú kó túbọ̀ lágbára. Láti ọdún 1870 sí ọdún 1932, ńṣe làwọn tó wà nínú ìjọ máa ń dìbò yan àwọn alàgbà àtàwọn díákónì. Nígbà tó wá di ọdún 1932, ètò Ọlọ́run ní kí ìjọ má dìbò yan àwọn alàgbà mọ́, pé ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ni kí wọ́n máa dìbò yàn láti ran ẹni tí ètò Ọlọ́run yàn sípò gẹ́gẹ́ bí olùdarí iṣẹ́ ìsìn lọ́wọ́. Lọ́dún 1938, ètò Ọlọ́run ṣètò bí a ó ṣe máa tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ láti yan gbogbo ìránṣẹ́ nínú ìjọ. Láti ọdún 1972, tá a bá fẹ́ yan alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ, a óò kọ́kọ́ dámọ̀ràn wọn fún ètò Ọlọ́run, tí ètò Ọlọ́run bá sì fọwọ́ sí i, wọ́n á fi lẹ́tà tá a fi yàn wọ́n sípò lọ́nà tó bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu ránṣẹ́ sí ìjọ. Gbogbo èyí jẹ́ lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń pọ̀ sí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyípadà ló sì ń wáyé láti mú kí iṣẹ́ wọn rọrùn sí i.

14. Ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ló bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1959?

14 Àgbéyẹ̀wò kínníkínní tó wáyé lórí Sáàmù 45:16 lọ́dún 1950 ló mú ká bẹ̀rẹ̀ ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan tá a ṣì ń ṣe títí dòní. Ẹsẹ Bíbélì náà sọ pé: “Ní ipò àwọn baba ńlá rẹ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò wà, àwọn tí ìwọ yóò yàn ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” Àwọn alàgbà tí wọ́n ń mú ipò iwájú nínú ìjọ nísinsìnyí ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣe nísinsìnyí àtèyí tí wọ́n máa ṣe lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Ọdún 1959 ni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba, tí à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lónìí, bẹ̀rẹ̀. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn ìránṣẹ́ ìjọ nìkan, ìyẹn àwọn tá à ń pè ní alága àwọn alábòójútó báyìí, ló ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí fún oṣù kan. Àmọ́ ní báyìí, ètò Ọlọ́run ti ṣètò ilé ẹ̀kọ́ yìí fún gbogbo àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lẹ́yìn táwọn arákùnrin wọ̀nyí bá ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tán, wọ́n á wá mú ipò iwájú nínú dídá ọ̀kọ̀ọ̀kan Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ìjọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Nípa báyìí, ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí yóò ran gbogbo àwọn ará lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, yóò sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Máàkù 13:10.

15. Ọ̀nà méjì wo la gbà ń mú kí ìjọ Ọlọ́run wà ní mímọ́?

15 Àwọn ohun kan wà táwọn tó bá fẹ́ di ara ìjọ Ọlọ́run ní láti ṣe. Gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ kó rí, a kì í gba àwọn tó jẹ́ olùyọṣùtì lóde òní láyè láti di ara ìjọ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí wọn ò ṣe gbà wọ́n láyè láti wọnú ọkọ̀ áàkì tí Nóà kàn. (2 Pétérù 3:3-7) Ní pàtàkì láti ọdún 1952, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti túbọ̀ kọ́wọ́ ti ètò kan tó máa jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́, ìyẹn yíyọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìronúpìwàdà lẹ́gbẹ́. Àmọ́ ṣá o, a máa ń fi ìfẹ́ ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà lóòótọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ‘ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ wọn.’—Hébérù 12:12, 13; Òwe 28:13; Gálátíà 6:1.

16. Ipò wo làwọn èèyàn Jèhófà wà nípa tẹ̀mí?

16 Kò yani lẹ́nu bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ní ọrọ̀ tẹ̀mí, kì í sì í ṣe pé ó ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ o. Jèhófà ti gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé: “Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu, ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe ẹkún nítorí ìrora ọkàn-àyà, ẹ ó sì hu nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó bùáyà.” (Aísáyà 65:13, 14) Lóòrèkóòrè ni Jèhófà ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ fún wa lákòókò tó bá a mu wẹ́kú ká lè lágbára nípa tẹ̀mí.—Mátíù 24:45.

Múra Sílẹ̀ Kó O Lè Rí Ìgbàlà

17. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ìgbàlà?

17 Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ìsinsìnyí gan-an ni àkókò tó yẹ ká máa “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.” (Hébérù 10:23-25) Tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98,000], tá a sì ń kópa déédéé nínú ìgbòkègbodò ìjọ, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ìgbàlà. Àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa yóò máa tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń sapá láti fi “àkópọ̀ ìwà tuntun” hàn, tá a sì ń sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ètò tí Jèhófà ti ṣe fún ìgbàlà.—Éfésù 4:22-24; Kólósè 3:9, 10; 1 Tímótì 4:16.

18. Kí nìdí tó o fi pinnu láti túbọ̀ fara mọ́ ìjọ Ọlọ́run?

18 Sátánì àti ayé búburú rẹ̀ ń sapá lójú méjèèjì láti fẹ̀tàn mú wa kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run. Àmọ́, a lè dúró gbọn-in nínú ìjọ Ọlọ́run ká sì la ìparun tó ń bọ̀ sórí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já. Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti ẹ̀mí ìmoore tá a ní fún àwọn nǹkan tó ń fi ìfẹ́ pèsè mú ká túbọ̀ pinnu láti má ṣe jẹ́ kí Sátánì rí wa mú. Àṣàrò tá a bá ń ṣe lórí ìbùkún tá a ní nísinsìnyí yóò jẹ́ ká lè dúró gbágbáágbá ti ìpinnu wa. A óò jíròrò díẹ̀ lára ìbùkún wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

• Báwo lohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tiwa yìí ṣe bá ti ìgbà ayé Nóà mu?

• Kí ló ṣe pàtàkì ká ní tá a bá fẹ́ rí ìgbàlà?

• Àwọn àyípadà tó ń wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé wo ló ń mú kí ètò tí Jèhófà ṣe láti dáàbò bò wá túbọ̀ lágbára?

• Báwo ni kálukú wa ṣe lè múra sílẹ̀ ká lè rí ìgbàlà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn èèyàn tó wà nígbà ayé Nóà kò kọbi ara sí ohun tí Nóà ń ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kí nìdí tí ètò Ọlọ́run fi ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àkókò tá a wà yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ fara mọ́ ìjọ Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́