Ṣé Àpẹẹrẹ Ààtò Ìwẹ̀nùmọ́ Àwọn Júù Ni Ìrìbọmi Jẹ́?
JÒHÁNÙ OLÙBATISÍ “wàásù ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà.” Jésù náà pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn kí wọ́n sì máa batisí wọn.—Máàkù 1:4; Mátíù 28:19.
Bíbélì fi hàn pé tí Kristẹni bá fẹ́ ṣèrìbọmi, wọ́n ní láti rì í sínú omi pátápátá. Ìwé náà Jesus and His World (Jésù Àtàwọn Èèyàn Ìgbà Ayé Rẹ̀) sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ní onírúurú orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ni wọ́n ti ń ṣe irú ààtò kan náà láyé àtijọ́ àti lóde òní.” Ìwé yìí wá fi kún un pé “àpẹẹrẹ àwọn ẹlẹ́sìn Júù làwọn Kristẹni tẹ̀ lé táwọn náà fi ń ṣèrìbọmi.” Ṣé òótọ́ ni?
Àwọn Ìkùdu Táwọn Júù Ti Ń Ṣe Ààtò Ìwẹ̀nùmọ́
Àwọn awalẹ̀pìtàn kan tó ń gbẹ́ ibì kan nítòsí àgbàlá Tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù walẹ̀ kan àwọn ìkùdu tí ó tó ọgọ́rùn-ún táwọn Júù ti ń wẹ̀ láti fi ṣe ààtò ìwẹ̀nùmọ́. Wọ́n sọ pé nǹkan bí ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni làwọn Júù lo àwọn ìkùdu yìí. Àkọlé kan tí wọ́n rí lára sínágọ́gù kan tí wọ́n lò láàárín ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Kristẹni fi hàn pé àwọn “àlejò tí wọ́n bá fẹ́ láti wẹ̀” ni wọ́n ṣe irú àwọn ìkùdu bẹ́ẹ̀ fún. Wọ́n tún rí àwọn ìkùdu kan láwọn àgbègbè kan tí ìdílé àwọn ọlọ́lá àtàwọn àlùfáà ń gbé láyé àtijọ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé ibẹ̀ ló ní ìkùdu tirẹ̀ tí wọ́n ti ń wẹ̀ láti fi ṣe ààtò ìwẹ̀nùmọ́.
Ńṣe ni wọ́n máa ń gbẹ́ ìkùdu yẹn gbọọrọ tí yóò sì ní igun mẹ́rin. Wọ́n lè gbẹ́ ẹ sínú àpáta tàbí kí wọ́n gbẹ́ ilẹ̀ lásán kí wọ́n wá fi bíríkì tàbí òkúta ṣe ògiri rẹ̀ nínú. Wọ́n á wá rẹ́ inú rẹ̀ kí omi rẹ̀ má bàa máa jò dà nù. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìkùdu yìí máa ń jìn tó nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà sí mẹ́sàn-án. Wọ́n sì máa ń ṣe ibi tí omi òjò yóò máa gbà ṣàn wá sínú ìkùdu yẹn. Omi inú rẹ̀ lè jìn tó ẹsẹ bàtà mẹ́rin kó lè bo gbogbo ara ẹni tó bá bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ sínú rẹ̀. Nígbà míì wọ́n máa ń fi ògiri kékeré kan pín ibi àtẹ̀gùn tí wọ́n máa ń bá wọ adágún omi náà sí méjì. Àwọn òpìtàn gbà pé ńṣe lẹni tó fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ máa ń gba ẹ̀gbẹ́ kan wọnú ìkùdu náà láti wẹ̀, yóò sì wá gba ẹ̀gbẹ́ kejì jáde tó bá wẹ̀ tán kó má bàa lọ fara kan ohun tó lè sọ ọ́ di aláìmọ́.
Ààtò ìwẹ̀nùmọ́ àwọn Júù ni wọ́n máa ń ṣe nínú ìkùdu wọ̀nyẹn. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń ṣe ààtò ọ̀hún?
Ohun Tí Òfin Mósè àti Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Sọ Nípa Ìwẹ̀ Wíwẹ̀
Òfin Mósè sọ pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ nínú ìjọsìn wọn kí wọ́n sì máa ṣe ìmọ́tótó ara. Onírúurú nǹkan ló lè mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìmọ́, èyí tó máa mú kó di dandan fún wọn láti wẹ̀ kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn kí wọ́n lè mọ́.—Léfítíkù 11:28; 14:1-9; 15:1-31; Diutarónómì 23:10, 11.
Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ẹni mímọ́ délẹ̀délẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Ó sọ fún àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n tó wá síbi pẹpẹ òun tí wọn ò bá fẹ́ kú.—Ẹ́kísódù 30:17-21.
Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà gbọ́ pé nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní, àwọn olórí ẹ̀sìn àwọn Júù ti sọ ìwẹ̀nùmọ́ táwọn àlùfáà máa ń ṣe di dandan fáwọn tí kì í ṣe ọmọ Léfì. Àwọn Farisí àtàwọn ẹgbẹ́ Essene máa ń tẹ̀ lé ààtò ìwẹ̀nùmọ́. Ohun tí ìwé kan tiẹ̀ sọ nípa ìgbà ayé Jésù ni pé: “Kí Júù kan tó lè wọ àgbàlà Tẹ́ńpìlì, kó tó lè rúbọ, kí àlúfàá tó lè bá a lọ́wọ́ sí ààtò ẹbọ kankan tàbí àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ tẹ̀ lé ààtò ìwẹ̀nùmọ́.” Ìwé Támọ́dì sì sọ pé ẹni tó bá ń tẹ̀ lé ààtò ìwẹ̀nùmọ́ gbọ́dọ̀ ri gbogbo ara rẹ̀ bọmi pátápátá.
Jésù sọ fáwọn Farisí pé kò tọ̀nà bí wọ́n ṣe sọ ìwẹ̀nùmọ́ di dandan fáwọn èèyàn. Ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ń ṣe “onírúurú ìbatisí,” títí kan ìbatisí “àwọn ife àti àwọn orù àti àwọn ohun èlò bàbà.” Jésù sọ pé ńṣe làwọn Farisí ń tẹ òfin Ọlọ́run lójú bí wọ́n ṣe sọ ọ́ di dandan fáwọn èèyàn láti máa tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọ́n fúnra wọn gbé kalẹ̀. (Hébérù 9:10; Máàkù 7:1-9; Léfítíkù 11:32, 33; Lúùkù 11:38-42) Kò síbì kankan nínú Òfin Mósè tó sọ pé káwọn èèyàn máa ri gbogbo ara wọn bọmi.
Ṣé àpẹẹrẹ ààtò ìwẹ̀nùmọ́ táwọn Júù ń ṣe làwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé ni táwọn náà fi ń ṣèrìbọmi? Rárá o!
Ìyàtọ̀ Tó Wà Nínú Ààtò Ìwẹ̀nùmọ́ Àwọn Júù àti Ìrìbọmi Àwọn Kristẹni
Ńṣe ni Júù tó bá ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ máa ń wẹ fúnra rẹ̀. Àmọ́ ìrìbọmi tí Jòhánù ń ṣe fáwọn èèyàn yàtọ̀ sí ààtò ìwẹ̀nùmọ́ táwọn Júù máa ń ṣe yìí. Pípè tí wọ́n ń pe Jòhánù ní Olùbatisí fi hàn pé ìrìbọmi tó ń ṣe yàtọ̀ sí ààtò tiwọn. Kódà àwọn aṣáájú ìsìn rán àwọn èèyàn lọ bi í pé: “Èé ṣe tí o . . . fi ń batisí?”—Jòhánù 1:25.
Ìwẹ̀nùmọ́ tí Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe jẹ́ èyí tí wọ́n ní láti máa ṣe ní gbogbo ìgbà tí ohunkóhun bá sọ wọ́n di aláìmọ́. Ṣùgbọ́n ìrìbọmi tí Jòhánù ń ṣe fáwọn èèyàn àti ìrìbọmi táwọn Kristẹni ń ṣe lẹ́yìn ìgbà tirẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni ìrìbọmi táwọn èèyàn ń ṣe nígbà ayé Jòhánù fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà, wọ́n sì ti kọ irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ sílẹ̀. Ìrìbọmi tàwa Kristẹni náà ń ṣe jẹ́ àmì pé ẹni tó ṣèrìbọmi ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo la máa ń ṣèrìbọmi ọ̀hún, a kì í ṣe é láṣetúnṣe.
Ààtò ìwẹ̀nùmọ́ tí wọ́n ń ṣe nílé àwọn àlùfáà àti láwọn ibi ìwẹ̀ gbogbo gbòò tó wà nítòsí àgbàlá Tẹ́ńpìlì kàn jọ ìrìbọmi àwa Kristẹni ni. Ìtumọ̀ nǹkan méjèèjì yàtọ̀ síra pátápátá. Ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì náà The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pé kì í ṣe ààtò ìrìbọmi táwọn èèyàn ìgbà ayé Jòhánù [Olùbatisí] ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ [ìyẹn tàwọn ẹlẹ́sìn Júù] ni Jòhánù tẹ̀ lé.” Bákan náà, ìrìbọmi tí ìjọ Kristẹni ń ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ààtò àwọn ẹlẹ́sìn Júù.
Ìrìbọmi táwọn Kristẹni ń ṣe dúró fún “ìbéèrè tí a ṣe sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún ẹ̀rí-ọkàn rere.” (1 Pétérù 3:21) Ó jẹ́ ẹ̀rí pé onítọ̀hún ti di ọmọlẹ́yìn Ọmọ Ọlọ́run àti pé ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà láti máa sìn ín. Rírì tí wọ́n ri onítọ̀hún bọmi pátápátá jẹ́ àmì tó bá a mu láti fi irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Omi tó bo onítọ̀hún pátápátá jẹ́ àpẹẹrẹ pé ẹni náà ti di òkú sí ìgbésí ayé tó ń gbé tẹ́lẹ̀. Gbígbé tí wọ́n sì gbé e jáde látinú omi jẹ́ àpẹẹrẹ pé a ti sọ ọ́ di ààyè láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Jèhófà Ọlọ́run máa ń fún àwọn tó bá ṣe irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi ní ẹ̀rí ọkàn rere. Ìyẹn ni àpọ́sítélì Pétérù tí Ọlọ́run mí sí fi lè sọ fún àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ pé: “[Ìbatisí] ń gbà yín là nísinsìnyí.” Bó ṣe wù kí ẹnì kan tẹ̀ lé ààtò ìwẹ̀nùmọ́ àwọn Júù tó ìyẹn ò lè mú kó ní ẹ̀rí ọkàn rere.