ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 6/15 ojú ìwé 12-15
  • Mọ̀ Dájú Pé O Lè Rí Ayọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mọ̀ Dájú Pé O Lè Rí Ayọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jèhófà Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní Ayọ̀
  • Gbígba Ìbáwí Ń Mú Kí Ayọ̀ Ẹni Pọ̀ Sí I
  • Gbígba Tàwọn Ẹlòmíràn Rò Ń Jẹ́ Kéèyàn Láyọ̀
  • Ayọ Tootọ Ninu Ṣiṣiṣẹsin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Ń Sin “Ọlọ́run Aláyọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Awọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun—Awọn Ènìyàn Aláyọ̀ Tí Wọn Wà Létòlétò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 6/15 ojú ìwé 12-15

Mọ̀ Dájú Pé O Lè Rí Ayọ̀

OJÚLÓWÓ ayọ̀, ayọ̀ tó wà títí lọ, kì í ṣe ohun tó rọrùn láti rí. Ohun kan pàtàkì tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń wá ojúlówó ayọ̀ lọ síbi tí wọn kò ti lè rí i. Ì bá dára gan-an ká ní wọ́n ní ọ̀rẹ́ kan tó ṣeé fọkàn tán tó lè fọ̀nà bí wọ́n ṣe lè rí i hàn wọ́n!

Inú Bíbélì làwa èèyàn ti lè rí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé ẹyọ kan péré lára àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì yẹ̀ wò, ìyẹn ìwé Sáàmù. Àádọ́jọ [150] orin ìyìn sí Jèhófà Ọlọ́run ló wà nínú ìwé yìí. Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ló sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ ìdajì wọn. Àmọ́ ohun kan wà tó tún ṣe pàtàkì ju kéèyàn mọ ẹni tó kọ ìwé yìí. Ohun náà ni pé Jèhófà, Ọ̀rẹ́ aráyé tímọ́tímọ́ jù lọ, ló fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí àwọn tó kọ ìwé náà. Èyí mú kó dá wa lójú pé àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tó wà fún àǹfààní wa ló wà nínú rẹ̀, ó sì tún sọ àwọn ohun tó lè jẹ́ ká ní ayọ̀.

Ó dá àwọn tó kọ ìwé Sáàmù lójú hán-ún pé àjọṣe tó dára téèyàn bá ní pẹ̀lú Ọlọ́run ló lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Onísáàmù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà.” (Sáàmù 112:1) Kò sí àjọṣe téèyàn lè ní pẹ̀lú ẹlòmíràn, kò sóhun ìní téèyàn lè ní, kò sì sóhun téèyàn lè gbé ṣe láyé tó lè fúnni láyọ̀ bíi kéèyàn jẹ́ ara “àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn.” (Sáàmù 144:15) Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn lóde òní ló fi hàn pé òótọ́ pọ́nńbélé lọ̀rọ̀ yẹn.

Ó dá arábìnrin kan tó ń jẹ́ Susanne tó ti lé lọ́mọ ogójì ọdún lójú pé àjọṣe èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run ló lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀.a Arábìnrin yìí sọ pé: “Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wọ ẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn kí wọ́n lè jọ máa lé ohun kan náà. Àmọ́, àwọn tó wà nírú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í sábà ka gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ sí ọ̀rẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ láàárín àwa èèyàn Jèhófà. Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà mú ká nífẹ̀ẹ́ ara wa. Ibi yòówù kí àwa èèyàn Ọlọ́run ti pàdé ara wa, bí ọmọ ìyá la máa ń ṣe. Ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa yìí ti mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ gan-an. Ta ló lè sọ pé òun ní onírúurú èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà, àti orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ báyìí bí àwa èèyàn Jèhófà? Mo lè fọwọ́ sọ̀yà pé kéèyàn jẹ́ ara àwọn èèyàn Jèhófà lohun tó ń jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀.”

Arábìnrin mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Maree tí wọ́n bí sórílẹ̀-èdè Scotland náà rí i pé níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà ló lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Ó sọ pé: “Kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mo máa ń wo fíìmù tó ń dẹ́rù bani gan-an. Àmọ́ mi ò kì í lè sùn lóru nítorí ìbẹ̀rù àwọn òkú àti àǹjọ̀nnú tó wà nínú ọ̀pọ̀ fíìmù tí mo máa ń wò, àyàfi tí mo bá mú àgbélébùú tí mo lè fi lé wọn dà nù dání. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí mo sì dẹ́kun wíwo irú àwọn fíìmù bẹ́ẹ̀, àjọṣe tí mo wá ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti sùn lóru láìbẹ̀rù ohunkóhun, mo sì wá ń fi ayọ̀ sin Ọlọ́run tí agbára rẹ̀ ju tàwọn ẹ̀mí èṣù àtàwọn àǹjọ̀nnú tí mo rò pé mò ń rí lọ fíìfíì.”

Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jèhófà Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní Ayọ̀

Kò sídìí tó fi yẹ ká máa ṣiyèméjì nípa jíjẹ́ tí Ẹlẹ́dàá jẹ́ Olódùmarè àtẹni tí ọgbọ́n rẹ̀ kò láàlà. Dáfídì mọ̀ pé ẹni tóun lè gbára lé pátápátá tóun sì lè sá di ni Jèhófà, ìdí nìyí tó fi kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi Jèhófà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.”—Sáàmù 40:4.

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Maria sọ pé: “Ohun tójú mi rí lórílẹ̀-èdè Sípéènì àti láwọn ibòmíràn jẹ́ kí n mọ̀ pé ṣíṣe nǹkan ní ọ̀nà Jèhófà la fi lè ṣàṣeyọrí, àní bí ọkàn wa bá tiẹ̀ fẹ́ ká ṣe é lọ́nà míì pàápàá. Èyí máa ń fúnni láyọ̀ nítorí pé ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ ká máa gbà ṣe nǹkan ló dára jù nígbàkigbà.”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí alàgbà kan tó ń jẹ́ Andreas tó ti sìn ní onírúurú ibi nílẹ̀ Yúróòpù ti jẹ́ kó mọ̀ pé ẹni téèyàn lè gbẹ́kẹ̀ lé ni Jèhófà. Ó sọ pé: “Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa lórí mi gan-an ní kékeré, ńṣe ló máa ń gbà mí níyànjú pé kí n lépa ohun tó máa jẹ́ kí n di ọlọ́rọ̀. Ìjákulẹ̀ ńlá ló jẹ́ fún un nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, tí mi ò ṣiṣẹ́ tí màá fi lè ní owó ìfẹ̀yìntì táwọn èèyàn rò pé kì í jẹ́ kéèyàn jìyà lọ́jọ́ alẹ́. Látìgbà tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, ìyà ohunkóhun ò jẹ mí, mo sì ní ọ̀pọ̀ ìbùkún tó wu àwọn ẹlòmíì láti ní àmọ́ tí wọn ò ní.”

Lọ́dún 1993, àwọn alábòójútó ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Selters, nílẹ̀ Jámánì, ní kí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Felix wá ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ilé mìíràn láfikún sí ti tẹ́lẹ̀ láti mú kí ẹ̀ka náà tóbi sí i. Nígbà tí iṣẹ́ náà parí, wọ́n ní kó kúkú di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀? Ó ní: “Mo fara mọ́ ọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń ṣiyèméjì. Àmọ́, ọdún kẹwàá rèé tí mo ti wà ní ẹ̀ka yìí, ó sì dá mi lójú pé Jèhófà gbọ́ àdúrà mi. Ó mọ ohun tó máa ṣe mí láǹfààní jù lọ. Mo jẹ́ kí Jèhófà fi ohun tó fẹ́ kí n ṣe hàn mí nípa fífi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé e àti nípa jíjẹ́ kó máa darí mi.”

Susanne tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fẹ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn ẹni tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù, àmọ́ ó wáṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ tó máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà títí kò rí. Lẹ́yìn tó wáṣẹ́ yìí fún ọdún kan tí kò rí, ó ṣe ohun kan tó fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ó ní: “Mo gba fọ́ọ̀mù iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ṣáájú ìgbà yẹn, mo ti tọ́jú owó tó máa gbé mi fún nǹkan bí oṣù kan sílẹ̀. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, oṣù yẹn lárinrin gan-an ni! Ayọ̀ tí mo rí nínú iṣẹ́ ìwàásù lóṣù yẹn kì í ṣe kékeré, ṣùgbọ́n nínú gbogbo ibi tí mo lọ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kò séyìí tí wọ́n ti gbà mí síṣẹ́. Àmọ́, Jèhófà ò pa mí tì gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn oṣù yẹn, mo rí iṣẹ́ kan. Mo wá rí i kedere pé ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ni Jèhófà! Ìrírí mi àkọ́kọ́ yìí nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún mú kí n dẹni tó ní ọ̀pọ̀ ìbùkún àti ayọ̀.”

Gbígba Ìbáwí Ń Mú Kí Ayọ̀ Ẹni Pọ̀ Sí I

Dáfídì Ọba ṣe àwọn àṣemáṣe kan nígbà ayé rẹ̀. Nígbà mìíràn, èyí máa ń gba pé kí wọ́n bá a wí. Ṣé àwa náà máa ń fi tinútinú gba ìbáwí àti ìtọ́ni bíi ti Dáfídì?

Nígbà kan, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Aida nílẹ̀ Faransé rí i pé òun ti ṣe àṣemáṣe kan. Ó ní: “Ohun tó jẹ mí lógún jù lọ ni bí màá ṣe padà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Òun ló jẹ mí lọ́kàn jù lọ.” Ó lọ bá àwọn alàgbà ìjọ, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. Ní báyìí tó ti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún fọ́dún mẹ́rìnlá, ó sọ pé: “Inú mi dùn gan-an ni láti mọ̀ pé Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí!”

Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run, a tiẹ̀ lè má ṣe àṣemáṣe rárá. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Judith sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún ọdún, ìfẹ́ ọmọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tá a jọ ń ṣòwò tó sì ń ṣe gbogbo nǹkan láti fa ojú mi mọ́ra kó sí mi lórí. Àwọn èèyàn gba tiẹ̀, ó sì rọ́wọ́ mú nídìí okòwò rẹ̀. Ó sì ti níyàwó o! Mo rí i pé mo ní láti ṣèkan nínú kí n pa àwọn òfin Jèhófà mọ́ àbí kí n má pa á mọ́. Mo fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí mi. Bàbá mi ò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ rárá nígbà tó ń rán mi létí ohun tí Jèhófà yóò fẹ́ kí n ṣe nírú ipò yẹn. Ó bá mi wí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Ohun tí mo sì nílò gan-an nìyẹn! Síbẹ̀ náà, mo ṣì ń wá ọgbọ́n tí màá fi ṣe ohun tí ń bẹ lọ́kàn mi. Àmọ́, ní alaalẹ́, màmá mi máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn òfin Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó àti bó ṣe ń gbani là. Ó sì ṣe èyí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀. Mo dúpẹ́ pé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọkàn mi padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ìbáwí àti ẹ̀kọ́ tí mo gbà lọ́dọ̀ Jèhófà fún mi láyọ̀ púpọ̀. Lára ayọ̀ ọ̀hún sì ni ọ̀pọ̀ ọdún tó lérè tí mo ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, àti ọkọ gidi tí mo ní tó nífẹ̀ẹ́ mi tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn.”

Àwọn ìrírí bí èyí fi hàn kedere pé ọ̀rọ̀ pàtàkì tó sì jóòótọ́ ni Dáfídì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kò ka ìṣìnà sí lọ́rùn.”—Sáàmù 32:1, 2.

Gbígba Tàwọn Ẹlòmíràn Rò Ń Jẹ́ Kéèyàn Láyọ̀

Dáfídì kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀; ní ọjọ́ ìyọnu àjálù, Jèhófà yóò pèsè àsálà fún un. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ, yóò sì pa á mọ́ láàyè. A óò máa pè é ní aláyọ̀.” (Sáàmù 41:1, 2) Ẹ̀mí ìgbatẹnirò tí Dáfídì fi hàn sí Mefibóṣẹ́tì arọ tó jẹ́ ọmọ Jónátánì ọ̀rẹ́ Dáfídì tímọ́tímọ́, jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà ọmọlúwàbí tó yẹ kéèyàn máa hù sáwọn ẹni rírẹlẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 9:1-13.

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Marlies tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì láti ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta sẹ́yìn láǹfààní láti máa wàásù fáwọn tó sá kúrò láwọn àgbègbè eléwu nílẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà, àti Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Ó sọ pé: “Onírúurú ìṣòro ló ń bá àwọn èèyàn náà fínra, ojú àtọ̀húnrìnwá ni wọ́n sì gbà pé àwọn èèyàn fi ń wo àwọn, àní wọ́n tún gbà pé àwọn èèyàn ò kà wọ́n sí rárá. Àmọ́, kò sígbà téèyàn ran irú wọn lọ́wọ́ téèyàn kì í láyọ̀.”

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Marina tó lé díẹ̀ lẹ́ni ogójì ọdún kọ̀wé pé: “Àìlọ́kọ mi jẹ́ kí n mọ̀ pé ìtura ńlá lèèyàn máa ń ní béèyàn bá rẹ́ni dúró ti òun nígbà ìṣòro. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń lo tẹlifóònù àti lẹ́tà láti fi fún àwọn èèyàn níṣìírí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí mo fún níṣìírí ló ti dúpẹ́ lọ́wọ́ mi. Bí mo sì ṣe ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ yìí ń fún mi láyọ̀.”

Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Dimitar tó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sọ pé: “Ìyá mi nìkan ló tọ́ mi dàgbà. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wa máa ń mú mi dání lọ sóde ìwàásù, táá sì máa kọ́ mi ní bá a ṣe ń wàásù. Mi ò lè gbàgbé nǹkan tó ṣe fún mi láé. Mo mọ̀ pé nígbà míì, n kì í tètè tẹ̀ síwájú, àmọ́ kò jáwọ́ lọ́rọ̀ mi.” Ẹ̀mí ìmọrírì tí Dimitar ní fún ìrànlọ́wọ́ tóun alára rí gbà yìí mú kóun náà máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Ó ní: “Mo máa ń gbìyànjú láti bá ọ̀dọ́ kan àti àgbàlagbà kan jáde òde ẹ̀rí, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lóṣù.”

Ìwé Sáàmù tún mẹ́nu kan àwọn nǹkan mìíràn tó ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Ọ̀kan lára wọn ni pé ká gbára lé Jèhófà fún okun dípò ká gbára lé ara wa. Ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí okun wọn ń bẹ nínú [Jèhófà].”—Sáàmù 84:5.

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Corinna rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè kan táwọn Ẹlẹ́rìí ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí. Ó sọ pé: “Èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀, àṣà wọn àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú yàtọ̀ pátápátá sí tibi tí mo ti kúrò. Ńṣe ló dà bíi pé ayé mìíràn ni mo wà. Nígbà tí mo ronú kan ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ àjèjì yìí, ńṣe làyà mi là gàrà. Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, ọpẹ́lọpẹ́ okun tó fún mi ni mo fi lè wàásù látàárọ̀ ṣúlẹ̀ ní àgbègbè àdádó yìí. Nígbà tó yá, ó mọ́ mi lára. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà mo ṣì ń jàǹfààní lílọ tí mo lọ síbẹ̀ títí dòní. Mo rí i pé pẹ̀lú agbára Jèhófà, èèyàn lè borí àwọn ìṣòro tó dà bí òkè ńlá.”

Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀, irú bíi níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀, fífi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, gbígba ìbáwí rẹ̀, àti gbígba tàwọn ẹlòmíràn rò. Tá a bá ń rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà tá a sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, a óò láyọ̀ nítorí pé Jèhófà yóò máa fojú rere wò wá.—Sáàmù 89:15; 106:3; 112:1; 128:1, 2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Maria

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Maree

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Susanne àti Andreas nìyí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Corinna

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Dimitar

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́