ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 1/15 ojú ìwé 14-16
  • Sámúẹ́lì Gbé Ìjọsìn Tòótọ́ Lárugẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sámúẹ́lì Gbé Ìjọsìn Tòótọ́ Lárugẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbà Tó Wà Lọ́mọdé
  • Sámúẹ́lì Di Wòlíì
  • Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Láwọn Ń Fẹ́ Ọba
  • Ọba Kìíní àti Ìkejì Tó Jẹ Ní Ísírẹ́lì
  • Àpẹẹrẹ Tí Sámúẹ́lì Fi Lélẹ̀
  • Ó Fara Da Ìjákulẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ó Lo Ìfaradà Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Já A Kulẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó “Ń Bá A Lọ Ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ó “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 1/15 ojú ìwé 14-16

Sámúẹ́lì Gbé Ìjọsìn Tòótọ́ Lárugẹ

WÒLÍÌ SÁMÚẸ́LÌ bá àwọn tóun àtàwọn jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run wí gidigidi nítorí wọ́n sọ pé àwọn ń fẹ́ ọba, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Sámúẹ́lì fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé wòlíì Ọlọ́run lòun, ìdí nìyẹn tó fi bẹ Ọlọ́run pé kó ṣe àmì kan. Àmì tó ń fẹ́ ni pé kí Ọlọ́run mú kí ìjì jà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kì í sábà sí òjò oníjì nílẹ̀ Ísírẹ́lì lásìkò yẹn tó jẹ́ àsìkò ìkórè àlìkámà. Síbẹ̀, Ọlọ́run mú kí òjò rọ̀ tòun ti ààrá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kẹ́rù Jèhófà àti Sámúẹ́lì, aṣojú rẹ̀, ba àwọn èèyàn náà gan-an.—1 Sámúẹ́lì 12:11-19.

Yàtọ̀ sí pé Sámúẹ́lì jẹ́ wòlíì, òǹkọ̀wé tún ni. Ó kọ ìtàn tó kún fún ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ èyí tó wáyé láàárín àádọ́rin dín nírínwó [330] ọdún. Lára ohun tó sì kọ̀wé nípa rẹ̀ ni iṣẹ́ ribiribi táwọn onídàájọ́ ilẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ ìtàn ìgbésí ayé Sámúsìnì, ọkùnrin tó lágbára jù lọ nínú gbogbo àwọn tó ti ń gbé láyé. Ìtàn Sámúsìnì yìí wá di ohun táwọn èèyàn ń gbé jáde nínú ewì, tí wọ́n sì tún ń gbé jáde nínú eré orí ìtàgé àti ti fídíò. (Onídàájọ́, orí 13 sí 16) Sámúẹ́lì tún kọ̀wé nípa àwọn opó méjì kan tí wọ́n jẹ́ aláìní, àwọn ni Rúùtù àti Náómì ìyá ọkọ rẹ̀. Bí ìtàn Sámúsìnì ṣe wúni lórí ni ìtàn àwọn obìnrin méjì yìí náà wúni lórí.—Rúùtù, orí 1 sí 4.

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìtàn tí Sámúẹ́lì kọ, ẹ̀kọ́ wo sì ni ìtàn ìgbésí ayé tirẹ̀ fúnra rẹ̀ kọ́ wa? Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ?

Ìgbà Tó Wà Lọ́mọdé

Olùjọsìn Jèhófà ni Ẹlikénà bàbá Sámúẹ́lì, ọkọ rere sì ni. Hánà ìyàwó Ẹlikénà jẹ́ ẹnì kan tó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run. Láàárín ìgbà tí ò rọ́mọ bí, ó lọ sílé Jèhófà tó wà ní Sílò níbi tó ti gbàdúrà tọkàntọkàn tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, láìkùnà, bí ìwọ yóò bá wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ níṣẹ̀ẹ́, tí o sì rántí mi ní ti tòótọ́, tí ìwọ kì yóò sì gbàgbé ẹrúbìnrin rẹ, tí o sì fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ fẹ́lẹ́ kì yóò sì kan orí rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 1:1-11) Ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ yìí fi hàn pé ńṣe ló máa fi ọmọ náà fún Jèhófà láti fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Ọlọ́run.

Àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ni Hánà gbà. Ìtàn yẹn sọ pé “ètè rẹ̀ nìkan ni ó ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.” Élì tí í ṣe Àlùfáà Àgbà ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó rò pé ńṣe ni Hánà mutí yó, ló bá fi ohùn líle bá a wí. Àmọ́, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni Hánà fi ṣàlàyé ohun tó ń ṣe fún un, nígbà náà ni Élì wá sọ pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.” Jèhófà gbọ́ àdúrà Hánà lóòótọ́, nítorí ìtàn náà sọ pé: “Ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípo ọdún pé Hánà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, nítorí, ó wí pé, ‘ọwọ́ Jèhófà ni mo ti béèrè rẹ̀.’”—1 Sámúẹ́lì 1:12-20.

Àwọn òbí Sámúẹ́lì tọ́ ọ dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Lẹ́yìn tí wọ́n já Sámúẹ́lì lẹ́nu ọmú, Hánà mú un wá sílé Ọlọ́run ní Ṣílò, ó sì fà á lé Élì Àlùfáà Àgbà lọ́wọ́. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni Sámúẹ́lì sì wà títí tó fi “di òjíṣẹ́ Jèhófà.” Inú Hánà dùn gan-an ni. Ọ̀rọ̀ tó wúni lórí tó fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba, èyí tí Sámúẹ́lì kọ sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, fi èyí hàn.—1 Sámúẹ́lì 2:1-11.

Tó bá jẹ́ pé òbí ni ọ́, ǹjẹ́ ò ń gba ọmọ rẹ níyànjú pé kó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ohun tó dára jù lọ téèyàn lè lo okun rẹ̀ fún ni pé kó máa fi gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ.

Ara Sámúẹ́lì tètè mọlé nílé ìjọsìn Ọlọ́run tí wọ́n mú un lọ. Ó “ń bá a lọ ní dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà . . . ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.” Ó ní àwọn ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí, èyí sì mú káwọn èèyàn fẹ́ràn rẹ̀ púpọ̀.—1 Sámúẹ́lì 2:21, 26.

Ọ̀rọ̀ tàwọn ọmọ Élì, ìyẹn Hófínì òun Fíníhásì, yàtọ̀ pátápátá síyẹn nítorí pé wọn ò dáa fóhunkóhun, “wọn kò ka Jèhófà sí.” Wọ́n ń bá àwọn obìnrin ṣèṣekúṣe, wọ́n sì tún ń mú èyí tó dára jù lọ lára ohun táwọn èèyàn bá wá fi rúbọ sí Ọlọ́run. Ọlọ́run ti kọ́kọ́ rán wòlíì rẹ̀ kan pé kó lọ sọ ìyà tó máa jẹ ìdílé Élì fún Élì. Lára ìyà ọ̀hún sì ni pé àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì yóò kú. (1 Sámúẹ́lì 2:12, 15-17, 22-25, 27, 30-34) Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà rán Sámúẹ́lì pé kó lọ sọ ìdájọ́ mìíràn fún Élì.

Sámúẹ́lì Di Wòlíì

Ọlọ́run sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Kí o sì sọ fún [Élì] pé èmi yóò ṣe ìdájọ́ ilé rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin nítorí ìṣìnà tí ó mọ̀, nítorí pé àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ń pe ibi wá sórí Ọlọ́run, òun kò sì bá wọn wí lọ́nà mímúná.” Iṣẹ́ yìí kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn láti jẹ́, Élì sì sọ fún Sámúẹ́lì pé kò gbọ́dọ̀ fìkankan pa mọ́ nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an sóun. Torí náà Sámúẹ́lì sọ gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó sọ fún Élì. Kò rọrùn rárá, ó gba ìgboyà!—1 Sámúẹ́lì 3:10-18.

Bí Sámúẹ́lì ṣe ń di géńdé, gbogbo Ísírẹ́lì wá mọ̀ pé wòlíì Ọlọ́run ní í ṣe. (1 Sámúẹ́lì 3:19, 20) Ìdájọ́ tí Sámúẹ́lì sọ pé ó máa dé bẹ̀rẹ̀ sí í dé nígbà táwọn Filísínì pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípakúpa. Ogun yẹn ni Hófínì àti Fíníhásì bá lọ, àwọn Filísínì sì gba àpótí májẹ̀mú Jèhófà lọ. Nígbà tí ìròyìn dé etígbọ̀ọ́ Élì pé àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì ti kú sógun, àti pé wọ́n ti gba àpótí májẹ̀mú lọ, ó ṣubú sẹ́yìn látorí àga tó jókòó sí, ọrùn rẹ̀ sì ṣẹ́, òun náà bá kú.—1 Sámúẹ́lì 4:1-18.

Ogún ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Sámúẹ́lì rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jáwọ́ pátápátá nínú ìjọsìn èké. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí Sámúẹ́lì lẹ́nu, wọ́n kó gbogbo òrìṣà wọn dà nù, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Sámúẹ́lì gbàdúrà fún wọn, ó sì rú ọrẹ ẹbọ sísun nítorí tiwọn. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ohun tó yọrí sí ni pé nígbà táwọn Filísínì gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run kó ṣìbáṣìbo bá àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣẹ́gun wọn. Jèhófà ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ gan-an, èyí sì mú kí ipò wọn sàn sí i débi pé wọ́n gba gbogbo ìlú táwọn Filísínì gbà lọ́wọ́ wọn padà.—1 Sámúẹ́lì 7:3-14.

Kò sí àní-àní pé Sámúẹ́lì gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó rí sí i pé wọ́n lò lára àwọn ohun tí wọ́n rí kó nígbà ogun láti fi tún àgọ́ ìjọsìn ṣe. Ó ṣètò àjọyọ̀ Ìrékọjá, ó sì tún ṣètò bí àwọn ọmọ Léfì á ṣe máa ṣọ́ bodè. (1 Kíróníkà 9:22; 26:27, 28; 2 Kíróníkà 35:18) Lọ́dọọdún, Sámúẹ́lì máa ń ti ilé rẹ̀ ní Rámà lọ sí onírúurú ìlú láti lọ ṣe ìdájọ́. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ èèyàn tí kì í ṣe ojúṣàájú. Ẹni iyì ni Sámúẹ́lì jẹ́ lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, ìdí nìyẹn tó fi lè máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (1 Sámúẹ́lì 7:15-17; 9:6-14; 12:2-5) Ó dájú pé jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ àtẹni tó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Ǹjẹ́ bí Sámúẹ́lì ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀ jẹ́ ìṣírí fún ìwọ náà?

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Láwọn Ń Fẹ́ Ọba

Nígbà tí Sámúẹ́lì darúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀, Jóẹ́lì òun Ábíjà, gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. Àwọn ọmọ náà “kò . . . rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ní ìtẹ̀sí láti tẹ̀ lé èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu, wọn a sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọn a sì yí ìdájọ́ po.” Ìwà wọn mú káwọn àgbà Ísírẹ́lì sọ fún Sámúẹ́lì pé àwọn ń fẹ́ ọba. (1 Sámúẹ́lì 8:1-5) Ohun tí wọ́n ń béèrè yìí ò tọ̀nà rárá lójú Sámúẹ́lì. Àmọ́ nígbà tí Sámúẹ́lì gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa ọ̀ràn náà, Jèhófà sọ fún un pé: “Kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba lórí wọn.” (1 Sámúẹ́lì 8:6, 7) Ọlọ́run sọ fún Sámúẹ́lì pé kó ṣe ohun táwọn èèyàn náà ń fẹ́ fún wọn, kó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá ti lè lọ́ba, òmìnira wọn dín kù nìyẹn o. Nígbà táwọn èèyàn náà ranrí pé àfi káwọn lọ́ba, Jèhófà ṣètò pé kí Sámúẹ́lì fòróró yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.—1 Sámúẹ́lì 8:6-22; 9:15-17; 10:1.

Ètò ọlọ́ba dé yìí ò fi Sámúẹ́lì lọ́kàn balẹ̀, síbẹ̀ ó kọ́wọ́ ti ètò náà. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì, Sámúẹ́lì pè wọ́n jọ sí Gílígálì kó lè fòróró yan Sọ́ọ̀lù lákọ̀tun gẹ́gẹ́ bí ọba. (1 Sámúẹ́lì 10:17-24; 11:11-15) Níbẹ̀, Sámúẹ́lì rán àwọn èèyàn náà létí ìgbé ayé wọn àtẹ̀yìnwá, ó sì gba ọba tuntun yìí àtàwọn èèyàn náà níyànjú pé kí wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà. Ọlọ́run dáhùn àdúrà Sámúẹ́lì nípa mímú kí òjò oníjì rọ̀ gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ìjì náà mú káwọn èèyàn yìí rí i pé àṣìṣe ńlá gbáà làwọn ṣe báwọn ṣe kọ Jèhófà lọ́ba. Wọ́n ní kí Sámúẹ́lì gbàdúrà fáwọn, Sámúẹ́lì sì sọ fún wọn pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ṣẹ̀ sí Jèhófà nípa ṣíṣíwọ́ láti gbàdúrà nítorí yín; èmi yóò sì fún yín ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rere àti títọ́.” Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Sámúẹ́lì ní sí Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀! (1 Sámúẹ́lì 12:6-24) Ǹjẹ́ ìwọ náà múra tán bíi ti Sámúẹ́lì láti kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà kó o sì máa gbàdúrà fáwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

Ọba Kìíní àti Ìkejì Tó Jẹ Ní Ísírẹ́lì

Níbẹ̀rẹ̀, Sọ́ọ̀lù jẹ́ ẹnì kan tí kì í kọjá ayé ẹ̀, Ọlọ́run sì fẹ́ràn rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 9:21; 11:6) Àmọ́ nígbà tó yá, kò tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run mọ́. Bí àpẹẹrẹ, lákòókò kan, Sámúẹ́lì sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ rú ẹbọ kan kóun tó dé, àmọ́ ó lọ fi ìwàǹwára rú ẹbọ ọ̀hún. Sámúẹ́lì sì bá a wí gidigidi. (1 Sámúẹ́lì 13:10-14) Lákòókò mìíràn, ó yẹ kí Sọ́ọ̀lù pa Ágágì ọba Ámálékì, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Sámúẹ́lì wá sọ fún un pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso ọba Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí, dájúdájú, yóò sì fi í fún ọmọnìkejì rẹ tí ó sàn jù ọ́.” Sámúẹ́lì wá fúnra rẹ̀ pa Ágágì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù. —1 Sámúẹ́lì 15:1-35.

Nígbà tó yá, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù, nígbà tí ó jẹ́ pé èmi, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ti kọ̀ ọ́ láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì?” Jèhófà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé kó lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti lọ fòróró yan ọmọ Jésè kan gẹ́gẹ́ bí ọba. Nígbà tí Sámúẹ́lì dọ́hùn-ún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn ọmọ Jésè níkọ̀ọ̀kan títí tó fi dórí Dáfídì tí í ṣe àbíkẹ́yìn. Dáfídì yìí sì ni Jèhófà fọwọ́ sí pé kó fòróró yàn. Lọ́jọ́ yẹn, Sámúẹ́lì kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ ọ̀hún sì ni pé: “Kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:1-13.

Níwọ̀n bí àìgbọràn Sọ́ọ̀lù ti dun Sámúẹ́lì gan-an, ó dájú pé bí Sọ́ọ̀lù ṣe kórìíra Dáfídì débi pé ó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀ ti ní láti kó ẹ̀dùn ọkàn bá Sámúẹ́lì gidigidi! Àmọ́ láìka gbogbo ìyẹn sí, Sámúẹ́lì ò dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó ń sa gbogbo ipa rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti darúgbó.—1 Sámúẹ́lì 19:18-20.

Àpẹẹrẹ Tí Sámúẹ́lì Fi Lélẹ̀

Sámúẹ́lì jẹ́ ẹnì kan tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì nígboyà, ó sì tún ní ipa tó dáa lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn. Nígbà tó kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 25:1) Lóòótọ́ Sámúẹ́lì kì í ṣe ẹni pípé, ó sì máa ń ṣàṣìṣe nínú ìdájọ́ rẹ̀ nígbà míì. Àmọ́ láìka gbogbo ìyẹn sí, tọkàntọkàn ló fi ń sin Jèhófà, ó sì tún sapá gidigidi láti rí i pé òun ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

Lóòótọ́, nǹkan ò rí bíi ti ìgbà ayé Sámúẹ́lì láyé ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì ni ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ kọ́ wa. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, Sámúẹ́lì jọ́sìn Jèhófà, ó sì tún gbé ìjọsìn Rẹ̀ lárugẹ. Ṣé ohun tí ìwọ náà ń ṣe nìyẹn?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

RONÚ LÓRÍ ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ SÁMÚẸ́LÌ

• Bí àwọn òbí Sámúẹ́lì ṣe fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ ọ, á dára kí ìwọ náà tọ́ àwọn ọmọ rẹ “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.

• Gba àwọn ọmọ rẹ níyànjú pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì nípa fífi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

• Àwọn ànímọ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn tí Sámúẹ́lì ní mú káwọn èèyàn fẹ́ràn rẹ̀, èyí sì mú kó jẹ́ àpẹẹrẹ rere tá a lè tẹ̀ lé.

• Sámúẹ́lì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ, ohun tó sì yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Sámúẹ́lì gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ, ó sì tún fi tinútinú ran àwọn míì lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́