ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 12/15 ojú ìwé 4-7
  • Ọ̀nà Tí Ìbí Jésù Gbà Mú Àlàáfíà Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Tí Ìbí Jésù Gbà Mú Àlàáfíà Wá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọba Tí Ọlọ́run Sọ Tẹ́lẹ̀
  • ‘Ìhìn Rere Ìdùnnú Ńlá’
  • Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Ká Fìwà Jọ Kristi Jálẹ̀ Ọdún?
  • Mèsáyà Dé
    Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • “Èyí Ni Ọmọ Mi”
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Jehofa Ṣe Ojúrere sí I Lọ́nà Gíga
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 12/15 ojú ìwé 4-7

Ọ̀nà Tí Ìbí Jésù Gbà Mú Àlàáfíà Wá

ÌKÉDE “àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà” nìkan kọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ ìbí Jésù o. Yàtọ̀ sí ìkéde yìí táwọn áńgẹ́lì ṣe fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ẹnu yà gidigidi, Ọlọ́run ti kọ́kọ́ fiṣẹ́ rán áńgẹ́lì sí Màríà àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ nípa Jésù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà. Tá a bá gbé iṣẹ́ wọ̀nyẹn yẹ̀ wò, a óò túbọ̀ mọ̀ nípa ìbí Jésù, a ó sì mọ ìdí tí ìlérí táwọn áńgẹ́lì náà ṣe pé àlàáfíà máa wà láàárín àwọn èèyàn fi ṣe pàtàkì.

Kí Màríà tó bí Jésù, kódà kó tó lóyún rẹ̀, áńgẹ́lì kan tí Bíbélì pè ní Gébúrẹ́lì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tó débẹ̀, ó kí i, ó ní: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” Èyí bá Màríà láìròtẹ́lẹ̀ débi pé ọkàn rẹ̀ ò lélẹ̀, kó máa rò ó pé, irú ìkíni wo lèyí?

Gébúrẹ́lì sọ fún un pé: “Wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” Nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ̀rọ̀ tán, Màríà béèrè bí ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe nígbà tó jẹ́ pé wúńdíá tí ò tíì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kankan rí lòun. Ni Gébúrẹ́lì bá sọ fún un pé nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni yóò fi lóyún náà, nítorí àkàndá èèyàn lọmọ tó máa bí.—Lúùkù 1:28-35.

Ọba Tí Ọlọ́run Sọ Tẹ́lẹ̀

Ọ̀rọ̀ tí Gébúrẹ́lì sọ yìí á ti jẹ́ kí Màríà mọ̀ pé ẹni táwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà láéláé sọ nípa rẹ̀ lọmọ tóun fẹ́ bí. Ohun tí áńgẹ́lì náà sọ pé Jèhófà yóò fún ọmọ tí Màríà máa bí ní “ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀,” á mú kí Màríà àti Júù èyíkéyìí tó bá mọ Ìwé Mímọ́ rántí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Dáfídì ọba Ísírẹ́lì.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Jèhófà ti tipasẹ̀ wòlíì Nátánì sọ fún Dáfídì pé: “Ilé rẹ àti ìjọba rẹ yóò . . . fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin dájúdájú fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ pàápàá yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (2 Sámúẹ́lì 7:4, 16) Jèhófà tún sọ nípa Dáfídì pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé àti ìtẹ́ rẹ̀ bí àwọn ọjọ́ ọ̀run. Irú-ọmọ rẹ̀ yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oòrùn ní iwájú mi.” (Sáàmù 89:20, 29, 35, 36) Nítorí náà, kì í ṣe pé ó kàn ṣèèṣì bọ́ sí i pé Màríà àti Jósẹ́fù wá láti ìlà ìdílé Dáfídì.

Yàtọ̀ sáwọn wọ̀nyí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tún wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nípa ọmọ Dáfídì tó máa jẹ́ ọba. Màríà á ti mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó sọ pé: “Nítorí a ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.”—Aísáyà 9:6, 7.

Nítorí náà, ohun tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì kéde fún Màríà ju pé ó máa bí ọmọ kan lọ́nà ìyanu o. Ọmọ tí yóò bí ló máa jogún ìtẹ́ Dáfídì Ọba, òun ló máa ṣàkóso Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ títí láé. Ohun tí Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ipa tí Jésù yóò kó lọ́jọ́ iwájú ṣe pàtàkì gan-an fún gbogbo wa.

Nígbà tí Màríà sọ fún Jósẹ́fù àfẹ́sọ́nà rẹ̀ pé òun ti lóyún, Jósẹ́fù pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé àwọn ò ní fẹ́ra mọ́. Ó mọ̀ pé òun kọ́ lòun ni oyún náà nítorí pé òun àti Màríà àfẹ́sọ́nà rẹ̀ kò ní ìbálòpọ̀ rí. Bí ìwọ náà bá ro ọ̀rọ̀ yìí, wàá rí i pé kò ní rọrùn fún Jósẹ́fù láti gba Màríà gbọ́ nígbà tó ń ṣàlàyé bó ṣe lóyún fún un. Ìhìn Rere Mátíù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fún wa, ó ní: “Áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án nínú àlá, ó wí pé: ‘Jósẹ́fù, ọmọkùnrin Dáfídì, má fòyà láti mú Màríà aya rẹ sí ilé, nítorí èyíinì tí ó lóyún rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Yóò bí ọmọkùnrin kan, kí ìwọ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.’”—Mátíù 1:20, 21.

Bíbélì ò sọ bóyá Jósẹ́fù ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa bí ọmọ náà yóò ṣe “gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn” tàbí kò ní. Bó ti wù kó rí, ohun tí áńgẹ́lì náà sọ ti tó fún Jósẹ́fù láti mọ̀ pé ìṣekúṣe kọ́ ni Màríà ṣe tó fi lóyún. Ni Jósẹ́fù bá ṣe ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fún un, ó mú Màríà wá sílé rẹ̀, mímú tó sì mú un wá sílé rẹ̀ yìí túmọ̀ sí pé wọ́n ti ṣègbéyàwó.

Ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì míì sọ mú ká lóye ohun tí áńgẹ́lì tó bá Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ ní lọ́kàn. Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ẹ̀dá èèyàn, áńgẹ́lì kan tó di ọlọ̀tẹ̀ fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ ká mọ̀ pé ara àwọn ohun tí ọlọ̀tẹ̀ náà sọ ni pé Ọlọ́run kò ṣàkóso lọ́nà òdodo, ó sì tún sọ pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn èèyàn tí yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tó bá rí ìdánwò. (Jẹ́nẹ́sísì 3:2-5; Jóòbù 1:6-12) Ádámù ní tiẹ̀ kò jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù ṣẹ̀ yìí ni pé gbogbo àwa èèyàn jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ náà ló sì fa ikú. (Róòmù 5:12; 6:23) Àmọ́ nígbà tí Màríà bí Jésù, Jésù kò jogún ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé ẹ̀dá èèyàn kọ́ ni bàbá rẹ̀. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé èèyàn pípé ni Jésù, ìràpadà tó san nígbà tó fínnúfíndọ̀ fẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Ádámù pàdánù, ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fún un láti gba àwa èèyàn là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa ká sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Tímótì 2:3-6; Títù 3:6, 7; 1 Jòhánù 2:25.

Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ káwọn èèyàn róye bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tóun bá mú gbogbo ohun tó jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Ó wo onírúurú àìsàn sàn, kódà ó jí òkú dìde. (Mátíù 4:23; Jòhánù 11:1-44) Ńṣe làwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe yẹn wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Òun alára sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [mi], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

Ìlérí tí Jésù ṣe nípa àjíǹde tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú yìí jẹ́ ká rí ìdí tí ìbí Jésù fi ṣe pàtàkì gan-an fún wa, àti bí ikú rẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ. Jòhánù 3:17 sọ pé Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé “kí a lè gba ayé là nípasẹ̀ rẹ̀.” Ìhìn rere tó kàmàmà yìí tún mú wa rántí ìkéde táwọn áńgẹ́lì ṣe fáwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn lóru ọjọ́ tí Màríà bí Jésù.

‘Ìhìn Rere Ìdùnnú Ńlá’

Dájúdájú, ‘ìhìn rere ìdùnnú ńlá’ ló jẹ́ fún aráyé nígbà táwọn áńgẹ́lì kéde ìbí ‘Olùgbàlà kan, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa.’ (Lúùkù 2:10, 11) Ọmọ yìí ló máa jẹ́ Mèsáyà, Wòlíì ńlá náà àti Alákòóso táwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń retí tipẹ́tipẹ́. (Diutarónómì 18:18; Míkà 5:2) Ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti ikú rẹ̀ máa kó ipa pàtàkì nínú fífihàn pé Jèhófà nìkan ló yẹ kó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, ìdí sì nìyẹn táwọn áńgẹ́lì náà fi sọ pé: “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè.”—Lúùkù 2:14.

Bí Jésù tí Bíbélì pè ní “Ádámù ìkẹyìn” ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀ fi hàn pé ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kódà lábẹ́ ìdánwò tó le jù lọ. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ àti ìkà ni Sátánì. Ohun tó ṣe yìí sì múnú àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lọ́run dùn.

Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká padà sórí ìbéèrè tá a béèrè nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, pé: “Ǹjẹ́ ìrètí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà pé ìkéde àlàáfíà táwọn áńgẹ́lì ṣe lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù á nímùúṣẹ?” Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa nímùúṣẹ! Àlàáfíà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ohun rere tó máa wà nígbà tí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé bá ṣẹ, ara ohun tí Ọlọ́run sì ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé ni pé kó padà di Párádísè. Nígbà tí gbogbo ayé bá di Párádísè, gbogbo èèyàn á nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọn ò sì ní dalẹ̀ ara wọn. Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé kí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn tó lè ṣẹ, ó gbọ́dọ̀ pa gbogbo àwọn tó bá ń ṣàtakò sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ run. Ìròyìn ìbànújẹ́ lèyí jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá ń ti Sátánì lẹ́yìn láti fi hàn pé àwọn ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ kò dára. Ìparun ló ń dúró dè wọ́n.—Sáàmù 37:11; Òwe 2:21, 22.

Jọ̀wọ́, kíyè sí i pé àwọn áńgẹ́lì náà ò sọ fáwọn olùṣọ́ àgùntàn pé gbogbo èèyàn ló máa rí àlàáfíà tó sì máa jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n kéde ni pé ‘àlàáfíà yóò wà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.’ Ohun tíyẹn sì túmọ̀ sí ni pé àárín àwọn tí wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run nìkan ni àlàáfíà máa wà. Àwọn ti wọ́n ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà máa ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ojoojúmọ́ ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ọ̀làwọ́ sáwọn ẹlòmíì tí wọ́n sì máa ń ṣe inúure sí wọn, kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe fún ọjọ́ mélòó kan nínú ọdún.

Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Ká Fìwà Jọ Kristi Jálẹ̀ Ọdún?

Ìhìn rere tí Jésù wàásù ti tún ìgbésí ayé àìmọye èèyàn ṣe. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe nígbèésí ayé wọn. Àwọn kan tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, ‘Ká ní Jésù ló wà nípò tí mo wà yìí, kí ló máa ṣe?’ Àwọn kan tó jẹ́ pé ohun ìní tara àti adùn ni wọ́n ń lé ti wá mọ̀ pé àwọn ohun tó jẹ mọ́ àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìjọsìn rẹ̀ ló ṣe pàtàkì jù lọ, wọ́n sì tún mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn máa sọ èyí fáwọn èèyàn. Àwọn wọ̀nyí máa ń gbìyànjú láti jẹ́ ọ̀làwọ́ àti onínú rere jálẹ̀ ọdún. Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó o retí pé káwọn Kristẹni tòótọ́ máa ṣe nìyẹn?

Tó bá ṣe pé báwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ ṣe ń kà nípa ìkéde àlàáfíà táwọn áńgẹ́lì ṣe nígbà ìbí Jésù náà ní gbogbo wọn ṣe máa ń ronú lórí ìdí tó fi ṣe pàtàkì àtohun to túmọ̀ sí tí wọ́n sì ń gbé ìgbé ayé wọn níbàámu pẹ̀lú rẹ̀ ni, ayé ò ní rí bó ṣe rí yìí.

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ ìbí Jésù mú un dá àwọn tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run lójú pé wọ́n lè ní ojúlówó àlàáfíà títí láé. Kò sí àní-àní pé ohun tó o fẹ́ nìyẹn, àbí? Ó dá wa lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà tó wà nínú ìkéde ológo táwọn áńgẹ́lì ṣe nígbà ìbí Jésù á nímùúṣẹ láìkùnà. Ó ju bí wọ́n ṣe máa ń sọ ọ́ yẹpẹrẹ nígbà Kérésìmesì lọ o. Ó dájú hán-únhán-ún pé àlàáfíà tí ò ní lópin ń bọ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

A lè fìwà jọ Kristi jálẹ̀ ọdún, ó sì yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́