ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 11/1 ojú ìwé 27-31
  • Bá a Ṣe Lè Máa Fọ̀wọ̀ Hàn Fún Àwọn Àpéjọ Wa Tó Jẹ́ Mímọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá a Ṣe Lè Máa Fọ̀wọ̀ Hàn Fún Àwọn Àpéjọ Wa Tó Jẹ́ Mímọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọ Mímọ́ Làwọn Ìpàdé Wa Jẹ́
  • Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Àwọn Àpéjọ Wa
  • Ìwà Tó Yẹ Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
  • Ohun Kan Tí Kò Ní Yí Padà Nínú Ìjọsìn Wa
  • Mímọrírì Àwọn Ìpéjọpọ̀ Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń ṣamọ̀nà Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 11/1 ojú ìwé 27-31

Bá a Ṣe Lè Máa Fọ̀wọ̀ Hàn Fún Àwọn Àpéjọ Wa Tó Jẹ́ Mímọ́

“Dájúdájú, èmi yóò mú wọn wá sí òkè ńlá mímọ́ mi pẹ̀lú, èmi yóò sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi.”—AÍSÁYÀ 56:7.

1. Àwọn ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mú wo ló fi yẹ ká máa fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ìpàdé wa?

JÈHÓFÀ ti kó àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, láti máa jọ́sìn rẹ̀ ní “òkè ńlá mímọ́” rẹ̀. Ó ń mú kí wọ́n yọ̀ nínú “ilé àdúrà” rẹ̀, ìyẹn tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó jẹ́ “ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 56:7; Máàkù 11:17) Àwọn ohun tí Jèhófà ṣe yìí fi hàn pé ìjọsìn rẹ̀ jẹ́ mímọ́, ó mọ́ gaara, ó sì ta gbogbo ìjọsìn yòókù yọ. Bá a bá ń fọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ìpàdé níbi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ti ń jọ́sìn, ńṣe là ń fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ohun mímọ́ làwa náà fi ń wò ó.

2. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ka ibi tó yàn fún ìjọsìn rẹ̀ sí mímọ́, báwo sì ni Jésù ṣe fi hàn pé òun náà kà á sí mímọ́?

2 Ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ka ibi tí Jèhófà yàn pé kí wọ́n ti máa jọ́sìn òun sí mímọ́. Wọ́n ní láti fi òróró yan àgọ́ ìjọsìn àtàwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, títí kan àwọn ohun èlò inú rẹ̀, kí wọ́n sì yà wọ́n sí mímọ́, ‘kí wọ́n lè di mímọ́ jù lọ ní ti gidi.’ (Ẹ́kísódù 30:26-29) Yàrá méjì tí wọ́n pín ibùjọsìn náà sí ni wọ́n ń pè ní “Ibi Mímọ́” àti “Ibi Mímọ́ Jù Lọ.” (Hébérù 9:2, 3) Tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ló wá rọ́pò àgọ́ ìjọsìn náà nígbà tó yá. Níwọ̀n bí Jerúsálẹ́mù ti wá di ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn Jèhófà, wọ́n pè é ní “ìlú ńlá mímọ́.” (Nehemáyà 11:1; Mátíù 27:53) Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó fi ọ̀wọ̀ tó yẹ hàn fún tẹ́ńpìlì náà. Inú bí i gan-an sáwọn èèyàn kan nítorí wọ́n ń lo àgbàlá tẹ́ńpìlì náà lọ́nà tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn, wọ́n ń ṣòwò níbẹ̀, wọ́n sì ń gba ibẹ̀ kọjá lọ sápá ibòmíràn ní Jerúsálẹ́mù.—Máàkù 11:15, 16.

3. Àwọn ohun wo ló fi hàn pé àwọn àpéjọ tó wáyé ní Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́?

3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti jọ́sìn Jèhófà àti láti fetí sí àwọn tó ń ka Òfin rẹ̀. Wọ́n ń pe àwọn ọjọ́ kan lára àwọn ọjọ́ àjọyọ̀ wọn ní àpéjọ mímọ́, tàbí àpéjọ ọlọ́wọ̀, tó ń fi hàn pé àwọn àpéjọ wọ̀nyí jẹ́ mímọ́. (Léfítíkù 23:2, 3, 36, 37) Nígbà tí gbogbo wọ́n péjọ nígbà ayé Ẹ́sírà àti Nehemáyà, àwọn ọmọ Léfì “ń ṣàlàyé òfin fún àwọn ènìyàn.” Nítorí pé “gbogbo àwọn ènìyàn náà ń sunkún bí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin náà,” làwọn ọmọ Léfì bá bẹ̀rẹ̀ sí í “mú àwọn ènìyàn náà dákẹ́ pé: ‘Ẹ dákẹ́! nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ.’” Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà fún ọjọ́ méje, wọ́n sì “ní ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà.” Síwájú sí i, “kíka ìwé òfin Ọlọ́run tòótọ́ sókè sì wà láti ọjọ́ dé ọjọ́, láti ọjọ́ kìíní títí di ọjọ́ tí ó kẹ́yìn; wọ́n sì ń ṣe àjọyọ̀ fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ, àpéjọ tí ó ní ọ̀wọ̀ sì wà, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àfilélẹ̀.” (Nehemáyà 8:7-11, 17, 18) Àpéjọ mímọ́ làwọn àpéjọ wọ̀nyí jẹ́ lóòótọ́, nítorí náà, àwọn tó wá síbẹ̀ gbọ́dọ̀ fetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

Àpéjọ Mímọ́ Làwọn Ìpàdé Wa Jẹ́

4, 5. Kí làwọn ohun tá a máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa tó mú kí wọ́n jẹ́ àpéjọ mímọ́?

4 Lóòótọ́, Jèhófà kò ní ìlú mímọ́ kan lónìí lórí ilẹ̀ ayé tó ní tẹ́ńpìlì àkànṣe tá a yà sí mímọ́ fún ìjọsìn rẹ̀. Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé àpéjọ mímọ́ ni àwọn ìpàdé tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà. À ń pàdé pọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ láti ka Ìwé Mímọ́ àti láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. À “ń làdí” Ọ̀rọ̀ Jèhófà, a sì “ń fi ìtumọ̀ sí i” bíi ti ọjọ́ Nehemáyà. (Nehemáyà 8:8) Àdúrà la fi ń bẹ̀rẹ̀ gbogbo ìpàdé wa, a sì ń fi àdúrà parí wọn. A tún máa ń kọrin ìyìn sí Jèhófà léyìí tó pọ̀ jù lára àwọn ìpàdé náà. (Sáàmù 26:12) Ó yẹ ká ní ẹ̀mí ìfọkànsìn ká sì máa fetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láwọn ìpàdé, nítorí àwọn ìpàdé náà jẹ́ ara ìjọsìn wa.

5 Jèhófà máa ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ bí wọ́n ti ń péjọ láti jọ́sìn rẹ̀, tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ní ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin. Nígbà tó bá tó àkókò láti lọ sí ìpàdé, ó yẹ kó dá wa lójú pé ibẹ̀ ni ‘Jèhófà pàṣẹ pé kí ìbùkún wà.’ (Sáàmù 133:1, 3) Àwa náà yóò gbà lára ìbùkún yẹn tá a bá wá síbẹ̀ tá a sì ń fọkàn bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí náà lọ. Ní àfikún sí èyí, Jésù sọ pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọpọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.” Ọ̀rọ̀ tó yí gbólóhùn yìí ká fi hàn pé àwọn Kristẹni alàgbà tí wọ́n pàdé láti bójú tó ìṣòro àárín èèyàn méjì ni ibi yìí ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, àmọ́ a tún lè lo ìlànà tó wà níbẹ̀ fáwọn ìpàdé wa. (Mátíù 18:20) Bí Kristi bá tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ wà níbi táwọn Kristẹni ti péjọ pọ̀ ní orúkọ rẹ̀, ǹjẹ́ kò yẹ́ kí á ka irú àpéjọ bẹ́ẹ̀ sí ohun mímọ́?

6. Kí la lè sọ pé àwọn ibi ìpàdé wa jẹ́, yálà wọ́n tóbi tàbí wọ́n kéré?

6 Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í gbénú tẹ́ńpìlì táwọn èèyàn fi ọwọ́ kọ́. Síbẹ̀, ibi ìjọsìn tòótọ́ làwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa jẹ́. (Ìṣe 7:48; 17:24) À ń pàdé níbẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà, láti gbàdúrà sí i, ká sì kọrin ìyìn sí i. Ohun kan náà là ń ṣe láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa. Àwọn ibi àpéjọ ńláńlá, irú bíi gbọ̀ngàn àfihàn àtàwọn pápá ìṣiré tá a háyà láti máa fi ṣe àwọn àpéjọ wa jẹ́ ibi ìjọsìn lákòókò tá a bá ń lò wọ́n fún àwọn àpéjọ wa mímọ́. Ó yẹ ká máa fọ̀wọ̀ hàn nírú àwọn àkókò ìjọsìn bẹ́ẹ̀, yálà àwọn àpéjọ náà kéré tàbí wọ́n tóbi, kí èyí sì máa hàn nínú ìṣesí wa.

Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Àwọn Àpéjọ Wa

7. Ọ̀nà tó ṣe kedere wo la lè gbà fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn àpéjọ wa?

7 Àwọn ọ̀nà tó ṣe kedere wà tá a lè gbà fọ̀wọ̀ hàn fún àwọn àpéjọ wa. Ọ̀nà kan ni láti wà níbẹ̀ nígbà tá a bá ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ lára àwọn orin náà jẹ́ àdúrà ó sì yẹ ká kọ wọ́n tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Sáàmù 22, ó sọ́ nípa Jésù pé: “Ṣe ni èmi yóò máa polongo orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; ṣe ni èmi yóò máa fi orin yìn ọ́ ní àárín ìjọ.” (Hébérù 2:12) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ sọ ọ́ dàṣà láti máa jókòó kí alága tó pe orin tá a máa kọ, bá a sì ṣe ń kọrin náà, ká máa fọkàn bá ìtumọ̀ rẹ̀ lọ. Ẹ jẹ́ kí orin tá à ń kọ máa gbé èrò onísáàmù yọ, tó sọ pé: “Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé Jèhófà lárugẹ nínú àwùjọ tímọ́tímọ́ ti àwọn adúróṣánṣán àti ti àpéjọ.” (Sáàmù 111:1) Dájúdájú, kíkọrin ìyìn sí Jèhófà jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tó dára gan-an tó fi yẹ ká tètè máa dé sípàdé ká sì wà níbẹ̀ títí dìgbà tó fi máa parí.

8. Àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló yẹ ká máa fọkàn sí àwọn àdúrà tá à ń gbà láwọn ìpàdé wa?

8 Ohun mìíràn tó tún ń mú kí àwọn ìpàdé wa túbọ̀ lárinrin nípa tẹ̀mí ni àdúrà àtọkànwá tá à ń gbà nítorí gbogbo àwa tá a péjọ síbẹ̀. Nígbà kan, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Jerúsálẹ́mù pàdé pọ̀ wọ́n sì gbàdúrà àtọkànwá nípa gbígbé “ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.” Èyí mú kí wọ́n máa bá iṣẹ́ wọn lọ láìka inúnibíni sí, wọ́n sì “ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣe 4:24-31) Ǹjẹ́ a lérò pé àwọn tí wọ́n péjọ yìí yóò jẹ́ kí ọkàn àwọn pínyà nígbà tí àdúrà yẹn ń lọ lọ́wọ́? Rárá o, wọ́n gbàdúrà pẹ̀lú “ìfìmọ̀ṣọ̀kan.” Àdúrà tá à ń gbà láwọn ìpàdé wa máa ń fi ohun tó ń jẹ gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́kàn hàn. A gbọ́dọ̀ fọkàn sí àwọn àdúrà náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

9. Báwo ni aṣọ wa àti ìṣesí wa ṣe lè fi hàn pé à ń fọ̀wọ̀ hàn fún àwọn àpéjọ mímọ́?

9 Síwájú sí i, ọ̀nà tá à ń gbà múra tún lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí ọ̀wọ̀ tá a ní fún àwọn àpéjọ wa mímọ́ ti jinlẹ̀ tó. Ọ̀nà tá a gbà wọṣọ àti bá a ṣe ṣe irun wa túbọ̀ máa ń fi kún iyì àwọn ìpàdé wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé ní ibi gbogbo, kí àwọn ọkùnrin máa bá a lọ ní gbígbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè, láìsí ìrunú àti ọ̀rọ̀ fífà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tímótì 2:8-10) Nígbà tá a bá lọ sáwọn àpéjọ ńláńlá tá à ń ṣe láwọn gbọ̀ngàn ńlá tí kò ní òrùlé, a lè wọṣọ tó bá bí ojú ọjọ́ ṣe rí mu, síbẹ̀ kí ìmúra wa ṣì bójú mu. Síwájú sí i, ọ̀wọ̀ tá a ní fún àwọn àpéjọ wọ̀nyí yóò mú ká yàgò fún jíjẹ ṣingọ́ọ̀mù nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ń lọ lọ́wọ́. Aṣọ àti ìwà tó bójú mu ní àwọn àpéjọ wa máa ń bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run, ó ń bọlá fún ìjọsìn rẹ̀ àti fún àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọ́sìn.

Ìwà Tó Yẹ Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

10. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé ìwà tó dára gan-an la ní láti máa hù láwọn ìpàdé ìjọ?

10 Ní Kọ́ríńtì kìíní, orí kẹrìnlá, a rí ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni lórí bí wọ́n á ṣe máa ṣe àwọn ìpàdé ìjọ. Ohun tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Àwọn ìpàdé wa jẹ́ apá pàtàkì lára ìgbòkègbodò tó ń wáyé nínú ìjọ Kristẹni, ìwà tó sì yẹ àwọn èèyàn Jèhófà ló yẹ ká máa hù níbẹ̀.

11, 12. (a) Kí ló yẹ ká jẹ́ káwọn ọmọ wa tó ń wá sípàdé mọ̀? (b) Ọ̀nà tó dára wo làwọn ọmọ lè gbà máa fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ hàn láwọn ìpàdé wa?

11 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká kọ́ àwọn ọmọ wa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà láwọn ìpàdé wa. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí ní láti ṣàlàyé fáwọn ọmọ wọn pé Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ibi tá a ti ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kì í ṣe ibi eré. Ibi tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́. Sólómọ́nì Ọba ọlọ́gbọ́n náà sọ pé: “Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá ń lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́; kí sísúnmọ́ tòsí láti gbọ́ sì wà.” (Oníwàásù 5:1) Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítọ̀ọ́ni láti máa kóra jọ, àwọn àgbà àti “àwọn ọmọ kéékèèké.” Ó sọ pé: “Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀ . . . kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́, bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ṣe. Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ sì fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà.”—Diutarónómì 31:12, 13.

12 Bákan náà lónìí, àwọn ọmọ wa ń bá àwọn òbí wọn wá sáwọn ìpàdé láti fetí sílẹ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́. Bí wọ́n bá ti lè máa fọkàn bá ọ̀rọ̀ lọ tí wọ́n sì lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì, àwọn ọmọ náà lè máa “polongo” ìgbàgbọ́ wọn “ní gbangba” nípa kíkópa nínú dídáhùn àwọn ìbéèrè tó bá jẹ yọ. (Róòmù 10:10) Ọmọ kékeré kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn nípa sísọ gbólóhùn ṣókí láti fi dáhùn ìbéèrè kan tó lóye rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni yóò máa ka àwọn ìdáhùn náà, àmọ́ nígbà tó bá yá, yóò gbìyànjú láti máa sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Èyí yóò ṣe ọmọ náà láǹfààní yóò sì múnú rẹ̀ dùn. Irú ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ tó ń wá látọkàn ọmọ náà tún máa ń múnú àwọn àgbà tó wà níbẹ̀ dùn. Àwọn òbí fúnra wọn ló yẹ kí wọ́n fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ láti rí i pé àwọn fúnra wọn ń dáhùn ìbéèrè. Tó bá ṣeé ṣe, ó dára káwọn ọmọ ní Bíbélì àti ìwé orin tiwọn, kí wọ́n sì ní ẹ̀dà ìwé tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ìwé náà játijàti. Gbogbo ìwọ̀nyí yóò jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ̀ pé àwọn ìpàdé wa jẹ́ àpéjọ mímọ́.

13. Kí la retí pé káwọn tó wá sípàdé wa fún ìgbà àkọ́kọ́ sọ?

13 Ó dájú pé a kò ní fẹ́ káwọn ìpàdé wa dà bí àwọn ìsìn inú ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ pé wọ́n kì í tani jí tàbí tí wọ́n máa ń dá lórí òdodo àṣehàn. Bẹ́ẹ̀ la ò ní fẹ́ kí wọ́n jẹ́ ibi tá a ti ń pariwo gèè bíi ti ilé ijó. Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ní láti fani mọ́ra kó sì tuni lára, àmọ́ a ò ní jẹ́ kó dà bíi pé ibi ìṣiré ni. Nítorí ká lè jọ́sìn Jèhófà la ṣe ń pàdé níbẹ̀, nítorí náà a gbọ́dọ̀ máa fọ̀wọ̀ hàn fáwọn ìpàdé wa. Ohun tá a fẹ́ ni pé káwọn tó wá sípàdé wa fún ìgbà àkọ́kọ́, tí wọ́n gbọ́ àwọn ẹ̀kọ́ wa, tí wọ́n sì kíyè sí ìwà wa àti tàwọn ọmọ wa, sọ pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.”—1 Kọ́ríńtì 14:25.

Ohun Kan Tí Kò Ní Yí Padà Nínú Ìjọsìn Wa

14, 15. (a) Báwo la ṣe lè yẹra fún ‘ṣíṣàìnáání ilé Ọlọ́run wa’? (b) Báwo ni Aísáyà 66:23 ṣe ń ní ìmúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́?

14 Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ ṣáájú, Jèhófà ń kó àwọn èèyàn rẹ̀ jọ ó sì ń mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú “ilé àdúrà” rẹ̀, ìyẹn tẹ́ńpìlì rẹ̀ tẹ̀mí. (Aísáyà 56:7) Nehemáyà olóòótọ́ rán àwọn Júù ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ létí pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀wọ̀ hàn fún tẹ́ńpìlì nípa mímú ọrẹ wá. Ó sọ pé: “A kò sì gbọ́dọ̀ ṣàìnáání ilé Ọlọ́run wa.” (Nehemáyà 10:39) Síwájú sí i, a kò gbọ́dọ̀ ṣàìnáání pípè tí Jèhófà pè wá láti wá jọ́sìn òun nínú “ilé àdúrà” rẹ̀.

15 Nígbà tí Aísáyà ń sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa pàdé déédéé láti jọ́sìn Ọlọ́run, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “‘Dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì, gbogbo ẹran ara yóò wọlé wá tẹrí ba níwájú mi,’ ni Jèhófà wí.” (Aísáyà 66:23) Èyí ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ làwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti jọ́sìn Jèhófà. Lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti lílọ sí òde ìwàásù wà lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe. Ǹjẹ́ o wà lára àwọn tó ń ‘wọlé wá tẹrí ba níwájú Jèhófà’ déédéé?

16. Kí nìdí tí lílọ sípàdé déédéé fi jẹ́ ohun tó yẹ kó mọ́ wa lára nísinsìnyí?

16 Ìwé Aísáyà 66:23 yóò ṣẹ ní kíkún nínú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí. Lákòókò yẹn, ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àti lóṣooṣù, “gbogbo ẹran ara,” ìyẹn gbogbo èèyàn, yóò “wọlé wá tẹrí ba níwájú” Jèhófà, ìyẹn ni pé wọn yóò máa jọ́sìn Jèhófà, èyí á sì jẹ́ títí ayérayé. Níwọ̀n bí pípàdé pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà yóò ti jẹ́ ohun tá a óò máa ṣe títí lọ nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run nínú ètò tuntun, ǹjẹ́ kò yẹ ká sọ lílọ sáwọn àpéjọ wa mímọ́ déédéé di ohun tó mọ́ wa lára nísinsìnyí?

17. Kí nìdí tá a fi nílò àwọn ìpàdé wa “pàápàá jù lọ bí [a] ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé”?

17 Bí òpin ti ń sún mọ́lé, ó yẹ ká túbọ̀ pinnu ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé a óò máa lọ sáwọn àpéjọ Kristẹni láti jọ́sìn. Nítorí pé àwọn ìpàdé wa jẹ́ mímọ́, a ò ní jẹ́ kí iṣẹ́ wa, iléèwé ìrọ̀lẹ́, tàbí iṣẹ́ iléèwé àṣetiléwá, dí wa lọ́wọ́ pípéjọ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. A nílò okun tá à ń rí gbà nígbà tá a bá péjọ pọ̀. Àwọn ìpàdé ìjọ ń fún wa láǹfààní láti mọ ara wa, láti fún ara wa níṣìírí àti láti ru ara wa sókè sí “ìfẹ́ àti iṣẹ́ àtàtà.” A nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí “pàápàá jù lọ bí [a] ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀wọ̀ tó yẹ hàn fún àwọn àpéjọ mímọ́ nípa lílọ síbẹ̀ déédéé, nípa wíwọ aṣọ tó bójú mu àti nípa híhùwà tó yẹ. Tá a bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, à ń fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ohun mímọ́ làwa náà fi ń wò wọ́n.

Àtúnyẹ̀wò

• Kí nìdí tó fi yẹ ká ka àpéjọ àwọn èèyàn Jèhófà sí mímọ́?

• Kí làwọn ohun tá a máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa tó mú kí wọ́n jẹ́ àpéjọ mímọ́?

• Ọ̀nà wo làwọn ọmọ wa lè gbà fi hàn pé wọ́n ka àwọn ìpàdé wa sí ohun mímọ́?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí wíwá sípàdé déédéé jẹ́ ohun tó mọ́ wa lára nísinsìnyí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ibikíbi yòówù ká ti máa ṣe àwọn ìpàdé wa láti jọ́sìn Jèhófà, àpéjọ mímọ́ ni wọ́n jẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìdí táwọn ọmọ wa fi ń lọ sáwọn ìpàdé ni pé kí wọ́n lè fetí sílẹ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́