Ayọ̀ Tó Wà Nínú Rírìn Nínú Ìwà Títọ́
“Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—ÒWE 10:22.
1, 2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí ìrònú nípa ọjọ́ iwájú gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ?
Ọ̀MỌ̀RÀN ọmọ Amẹ́ríkà kan sọ pé: “Téèyàn bá ti ń ronú jù nípa ọjọ́ iwájú, èèyàn ò ní lè rí àǹfààní tóun ní nísinsìnyí.” Bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé ṣe rí nìyẹn. Ohun tí wọ́n máa ṣe nígbà tí wọ́n bá dàgbà máa ń gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọn kì í rántí pé ìgbà ọmọdé ní àǹfààní tirẹ̀. Tí wọ́n bá wá dàgbà tán, á máa ká wọn lára pé àwọn ì bá mọ̀ káwọn ti gbádùn ìgbà ọmọdé àwọn dáadáa.
2 Àwọn olùjọsìn Jèhófà pàápàá máa ń ronú jù nípa ọjọ́ iwájú nígbà míì. Ẹ wo àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí. Ara àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lọ́nà láti rí ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa sọ ayé yìí di Párádísè. À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí àìsàn, ọjọ́ ogbó, ìrora, àti ìyà kò ní sí mọ́. Kò burú láti máa fojú sọ́nà fún àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, àmọ́ tí àwọn ìbùkún nípa tara tí a ó ní lọ́jọ́ iwájú bá gbà wá lọ́kàn débi pé a ò tiẹ̀ ronú nípa àwọn ìbùkún tẹ̀mí tá a ní nísinsìnyí ńkọ́? Ìyẹn á mà burú o! Ká tó mọ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí ‘ọkàn-àyà wa máa ṣàìsàn nítorí ìfojúsọ́nà tó sún síwájú’ kọjá ìgbà tá a ń retí. (Òwe 13:12) Onírúurú ìṣòro tá à ń rí nígbèésí ayé lè mú kí gbogbo nǹkan tojú sú wa tàbí kó tiẹ̀ mú ká kárí sọ. Dípò ká máa fàyà rán irú ipò tí kò bára dé bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, tó bá jẹ́ pé ńṣe là ń ronú nípa àwọn ìbùkún tá a ní nísinsìnyí tá a sì mọrírì wọn, gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn ò ní ṣẹlẹ̀ sí wa.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Òwe 10:22 sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà-èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” Ǹjẹ́ ọrọ̀ tẹ̀mí tí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní lóde òní kò tó ohun tó yẹ kó máa múnú wa dùn? Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ọ̀pọ̀ nǹkan tá à ń gbádùn nínú ìjọsìn wa tó mú ká jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí, ká sì rí ire tó ń ṣe fún wa lẹ́ni kọ̀ọ̀kan. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ìbùkún tí Jèhófà ti rọ̀jò sórí ‘àwọn olódodo tó ń rìn nínú ìwà títọ́,’ yóò mú ká túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa láti máa fi ayọ̀ sin Baba wa ọ̀run nìṣó.—Òwe 20:7.
‘Àwọn Ìbùkún Tí Ń Sọni Di Ọlọ́rọ̀’ Nísinsìnyí
4, 5. Ẹ̀kọ́ Bíbélì wo ló wù ọ́ jù lọ, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
4 A lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́, àmọ́ wọn ò fohùn ṣọ̀kan nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Kódà àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ẹ̀sìn kan náà pàápàá ò fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ohun tí Ìwé Mímọ fi kọ́ni gan-an. Ẹ ò rí i pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí wọn! Bí orílẹ̀-èdè àti àṣà ìbílẹ̀ wa tiẹ̀ yàtọ̀ síra, gbogbo wa la jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run tá a mọ orúkọ rẹ̀. Ọlọ́run yìí kì í sì í ṣe ọlọ́run mẹ́talọ́kan táwọn èèyàn gbà pé ó jẹ́ àdììtú. (Diutarónómì 6:4; Sáàmù 83:18; Máàkù 12:29) A tún mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, tó jẹ́ ọ̀ràn pàtàkì, máa tó yanjú, jíjẹ́ tá a bá sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ni kálukú wa yóò fi ṣe ipa tirẹ̀ nínú ọ̀ràn náà. A mọ ipò táwọn òkú wà, a ò sì sí lára àwọn tó ń bẹ̀rù nítorí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ, pé Ọlọ́run máa dá àwọn èèyàn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì tàbí pé ó máa sọ wọ́n sí pọ́gátórì.—Oníwàásù 9:5, 10.
5 Yàtọ̀ síyẹn, inú wa dùn láti mọ̀ pé àwa ẹ̀dá èèyàn ò ṣàdédé wà lórí ilẹ̀ ayé bí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe ń sọ. Dípò ìyẹn, Ọlọ́run ló dá wa, ńṣe ló sì dá wa ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Málákì 2:10) Onísáàmù kan kọrin sí Ọlọ́run rẹ̀ pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.”—Sáàmù 139:14.
6, 7. Àwọn àyípadà wo lo ti ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ tàbí èyí tó o rí táwọn mìíràn ṣe tó ti mérè wá?
6 A bọ́ nínú ìwà àti ìṣe tó ń ṣàkóbá fúnni. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń sọ ọ́ lórí rédíò, tẹlifíṣọ̀n àti nínú ìwé ìròyìn pé sìgá mímu, ọtí àmujù, àti ìṣekúṣe ń ṣàkóbá fúnni. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ wọ̀nyí. Kí lẹni tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn máa ń ṣe nígbà tó bá kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run tòótọ́ kórìíra irú ìwà wọ̀nyẹn, àti pé inú rẹ̀ kò dùn sáwọn tó ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀? Họ́wù, ńṣe nírú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń dẹ́kun híhu irú ìwà wọ̀nyẹn! (Aísáyà 63:10; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 7:1; Éfésù 4:30) Lóòótọ́, ohun tó mú kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe ìyípadà ni pé ó fẹ́ múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn, àmọ́ àwọn èrè kan wà tó máa jẹ, ìyẹn ni ìlera tó dára àti ìbàlẹ̀ ọkàn.
7 Ó máa ń ṣòro gan-an fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti jáwọ́ nínú ìwàkiwà tó ti mọ́ wọn lára. Síbẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń jáwọ́ nínú ìwàkiwà lọ́dọọdún. Wọ́n ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe ìrìbọmi láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé àwọn ti jáwọ́ pátápátá nínú àwọn ìwà tínú Ọlọ́run ò dùn sí. Ẹ ò rí i pé ìṣírí ńlá lèyí jẹ́ fún gbogbo wa! Ńṣe ni ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé yẹn ń mú ká túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa pé a ò ní di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn ìwà tó ń ṣàkóbá fúnni.
8. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló ń mú kí ìdílé láyọ̀?
8 A mọ ohun tó lè jẹ́ ká ní ìdílé aláyọ̀. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ńṣe ni ìdílé àwọn èèyàn ń tú ká. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ti jáwèé fúnra wọn, tí wọ́n sì fi àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀dùn ọkàn. Láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù, ká sọ pé ọgọ́rùn-ún ni gbogbo ìdílé tó wà níbẹ̀, nǹkan bí ogún nínú wọn ló jẹ́ ìdílé olóbìí kan. Báwo ni Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn nínú ìwà títọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ìdílé? Jọ̀wọ́ ka Éfésù orí karùn-ún ẹsẹ kejìlélógún sí orí kẹfà ẹsẹ ìkẹrin, kó o wá fiyè sí ìmọ̀ràn rere tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ọkọ, àwọn aya, àtàwọn ọmọ. Tí ọkọ àti aya bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn ẹsẹ yẹn àtèyí tó wà níbòmíràn nínú Ìwé Mímọ́, wọ́n á gbádùn ìgbéyàwó wọn, ìmọ̀ràn yẹn yóò sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn bó ṣe yẹ, yóò sì jẹ́ kí wọ́n lè ní ìdílé aláyọ̀. Ǹjẹ́ ìbùkún yìí ò tó ohun tó ń múnú èèyàn dùn?
9, 10. Báwo ni ohun tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú ṣe yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn ayé?
9 Ó dá wa lójú pé àwọn ìṣòro ayé máa tó dópin. Pẹ̀lú gbogbo ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, àti bí àwọn aṣáájú ayé kan ṣe ń sa gbogbo ipá wọn, àwọn ìṣòro ńlá tó wà nínú ayé kò tíì yanjú síbẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Klaus Schwab tí í ṣe olùdásílẹ̀ Àpérò Lórí Ètò Ọrọ̀ Ajé Àgbáyé sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé “àwọn ìṣòro ayé ń pọ̀ sí i, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ sí àkókò mọ́ láti yanjú wọn.” Ó sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ewu tó dojú kọ gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ìyẹn àwọn ewu bíi ìpániláyà, ìbàyíkájẹ́ àti ìṣòro ọrọ̀ ajé.” Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Schwab sọ pé: “Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò tó yẹ kí gbogbo ayé fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ kánkán láti yanjú àwọn ìṣòro ayé.” Bá a ṣe túbọ̀ ń wọnú ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, kò sí àmì pé nǹkan máa sàn lọ́jọ́ iwájú.
10 Ẹ wo bó ṣe múnú wa dùn tó láti mọ̀ pé Jèhófà ti ṣe ètò kan láti yanjú gbogbo ìṣòro ẹ̀dá èèyàn! Ètò náà ni Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà máa jẹ́ alákòóso rẹ̀. Ọlọ́run tòótọ́ yóò lo ìjọba yìí láti “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀,” àti láti mú kí “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà” wà lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 46:9; 72:7) Jésù Kristi, ẹni tí Ọlọ́run fi jẹ ọba ìjọba náà yóò ‘dá àwọn òtòṣì, àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, àtàwọn ẹni rírẹlẹ̀ nídè kúrò lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.’ (Sáàmù 72:12-14) Lábẹ́ ìjọba Jésù, oúnjẹ á pọ̀ lọ súà. (Sáàmù 72:16) Jèhófà “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Ìjọba yẹn ti bẹ̀rẹ̀ lọ́run kò sì ní pẹ́ gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú gbogbo ìṣòro tó wà lórí ilẹ̀ ayé.—Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 11:15.
11, 12. (a) Ǹjẹ́ ìlépa fàájì lè jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ tó wà títí lọ? Ṣàlàyé. (b) Kí ló ń jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀?
11 A mọ ohun tó ń jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀. Kí ló ń jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀ gan-an? Ọkùnrin kan tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá sọ pé ohun mẹ́ta ló ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Àwọn ni fàájì, kọ́wọ́ má dilẹ̀ (irú bíi kéèyàn máa ṣiṣẹ́ tàbí kéèyàn máa bójú tó ìdílé), àti kéèyàn máa ṣe ohun tó nítumọ̀ (ìyẹn ohun tó máa ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní). Ọkùnrin yìí sọ pé èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni fàájì, ó wá sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ńlá lọ̀rọ̀ yìí o nítorí pé fàájì lohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lépa.” Kí ni Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí?
12 Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Èmi, àní èmi, sọ nínú ọkàn-àyà mi pé: ‘Wá nísinsìnyí, jẹ́ kí n fi ayọ̀ yíyọ̀ dán ọ wò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, rí ohun rere.’ Sì wò ó! asán ni èyíinì pẹ̀lú. Mo sọ fún ẹ̀rín pé: ‘Ìsínwín!’ àti fún ayọ̀ yíyọ̀ pé: ‘Kí ni eléyìí ń ṣe?’” (Oníwàásù 2:1, 2) Tá a bá fi ojú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ wò ó, a óò rí i pé ayọ̀ téèyàn ń rí nínú fàájì kì í pẹ́ lọ títí. Iṣẹ́ ṣíṣe wá ńkọ́? Iṣẹ́ tó nítumọ̀ jù lọ là ń ṣe, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Iṣẹ́ sísọ ọ̀rọ̀ ìgbàlà tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn jẹ́ iṣẹ́ tó lè yọrí sí ìgbàlà àwa fúnra wa àti tàwọn tó ń fetí sí wa. (1 Tímótì 4:16) Àwa tá a jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” ń rí i pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (1 Kọ́ríńtì 3:9; Ìṣe 20:35) Ńṣe ni iṣẹ́ yìí ń jẹ́ kí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀, ó sì ń jẹ́ kí Ẹlẹ́dàá rí èsì fún Sátánì Èṣù tó ń ṣáátá rẹ̀. (Òwe 27:11) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé ìfọkànsin Ọlọ́run ló ń jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀ tó wà títí lọ.—1 Tímótì 4:8.
13. (a) Kí làwọn àǹfààní tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tó yẹ kó máa múnú wa dùn? (b) Àǹfààní wo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe fún ọ?
13 A ní ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe pàtàkì tó sì ṣàǹfààní. Alàgbà ni Gerhard nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó rántí ìgbà tó jẹ́ ọ̀dọ́, ó ní: “Nígbà tí mo ṣì kéré, mo ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ. Tó bá ti di pé nǹkan ga mí lára, mi kì í lè sọ̀rọ̀ kó já gaara, màá wá bẹ̀rẹ̀ sí í kólòlò. Èyí jẹ́ kí n máa wo ara mi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan, ó sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Àwọn òbí mi fi mí sílé ẹ̀kọ́ tí màá ti kọ́ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ dáadáa àmọ́ pàbó ló já sí. Ahọ́n mi kọ́ ló níṣòro, ohun tí mò ń rò ni ìṣòro mi. Àmọ́, ohun àgbàyanu kan wà tí Jèhófà ti pèsè, ìyẹn ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ kí n ní ìgboyà. Mo sì gbìyànjú láti máa fi àwọn nǹkan tí mò ń kọ́ dánra wò. Bí ìṣòro mi mà ṣe yanjú nìyẹn o! Mo wá dẹni tí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ lẹ́nu, ìrẹ̀wẹ̀sì mi fò lọ, mo tún nígboyà láti máa wàásù lóde ẹ̀rí. Ní báyìí, mo ti ń sọ àsọyé nípàdé. Mó dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà, ẹni tó lo ilé ẹ̀kọ́ yìí láti mú kí ayé mi dára sí i.” Ǹjẹ́ bí Jèhófà ṣe ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ò tó ohun tó ń múnú ẹni dùn?
14, 15. Ìrànlọ́wọ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó lákòókò ìdààmú? Mú àpẹẹrẹ kan wá.
14 A ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, a sì ń rí ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé tó sì wà níṣọ̀kan. Nígbà tí arábìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Katrin tó ń gbé nílẹ̀ Jámánì gbọ́ nípa ìmìtìtì ilẹ̀ àti omíyalé tó wáyé ní gúúsù ìlà oòrùn Éṣíà, ìdààmú bá a gidigidi. Ọmọ arábìnrin yìí lọ sórílẹ̀-èdè Táíláǹdì lákòókò tí jàǹbá yìí wáyé. Fún odindi ọjọ́ kan àti wákàtí mẹ́jọ, arábìnrin yìí ò mọ̀ bóyá ọmọ òun ṣì wà láàyè tàbí ó wà lára àwọn tó fara pa tàbí àwọn tó ti kú tí iye wọn ń lé sí i ṣáá. Ọkàn Katrin balẹ̀ gan-an nígbà tí wọ́n sọ fún un lórí tẹlifóònù pé kò sí nǹkan kan tó ṣe ọmọbìnrin rẹ̀!
15 Kí ló ran Katrin lọ́wọ́ ní gbogbo àkókò tó fi wà nínú ìdààmú? Ó sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àkókò yẹn ni mo fi ń gbàdúrà sí Jèhófà. Mo ṣàkíyèsí pé àdúrà tí mò ń gbà ló ń fún mi lókun àti ìbàlẹ̀ ọkàn ní gbogbo àkókò yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin onífẹ̀ẹ́ ò yéé wá sọ́dọ̀ mi, wọn ò fi mí sílẹ̀.” (Fílípì 4:6, 7) Ẹ ò rí i pé nǹkan ì bá nira fún un jùyẹn lọ tí kì í bá ṣe àdúrà tó ń gbà sí Jèhófà àti àwọn ará tí wọ́n dúró tì í! Àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ àti ìfararora pẹ̀lú àwọn ará jẹ́ ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ tó ṣeyebíye tí kò yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú.
16. Sọ ìrírí kan tó fi bí ìrètí àjíǹde ṣe ṣe pàtàkì tó hàn.
16 A ní ìrètí láti padà rí àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú. (Jòhánù 5:28, 29) Ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Matthias sí. Nígbà tó wà lọ́mọdé, kò mọyì àwọn ìbùkún tó ní, ìdí nìyẹn tó fi ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run. Nísinsìnyí tó ti dàgbà, ó kọ̀wé pé: “Èmi àti bàbá mi ò jọ jókòó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí bàbá àti ọmọ rí. Ọ̀rọ̀ wa kì í bára mu. Síbẹ̀, bó ṣe máa dáa fún mi nígbèésí ayé ló jẹ bàbá mi lógún. Ó fẹ́ràn mi púpọ̀, àmọ́ mi ò mọ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà yẹn. Lọ́dún 1996, bí mo ṣe jókòó tì í níbi tó dùbúlẹ̀ sí nígbà tó ń ṣàìsàn, mo di ọwọ́ rẹ̀ mú bẹ́ẹ̀ ni omijé ń dà lójú mi wàràwàrà. Mo bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú fún gbogbo nǹkan tí mo ti ṣe sẹ́yìn, mo sì sọ fún un pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ púpọ̀. Àmọ́ bàbá mi ò lè gbọ́ ohun tí mò ń sọ mọ́. Àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni bàbá mi dákẹ́. Tí mo bá padà rí i nígbà àjíǹde, gbogbo nǹkan táwa méjèèjì ò lè ṣe pa pọ̀ tẹ́lẹ̀ la máa ṣe. Ó sì dájú pé inú bàbá mi á dùn láti gbọ́ pé mo di alàgbà àti pé èmi àti ìyàwó mi ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé.” Ìbùkún ńlá gbáà ni ìrètí àjíǹde jẹ́ fún wa o!
‘Kì Í Fi Ìrora Kún Un’
17. Kí ló yẹ kí àṣàrò lórí àwọn ìbùkún Jèhófà mú wa ṣe?
17 Jésù Kristi sọ ọ̀rọ̀ kan nípa Baba rẹ̀ ọ̀run, ó ní: “Ó . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:45) Bí Jèhófà Ọlọ́run bá lè máa bù kún àwọn aláìṣòdodo àtàwọn èèyàn burúkú, mélòó-mélòó ni àwọn tó ń rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́! Sáàmù 84:11 sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.” Ẹ wo bí ọpẹ́ wa àti ayọ̀ wa ṣe máa ń pọ̀ tó nígbàkigbà tá a bá ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe ń ṣìkẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe jẹ ẹ́ lógún tó!
18. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà kì í fi ìrora kankan kún ìbùkún rẹ̀? (b) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin fi ń rí ìpọ́njú?
18 “Ìbùkún Jèhófà” ló mú káwọn èèyàn rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. Ọlọ́run sì ti ṣèlérí fún wa pé òun ò ní “fi ìrora kún un.” (Òwe 10:22) Kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin fi ń rí àdánwò àti ìṣòro tó ń mú kí wọ́n wà nínú ìrora àti ìpọ́njú púpọ̀? Ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń mú kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa rí ìṣòro àti ìpọ́njú. Ìkínní, ọkàn èèyàn tó máa ń fà sí ẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5; 8:21; Jákọ́bù 1:14, 15) Ìkejì, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. (Éfésù 6:11, 12) Ìkẹta, ayé búburú tá a wà yìí. (Jòhánù 15:19) Bí Jèhófà tiẹ̀ fàyè gba ohun búburú láti ṣẹlẹ̀ sí wa, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé òun ló fà á. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Jákọ́bù 1:17) Kò sí ìrora kankan nínú ìbùkún Jèhófà.
19. Kí ni yóò jẹ́ èrè àwọn tó bá ń rìn nínú ìwà títọ́ nìṣó?
19 A ò lè ní ọrọ̀ tẹ̀mí láìjẹ́ pé a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀, ńṣe là ń ‘fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wa de ẹ̀yìn ọ̀la, kí a lè di ìyè tòótọ́ [ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun] mú gírígírí.’ (1 Tímótì 6:12, 17-19) Tó bá sì wá di inú ayé tuntun tí Ọlọ́run máa mú wá, Ọlọ́run yóò fún wa ní ọ̀pọ̀ ìbùkún nípa tara láfikún sí ọrọ̀ tẹ̀mí tá a ní nísinsìnyí. Ìyè tòótọ́ ló máa jẹ́ èrè gbogbo àwọn tó “ń bá a nìṣó láti máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run.” (Diutarónómì 28:2) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a ó máa fi ayọ̀ rìn nínú ìwà títọ́ nìṣó.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti jẹ́ kí ìrònú nípa ọjọ́ iwájú gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ?
• Àwọn ìbùkún wo là ń gbádùn nísinsìnyí?
• Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ fi ń rí ìpọ́njú?