Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Borí Onírúurú Ìṣòro
GẸ́GẸ́ BÍ DALE IRWIN ṢE SỌ Ọ́
“ỌLỌ́MỌ MẸ́RIN TÚN BÍ ÌBẸRIN! ÌṢÒRO DI ÌLỌ́PO MÉJÌ.” Ohun tí wọ́n fi ṣe àkọlé ìwé ìròyìn kan tó sọ nípa àwọn ìbẹrin tá a bí tẹ̀ lé àwọn ọmọbìnrin wa mẹ́rin nìyẹn. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mi ò ní in lọ́kàn pé mo máa gbéyàwó, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tọmọ bíbí. Àmọ́, èmi ni mo wá di bàbá ọlọ́mọ mẹ́jọ yìí!
ỌDÚN 1934 ni wọ́n bí mi nílùú Mareeba, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Èmi ni àbíkẹ́yìn nínú àwa ọmọ mẹ́ta táwọn òbí mi bí. Nígbà tó yá, ìdílé wa kó lọ sílùú Brisbane, níbi tí màmá mi ti ń kọ́ àwọn ọmọdé nílé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi ní ìjọ Mẹ́tọ́díìsì.
Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1938, ìwé ìròyìn kan ládùúgbò sọ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n má fún Joseph F. Rutherford tó ń bọ̀ láti orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìwé àṣẹ láti wọ orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Màmá mi wá bi Ẹlẹ́rìí tó wá sílé wa lẹ́yìn ìgbà yẹn pé: “Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe irú nǹkan yìí sí Rutherford?” Ẹlẹ́rìí náà dáhùn pé: “Ṣé Jésù ò ti sọ pé àwọn èèyàn máa ṣenúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn òun ni?” Màmá mi wá gba ìwé kékeré kan tí wọ́n pè ní Cure [ojútùú], èyí tó sọ ọ̀pọ̀ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké.a Ohun tí màmá mi kà nínú ìwé kékeré yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, bó ṣe kó àwa ọmọ nìyẹn, tá a lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e. Bàbá mi kọ́kọ́ yarí pé òun ò ní gbà, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó máa ń kọ àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì fún màmá mi pé kó fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin níbẹ̀, kó sì gba ìdáhùn bọ̀. Arákùnrin náà yóò wá kọ àwọn ìdáhùn tó bá Ìwé Mímọ́ mu fún màmá mi pé kó fún bàbá mi.
Lọ́jọ́ Sunday kan, bàbá mi tẹ̀ lé wa lọ sípàdé. Ó fẹ́ wá sọ ìdí tóun ò fi fara mọ́ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Àmọ́, lẹ́yìn tóun àti alábòójútó arìnrìn-àjò tó ń bẹ ìjọ wa wò lákòókò yẹn sọ̀rọ̀ tán, bàbá mi yí ìṣesí rẹ̀ padà. Ó tiẹ̀ ní kí wọ́n wá máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nílé wa, àwọn olùfìfẹ́hàn tó wà lágbègbè yẹn sì ń wá.
Àwọn òbí mi ṣèrìbọmi lóṣù September, ọdún 1938. Èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi náà sì ṣèrìbọmi ní December ọdún 1941 nípàdé àgbègbè kan tá a ṣe ní Hargreave Park nílùú Sydney, ní ìpínlẹ̀ New South Wales. Ọmọ ọdún méje ni mí nígbà yẹn. Lẹ́yìn ìgbà náà, mo máa ń bá àwọn òbí mi jáde lọ wàásù déédéé. Láyé ìgbà yẹn, ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí máa ń gbé ẹ̀rọ agbóhùnjáde tó ṣeé gbé láti ilé dé ilé kiri, wọ́n á ṣí i kí onílé lè gbọ́ àwọn ìjíròrò Bíbélì tí wọ́n ti gbà sínú ẹ̀rọ náà.
Ẹlẹ́rìí kan tí mo rántí dáadáa pé ó máa ń ṣe èyí ni Bert Horton. Ó ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, ó sì so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ńlá kan tó lágbára mọ́ ọn lórí. Téèyàn bá bá arákùnrin Bert ṣiṣẹ́, èèyàn máa ń gbádùn rẹ̀ gan-an, pàápàá irú èmi tí mo jẹ́ ọmọ kékeré. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá ń polongo àsọyé Bíbélì kan láti orí òkè kan, a sábà máa ń rí ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n á máa bọ̀ lọ́dọ̀ wa. Ojú ẹsẹ̀ ni Bert máa ń pa ẹ̀rọ náà, tí yóò sì wakọ̀ rẹ̀ lọ síbi tó jìnnà gan-an sí àgbègbè yẹn, tá a sì tún fi àwo mìíràn sí i káwọn èèyàn lè gbọ́ ọ. Mo kọ́ ẹ̀kọ́ tó pọ̀ gan-an lọ́dọ̀ Bert àtàwọn arákùnrin mìíràn tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin àti onígboyà bíi tirẹ̀ pé ó yẹ kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó sì jẹ́ onígboyà.—Mátíù 10:16.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, èmi nìkan máa ń dá wàásù déédéé nígbà tá a bá jáde nílé ìwé. Ìgbà kan wà tí mo bá ìdílé kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Adshead sọ̀rọ̀. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn òbí méjèèjì àtàwọn ọmọ wọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ, àti ọ̀pọ̀ ọmọ ọmọ wọn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi tí mo jẹ́ ọmọ kékeré nígbà yẹn ló lò láti kọ́ ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run yìí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Mátíù 21:16.
Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tí Mo Ní
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, mo di aṣáájú ọ̀nà alákòókò-kíkún, wọ́n sì ní kí n lọ máa wàásù ní ìlú Maitland, ní ìpínlẹ̀ New South Wales. Lọ́dún 1956, wọ́n pè mí kí n wá sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ti Ọsirélíà, èyí tó wà nílùú Sydney. Nínú àwa ogún èèyàn tó ń sìn níbẹ̀, nǹkan bí ìdá mẹ́ta lára wa ló jẹ́ ẹni àmì òróró, tí wọ́n ní ìrètí bíbá Kristi jọba nínú Ìjọba rẹ̀ lọ́run. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀!—Lúùkù 12:32; Ìṣípayá 1:6; 5:10.
Nígbà tí mo rí Judy Helberg, kíá ni mo gbàgbé ìpinnu tí mo ṣe pé mi ò ní gbéyàwó. Aṣáájú ọ̀nà ni arábìnrin yìí, ó sì jojú ní gbèsè. Wọ́n pè é wá sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa pé kó wá ràn mí lọ́wọ́ fúngbà díẹ̀ lórí iṣẹ́ bàǹtàbanta kan tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́. Àwa méjèèjì nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an, a sì ṣègbéyàwó ní ọdún méjì lẹ́yìn náà. Lẹ́yìn ìyẹn, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká, èyí tó gba pé ká máa bẹ ìjọ kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ká sì máa fún àwọn ará níṣìírí.
Lọ́dún 1960, Judy bí àkọ́bí wa obìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kim. Lónìí, téèyàn bá ti bímọ, ńṣe ni wọ́n máa ń sọ pé kó fiṣẹ́ àyíká sílẹ̀ kó lè fìdí kalẹ̀ sójú kan. Àmọ́, ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n pè wá tí wọ́n ní ká máa bẹ àwọn ìjọ wò nìṣó. Lẹ́yìn tá a gbàdúrà gan-an lórí ọ̀rọ̀ náà, a fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ yìí. Láàárín oṣù méje tó tẹ̀ lé e, Kím bá wa rìnrìn àjò nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá kìlómítà nínú bọ́ọ̀sì, ọkọ̀ òfuurufú, àti ọkọ̀ ojú irin, bá a ṣe ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ìjọ tó jìnnà síra gan-an ní ìpínlẹ̀ Queensland àti ní ìpínlẹ̀ Northern Territory. A ò ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lákòókò yẹn.
Ilé àwọn ará la máa ń dé sí. Nítorí pé ooru máa ń mú gan-an, aṣọ ni wọ́n máa ń ta sẹ́nu ọ̀nà yàrá dípò ilẹ̀kùn láyé ìgbà yẹn, èyí sì máa ń jẹ́ kó ká wa lára gan-an nígbà tí Kim bá ń ké lóru. Nígbà tó yá, a wá rí i pé kò rọrùn rárá láti pa iṣẹ́ ọmọ títọ́ pọ̀ mọ́ iṣẹ́ àyíká. Bá a ṣe fìdí kalẹ̀ sílùú Brisbane nìyẹn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ bíbá àwọn èèyàn kọ nǹkan sára pátákó ìpolówó ọjà. Lẹ́yìn ọdún méjì tá a bí Kim, a tún bí ọmọbìnrin mìíràn tá a sọ ní Petina.
Bí Mo Ṣe Fara Da Ìbànújẹ́
Lọ́dún 1972, àrùn kan tí wọ́n ń pè ní Hodgkin ṣekú pa Judy nígbà tí ọmọbìnrin wa àgbà wà lọ́mọ ọdún méjìlá tí kékeré sì wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá. Ikú Judy yìí kó ìbànújẹ́ bá ìdílé wa gan-an. Àmọ́ ní gbogbo àkókò tí Judy fi ń ṣàìsàn àti lẹ́yìn ikú rẹ̀, Jèhófà tù wá nínú nípasẹ̀ Ọ̀rọ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àti ẹgbẹ́ ará. A tún rí okun gbà látinú Ilé Ìṣọ́ tó jáde kété lẹ́yìn àjálù náà. Ó ní àpilẹ̀kọ kan nínú tó sọ nípa béèyàn ṣe lè borí àwọn àdánwò, títí kan ohun téèyàn lè ṣe nígbà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹni. Ó sì jẹ́ ká mọ bí àdánwò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ tí kò ní jẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run bà jẹ́. Àwọn ànímọ́ náà ni ìfaradà, ìgbàgbọ́, àti ìwà títọ́.b—Jákọ́bù 1:2-4.
Lẹ́yìn ikú Judy, èmi àtàwọn ọmọ mi wá túbọ̀ sún mọ́ra gan-an. Àmọ́ kí n sòótọ́, kò rọrùn rárá láti pa iṣẹ́ ìyá pọ̀ mọ́ ti bàbá. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ mi obìnrin méjèèjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ tó wúlò gan-an mú kí iṣẹ́ náà rọrùn fún mi.
Mo Fẹ́ Ìyàwó Mìíràn, Mo sì Dẹni Tó Ní Ìdílé Ńlá
Nígbà tó yá, mo fẹ́ ìyàwó mìíràn. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà lọ̀rọ̀ èmi àti ìyàwó mi tuntun yìí fi jọra. Àrùn Hodgkin tó pa ìyàwó mi àkọ́kọ́ náà ló pa ọkọ tóun náà kọ́kọ́ fẹ́. Òun náà ní àwọn ọmọbìnrin méjì tórúkọ wọ́n ń jẹ́ Colleen àti Jennifer. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ni Petina ọmọ mi kejì fi ju Colleen lọ. Ìdílé mi wá ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin báyìí, ìkíní jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, èkejì ọmọ ọdún méjìlá, ẹ̀kẹta ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, ìkẹrin sì jẹ́ ọmọ ọdún méje.
Èmi àti Mary kọ́kọ́ pinnu pé kí oníkálùkù máa bá àwọn ọmọ tiẹ̀ wí, títí dìgbà tí yóò fi rọrùn fáwọn ọmọ náà láti gba ìbáwí látọ̀dọ̀ bàbá àti ìyá wọn tuntun. Ní ti àjọṣe àárín èmi àti Mary gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya, ìlànà méjì pàtàkì la gbé kalẹ̀ fún ara wa. Ọ̀kan ni pé a ò ní ní gbólóhùn asọ̀ lójú àwọn ọmọ wa láé, èkejì ni pé, gẹ́gẹ́ bí ìlànà Bíbélì tó wà nínú Éfésù 4:26, a ó máa sọ̀rọ̀ lórí èdèkòyédè àárín ara wa títí tá a fi máa yanjú rẹ̀, bó tiẹ̀ gba ọ̀pọ̀ wákàtí!
Kíá ni gbogbo wa mọwọ́ ara wa nínú ìdílé tuntun yìí, àmọ́ ìrònú nípa ikú àwọn olólùfẹ́ wa kò tètè kúrò lọ́kàn wa. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo alẹ́ ọjọ́ Monday ni Mary máa ń sunkún. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa, nígbà táwọn ọmọ bá lọ sùn, Mary kì í lè mú ọ̀ràn ọkọ rẹ̀ tó ti kú mọ́ra, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.
Mary fẹ́ ká ní ọmọ kan tó jẹ́ tàwa méjèèjì. Ó ṣeni láàánú pé oyún tó kọ́kọ́ ní bà jẹ́. Nígbà tí Mary tún padà lóyún, ohun tá ò retí rárá ló ṣẹlẹ̀. Ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń yẹ oyún wò fi hàn pé dípò ọmọ kan, ọmọ mẹ́rin ló wà níkùn Mary! Jìnnìjìnnì bò mí. Èmi tí mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta máa tó di bàbá ọlọ́mọ mẹ́jọ! Oṣù mẹ́jọ ni oyún náà nígbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún Mary láti bí àwọn ọmọ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù February, ọdún 1982. Clint tó jẹ́ ọkùnrin ló kọ́kọ́ bí, ó wọn ohun tó lé díẹ̀ ní kìlógíráàmù kan ààbọ̀, Cindy tó jẹ́ obìnrin ló bí ṣìkejì, ìyẹn wọn nǹkan bíi kìlógíráàmù méjì. Ó wá bí Jeremy tó jẹ ọkùnrin ṣèkẹta, ó wọn nǹkan bí kìlógíráàmù kan ààbọ̀, Danette tó jẹ́ obìnrin ló bí ṣìkẹrin, ìyẹn sì wọn ohun tó lé díẹ̀ ní kìlógíráàmù kan ààbọ̀. Àwọn ọmọ náà ò jọra rárá.
Kété tí Mary bímọ tán, dókítà rẹ̀ wá jókòó tì mí.
Ó bi mí pé: “Ṣé ẹ̀rù bó o ṣe máa tọ́jú àwọn ọmọ náà ń bà ọ́ ni?”
Mo ní: “Tóò, mi ò bára mi nírú ipò yìí rí.”
Ohun tó sọ tẹ̀ lé e yà mí lẹ́nu gan-an, ó sì gbé mi ró.
Ó ní: “Àwọn ará ìjọ ẹ ò ní já ẹ kulẹ̀. Kó o tó pe ẹnì kan, igba èèyàn á dá ọ lóhùn!”
A dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ dókítà tó mọṣẹ́ gan-an yìí àtàwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́. Ọmọ mẹ́rin tára wọn dá ṣáṣá la kó lọ sílé láti ilé ìwòsàn náà lẹ́yìn oṣù méjì tá a bí wọn.
Iṣẹ́ Títọ́ Àwọn Ìbẹrin
Kí nǹkan lè lọ létòlétò, èmi àti Mary ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ohun tá a ó máa ṣe lọ́sàn-án àti lóru. Àwọn ọmọbìnrin wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti bójú tó àwọn ọmọ náà. Ọ̀rọ̀ tí dókítà sọ yẹn sì já sóòótọ́, ká tó “pe ẹnì kan,” gbogbo ìjọ ti dìde ìrànwọ́. Ṣáájú ìgbà yẹn, Arákùnrin John MacArthur tá a ti jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ tipẹ́ ti ṣètò àwọn Ẹlẹ́rìí ti wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé pé kí wọ́n bá wa fẹ ilé wa sẹ́yìn kó lè tóbi sí i. Nígbà tá a kó àwọn ọmọ náà délé, ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin ló wá bá wa bójú tó wọn. Gbogbo inú rere tí wọ́n fi hàn yìí jẹ́ ká rí i pé lóòótọ́ ni ìfẹ́ wà láàárín àwọn Kristẹni.—1 Jòhánù 3:18.
Lọ́rọ̀ kan, “ọmọ àwọn ará ìjọ” làwọn ìbẹrin náà. Kódà títí dòní olónìí làwọn ìbẹrin náà ṣì ń ka gbogbo àwọn arákùnrin rere àtàwọn arábìnrin àtàtà tó dìde ìrànwọ́ nígbà yẹn sí mọ̀lẹ́bí wa. Mary ní tiẹ̀ jẹ́ aya àti ìyá rere tó bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ dáadáa. Ó fi àwọn ohun tó ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nínú ètò Ọlọ́run sílò gan-an. A mọ̀ pé kò síbòmíràn téèyàn ti lè rí ìmọ̀ràn tó dára jùyẹn lọ!—Sáàmù 1:2, 3; Mátíù 24:45.
Àwọn ìpàdé Kristẹni àti iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ apá pàtàkì nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ mẹ́rin tá a ń bójú tó kò jẹ́ kí èyí rọrùn fún wa. Ohun tó ràn wá lọ́wọ́ nígbà yẹn ni pé àwọn ìdílé tọkọtaya méjì kan máa ń wá sílé wa ká lè bá wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí mú kí nǹkan rọrùn fún wa díẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń rẹ Mary gan-an nígbà míì débi pé ó máa ń tòògbé nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń lọ lọ́wọ́, tí ọmọ kan á sì máa sùn lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yìí di arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí.
A Kọ́ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Kékeré
Kó tó di pé àwọn ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í rìn rárá ni èmi, Mary, àtàwọn ọmọ wa obìnrin tó dàgbà ti máa ń kó wọn lọ sóde ìwàásù. Nígbà tí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, èmi àti Mary máa ń mú wọn ní méjì méjì lọ sóde ìwàásù, èyí kò sì nira fún wa. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn gan-an la fi ń bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wa pẹ̀lú àwọn tára wọn yọ̀ mọ́ èèyàn. Lọ́jọ́ kan, mo bá ọkùnrin kan pàdé tó sọ pé ohun tí àmì ìràwọ̀ bá jẹ́ lọ́jọ́ tí wọ́n bí èèyàn ló máa pinnu irú ìwà tónítọ̀hún á máa hù. Mi ò bá a jiyàn rárá, àmọ́ mo bí i bóyá mo lè padà wá kó tó di ọ̀sán. Ó gbà pé kí n wá, mo wá kó àwọn ìbẹrin mi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ńṣe ló ń wò tìyanutìyanu bí mo ṣe ń tò wọ́n tẹ̀ léra gẹ́gẹ́ bá a ṣe bí wọ́n. A wá jọ sọ̀rọ̀ gan-an lẹ́yìn náà, kì í ṣe lórí bí wọn ò ṣe jọra wọn nìkan o, àmọ́ nípa bí ìṣe wọn tún ṣe yàtọ̀ síra pátápátá, ìyẹn ló wá járọ́ ohun tó sọ yẹn. Ó ní: “Kò tiẹ̀ yẹ kí n sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn létí ẹ rárá. Mo ni láti túbọ̀ ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà, àbí?”
Àtìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn làwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ò ti fẹ́ ká máa bá àwọn wí pa pọ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dára, ìdí nìyẹn tá a fi máa ń tọ́ oníkálukú wọn sọ́nà lọ́kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ìlànà kan náà ni gbogbo wọn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. Nígbà tí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ẹ̀rí ọkàn bá dìde nílé ìwé, wọn kì í yà kúrò lórí ìlànà Bíbélì rárá, ohun kan náà làwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin máa ń sọ, Cindy ló sì jẹ́ agbẹnusọ fún wọn. Kò pẹ́ táwọn èèyàn fi wá mọ̀ pé òṣùṣù ọwọ̀ làwọn ìbẹrin wọ̀nyí!
Iṣẹ́ ńlá tó máa ń já lé àwọn òbí léjìká nígbà táwọn ọmọ bá ń bàlágà já lé èmi àti Mary náà léjìká, ìyẹn ni ríran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Iṣẹ́ náà ì bá nira gan-an tí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ ìtìlẹ́yìn àwọn ará ìjọ wa tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àti ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ ètò Jèhófà. A sa gbogbo ipá wa láti rí i pé à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa déédéé, a sì máa ń bára wa sọ̀rọ̀ dáadáa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kì í sábà rọrùn. Síbẹ̀, ìsapá tá a ṣe yìí kò já sásán, nítorí pé gbogbo àwọn ọmọ wa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ló ń sin Jèhófà.
Bí Mo Ṣe Ń Bá Ìṣòro Ọjọ́ Ogbó Yí
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mo ti ní àwọn àǹfààní tó pọ̀ gan-an nínú ètò Jèhófà. Mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ, mò ń ṣe alábòójútó ìlú, mo tún ń ṣe adelé alábòójútó àyíká. Mo tún ti jẹ́ ọkàn lára àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn rí, ìyẹn àwọn tó ń ran àwọn dókítà lọ́wọ́ láti fara mọ́ ohun tí aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bá sọ nígbà tí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ gbígbà sára ṣẹlẹ̀. Odindi ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ló fi jẹ́ pé orúkọ mi ni wọ́n fi sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba pé kí n máa darí ètò ìgbéyàwó lábẹ́ òfin. Mo ti dárí ètò ìgbéyàwó bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́ta, títí kan táwọn ọmọbìnrin mi mẹ́fẹ̀ẹ̀fà.
Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí bí Judy, aya mi àkọ́kọ́ ṣe tì mí lẹ́yìn, tí Mary náà sì dúró tì mí gbágbáágbá títí di ìsinsìnyí. (Òwe 31:10, 30) Bí wọ́n ṣe ń tì mí lẹ́yìn nínú iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù, tí wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ káwọn ọmọ ní àwọn ànímọ́ tó bá ìlànà Ọlọ́run mu.
Lọ́dún 1996, àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fún mi fi hàn pé ibì kan nínú ọpọlọ mi ò ṣiṣẹ́ dáadáa, ìyẹn wá ń jẹ́ kí ọwọ́ mi máa gbọ̀n, mi ò sì lè dúró dáadáa. Nítorí bẹ́ẹ̀, mo fi iṣẹ́ kíkọ nǹkan sára pátákó ìpolówó ọjà tí mò ń ṣe sílẹ̀. Àmọ́, iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣì ń fún mi láyọ̀ gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Àǹfààní tí mo rí nínú àìsàn yìí ni pé, ó ti jẹ́ kí n túbọ̀ dẹni tó ń gba tàwọn arúgbó mìíràn rò gan-an.
Bí mo ṣe ń ronú nípa ìgbésí ayé mi, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń ran èmi àti ìdílé mi lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà, ìyẹn sì mú ká lè fayọ̀ borí onírúurú ìṣòro tá a ní. (Aísáyà 41:10) Èmi àti Mary àtàwọn ọmọ wa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tún dúpẹ́ gan-an fún àgbàyanu ìtìlẹ́yìn tá a rí látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú ìjọ. Gbogbo wọn ló fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa hàn lọ́nà tó pọ̀ kọjá ohun tá a lè fẹnu sọ.—Jòhánù 13:34, 35.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.
b Wo Ilé Ìṣọ́ March 15, 1973, ojú ìwé 170 sí 174.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Èmi, màmá mi, Garth ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àti Dawn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, nígbà tá a ń lọ sí ìpàdé àgbègbè tá a ṣe ní Sydney lọ́dún 1941
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Èmi pẹ̀lú Judy àti Kim tó jẹ́ ọmọ ọwọ́ nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ àyíká ní ìpínlẹ̀ Queensland
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Lẹ́yìn tá a bí àwọn ìbẹrin wa, àwọn ọmọbìnrin wa mẹ́rin tó ti dàgbà àti ìjọ dìde ìrànwọ́