Jóòbù Jẹ́ Oníwà Títọ́ ó Sì Ní Ìfaradà
“Ìwọ ha ti fi ọkàn-àyà rẹ sí ìránṣẹ́ mi Jóòbù, pé kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú?”—JÓÒBÙ 1:8.
1, 2. (a) Ìṣòro ńlá wo ló dé bá Jóòbù lójijì? (b) Sọ bí ipò nǹkan ṣe rí fún Jóòbù kí ìṣòro ńlá tó dé bá a.
ỌKÙNRIN kan wà láyé ìgbàanì tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. Ó lówó, ó lọ́rọ̀, ó ní ìdílé aláyọ̀, ara rẹ̀ le, gbajúmọ̀ sì ni láwùjọ. Àmọ́ lójijì, ìṣòro ńláńlá mẹ́ta dé bá a tẹ̀léra-tẹ̀léra. Gbogbo ọrọ̀ tó ní pòórá. Lẹ́yìn ìyẹn, ìjì líle kan tí irú rẹ̀ ṣọ̀wọ́n ṣekú pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀. Láìpẹ́ sígbà yẹn, àìsàn líle kan tó mú kí eéwo bo gbogbo ara rẹ̀ kọ lù ú. Ó ṣeé ṣe kó o ti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jóòbù là ń sọ, ẹni tí ìtàn inú ìwé Jóòbù dá lé lórí.—Jóòbù, orí 1 àti 2.
2 Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn ni Jóòbù fi sọ pé: “Ì bá ṣe pé mo wà gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní oṣù òṣùpá ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn!” (Jóòbù 3:3; 29:2) Tí ìṣòro bá dé báni, ta ni kì í ronú kan àkókò tí gbogbo nǹkan ṣì rọ̀ṣọ̀mù fóun? Jóòbù jẹ́ èèyàn dáadáa, ó sì dà bí ẹni pé Ọlọ́run ò jẹ́ kó ní ìyọnu kankan. Ńṣe làwọn tó jẹ́ gbajúmọ̀ láwùjọ máa ń wárí fún un, tí wọ́n sì máa ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbàmọ̀ràn. (Jóòbù 29:5-11) Jóòbù ní ọrọ̀, àmọ́ kò ka ọrọ̀ tó ní sí pàtàkì. (Jóòbù 31:24, 25, 28) Tó bá rí àwọn opó àtàwọn ọmọ aláìlóbìí tó ń jìyà, ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Jóòbù 29:12-16) Kò sì dalẹ̀ ìyàwó rẹ̀.—Jóòbù 31:1, 9, 11.
3. Lójú Jèhófà, irú èèyàn wo ni Jóòbù?
3 Jóòbù jẹ́ ẹnì kan tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ nítorí pé Ọlọ́run ló ń sìn. Jèhófà sọ pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” (Jóòbù 1:1, 8) Àmọ́ bí Jóòbù ṣe jẹ́ oníwà mímọ́ tó yẹn, ìṣòro ńlá dé bá a, ìyẹn sì fòpin sí gbogbo ìgbádùn tó ti ń jẹ bọ̀. Gbogbo nǹkan tó ṣe làálàá láti kó jọ ṣègbé, ó wá dẹni tí ìrora, ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ hàn léèmọ̀.
4. Kí nìdí tó fi dára ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù yẹ̀ wò?
4 Àmọ́ ṣá o, Jóòbù nìkan kọ́ ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ìṣòro ńlá dé bá o. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni lóde òní ló ní ìṣòro bíi tirẹ̀. Ìdí rèé tó fi yẹ ká ronú lórí ìbéèrè méjì yìí: Báwo ni gbígbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù yẹ̀ wò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro ńlá bá dé bá wa? Báwo ló sì ṣe lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fi ọ̀rọ̀ àwọn tó wà nínú ìpọ́njú ro ara wa wò?
Ọ̀ràn Tó Dá Lórí Ìdúróṣinṣin Tó sì Tún Jẹ́ Ìdánwò Ìwà Títọ́
5. Kí ni Sátánì sọ pé ó ń mú kí Jóòbù máa sin Ọlọ́run?
5 Irú ohun tó ṣe Jóòbù yìí kò ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni rí. Jóòbù ò mọ̀ pé Èṣù ti sọ ọ̀rọ̀ òun pé kì í ṣe tọkàntọkàn lòun fi ń sin Ọlọ́run. Nígbà kan táwọn áńgẹ́lì pé jọ ní ọ̀run, tí Jèhófà sọ fún Sátánì pé kó kíyè sí àwọn ànímọ́ rere tí Jóòbù ní, Sátánì fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká?” Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé àwọn ohun tí Jóòbù ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló mú kó máa sin Ọlọ́run, ohun kan náà ló sì tún ń sọ nípa gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yòókù. Sátánì sọ fún Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.”—Jóòbù 1:8-11.
6. Ọ̀ràn ńlá wo ni Sátánì dá sílẹ̀?
6 Ọ̀ràn kékeré kọ́ ni Sátánì dá sílẹ̀ yìí o. Ó sọ pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run kò tọ̀nà. Àmọ́, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Ọlọ́run máa fi ìfẹ́ ṣàkóso ayé òun ọ̀run? Àti pé, ṣé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ pé èèyàn ní yẹn náà lèèyàn fi ń sin Ọlọ́run lóòótọ́? Jèhófà fún Èṣù láyè láti dán Jóòbù wò, torí ó mọ̀ pé Jóòbù jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin. Èyí fi hàn pé Sátánì gan-an lẹni tó fa onírúurú ìṣòro tó bá Jóòbù léraléra. Nígbà tí Sátánì kó ìṣòro àkọ́kọ́ bá Jóòbù tí Jóòbù ò bọ́hùn, ló bá fi àìsàn burúkú kan ṣe é. Èṣù sọ pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.”—Jóòbù 2:4.
7. Àwọn ìṣòro wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń ní lóde òní tó dà bíi ti Jóòbù?
7 Òótọ́ ni pé ìpọ́njú tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni ń rí lóde òní kò tó ti Jóòbù, síbẹ̀ onírúurú ìṣòro ló ń bá wọn fínra. Ọ̀pọ̀ ń fojú winá inúnibíni tàbí ogun ìdílé. Ìṣòro àtijẹ-àtimu àti àìsàn kò jẹ́ káwọn míì gbádùn. Wọ́n ti pa àwọn kan nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Àmọ́ kì í ṣe pé ká kúkú wá di ẹ̀bi gbogbo ìṣòro tó bá ti dé bá ẹnì kọ̀ọ̀kan ru Sátánì o. Ká sòótọ́, àwọn àṣìṣe wa tàbí àìpé tá a ti jogún ló ń fa àwọn ìṣòro mìíràn. (Gálátíà 6:7) Kò sẹ́ni tí àjálù ò lè dé bá, kò sì sẹ́ni tó lè sọ pé ìṣòro ọjọ́ ogbó ò ní kan òun. Bíbélì fi hàn kedere pé lákòókò tá a wà yìí, Jèhófà ò ràdọ̀ bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kí èyíkéyìí nínú àwọn ìṣòro wọ̀nyí má bàa kàn wọ́n.—Oníwàásù 9:11.
8. Ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà lo ìpọ́njú tó bá dé bá wa?
8 Síbẹ̀, Sátánì lè lo ìpọ́njú tó bá dé bá wa láti sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ‘ẹ̀gún kan wà nínú ẹran ara òun, tí í ṣe áńgẹ́lì Sátánì tí ń gbá òun ní àbàrá ṣáá.’ (2 Kọ́ríńtì 12:7) Yálà àìlera kan ni ẹ̀gún yìí, irú bí ìṣòro ojú, tàbí nǹkan míì, Pọ́ọ̀lù mọ̀ dájú pé Sátánì lè lo ìṣòro yìí àti ìbànújẹ́ tó lè tìdí rẹ̀ yọ láti fi ba ayọ̀ àti ìwà títọ́ òun jẹ́. (Òwe 24:10) Lóde òní, Sátánì lè lo bàbá, ìyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn ọmọ ilé ìwé ẹni tàbí ìjọba bóofẹ́-bóokọ̀ pàápàá láti ṣe inúnibíni sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láwọn ọ̀nà kan.
9. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu tá a bá ń rí ìṣòro tàbí inúnibíni?
9 Kí la lè ṣe tí gbogbo ìṣòro wọ̀nyí ò fi ní borí wa? Òun ni pé kí á ka àwọn ìṣòro yìí sí ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn a sì ti fi ara wa sábẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. (Jákọ́bù 1:2-4) Ohun tí ì báà fa ìpọ́njú bá wa, tá a bá mọ bí jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì tó, mìmì kankan ò ní lè mì wá nínú ìjọsìn wa sí Jèhófà. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn Kristẹni pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí iná tí ń jó láàárín yín rú yín lójú, èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí yín fún àdánwò, bí ẹni pé ohun àjèjì ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí yín.” (1 Pétérù 4:12) Pọ́ọ̀lù náà sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Títí dòní, Sátánì ṣì ń sọ pé kì í ṣe tọkàntọkàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń sin Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ nípa Jóòbù. Bíbélì tiẹ̀ fi hàn pé ńṣe ni Sátánì túbọ̀ ń fúngun mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Ìṣípayá 12:9, 17.
Jóòbù Ò Lóye Ọ̀ràn Tó Wà Nílẹ̀, Kò Tún Rí Ìmọ̀ràn Rere Gbà
10. Kí lohun tí Jóòbù ò mọ̀?
10 Ohun kan wà tí Jóòbù ò mọ̀ àmọ́ tó yẹ káwa ti mọ̀. Ohun náà ni pé Jóòbù ò mọ ìdí tí gbogbo ìṣòro wọ̀nyẹn fi dé bá òun. Ó sọ pé, “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fi fúnni, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti gbà lọ.” Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 1:21) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Sátánì mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ jẹ́ kí Jóòbù rò pé Ọlọ́run ló fa ìpọ́njú tó dé bá a.
11. Sọ bí ìṣòro tó dé bá Jóòbù ṣe rí lára rẹ̀.
11 Ìrẹ̀wẹ̀sì ńlá dé bá Jóòbù, àmọ́ kò bú Ọlọ́run bí ìyàwó rẹ̀ ṣe sọ pé kó ṣe. (Jóòbù 2:9, 10) Jóòbù sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé nǹkan dára fáwọn ẹni burúkú ju òun lọ. (Jóòbù 21:7-9) Ńṣe ni yóò máa rò ó pé: ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ń fìyà jẹ mí?’ Àwọn ìgbà míì tiẹ̀ wà tó wò ó pé ó sàn kóun kú. Ó sọ pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù, pé ìwọ yóò pa mí mọ́ ní ìkọ̀kọ̀ títí ìbínú rẹ yóò fi yí padà!”—Jóòbù 14:13.
12, 13. Àkóbá wo ni ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ ṣe fún Jóòbù?
12 Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n láwọn wá “bá a kẹ́dùn, kí wọ́n sì tù ú nínú.” (Jóòbù 2:11) Àmọ́, “olùtùnú tí ń dani láàmú” ni wọ́n jẹ́. (Jóòbù 16:2) Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan tí Jóòbù lè sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ti wá tù ú nínú, àmọ́ ńṣe làwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta yìí tún dá kún ìṣòro rẹ̀, wọ́n mú kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pọ̀ sí i.—Jóòbù 19:2; 26:2.
13 Jóòbù á ti máa bi ara rẹ̀ pé: ‘Kí ló dé tó fi jẹ́ pé èmi nirú nǹkan báyìí wá ṣẹlẹ̀ sí? Kí lẹ̀ṣẹ̀ mi tí gbogbo ìṣòro yìí fi dé bá mi?’ Ohun táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ pé ó fa ìṣòro rẹ̀ kọ́ ló fà á. Wọ́n ní àfọwọ́fà rẹ̀ ni, pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó dá ló ń jẹ. Élífásì béèrè pé: “Ta ni aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ tí ó ṣègbé rí? . . . Gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo rí, àwọn tí ń hùmọ̀ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ àti àwọn tí ń fúnrúgbìn ìjàngbọ̀n, àwọn fúnra wọn ni yóò ká a.”—Jóòbù 4:7, 8.
14. Tẹ́nì kan bá níṣòro, kí nìdí tí kò fi yẹ ká yára gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló fà á?
14 Lóòótọ́, téèyàn bá fúnrúgbìn nípa ti ara tí kì í ṣe nípa ti ẹ̀mí, èèyàn lè ko ìṣòro. (Gálátíà 6:7, 8) Àmọ́, nínú ètò àwọn nǹkan tá a wà yìí, ìṣòro lè dé báni yálà ìwà rere lèèyàn ń hù tàbí ìwà búburú. Yàtọ̀ síyẹn, irọ́ gbuu ni pé àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kì í níṣòro kankan. Jésù Kristi tó jẹ́ “aláìlẹ́gbin, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” kú ikú oró lórí òpó igi, wọ́n sì pa àpọ́sítélì Jákọ́bù nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. (Hébérù 7:26; Ìṣe 12:1, 2) Èrò òdì tí Élífásì àtàwọn méjì tó kù ní yìí ló mú kí Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í jà fún orúkọ rere tó ní, òun ló sì mú kó máa rin kinkin mọ́ ọn pé aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ lòun. Ó sì tún lè jẹ́ pé ẹ̀sùn táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù fi kàn án pé ẹ̀ṣẹ̀ tó dá ló kó o síyọnu ló mú kí Jóòbù rò pé Ọlọ́run ṣàìdáa sóun.—Jóòbù 34:5; 35:2.
Bá A Ṣe Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Nígbà Ìṣòro
15. Irú èrò wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro?
15 Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ kankan wà tá a lè rí kọ́ lára Jóòbù? Ẹnì kan lè máa wò ó pé kò yẹ kó jẹ́ òun ni àjálù, àìsàn, tàbí inúnibíni máa dé bá. Ó lè jọ pé púpọ̀ lára àwọn ìṣòro wọ̀nyí kì í ta bá àwọn kan. (Sáàmù 73:3-12) Àmọ́, nígbà míì, á dára ká bi ara wa láwọn ìbéèrè pàtàkì wọ̀nyí: ‘Ǹjẹ́ ìfẹ́ tí mo ní sí Ọlọ́run yóò mú kí n máa sìn ín láìka ìṣòro èyíkéyìí sí? Ǹjẹ́ ó máa ń wù mí láti ṣe ohun táá jẹ́ kí Jèhófà lè “fún ẹni tí ń ṣáátá rẹ̀ lésì?”’ (Òwe 27:11; Mátíù 22:37) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ táwọn kan ń sọ mú ká máa rò pé bóyá ni Baba wa ọ̀run máa ràn wá lọ́wọ́. Nígbà kan, arábìnrin olóòótọ́ kan tó ṣàìsàn líle fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Mo mọ̀ pé bí Jèhófà bá fàyè gba ohunkóhun kó ṣẹlẹ̀ sí mi, màá lè fara dà á. Mo mọ̀ dájú pé Jèhófà máa fún mi lókun láti fara dà á. Kò já mi kulẹ̀ rí.”
16. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ní ìṣòro tó le koko?
16 Ohun kan wà tá a mọ̀ nípa ọgbọ́n àrékérekè tí Sátánì máa ń lò àmọ́ tí Jóòbù ò mọ̀. Bíbélì sọ pé: “Àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀,” tàbí ọgbọ́n àyínìke rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Yàtọ̀ síyẹn, a tún ní àwọn ohun tó lè jẹ́ ká di ọlọgbọ́n. Nínú Bíbélì, a lè rí ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí wọ́n fara da onírúurú ìṣòro. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jìyà ju ọ̀pọ̀ Kristẹni lọ kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ẹlẹ́rìí kan nílẹ̀ Yúróòpù tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì fi oúnjẹ rẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta ṣe pàṣípààrọ̀ nítorí Bíbélì. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èrè ni mo jẹ bí mo ṣe fi oúnjẹ mi ṣe pàṣípààrọ̀ nítorí Bíbélì! Bí ebi tilẹ̀ pa mí nígbà yẹn, mo rí oúnjẹ tẹ̀mí tó fún èmi àtàwọn míì lókun ní gbogbo àkókò ìṣòro yẹn. Bíbélì ọ̀hún ṣì wà lọ́wọ́ mi títí dòní.”
17. Àwọn ohun wo ni Ọlọ́run pèsè tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro?
17 Yàtọ̀ sí ìtùnú tá à ń rí látinú Ìwé Mímọ́, a tún ní ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó jíire nípa bá a ṣe lè borí ìṣòro. Tó o bá wo ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index, ó ṣeé ṣe kó o rí ìrírí olùjọsìn Jèhófà kan tó ti ní irú ìṣòro tó o ní. (1 Pétérù 5:9) Ohun mìíràn tó tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ni pé kó o fi ọ̀rọ̀ rẹ lọ àwọn alàgbà tó ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni àdúrà gbígbà, òun ló máa jẹ́ kó o rí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù lè fara da “àbàrá” tí Sátánì ń gbá a? Ohun náà ni pé ó gbára lé agbára Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 12:9, 10) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.
18. Báwo làwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ṣe lè fún wa lókun?
18 O lè wá rí i báyìí pé ìrànlọ́wọ́ ń bẹ, má sì ṣaláì wá a. Ìwé Òwe sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Gẹ́gẹ́ bí ikán ṣe lè jẹ ilé tí wọ́n bá fi igi kọ́ kí ilé ọ̀hún sì wó lulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìrẹ̀wẹ̀sì ṣe lè sọ àwa Kristẹni dẹni tí kò lágbára láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, Jèhófà máa ń lo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bíi tiwa láti ràn wá lọ́wọ́. Lọ́jọ́ tí wọ́n wá mú Jésù, áńgẹ́lì kan yọ sí i, ó sì fún un lókun. (Lúùkù 22:43) Nígbà tí wọ́n ń mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, tó sì pàdé àwọn ará ní Ibi Ọjà Ápíọ́sì àti Ilé Èrò Mẹ́ta, ó “dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.” (Ìṣe 28:15) Títí dòní yìí, arábìnrin ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan ṣì máa ń rántí bí àwọn ará ṣe ràn án lọ́wọ́ nígbà tó dé àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Ravensbrück. Ọ̀dọ́ ni arábìnrin yìí lásìkò yẹn, ẹ̀rù sì ń bà á gan-an. Ó ní: “Arábìnrin kan wá mi kàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Arábìnrin mìíràn tọ́jú mi, ó ń ṣe bí ìyá fún mi, ó ń ràn mí lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí.”
“Jẹ́ Olùṣòtítọ́”
19. Kí ló ran Jóòbù lọ́wọ́ tí Sátánì ò fi rí i mú?
19 Jèhófà sọ pé Jóòbù jẹ́ ẹnì kan tó “di ìwà títọ́ rẹ̀ mú ṣinṣin.” (Jóòbù 2:3) Bí ìrẹ̀wẹ̀sì tiẹ̀ bá Jóòbù tí kò sì mọ ìdí tóun fi ń jìyà, síbẹ̀ ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Jóòbù pinnu pé òun ò ní fi Ọlọ́run sílẹ̀. Ó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5.
20. Kí nìdí tí ìfaradà fi ṣe pàtàkì?
20 Táwa náà bá ṣe irú ìpinnu yẹn, a óò lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ nínú ipòkípò tá a bá wà, yálà a wà nínú ìṣòro ńlá, ohun kan ń dán ìgbàgbọ́ wa wò tàbí wọ́n ń ṣàtakò sí wa. Jésù sọ fún ìjọ tó wà ní Símínà pé: “Má fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀. Wò ó! Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún, kí ẹ sì lè ní ìpọ́njú [ìdààmú, ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìnilára] fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.”—Ìṣípayá 2:10.
21, 22. Nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, kí lohun tó lè tù wá nínú?
21 Nínú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí, kò sí bí a ò ṣe ní rí ohun táá dán ìfaradà àti ìwà títọ́ wa wò. Àmọ́, Jésù fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé bá a ṣe ń retí ìpọ́njú tó máa dé lọ́jọ́ iwájú, kò yẹ kí ẹ̀rù bà wá. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká jẹ́ olóòótọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìpọ́njú náà . . . jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,” àmọ́ “ògo,” ìyẹn èrè tí Jèhófà ṣèlérí fún wa ‘tayọ síwájú àti síwájú sí i, ó sì jẹ́ àìnípẹ̀kun.’ (2 Kọ́ríńtì 4:17, 18) Kódà, ìgbà díẹ̀ ni Jóòbù fi wà nínú ìpọ́njú tá a bá fi èyí wé ọ̀pọ̀ ọdún aláyọ̀ tó lò láyé kí ìṣòro tó dé bá a àtèyí tó lò lẹ́yìn ìyẹn.—Jóòbù 42:16.
22 Síbẹ̀, àwọn ìgbà kan lè wà nígbèésí ayé wa tó máa dà bíi pé ìṣòro wa ò lópin táá sì jọ pé a ò lè fara dà á mọ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a óò jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù lè kọ́ wa nípa bá a ṣe lè lẹ́mìí ìfaradà. A óò tún jíròrò àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà fún àwọn mìíràn tó wà nínú ìṣòro lókun.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ọ̀ràn wo ni Sátánì dá sílẹ̀ nípa ìwà títọ́ Jóòbù?
• Tá a bá níṣòro, kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fara dà á?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣíṣe ìwádìí nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, fífi ọ̀rọ̀ lọ àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú, àti àdúrà gbígbà lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro