Bá a Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọmọnìkejì Wa
“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—MÁTÍÙ 22:39.
1. Báwo la ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
KÍ NI Jèhófà fẹ́ káwọn tó ń jọ́sìn òun ṣe? Gbólóhùn kan tó ṣe ṣókí tó sì fa kíki ni Jésù fi dáhùn ìbéèrè yìí. Ó sọ pé òfin tó tóbi ju gbogbo òfin lọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo àyà, ọkàn, èrò inú, àti okun wa. (Mátíù 22:37; Máàkù 12:30) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí pé ká máa ṣègbọràn sí i, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kò ka ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ sí ohun ìnira rárá; ńṣe ló máa ń múnú wọn dùn.—Sáàmù 40:8; 1 Jòhánù 5:2, 3.
2, 3. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àṣẹ tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?
2 Jésù sọ pé òfin kejì tó tóbi jù lọ tún jọ ti àkọ́kọ́, òun ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Àṣẹ kejì yìí la máa jíròrò báyìí, ó sì nídìí pàtàkì tá a fẹ́ fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìfẹ́ òdì ló kúnnú ayé lákòókò tá a wà yìí. Nígbà tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ bí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ṣe máa rí, ó kọ̀wé pé àwọn èèyàn á nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó àti adùn dípò kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní í ní “ìfẹ́ni àdánidá,” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ Bíbélì kan ṣe sọ ọ́, wọn ò ní í “ní ìfẹ́ téèyàn máa ń ní fún ìdílé rẹ̀.” (2 Tímótì 3:1-4) Jésù Kristi sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn . . . yóò sì da ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, wọn yóò sì kórìíra ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. . . . Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”—Mátíù 24:10, 12.
3 Àmọ́ ṣá o, kíyè sí i pé Jésù kò sọ pé ìfẹ́ gbogbo èèyàn yóò di tútù. Kò sígbà kan rí tá ò ráwọn èèyàn tó nírú ìfẹ́ tí Jèhófà fẹ́ ká ní sí òun yìí, ìfẹ́ náà sì tọ́ sí i. Gbogbo ìgbà nírú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ á sì máa wà. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà á sapá láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n. Àwọn wo wá ni ọmọnìkejì wa tá a gbọ́dọ̀ fìfẹ́ hàn sí? Báwo ló ṣe yẹ ká fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọnìkejì wa? Ìwé Mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí.
Ta Ni Ọmọnìkejì Mi?
4. Gẹ́gẹ́ bí Léfítíkù orí kọkàndínlógún ti sọ, àwọn wo làwọn Júù gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí?
4 Nígbà tí Jésù ń sọ fáwọn Farisí pé àṣẹ kejì tó tóbi jù lọ ni kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ bí ara rẹ̀, òfin kan pàtó tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ń tọ́ka sí. Òfin yìí wà nínú Léfítíkù 19:18. Nínú orí kan náà yẹn, Ọlọ́run sọ fáwọn Júù pé kí wọ́n ka àwọn mìíràn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì sí ọmọnìkejì wọn. Ẹsẹ kẹrìnlélọ́gbọ̀n sọ pé: “Kí àtìpó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ, nítorí ẹ di àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fìfẹ́ hàn sáwọn tí kì í ṣe Júù, àgàgà àwọn aláwọ̀ṣe, ìyẹn àwọn tó yí padà di ẹlẹ́sìn Júù.
5. Báwo làwọn Júù ṣe lóye ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni?
5 Àmọ́, ojú táwọn aṣáájú ìsìn Júù ìgbà ayé Jésù fi wo ọ̀ràn náà yàtọ̀ pátápátá. Àwọn kan rò pé kìkì àwọn Júù ni ọ̀rọ̀ náà “ọ̀rẹ́” àti “aládùúgbò” wà fún. Pé ó yẹ káwọn kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù. Ohun tí irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ ní lọ́kàn ni pé àwọn tó ń sin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kórìíra àwọn tí kò sin Ọlọ́run. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, “kò sọ́gbọ́n téèyàn lè dá tí ìkórìíra ò fi ní gbilẹ̀ nírú ipò bẹ́ẹ̀. Nítorí pé ohun tó máa mú kó gbilẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ.”
6. Kókó méjì wo ni Jésù tẹnu mọ́ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni?
6 Nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tó yẹ kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí. Ó ní: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:43-45) Jésù jẹ́ kí kókó méjì ṣe kedere níbí yìí. Èkíní ni pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́, ó sì ń fi inúure hàn sí ẹni rere àti ẹni búburú. Èkejì ni pé ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.
7. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àkàwé ará Samáríà tó jẹ́ ọmọnìkejì rere?
7 Lákòókò mìíràn, Júù kan tó mọ̀ nípa Òfin gan-an béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Jésù fèsì nípa sísọ àkàwé ará Samáríà kan tó rí Júù kan táwọn ọlọ́ṣà ti lù ní àlùbolẹ̀ tí wọ́n sì kó gbogbo ẹrù rẹ̀ lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kórìíra àwọn ará Samáríà, síbẹ̀ ará Samáríà yìí di ọgbẹ́ ọkùnrin náà, ó sì gbé e lọ síbi tó ti máa gbàtọ́jú kí ara rẹ̀ lè yá. Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa? A tún gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn mìíràn yàtọ̀ sáwọn tá a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà, ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà, tàbí àwọn tá a jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà.—Lúùkù 10:25, 29, 30, 33-37.
Bá A Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọmọnìkejì Wa
8. Kí ni Léfítíkù orí kọkàndínlógún sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn?
8 Bí ìfẹ́ fún Ọlọ́run ṣe rí náà ni ìfẹ́ fún ọmọnìkejì ẹni ṣe rí, kì í ṣe ohun téèyàn kàn ń rò lọ́kàn, ó gba pé ká ṣe ohun kan. Á dára ká túbọ̀ gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó yí òfin tó wà nínú Léfítíkù orí kọkàndínlógún yẹn yẹ̀ wò, èyí tó gba àwọn èèyàn Ọlọ́rùn níyànjú láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn bí ara wọn. Ibẹ̀ la ti kà á pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ fún àwọn ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àtàwọn àtìpó láyè láti nípìn-ín nínú irè oko wọn. Ìyẹn ni kò ní jẹ́ kí wọ́n jalè, kò ní jẹ́ kí wọ́n hùwà ẹ̀tàn, tàbí kí wọ́n máa ṣe màgòmágó. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ ṣojúsàájú tó bá kan ọ̀ràn ìdájọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè báni wí nígbà tó bá yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ òfin Ọlọ́run sọ fún wọn ní pàtó pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn-àyà rẹ.” Èyí àtàwọn àṣẹ mìíràn ni Jésù kó pọ̀ nígbà tó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Léfítíkù 19:9-11, 15, 17, 18.
9. Kí nìdí tí Jèhófà fi pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn, síbẹ̀ wọ́n tún gbọ́dọ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó jẹ́ abọ̀rìṣà. Jèhófà kìlọ̀ fún wọn nípa ewu tó wà nínú kíkó ẹgbẹ́ búburú àti àbájáde tó máa ń ní. Bí àpẹẹrẹ, àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn orílẹ̀-èdè táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gba ilẹ̀ wọn ni pé: “Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. Ọmọbìnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fún ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú fún ọmọkùnrin rẹ. Nítorí òun yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn, dájúdájú, wọn yóò sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn; ní tòótọ́, ìbínú Jèhófà yóò sì ru sí yín.”—Diutarónómì 7:3, 4.
10. Kí ni nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún?
10 Bákan náà làwọn Kristẹni kì í ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn tó lè mú kí iná ìgbàgbọ́ wọn jó àjórẹ̀yìn. (1 Kọ́ríńtì 15:33) A gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́,” ìyẹn àwọn tí kì í ṣe ara ìjọ Kristẹni. (2 Kọ́ríńtì 6:14) Bíbélì tún gba àwa Kristẹni níyànjú síwájú sí i pé ká ní ọkọ tàbí aya “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Síbẹ̀, a ó gbọ́dọ̀ kórìíra àwọn tí kò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Kristi kú fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ tó sì ti ṣe ohun búburú nígbà kan rí ló ti yí ọ̀nà wọn padà tí wọ́n sì wá di ọrẹ Ọlọ́run.—Róòmù 5:8; 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
11. Ọ̀nà tó dáa jù lọ wo la lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn tí kò sin Jèhófà, kí sì nìdí?
11 Tá a bá fẹ́ máa fìfẹ́ hàn sáwọn tí kò sin Ọlọ́run, ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká fara wé Jèhófà fúnra rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kórìíra ìwà ibi, ó fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn nípa fífún wọn ní àǹfààní láti yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn kí wọ́n lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìsíkíẹ́lì 18:23) Jèhófà “fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ohun tó wù ú ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi pa á láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù, kí wọ́n kọ́ni, kí wọ́n sì “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa, títí kan àwọn ọ̀tá wa pàápàá!
Ìfẹ́ Tá A Ní Fáwọn Tá A Jọ Jẹ́ Kristẹni
12. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù kọ nípa ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ arákùnrin wa?
12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó pọn dandan fún wa láti fìfẹ́ hàn sáwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́, ìyẹn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tá a jọ ń sin Ọlọ́run. Báwo ni ìfẹ́ yìí ti ṣe pàtàkì tó? Kókó tó lágbára yìí ni àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ nígbà tó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn . . . Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòhánù 3:15; 4:20) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí lágbára gan-an. Sátánì Èṣù ni Jésù Kristi pé ní “apànìyàn” àti “òpùrọ́.” (Jòhánù 8:44) A ò sí ní fẹ́ kí wọ́n pè wá nírú orúkọ yẹn láé!
13. Ọ̀nà wo la lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
13 ‘Ọlọ́run ti kọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn.’ (1 Tẹsalóníkà 4:9) A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́, “kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòhánù 3:18) Ìfẹ́ wa kò gbọ́dọ̀ ní “àgàbàgebè” nínú. (Róòmù 12:9) Ìfẹ́ ló ń mú ká jẹ́ onínúure, oníyọ̀ọ́nú, òun ló ń jẹ́ ká máa dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ wá, òun ló sì ń jẹ́ ká máa ní ìpamọ́ra. Òun ní kì í jẹ́ ká jowú, kì í jẹ́ ká fọ́nnu, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jẹ́ ká wú fùkẹ̀ tàbí ká jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5; Éfésù 4:32) Ó máa ń mú ká ‘sìnrú fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Gálátíà 5:13) Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. (Jòhánù 13:34) Nítorí ìdí èyí, tó bá pọn dandan, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ múra tán láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀.
14. Báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn láàárín ìdílé?
14 Inú ìdílé Kristẹni ló yẹ ká ti máa fìfẹ́ hàn jù lọ, àgàgà láàárín ọkọ àti aya. Àárín tọkọtaya gbọ́dọ̀ gún régé, ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” Ó tún fi kún un pé: “Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.” (Éfésù 5:28) A rí i pé Pọ́ọ̀lù tún ọ̀rọ̀ yìí sọ ní ẹsẹ márùn-ún lẹ́yìn ẹsẹ yìí. Ọkọ tó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ kò ní ṣe bíi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbà Málákì tí wọ́n ṣe àdàkàdekè sí ẹnì kejì wọn. (Málákì 2:14) Ńṣe ni yóò máa ṣìkẹ́ rẹ̀. Yóò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ ìjọ. Bákan náà ni ìfẹ́ yóò mú kí aya máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.—Éfésù 5:25, 29-33.
15. Kí ni ìfẹ́ ará táwọn kan ṣàkíyèsí mú kí wọ́n sọ, kí ni wọ́n sì ṣe?
15 Ó hàn gbangba pé irú ìfẹ́ yìí ni àmì tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ìfẹ́ tá a ní fún ara wa ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run tá a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tá a sì ń ṣojú fún. Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn tá a gbọ́ nípa ìdílé Ẹlẹ́rìí kan láti orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì rèé: “A ò rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí. Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, ìjì líle kan bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́, bí òjò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ nìyẹn tí yìnyín sì ń já bọ́. Ìjì líle náà ba ilé wa tá a fi koríko kọ́ jẹ́, ó sì ṣí páànù orí rẹ̀ dà nù. Nígbà táwọn ará tó wà láwọn ìjọ itòsí wá ràn wá lọ́wọ́ láti tún ilé wa kọ́, ẹnu ya àwọn aládùúgbò wa gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: ‘Ẹ̀sìn yín dára gan-an ni o. Àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì wa ò tíì wá ràn wá lọ́wọ́ bíi tiyín rí.’ A ṣí Bíbélì, a sì fi ohun tó wà nínú ìwé Jòhánù 13:34, 35 hàn wọ́n. Ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò wa ló ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí.”
Bá A Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan
16. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lápapọ̀ àti ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
16 Kò ṣòro rárá láti nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà láyìíká wa lápapọ̀. Àmọ́, ìfẹ́ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, ìfẹ́ táwọn kan ní fún ọmọnìkejì wọn kò kọjá kí wọ́n dáwó fún àwọn ẹgbẹ́ aláàánú kan. Ká sòótọ́, ó rọrùn gan-an láti sọ pé a nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa, àmọ́ kì í rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tí kò bìkítà nípa wa, tàbí ẹnì kan tó ń gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wa tí ìṣe rẹ̀ máa ń bí wa nínú, tàbí ọ̀rẹ́ kan tó já wa kulẹ̀.
17, 18. Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kì sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Jésù, ẹni tó fi àwọn ànímọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù láìkù síbì kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wá sáyé láti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ayé lọ, síbẹ̀ ó fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, àwọn bí, obìnrin kan tó ń ṣàìsàn, adẹ́tẹ̀ kan, àti ọmọ kékeré kan. (Mátíù 9:20-22; Máàkù 1:40-42; 7:26, 29, 30; Jòhánù 1:29) Bẹ́ẹ̀ làwa náà ṣe ní láti máa fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wa nípa bá a ṣe ń ṣe sáwọn tá a ń bá pàdé lójoojúmọ́.
18 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé láé pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ló ń mú ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, síbẹ̀ ìdí tó fi ń ṣe gbogbo èyí tó sì tún ń kọ́ àwọn èèyàn ni kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 5:19) Jésù ṣe gbogbo nǹkan fún ògo Ọlọ́run, kò fìgbà kan gbàgbé pé Ọlọ́run tóun nífẹ̀ẹ́ sí lóun ń ṣojú fún, àti pé àwọn ànímọ́ rẹ̀ lòún fi ń ṣèwà hù. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Nípa fífarawé àpẹẹrẹ Jésù, àwa náà lè fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wa, síbẹ̀ ká rí i dájú pé a ò bá àwọn èèyàn ayé tí wọ́n jẹ́ ẹni ibi da nǹkan pọ̀.
Ọ̀nà Wo La Ń Gbà Nífẹ̀ẹ́ Ọmọnìkejì Wa Bí Ara Wa?
19, 20. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bí ara wa?
19 Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Ìwà ẹ̀dá ni pé èèyàn kì í fi ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ṣeré, èèyàn sì máa ń gbé ara rẹ̀ níyì. Tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, àṣẹ yẹn ì bá má lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ojúlówó ìfẹ́ tá a sọ pé a ní fún ara wa yìí kì í ṣe ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ nínú 2 Tímótì 3:2. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni kéèyàn mọ̀ pé òun níyì lọ́wọ́ ara òun. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì sọ pé ohun tó túmọ̀ sí ni “kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́nà tó bójú mu, kì í ṣe kó máa rò pé òun sàn ju àwọn mìíràn lọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe kó máa rò pé òun ò já mọ́ nǹkan kan.”
20 Nínífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí ara wa túmọ̀ sí pé irú ojú tá a fẹ́ káwọn ẹlòmíràn máa fi wò wá làwa náà á máa fi wò wọ́n, ìwà tá a sì fẹ́ káwọn èèyàn máa hù sí wa làwa náà á máa hù sí wọn. Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Kíyè sí i pé Jésù ò ní ká máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn ti ṣẹ̀ wá ká sì máa wá bá a ṣe máa gbẹ̀san o. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti ronú nípa bó ṣe wù wá káwọn èèyàn máa ṣe sí wa, káwa náà sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú. Tún kíyè sí i pé Jésù ò sọ pé kìkì àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn arákùnrin wa nìkan ni ká fìfẹ́ hàn sí. Ó lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ènìyàn,” bóyá láti fi hàn pé bá a ṣe gbọ́dọ̀ máa bá gbogbo èèyàn lò nìyẹn, ìyẹn ẹnikẹ́ni tá a bá bá pàdé.
21. Kí là ń fi hàn, nígbà tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?
21 Ìfẹ́ ọmọnìkejì wa kò ní jẹ́ ká ṣe ohun búburú kankan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àkójọ òfin náà, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò,’ àti àṣẹ mìíràn yòówù kí ó wà, ni a ṣàkópọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yìí, èyíinì ni, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni.” (Róòmù 13:9, 10) Ìfẹ́ á mú ká máa wá ọ̀nà tá a lè gbà ṣe ohun tó dára fáwọn èèyàn. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi tiwa, a ò máa tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹni tó dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àwọn wo ló yẹ ká fìfẹ́ hàn sí, kí sì nìdí?
• Báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn tí kò sin Jèhófà?
• Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìfẹ́ tó yẹ ká ní fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
• Báwo la ṣe lè máa nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bí ara wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan