Bá A Ṣe Lè Dá Aṣòdì-sí-Kristi Mọ̀
TÓ O bá gbọ́ pé àìsàn kan tó lè gbẹ̀mí èèyàn ti dé ságbègbè rẹ, kí ni wàá ṣe láti dáàbò bo ara rẹ? Kò sí àní-àní pé gbogbo ohun tó o bá lè ṣe ni wàá ṣe kí àrùn náà má ba kọ lù ọ́, wàá sì tún yẹra pátápátá fáwọn tó lè kó àrùn náà ràn ọ́. Ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe náà nìyẹn tó bá kan ọ̀ràn ìjọsìn ẹni sí Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé aṣòdì-sí-Kristi “ti wà ní ayé” báyìí. (1 Jòhánù 4:3) Tá ò bá fẹ́ kó sí i lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ dá a mọ̀. A dúpẹ́ pé Bíbélì là wá lóye gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Ìtumọ̀ “aṣòdì-sí-Kristi” ni ẹni tó lòdì sí Kristi. Nítorí náà, tá a bá ń sọ ibi tí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí gbòòrò dé, gbogbo àwọn tó lòdì sí Kristi tàbí tí wọ́n ń purọ́ pé Kristi tàbí aṣojú rẹ̀ làwọn, ni ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì kó jọ pẹ̀lú mi ń tú ká.”—Lúùkù 11:23.
A mọ̀ pé nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú, tó jíǹde, tó sì ti lọ sọ́run ni Jòhánù kọ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa aṣòdì-sí-Kristi. Nítorí náà, ohun tó máa jẹ́ ká mọ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn aṣòdì-sí-Kristi ni bí wọ́n ṣe ń ṣe sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 25:40, 45.
Aṣòdì-sí-Kristi Ni Ẹni Tó Ń Gbógun Ti Àwọn Kristẹni
Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, aráyé á kórìíra wọn. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké yóò sì dìde, wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà.”—Mátíù 24:9, 11.
Nítorí pé “ní tìtorí orúkọ [Jésù]” ni wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, dájúdájú aṣòdì-sí-Kristi làwọn tó ń ṣenúnibíni sí wọn. Bákan náà, àwọn “wòlíì èké,” táwọn kan lára wọn jẹ́ Kristẹni nígbà kan rí, wà lára àwọn tó jẹ́ aṣòdì-sí-Kristi. (2 Jòhánù 7) Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ [àwọn] aṣòdì sí Kristi” yìí “jáde lọ láti ọ̀dọ̀ wa, ṣùgbọ́n wọn kò sí ní ìsọ̀wọ́ wa; nítorí ká ní wọ́n wà ní ìsọ̀wọ́ wa ni, wọn ì bá dúró pẹ̀lú wa.”—1 Jòhánù 2:18, 19.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù àti Jòhánù sọ jẹ́ ká rí i kedere pé aṣòdì-sí-Kristi kì í ṣe ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo, àmọ́ wọ́n pọ̀, wọ́n sì wà lóríṣiríṣi. Yàtọ̀ síyẹn, nítorí pé wòlíì èké ni wọ́n, olórí ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni kí wọ́n máa fi ẹ̀sìn tan àwọn èèyàn jẹ. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe é?
Wọ́n Máa Ń Tan Ẹ̀kọ́ Èké Kálẹ̀
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù pé kó ṣọ́ra fún ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì, tó jẹ́ pé “bí egbò kíkẹ̀” ni ‘ọ̀rọ̀ wọn yóò ṣe tàn kálẹ̀.’ Pọ́ọ̀lù fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí pàápàá ti yapa kúrò nínú òtítọ́, wọ́n ń sọ pé àjíǹde ti ṣẹlẹ̀ ná; wọ́n sì ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé.” (2 Tímótì 2:16-18) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì ń kọ́ àwọn èèyàn ni pé àjíǹde kì í ṣe kéèyàn jí dìde ní ti gidi, pé Ọlọ́run ti jí àwọn Kristẹni dìde nípa tẹ̀mí. Òótọ́ ni pé, dídi ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi máa ń sọ èèyàn dẹni tó wà láàyè ní ti gidi lójú Ọlọ́run, Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ sì sọ bẹ́ẹ̀. (Éfésù 2:1-5) Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì ta ko ìlérí Jésù pé àjíǹde òkú yóò ṣẹlẹ̀ ní ti gidi nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso.—Jòhánù 5:28, 29.
Bí àkókò ti ń lọ, àwọn kan tí wọ́n ń pè ní ẹlẹ́sìn Gnostic tún ní irú èrò yìí kan náà, wọ́n ní àpẹẹrẹ pọ́ńbélé ni àjíǹde jẹ́. Nítorí pé àwọn ẹlẹ́sìn yìí gbà pé èèyàn lè ní ìmọ̀ nípasẹ̀ agbára àràmàǹdà, wọ́n pa ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni tó ti di apẹ̀yìndà pọ̀ mọ́ èrò àwọn Gíríìkì àti ẹ̀kọ́ fífi-òye-mọ-Ọlọ́run tó wọ́pọ̀ lápá Ìlà Oòrùn ayé. Bí àpẹẹrẹ, ìgbàgbọ́ wọn ni pé gbogbo ohun tó bá ti ṣeé fojú rí ló jẹ́ ibi, pé fún ìdí yìí, Jésù kò wá nínú ẹran ara, ńṣe ló kàn dà bíi pé ó ní ara èèyàn. Ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sì sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn.—1 Jòhánù 4:2, 3; 2 Jòhánù 7.
Ẹ̀kọ́ èké mìíràn tí wọ́n tún gbé kalẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n pè ní Mẹ́talọ́kan mímọ́, èyí tó sọ pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè, òun náà sì tún ni Ọmọ Ọlọ́run. Nínú ìwé kan tí Ọ̀mọ̀wé Alvan Lamson kọ, tó pè ní The Church of the First Three Centuries, ó sọ pé “àtinú ẹ̀sìn tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ àwọn Júù àti (Ìwé Mímọ́) tàwọn Kristẹni ni [ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan] ti wá; ẹ̀kọ́ náà gbèrú, àwọn Alátìlẹyìn Ẹ̀kọ́ Plato sì mú un wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.” Àwọn wo làwọn “Alátìlẹyìn Ẹ̀kọ́ Plato” yìí? Àwọn àlùfáà tó jẹ́ apẹ̀yìndà ni, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ẹ̀kọ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí tó sì tún jẹ́ abọ̀rìṣà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Plato.
Mímú tí wọ́n mú ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan wọnú ẹ̀sìn Kristẹni lóhun tó burú jù lọ táwọn apẹ̀yìndà ṣe, torí ńṣe ni ẹ̀kọ́ yìí mú kí Ọlọ́run dà bí ẹni ti kò ṣeé lóye, tí kò sì jẹ́ kéèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín òun àti Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 14:28; 15:10; Kólósè 1:15) Ìwọ náà rò ó wò ná, báwo lèèyàn ṣe máa lè “sún mọ́ Ọlọ́run” gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti rọ̀ wá pé ká ṣe, tó bá jẹ́ pé ẹni téèyàn ò lè lóye ni?—Jákọ́bù 4:8.
Ohun tó tún wá dá kún ìdàrúdàpọ̀ yìí ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ti yọ Jèhófà tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run, kúrò nínú àwọn Bíbélì wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje ìgbà tí orúkọ yìí fara hàn nínú Bíbélì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀! Dájúdájú, bí wọ́n ṣe sọ Ọlọ́run Olódùmarè di ẹni àdììtú téèyàn ò lè lóye, tí wọ́n tiẹ̀ tún wá sọ pé ẹni àdììtú yìí kò lórúkọ, jẹ́ ìwà àfojúdi ńlá gbáà sí Ẹlẹ́dàá wa, kò sì fọ̀wọ̀ hàn rárá fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. (Ìṣípayá 22:18, 19) Ìyẹn nìkan kọ́, fífi àwọn ọ̀rọ̀ bí Olúwa tàbí Ọlọ́run rọ́pò orúkọ rẹ̀, lòdì pátápátá sí àdúrà tí Jésù kọ́ wa, èyí tó sọ lápá kan pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Mátíù 6:9.
Àwọn Aṣòdì-sí-Kristi Kò Fára Mọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Ibi gbogbo làwọn aṣòdì-sí-Kristi wà báyìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2 Tímótì 3:1) Olóri ohun tó sì wà lọ́kàn àwọn ẹlẹ́tàn ọjọ́ òní yìí ni láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà kí wọ́n má bàa mọ ipa tí Jésù ń kó gẹ́gẹ́ bí Ọba ti Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé láìpẹ́.—Dáníẹ́lì 7:13, 14; Ìṣípayá 11:15.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn olórí ẹ̀sìn kan ń wàásù pé inú ọkàn èèyàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà, ẹ̀kọ́ yìí kò sì sí nínú Ìwé Mímọ́ rárá. (Dáníẹ́lì 2:44) Àwọn mìíràn sì ń sọ pé Kristi ń lo àwọn ìjọba èèyàn àtàwọn ètò tí ẹ̀dá èèyàn gbé kalẹ̀. Síbẹ̀, ohun tí Jésù sọ ni pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Ká sòótọ́, Sátánì ni “olùṣàkóso ayé” àti “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” kì í ṣe Kristi. (Jòhánù 14:30; 2 Kọ́ríńtì 4:4) Ìdí sì nìyí tí Jésù fi máa mú gbogbo ìjọba èèyàn kúrò láìpẹ́ táá sì wá di Alákòóso kan ṣoṣo lórí gbogbo ayé. (Sáàmù 2:2, 6-9; Ìṣípayá 19:11-21) Ohun táwọn èèyàn sì ń gbàdúrà pé kó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyí nígbà tí wọ́n bá ń ka àdúrà Olúwa, pé: ‘Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.’—Mátíù 6:10.
Nítorí pé àwọn olórí ìsìn ń ṣètìlẹ́yìn fún ètò ìṣèlú ayé, ọ̀pọ̀ wọn ló ń ta ko àwọn tó ń wàásù ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, kódà wọ́n tún ń ṣenúnibíni sí wọn. Abájọ tí ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì fi sọ nípa “Bábílónì Ńlá” tó pè ní aṣẹ́wó, àti pé aṣẹ́wó yìí “ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Jésù ní àmupara.” (Ìṣípayá 17:4-6) Aṣẹ́wó yìí tún ń ṣàgbèrè, nípa títí “àwọn ọba” ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn alákòóso ìṣèlú lẹ́yìn, ó sì ń tipa báyìí rí ojú rere wọn. Aṣẹ́wó yìí kì í ṣe ẹlòmíràn o bí kò ṣe àwọn ìsìn èké ayé yìí. Apá pàtàkì ló sì jẹ́ lára aṣòdì-sí-Kristi.—Ìṣípayá 18:2, 3; Jákọ́bù 4:4.
Aṣòdì-sí-Kristi ‘Ń Rin Àwọn Èèyàn Létí’
Yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ti kẹ̀yìn sí ẹ̀kọ́ inú Bíbélì, wọn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Bíbélì gbé kalẹ̀ nípa irú ìwà tó yẹ kí Kristẹni máa hù, ohun tó gbòde kan ni wọ́n ń ṣe. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú nǹkan báyìí yóò ṣẹlẹ̀, ó ní: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn [àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run] kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí.” (2 Tímótì 4:3) Bíbélì tún pe àwọn olùkọ́ èké yìí ní “èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa ara wọn dà di àpọ́sítélì Kristi.” Bíbélì tún sọ pé: “Òpin wọn dájúdájú yóò rí bí iṣẹ́ wọn.”—2 Kọ́ríńtì 11:13-15.
Lára àwọn iṣẹ́ wọn ni “ìwà àìníjàánu,” ìyẹn sì yàtọ̀ pátápátá sí ìwà rere tó yẹ kéèyàn máa hù. (2 Pétérù 2:1-3, 12-14) Ǹjẹ́ a ò rí i pé ńṣe làwọn olórí ìsìn àtàwọn ọmọlẹ́yìn wọn tí wọ́n ń hu àwọn ìwà tí kò bá ẹ̀sìn Kristẹni mu, tàbí ó kéré tán tí wọ́n fàyè gbà á, túbọ̀ ń pọ̀ sí i? Lára àwọn ìwà yìí ni ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ ẹni tàbí aya ẹni. Jọ̀wọ́, fara balẹ̀ wò ó bóyá èrò tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní yìí, àti irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé, bá ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí sọ mu. Àwọn ẹsẹ Bíbélì náà ni: Léfítíkù 18:22; Róòmù 1:26, 27; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Hébérù 13:4; Júúdà 7.
“Ẹ Dán Àwọn Àgbéjáde Onímìísí Wò”
Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti sọ yìí, ó yẹ ká ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ, pé ká má ṣe fọwọ́ kékeré mu àwọn ohun tá a gbà gbọ́ tàbí ká má ṣe rò pé wọn ò jẹ́ nǹkan kan. Jòhánù kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.”—1 Jòhánù 4:1.
Wo àpẹẹrẹ rere àwọn èèyàn kan tó ń gbé nílùú Bèróà ní ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n ní “ọkàn-rere.” Wọ́n “gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí [tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà sọ] rí.” (Ìṣe 17:10, 11) Àní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Bèróà nífẹ̀ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ gan-an, wọ́n ṣàyẹ̀wò láti rí i dájú pé ohun tí àwọ́n gbọ́ táwọn sì tẹ́wọ́ gbà fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nínú Ìwé Mímọ́.
Lóde òní náà, àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ kì í jẹ́ kí èrò táwọn èèyàn ní, èyí tí kò dúró sójú kan, nípa lórí àwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀kọ́ inú Bíbélì ni wọ́n rọ̀ mọ́ gbágbáágbá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èyí sì ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.”—Fílípì 1:9.
Bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, pinnu láti ní “ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún” nípa mímọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn tó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Bèróà kì í jẹ́ kí “ayédèrú ọ̀rọ̀” táwọn aṣòdì-sí-Kristi ń sọ tàn wọ́n jẹ. (2 Pétérù 2:3) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa ojúlówó Kristi àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti sọ wọ́n dòmìnira.— Jòhánù 8:32, 36.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA AṢÒDÌ-SÍ-KRISTI
“Ẹ̀yin ọ̀dọ́mọdé, wákàtí ìkẹyìn nìyí [ẹ̀rí fi hàn pé èyí jẹ́ ẹ̀yìn táwọn àpósítélì ti kú tán], àti pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀, nísinsìnyí pàápàá ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ni ó ti wà; láti inú òtítọ́ tí àwa ti jèrè ìmọ̀ pé wákàtí ìkẹyìn nìyí.”—1 Jòhánù 2:18.
“Ta ni òpùrọ́ bí kì í bá ṣe ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù ni Kristi? Èyí ni aṣòdì sí Kristi, ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ.”—1 Jòhánù 2:22.
“Gbogbo àgbéjáde onímìísí tí kò bá jẹ́wọ́ Jésù kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Síwájú sí i, èyí ni àgbéjáde onímìísí ti aṣòdì sí Kristi èyí tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, nísinsìnyí ó ti wà ní ayé ná.”—1 Jòhánù 4:3.
“Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti jáde lọ sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.”—2 Jòhánù 7.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
ẸLẸ́TÀN TÓ Ń LO ORÍṢIRÍṢI ỌGBỌ́N
Gbogbo àwọn to ta ko ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù Kristi, tí wọ́n ta ko Ìjọba rẹ̀, tí wọ́n sì ń hùwàkiwà sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà aṣòdì-sí-Kristi tọ́ka sí. Àwọn tó tún jẹ́ aṣòdì-sí-Kristi ni àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan, àwọn àjọ, àtàwọn orílẹ̀-èdè tó ń purọ́ pé àwọn ń ṣojú fún Kristi tàbí pé àwọn làwọn ń ṣe ohun tí Mèsáyà yóò ṣe, tí wọ́n ń fi ìgbéraga ṣèlérí ohun tó jẹ́ pé Kristi nìkan ló lè ṣe é, ìyẹn mímú ojúlówó àlàáfíà àti ààbò wá sáyé.
[Credit Line]
Augustine: ©SuperStock/age fotostock
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bíi tàwọn ará Bèróà, a gbọ́dọ̀ máa “ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́”