ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 3/1 ojú ìwé 8-12
  • Mò Ń retí Ìjọba Kan Tí “Kì í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mò Ń retí Ìjọba Kan Tí “Kì í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀tẹ̀ Bẹ̀rẹ̀!
  • Wọ́n Fúngun Mọ́ Wa Pé Ká Lọ́wọ́ Nínú Ọ̀tẹ̀ Náà
  • Wọ́n Fi Wa Síbi Tó Léwu Gan-An
  • Ìjà Bẹ̀rẹ̀
  • Ìgbàgbọ́ Wa Nínú Ìjọba Ọlọ́run Kò Yẹ̀
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
  • Mo Dúpẹ́ Pé Àdánwò Kò Mú Kí N dẹ́kun Láti Máa Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Àwọn Ìjọba Bóofẹ́bóokọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìlérí Tí Mo Múra Tán Láti Mú Ṣẹ
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 3/1 ojú ìwé 8-12

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mò Ń retí Ìjọba Kan Tí “Kì í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”

Gẹ́gẹ́ bí Nikolai Gutsulyak ṣe sọ ọ́

Odindi ọjọ́ mọ́kànlélógójì ni mo fi wá láàárín rògbòdìyàn kan tó wáyé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Òjijì ni ìbọn arọ̀jò ọta jí mi lójú oorun. Àwọn ọkọ̀ ogun àtàwọn sójà ya wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wọ́n sì dojú ìjà kọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ẹ̀mí mi wà nínú ewu.

BÁWO ni mo ṣe bára mi nírú ipò yìí? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé. Ọdún 1954 lọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni mí nígbà yẹn. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lábẹ́ ìjọba Soviet ni wọ́n mú nígbà yẹn, wọ́n sì mú èmi náà nítorí pé mi ò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú, mo sì ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àwa ọkùnrin mẹ́rìndínláàádọ́ta àtàwọn obìnrin mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n làwa Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kó sọ́gbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà. Inú ọgbà ẹ̀wọ̀n kan táwọn ẹlẹ́wọ̀n tí máa ń ṣiṣẹ́ bí ẹni máa kú nítòsí abúlé tí wọ́n ń pè ní Kengir láàárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Kazakhstan ni wọ́n kó wa sí. Ibẹ̀ la wà pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn mìíràn tá a jọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n.

Ọ̀gbẹ́ni Joseph Stalin, tó jẹ́ olórí ìjọba Soviet, ti kú ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá rò pé ìjọba tuntun ilẹ̀ Moscow yóò fetí sí ohun táwọn ń sọ nípa ipò tí kò bára dé tí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wà. Inú tó ń bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n nítorí ipò tí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wà wá di ọ̀tẹ̀ gidi nígbà tó yá. Lákòókò tí àríyànjiyàn náà ń lọ lọ́wọ́, àwa Ẹlẹ́rìí jẹ́ káwọn ọlọ̀tẹ̀ tínú ń bí yìí mọ̀ pé a ò lọ́wọ́ sí nǹkan tí wọ́n ń ṣe, a sì tún ṣàlàyé irú ẹni tá a jẹ́ fáwọn ológun tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ohun tá a ṣe yìí gba ìgbàgbọ́ gidi nínú Ọlọ́run.

Ọ̀tẹ̀ Bẹ̀rẹ̀!

Ọ̀tẹ̀ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù May. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé igba [3,200] yarí pé àwọn ò ní ṣiṣẹ́, wọ́n ní àfi tí ìjọba bá mú kí nǹkan dára sí i lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà, kí wọ́n sì fún àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀ràn ìṣèlú ní ẹ̀tọ́ wọn. Bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti ń ṣẹlẹ̀ ni òmíràn ń tẹ̀ lé e. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí kọ́kọ́ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ kúrò ní ọgbà náà. Wọ́n wá lu ihò káàkiri ara ògiri tó yí ọgbà náà ká. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wó àwọn ògiri tíjọba fi ya ibi táwọn obìnrin wà kúrò lára ibi táwọn ọkùnrin wà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọgbà náà di ibi tí tọkùnrin-tobìnrin ti jọ ń gbé lójú kan náà. Kódà, láwọn àkókò tínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ń dùn, àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan fẹ́ ara wọn, àwọn àlùfáà táwọn náà jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n ló sì dárí ìgbéyàwó náà. Láwọn ọgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí rògbòdìyàn náà ti wáyé, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn egbèje [14,000] ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀ ló kópa nínú ọ̀tẹ̀ náà.

Àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣètò ìgbìmọ̀ kan tó máa bá àwọn ológun fikùnlukùn lórí ọ̀ràn náà. Àmọ́, kò pẹ́ tí àríyànjiyàn fi bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn ìgbìmọ̀ náà, bó ṣe di pé àwọn tó ya ẹhànnà jù lọ ló wá ń bójú tó ọ̀rọ̀ tó ń lọ nínú ọgbà yìí nìyẹn. Gbogbo nǹkan túbọ̀ wá ń le sí i. Àwọn tó múpò iwájú nínú ọ̀tẹ̀ náà wá ṣètò onírúurú ẹ̀ka, wọ́n ní ẹ̀ka ètò ààbò, ọkàn fún ogun, àti èyí tó ń bójú tó ìròyìn, kí nǹkan lè máa lọ bí wọ́n ṣe fẹ́. Àwọn tó jẹ́ aṣáájú yìí wá ń lo àwọn gbohùn-gbohùn tí wọ́n gbé kọ́ ara àwọn òpó tí wọ́n ṣe yíká ọgbà náà láti fi polongo àwọn ìròyìn tó ń dáyà jáni gan-an, ìyẹn sì jẹ́ kí ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ náà gbóná janjan. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà kò tiẹ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bọ́ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ń fìyà jẹ ẹni tó bá sọ pé ohun tí wọ́n ń ṣe ò dáa, wọ́n sì sọ pé àwọn múra tán láti pa ẹnikẹ́ni tí kò bá fara mọ́ wọn. A tiẹ̀ gbọ́ pé wọ́n ti pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi mélòó kan.

Nítorí pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí mọ̀ pé ìgbàkigbà làwọn ológun lè dé, wọ́n ti múra sílẹ̀ dáadáa láti gbèjà ara wọn. Kí wọ́n lè rí i dájú pé àwọn tó pọ̀ jù lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà gbára dì láti jà fún ọgbà náà, àwọn tó jẹ́ olórí pàṣẹ pé kí gbogbo ẹlẹ́wọ̀n ní àwọn nǹkan ìjà lọ́wọ́. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá yọ irin ojú àwọn fèrèsé, wọ́n sì fi ṣe ọ̀bẹ àtàwọn ohun ìjà mìíràn. Kódà wọ́n rí àwọn ìbọn àtàwọn nǹkan míì tó lè bú gbàù kó wọlé.

Wọ́n Fúngun Mọ́ Wa Pé Ká Lọ́wọ́ Nínú Ọ̀tẹ̀ Náà

Ìgbà yẹn ni méjì lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà wá bá mi. Ọ̀kan lára wọn na ọ̀bẹ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pọ́n tó sì mú gan-an sí mi. Ó ní: “Gbà eléyìí! Wàá nílò rẹ̀ láti fi dáàbò bo ara rẹ.” Mo rọra gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo wá fèsì pé: “Kristẹni ni mí, mo sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí yòókù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yìí wà níbi nítorí pé àwọn ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí la ń bá jà, a kì í bá àwọn èèyàn jà. Ìgbàgbọ́ wa àti ìrètí tá a ní nínú Ìjọba Ọlọ́run sì ni ohun ìjà wa.”—Éfésù 6:12.

Ẹnu yà mí nígbà tí ọkùnrin náà mi orí rẹ̀ tó ní ọ̀rọ̀ náà ti yé òun. Àmọ́, ẹnì kejì rẹ̀ kàn mí lẹ́ṣẹ̀ẹ́ kan tó lágbára. Àwọn méjèèjì sì bá tiwọn lọ. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà wá ń lọ sínú àwọn ilé tó wà nínú ọgbà náà lọ́kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè fagbára mú àwọn Ẹlẹ́rìí láti lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ọ̀hún. Àmọ́ gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà níbẹ̀ ló kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ó ní lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ náà.

Wọ́n jíròrò ọ̀ràn àìdásí tọ̀túntòsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ọ̀kan lára àwọn ìpàdé táwọn ìgbìmọ̀ ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe. Wọ́n ní: “Gbogbo àwọn tó ń lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì míì ló dara pọ̀ mọ́ wa, àwọn Gba-Jésù wà níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ò gbẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ ìjọ Onítẹ̀bọmi àtàwọn yòókù. Kìkì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ wa. Kí ni ká ṣe fún wọn?” Ẹnì kan dámọ̀ràn pé kí wọ́n ju ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí sínú ààrò tí wọ́n ń dáná sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà kí ẹ̀rù lè ba àwa tó kù. Àmọ́ ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀gá sójà tẹ́lẹ̀, tóun náà ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́ táwọn yòókù sì bọ̀wọ̀ fún gan-an, dìde dúró ó sì sọ pé: “Ìyẹn ò mọ́gbọ́n dání. Ẹ jẹ́ ká kó gbogbo wọn sínú ilé kan tó wà nítòsí géètì àbáwọlé. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà táwọn sójà bá gbógun dé, àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n máa kọ́kọ́ pa. Kò sì sẹ́ni tó máa dá wa lẹ́bi pé àwa la pa wọ́n nígbà yẹn.” Àwọn tó kù fara mọ́ àbá rẹ̀ yìí.

Wọ́n Fi Wa Síbi Tó Léwu Gan-An

Kété lẹ́yìn ìyẹn làwọn ẹlẹ́wọ̀n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri inú ọgbà náà tí wọ́n ń lọgun pé: “Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ jáde síta!” Bí wọ́n ṣe kó gbogbo wa tá a jẹ́ ọgọ́rin lọ sí ilé tó wà nítòsí géètì nìyẹn. Wọ́n kó àwọn bẹ́ẹ̀dì alágbèékà tó wà nínú ilé náà jáde kí ibẹ̀ lè gbà wa, wọ́n sì pàṣẹ fún wa pé ká wọlé. Ilé yẹn wá di ọgbà ẹ̀wọ̀n mìíràn fún wa nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tá a wà.

Kí ọkùnrin àtobìnrin má bàa wà pa pọ̀, àwọn arábìnrin gán àwọn aṣọ kan pọ̀, a sì fi àwọn aṣọ náà pín inú ilé náà sí méjì, ọkàn fún àwa ọkùnrin, èkejì sì jẹ́ ti àwọn obìnrin. (Nígbà tó yá, arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wá ya àwòrán ọgbà yìí, òun ló wà nísàlẹ̀ yìí.) Gbogbo ìgbà la máa ń gbàdúrà pa pọ̀ nígbà tá à ń gbénú ibi tí wọ́n há wa mọ́ yẹn, ńṣe la máa ń bẹ Jèhófà ṣáá pé kó fún wa ní ọgbọ́n àti “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́ríńtì 4:7.

Ní gbogbo àkókò yẹn, ibi tó léwu jù lọ ni wọ́n fi wá sí, a wà láàárín àwọn ọlọ̀tẹ̀ àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Soviet. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó mọ ohun tí ìhà kọ̀ọ̀kan lè ṣe. Arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń sìn Jèhófà tọkàntọkàn wá sọ fún wa pé: “Ẹ má wulẹ̀ máa ronú nípa ìyẹn. Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀.”

Àwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n, àtọ̀dọ́ àtarúgbó, lo ìfaradà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọ̀kan lára wọn jẹ́ ẹni nǹkan bí ọgọ́rin ọdún, ó sì nílò ìrànlọ́wọ́ gidi. Àwọn mìíràn wà níbẹ̀ tí wọ́n ń ṣàìsàn tí wọ́n sí nílò oníṣègùn tó máa tọ́jú wọn. Ní gbogbo àkókò yẹn, ńṣe ni wọ́n ṣílẹ̀kùn ilé tí wọ́n kó wá sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà sílẹ̀ gbayawu káwọn ọlọ̀tẹ̀ náà lè máa rí gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ní àwọn ohun ìjà lọ́wọ́ máa ń wá síbi tí wọ́n kó wá sí yìí lóru. A máa ń gbọ́ tí wọ́n máa ń sọ nígbà mìíràn pé, “Ìjọba Ọlọ́run ti sùn.” Tí wọ́n bá jẹ́ ká lọ síbi tá a ti ń jẹun lọ́sàn, ńṣe ni gbogbo wa máa ń kóra wa jọ síbì kan tá a ó sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn.

A gbìyànjú láti máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbéra wa ró nínú àwọn ilé ẹ̀wọ̀n náà. Bí àpẹẹrẹ, Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn arákùnrin máa ń sọ ìtàn kan látinú Bíbélì, wọ́n á sì sọ ọ́ sókè ketekete kí gbogbo wa lè gbọ́ ohun tó ń sọ. Wọ́n á wá sọ bí ìtàn náà ṣe bá ipò wa mu. Arákùnrin àgbàlagbà kan sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ogun Gídíónì. Ó máa ń rán wa létí pé: “Ní orúkọ Jèhófà, àwọn ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkùnrin tí wọ́n mú àwọn ohun èlò orin lọ́wọ́ bá àwọn ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje [135,000] jagunjagun tó dìhámọ́ra ogun jà. Gbogbo àwọn ọ̀ọ́dúnrún náà ló sì padà wálé láìfarapa.” (Àwọn Onídàájọ́ 7:16, 22; 8:10) Èyí àtàwọn àpẹẹrẹ mìíràn nínú Bíbélì gbé ìgbàgbọ́ wa ró gan-an. Kò tíì pẹ́ rárá tí mo di Ẹlẹ́rìí nígbà yẹn, àmọ́ bí mo ṣe rí ìgbàgbọ́ tó lágbára táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti pẹ́ nínú ètò fi hàn, èyí fún mi níṣìírí gan-an. Mo rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa lóòótọ́.

Ìjà Bẹ̀rẹ̀

Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan túbọ̀ ń le sí i nínú ọgbà náà. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó ń lọ láàárín àwọn ọlọ̀tẹ̀ àtàwọn aláṣẹ túbọ̀ ń le sí i. Àwọn tó jẹ́ aṣáájú nínú àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn yarí pé àfi kí ìjọba ilẹ̀ Moscow rán àwọn aṣojú wá láti bá àwọn sọ̀rọ̀. Àwọn aláṣẹ ní tiwọn ń sọ pé káwọn ọlọ̀tẹ̀ náà jáwọ́ nínú wàhálà, kí wọ́n kó àwọn ohun ìjà tó wà lọ́wọ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì padà sẹ́nu iṣẹ́. Kò sí èyí tó múra tán lára wọn láti jáwọ́ nínú wàhálà náà. Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn sójà tí ko ohun ìjà ogun yí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ká, wọ́n múra láti bẹ̀rẹ̀ ìjà nígbàkigbà táwọn aláṣẹ bá sọ pé ó yá. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá ti múra ìjà, wọ́n ti mọ àwọn odi láti dènà àwọn sójà náà wọ́n sì ti kó àwọn ohun ìjà jọ pelemọ. Oníkálukú wa mọ̀ pé ìgbàkígbà ni gbẹgẹdẹ lè gbiná láàárín àwọn sójà àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n.

Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù June, ìró àwọn ìbọn arọ̀jò ọta tó ń dún kíkankíkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dini létí ló jí wa lójú oorun. Àwọn ọkọ̀ ogun wó àwọn ògiri tó yí ọgbà náà ká wọn sì wọnú ọgbà náà. Bí àwọn ọmọ ogun ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn nìyẹn tí ẹ̀rọ arọ̀jò ọta sì ń dún kíkankíkan. Ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà bá bẹ̀rẹ̀ tiwọn, tọkùnrin tobìnrin wọn ń sáré lọ síwájú àwọn ọkọ̀ ogun tó ń wọlé bọ̀, bí wọ́n ṣe ń hó yèè ni wọ́n ń ju òkò, tí wọ́n ń ju bọ́ǹbù táwọn fúnra wọn ṣe, àti ohunkóhun mìíràn tọ́wọ́ wọ́n bá ṣáà ti tẹ̀. Ìjà líle wá bẹ̀rẹ̀, àárín méjì àwọn tó ń bára wọn jà làwa Ẹlẹ́rìí sì wà. Báwo ni Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà tá a gbà pé kó ràn wá lọ́wọ́?

Òjijì làwọn sójà ya bo ibi tá a wà. Wọ́n ní: “Ẹ jáde síta, ẹ̀yìn ẹni mímọ́! Ẹ ṣe kíá kẹ́ ẹ jáde kúrò nínú ọgbà yìí!” Ọ̀gá tó ń darí wọn sọ fáwọn sójà náà pé wọn ò gbọ́dọ̀ yìnbọn sí wa, àmọ́ kí wọ́n ṣáà dúró tì wá kí wọ́n sì dáàbò bò wá. Ní gbogbo àkókò tógun yẹn ń lọ lọ́wọ́, ìta gbangba la wà tá a jókòó sórí koríko tá a ń wo ọgbà náà lọ́ọ̀ọ́kán. Odindi wákàtí mẹ́rin la fi ń gbọ́ ìró àwọn ohun abúgbàù, tí ìbọn ń dún, táwọn èèyàn ń lọgun, tá a sì ń gbọ́ báwọn kan ṣe ń sunkún kíkorò nínú ọgbà náà. Nígbà tó yá, gbogbo rẹ̀ dákẹ́ wẹ́lo. Nígbà tí ilẹ̀ wá mọ́, a rí àwọn sójà tí wọ́n ń kó àwọn òkú jáde látinú ọgbà náà. A gbọ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló fara pa, àwọn mìíràn sì kú.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀gá kan tí mo mọ̀ dáadáa wá bá wa. Ó ń yangàn, ó wá bi mí pé: “Nikolai, ta ló gbà yín là? Ṣé Jèhófà ni àbí àwa?” A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gan-an pé ó dáàbò bò wá, a wá fi kún un pé, “Ó dá wa lójú pé Jèhófà, Ọlọ́run wa Olódùmarè ló mú kó o dáàbò bò wá, bó ṣe lo àwọn èèyàn láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lákòókò tá a kọ Bíbélì.”—Ẹ́sírà 1:1, 2.

Ọ̀gá kan náà yìí ló wá jẹ́ ká mọ báwọn sójà yẹn ṣe mọ irú ẹni tá a jẹ́ àti ibi tá a wà. Ó sọ pé lákòókò tí ìjíròrò fi ń wáyé láàárín àwọn ológun àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn, àwọn ológun fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ̀tẹ̀ pé wọ́n ń pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí kò bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ náà. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà wá sọ pé rárá o, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ó ṣáà dá sí rògbòdìyàn yìí, a ò sì pa wọ́n. Ìyà tá a kàn fi jẹ wọ́n ò ju pé a ti gbogbo wọn mọ́nú ilé kan lára àwọn ilé tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà. Àwọn ọ̀gá ológun ò sì gbàgbé ohun táwọn ọlọ̀tẹ̀ náà sọ yìí.

Ìgbàgbọ́ Wa Nínú Ìjọba Ọlọ́run Kò Yẹ̀

Ọ̀gbẹ́ni Aleksandr Solzhenitsyn, tó jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó, mẹ́nu kan ọ̀tẹ̀ tó wáyé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yìí nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Gulag Archipelago. Ọ̀nà tó gbà kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà sílẹ̀ rèé, ó ní ọ̀tẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ nítorí pé “a fẹ́ òmìnira, . . . àmọ́ ta ló lè fún wa ní òmìnira?” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn náà fẹ́ òmìnira. Àmọ́ kì í kàn án ṣe òmìnira kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nìkan, bí kò ṣe òmìnira tí Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo lè fúnni. Lákòókò tá a wà lẹ́wọ̀n yẹn, a mọ̀ pé a nílò okun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ìjọba rẹ̀ má bàá yẹ. Jèhófà sì pèsè gbogbo ohun tá a nílò fún wa. Ó jẹ́ ká ṣẹ́gun láìlo ọ̀bẹ tàbí àwọn ohun ìjà mìíràn.—2 Kọ́ríńtì 10:3.

Jésù Kristi sọ fún Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà.” (Jòhánù 18:36) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá, a kì í dá sí ohunkóhun tó jẹ́ mọ́ ọ̀ràn ìṣèlú. Inú wa dùn pé ní gbogbo àkókò rògbòdìyàn yẹn, àwọn èèyàn rí i kedere pé Ìjọba Ọlọ́run la rọ̀ mọ́. Ohun tí Solzhenitsyn kọ nípa ìwà wa lákòókò náà rèé, ó ní: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò bẹ̀rù láti pa gbogbo ìlànà ẹ̀sìn wọn mọ́, wọ́n sì kọ̀ láti mọ odi tàbí kí wọ́n ṣe ibi ààbò fúnra wọn.”

Ó ti lé ni àádọ́ta ọdún báyìí tí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yẹn ti wáyé. Àmọ́, mo sábà máa ń ronú nípa àkókò yẹn, mo sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí pé mo kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò ṣeé gbàgbé, àwọn ẹ̀kọ́ bíi kéèyàn dúró de Jèhófà kó sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú agbára rẹ̀ tí kò láfiwé. Láìsí àní-àní, bíi ti ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí tá a jọ wà lábẹ́ ìjọba Soviet, mo ti rí i pé lóòótọ́, Jèhófà máa ń fúnni ní òmìnira, ó sì máa ń pèsè ààbò àti ìdáǹdè fún àwọn tó dúró de Ìjọba tí “kì í ṣe apá kan ayé yìí.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Àgọ́ ìfìyàjẹni tí wọ́n kó wa sí nílùú Kazakhstan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwòrán ibi tí wọ́n kó àwa Ẹlẹ́rìí sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, apá ibi táwọn obìnrin wà rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Èmi àtàwọn arákùnrin yòókù lẹ́yìn tá a kúrò lẹ́wọ̀n

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́