Wessel Gansfort “Ẹni Tó Ti Bẹ̀rẹ̀ Àtúnṣe Ìsìn Káwọn Alátùn-únṣe Tó Dé”
Gbogbo àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ nípa Àtúnṣe Ìsìn Ti Pùròtẹ́sítáǹtì, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1517, ló mọ àwọn orúkọ bíi Luther, Tyndale, àti Calvin bí ẹní mowó. Àmọ́ ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ Wessel Gansfort. Òun ni wọ́n pè ní “Ẹni tó ti bẹ̀rẹ̀ Àtúnṣe Ìsìn káwọn Alátùn-únṣe tó dé.” Ṣé wàá fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa ọkùnrin yìí?
ỌDÚN 1419 ni wọ́n bí Wessel ní ìlú kan tó ń jẹ́ Groningen lórílẹ̀-èdè Netherlands. Ní ọ̀rúndún karùndínlógún yẹn, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló láǹfààní àtilọ sílé ìwé, àmọ́ Wessel lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀wé gan-an, síbẹ̀ ó di dandan kó kúrò nílé ìwé nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án nítorí pé tálákà paraku làwọn òbí rẹ̀. Àmọ́, obìnrin opó kan tó jẹ́ olówó gbọ́ pé Wessel mọ̀wé gan-an, ló bá ní òun á san owó ilé ìwé rẹ̀. Bí Wessel tún ṣe ń bá ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ nìyẹn. Nígbà tó yá, ó gboyè kejì nílé ẹ̀kọ́ Yunifásítì. Ó dà bíi pé ó tún gba oyè ọ̀mọ̀wé nínú ẹ̀kọ́ ìsìn lẹ́yìn náà.
Ńṣe ni Wessel fẹ́ máa ní ìmọ̀ kún ìmọ̀ ni ṣáá. Àmọ́, àwọn ibi téèyàn ti lè rí ìwé kà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nígbà ayé rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí wọ́n máa ń to àwọn lẹ́tà rẹ̀, síbẹ̀ ọwọ́ ni wọ́n ṣì ń fi kọ ọ̀pọ̀ jù lọ ìwé tí wọ́n ń ṣe jáde nígbà yẹn, àwọn ìwé náà sì gbówó lórí gan-an. Wessel wà lára àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé kan tí wọ́n máa ń ti ibi ìkówèésí kan dé òmíràn tí wọ́n sì máa ń lọ sáwọn ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, tí wọ́n máa ń wá àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ kiri àtàwọn ìwé táyé ti gbàgbé tipẹ́. Gbogbo wọn á wá jọ sọ ohun tí wọ́n rí kọ́ látinú àwọn ìwé náà fún ara wọn. Wessel ní ìmọ̀ tó pọ̀ gan-an débi pé ó kọ ọ̀pọ̀ àyọlò ọ̀rọ̀ àtàwọn àyọkà látinú àwọn ìwé Gíríìkì àti ti Látìn ayé ọjọ́un sínú ìwé kan tó ń lò fúnra rẹ̀. Ara àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kì í balẹ̀ níbi tí Wessel bá wà nítorí pé ó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn fúnra wọn ò gbọ́ rí. Ọ̀gá Nínú Àtakò ni wọ́n máa ń pe Wessel.
“Kí Ló Dé Tí O Kò Darí Mi Sọ́dọ̀ Kristi?”
Ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún ṣáájú ìgbà táwọn Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Wessel pàdé Thomas à Kempis (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 1379 sí 1471). Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ọkùnrin yìí ló kọ ìwé De Imitatione Christi (Aláfarawé Kristi), táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa. Thomas à Kempis wà nínú ẹgbẹ́ Brethren of the Common Life, ìyẹn àjọ kan tó máa ń tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti gbé ìgbésí ayé olùfọkànsìn Ọlọ́run. Ẹnì kan tó kọ ìtàn ìgbésí ayé Wessel sílẹ̀ sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Thomas à Kempis gba Wessel níyànjú pé kó yíjú sí Màríà fún ìrànlọ́wọ́. Èsì tí Wessel máa ń fún un ni pé: “Kí ló dé tí o kò darí mi sọ́dọ̀ Kristi, ẹni tó fìfẹ́ ké sí gbogbo àwọn tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun?”
A gbọ́ pé Wessel kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò fẹ́ oyè àlùfáà. Nígbà tí wọ́n béèrè ìdí tí kò fi gé irun rẹ̀ lápá kan òrí, èyí tí wọ́n fi ń dá àwọn àlùfáà mọ̀, ó fèsì pé níwọ̀n ìgbà tó bá ti jẹ́ pé orí òun ò dàrú, òun ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, pé tí wọ́n bá máa yẹgi fóun kí wọ́n yáa yẹgi fóun. Ó dájú pé ohun tó ń sọ ni pé wọn kì í pe ẹni tí wọ́n bá ti fi joyè àlùfáà lẹ́jọ́. Irun tí wọ́n máa ń gé lápá kan orí yẹn sì ti gba ọ̀pọ̀ àlùfáà tó yẹ kí wọ́n ti yẹgi fún sílẹ̀. Wessel ò tún fara mọ́ àwọn àṣà kan tó wọ́pọ̀ nínú àwọn ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó kọ̀ láti gbà pé òótọ́ làwọn iṣẹ́ ìyanu kan tí wọ́n kọ sínú ìwé kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ dáadáa lákòókò yẹn ṣẹlẹ̀, wọ́n pe ìwé náà ní Dialogus Miraculorum. Ohun tó sọ fún wọn ni pé: “Ó kúkú sàn kéèyàn ka ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́.”
“Bí A Bá Ṣe Béèrè Ìbéèrè Tó La Ṣe Máa Mọ̀ Tó”
Wessel kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Hébérù àti Gíríìkì, ó sì ní ìmọ̀ tó pọ̀ gan-an nípa àwọn ìwé táwọn Baba Ìsàlẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì ayé ìgbàanì kọ. Ìfẹ́ tó ní sí èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ jọni lójú gan-an, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ó gbé ayé ṣáájú àwọn èèyàn bíi Erasmus àti Reuchlin.a Ìmọ̀ nípa èdè Gíríìkì kò wọ́pọ̀ rárá ṣáájú àkókò tí Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn. Ìwọ̀nba àwọn ọ̀mọ̀wé díẹ̀ péré ló mọ̀ nípa èdè Gíríìkì nílẹ̀ Jámánì, kò sì sáwọn ìwé tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kọ́ èdè náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun ìlú Kọnsitantinópù lọ́dún 1453, ó dà bíi pé Wessel bá àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì pàdé, tí wọ́n sá wá sí ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ó sì kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀díẹ̀ tó rọrùn láti mọ̀ nínú èdè Gíríìkì lọ́dọ̀ wọn. Láyé ìgbà yẹn, kìkì àwọn Júù nìkan ló máa ń sọ èdè Hébérù, ó sì dà bíi pé Wessel kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀díẹ̀ nínú èdè Hébérù látọ̀dọ̀ àwọn Júù tó di Kristẹni.
Wessel nífẹ̀ẹ́ Bíbélì gan-an. Ó kà á sí ìwé kan tí Ọlọ́run mí sí, ó sì nígbàgbọ́ pé kò sí èyí tó ta ko ara wọn nínú gbogbo ìwé tó wà nínú Bíbélì. Wessel gbà pé ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì gbọ́dọ̀ bá àwọn ọ̀rọ̀ tó yí wọn ká mu, èèyàn ò sì gbọ́dọ̀ túmọ̀ wọn lọ́nà òdì. Ó sì gbà pé ó yẹ kí wọ́n ka àlàyé èyíkéyìí tí kò bá bá Bíbélì mu sí ẹ̀kọ́ èké. Ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó fẹ́ràn jù lọ ni Mátíù 7:7, tó kà pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí.” Tìtorí ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni Wessel ṣe gbà gbọ́ pé ó dáa kéèyàn máa béèrè ìbéèrè. Èrò rẹ̀ ni pé “bí a bá ṣe béèrè ìbéèrè tó la ṣe máa mọ̀ tó.”
Ó Tọrọ Ohun Kan Tó Yani Lẹ́nu
Wessel lọ sí Róòmù lọ́dún 1473. Ibẹ̀ ni wọ́n ti fún un láyè láti bá Póòpù Sixtus Kẹrin sọ̀rọ̀. Póòpù yìí ni ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn póòpù mẹ́fà tí ìwà ìbàjẹ́ wọn pàpọ̀jù débi táwọn èèyàn kan fi dá Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn ti Pùròtẹ́sítáǹtì sílẹ̀. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Barbara W. Tuchman sọ pé Sixtus Kẹrin ló bẹ̀rẹ̀ àṣà “káwọn póòpù máa wá èrè àti agbára ìṣèlú lójú méjèèjì láìtiẹ̀ tijú rárá, tí wọn ò sì fi bò.” Gbogbo èèyàn ni ojúsàájú tó máa ń ṣe sí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ máa ń ṣe ní kàyéfì. Òpìtàn kan kọ̀wé pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Sixtus fẹ́ sọ oyè póòpù di òye ìdílé. Ṣàṣà làwọn tó láyà láti sọ pé ohun tó ń ṣe yìí ò dáa.
Àmọ́, Wessel Gansfort yàtọ̀ pátápátá ní tiẹ̀. Lọ́jọ́ kan, Sixtus sọ fún un pé: “Ọmọ mi, béèrè ohunkóhun tó o bá fẹ́, a ó sì fi fún ọ.” Kíá ni Wessel fèsì pé: “Baba mímọ́, . . . níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀yìn lẹ wà nípò àlùfáà àti olùṣọ́ àgùntàn tó ga jù lọ láyé yìí, mo bẹ̀ yín . . . pé kẹ́ ẹ lo ipò gíga tẹ́ ẹ wà yìí lọ́nà tó jẹ́ pé nígbà tí Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá àwọn àgùntàn . . . bá dé, á lè sọ fún un yín pé: ‘Ó káre láé, olóòótọ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rere, bọ́ sínú ayọ̀ Ọ̀gá rẹ.’” Sixtus wá dá a lóhùn pé, ojúṣe tòun nìyẹn, pé ńṣe ni kí Wessel béèrè ohun tó bá fẹ́. Wessel wá sọ pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mo fẹ́ kẹ́ ẹ fún mi ní Bíbélì èdè Gíríìkì àti ti Hébérù kan látinú ibi ìkówèésí ti Ìjọba Póòpù.” Póòpù yìí fún Wessel lóhun tó sọ pé òun fẹ́ yìí, àmọ́ ó wá sọ fún un pé ohun tó tọrọ yẹn kò mọ́gbọ́n dání rárá, pé ńṣe ló yẹ kó sọ pé kí wọ́n fi òun joyè bíṣọ́ọ̀bù!
“Irọ́ àti Ìṣìnà”
Nítorí pé Sixtus ń wá owó lójú méjèèjì láti fi kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Sistine tó wá lókìkí gan-an báyìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gba owó àdúrà ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òkú. Àwọn èèyàn sì wá fara mọ́ owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yìí gan-an. Ìwé kan tí wọ́n pè ní Vicars of Christ—The Dark Side of the Papacy sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Àwọn opó àtàwọn ọkùnrin tí ìyàwó wọn kú, títí kan àwọn òbí tó pàdánù àwọn ọmọ wọn wá bẹ̀rẹ̀ sí í ná gbogbo owó tí wọ́n ní káwọn èèyàn wọn tó ti kú lè jáde kúrò ní pọ́gátórì, ìyẹn ibi tí wọ́n gbà pé àwọn òkú ti ń joró.” Àwọn tó gbà pé póòpù lágbára láti mú káwọn èèyàn wọn tó ti kú lọ sọ́run fara mọ́ sísan owó àdúrà ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òkú.
Àmọ́, Wessel gbà pé Ìjọ Kátólíìkì, títí kan póòpù pàápàá, kò lágbára láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ẹnikẹ́ni. Wessel là á mọ́lẹ̀ kedere pé owó àdúrà ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń gbà yìí jẹ́ “irọ́ àti ìṣìnà.” Bẹ́ẹ̀ náà ni kò gbà gbọ́ pé jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn àlùfáà pọn dandan kéèyàn tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.
Wessel tún sọ pé irọ́ gbuu ni pé póòpù kò lè ṣàṣìṣe. Ó ní ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì yóò mẹ́hẹ tí wọ́n bá retí pé káwọn èèyàn máa gba ohun táwọn póòpù bá sọ gbọ́ ní gbogbo ìgbà, nítorí pé àwọn póòpù náà máa ń ṣàṣìṣe. Wessel kọ̀wé pé: “Bí àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì bá pa àṣẹ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tí wọ́n wá ń tẹ̀ lé àwọn àṣẹ àtọwọ́dọ́wọ́ ara wọn, . . . a jẹ́ pé ohun tí wọn ń ṣe àti àṣẹ tí wọ́n ń gbé kalẹ̀ kò ṣàǹfààní kankan nìyẹn.”
Wessel La Ọ̀nà Sílẹ̀ fún Àtúnṣe Ìsìn
Wessel kú lọ́dún 1489. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tako àwọn ohun kan tí kò dára tí ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe, síbẹ̀ kò fi ìjọ Kátólíìkì sílẹ̀. Ṣọ́ọ̀ṣì náà ò sì fìgbà kan fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ ohun tó lòdì sí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́, lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tí wọ́n gbé ọ̀ràn ẹ̀sìn karí nínú ìjọ Kátólíìkì gbìyànjú láti kó àwọn ìwé tó kọ dà nù nítorí pé wọ́n gbà pé àwọn ìwé náà lòdì sáwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Luther, orúkọ Wessel ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ohun ìgbàgbé pátápátá, kò sí èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú gbogbo ìwé tó kọ, ìwọ̀nba díẹ̀ ló sì ṣẹ́ kù lára àwọn ìwé tó fọwọ́ kọ. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n tẹ apá àkọ́kọ́ lára àwọn ìwé Wessel jáde láàárín ọdún 1520 sí 1522. Lẹ́tà tí Luther kọ tó fi ní kí wọ́n tẹ àwọn ìwé Wessel jáde sì wà nínú rẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Wessel kì í ṣe Alátùn-únṣe Ìsìn bíi ti Luther, ó jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé òun kò fara mọ́ àwọn kan lára àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni, ìyẹn ló sì wá yọrí sí dídá tí wọ́n wá dá Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn sílẹ̀ níkẹyìn. Kódà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tí McClintock àti Strong ṣe jáde sọ pé òun ni “ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo àwọn ará Jámánì tó ṣèrànwọ́ láti la ọ̀nà sílẹ̀ fún Àtúnṣe Ìsìn.”
Luther rí i pé Wessel jẹ́ ẹnì kan tí ìrònú rẹ̀ bá ti òun mu. Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ C. Augustijn sọ nínú ìwé rẹ̀ pé: “Luther fi àkókò tiẹ̀ àtohun tójú rẹ̀ rí wé ti Èlíjà. Bí wòlíì yẹn ṣe rò pé òun nìkan ṣoṣo ló ṣẹ́ kù láti ja ogun Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ni Luther ṣe rò pé òun nìkan ṣoṣo ló ń gbógun ti àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni. Àmọ́ nígbà tó wá ka àwọn ìwé tí Wessel kọ, ó wá rí i pé Olúwa ti dáàbò bo ‘àṣẹ́kù kékeré ní Ísírẹ́lì.’” “Luther tiẹ̀ bá ọ̀rọ̀ náà débi tó fi sọ pé: ‘Ká ní mo ti ka àwọn ìwé tí Wessel kọ ni, àwọn ọ̀tá mi ì bá rò pé ọ̀dọ̀ Wessel ni Luther ti kọ́ gbogbo ohun tó ń sọ, ẹ̀mí tó ní àti ìrònú rẹ̀ bá tèmi mu gan-an.’”b
‘Ẹ Ó sì Rí I’
Nígbà tí Àtúnṣe Ìsìn bẹ̀rẹ̀, kì í ṣe pé ó ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Onírúurú èrò táwọn èèyàn ní tó wá yọrí sí Àtúnṣe Ìsìn yẹn ti ń jà ràn-ín nílẹ̀ fúngbà díẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn. Wessel mọ̀ pé bópẹ́bóyá ìwà ìbàjẹ́ àwọn póòpù máa yọrí sí dídá àtúnṣe ìsìn sílẹ̀. Nígbà kan, ó sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ kan pé: “Ìwọ ọmọ tó o fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ yìí, ojú rẹ ló máa ṣe lọ́jọ́ kan nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tòótọ́ kò ní fara mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn . . . kìígbọ́-kìígbà ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Wessel rí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ èké náà àtàwọn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń hù nígbà ayé rẹ̀, síbẹ̀ kò ṣeé ṣe fún un láti ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Àmọ́, ó gbà pé Bíbélì jẹ́ ìwé kan téèyàn gbọ́dọ̀ kà kó sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ìwé kan tí wọ́n pè ní A History of Christianity, sọ pé Wessel “gbà pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ ló darí àwọn tó kọ Bíbélì, ohun tó bá sọ la gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé lórí ọ̀ràn ìsìn.” Láyé òde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí. (2 Tímótì 3:16) Àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì ò fara sin mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣòro láti rí. Òde òní gan-an la wá rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí.”—Mátíù 7:7; Òwe 2:1-6.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣe bẹbẹ láti mú káwọn èèyàn kọ́ èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Lọ́dún 1506, Reuchlin tẹ ìwé kan jáde tó dá lórí gírámà èdè Hébérù, ìyẹn ló wá jẹ́ káwọn èèyàn lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù jinlẹ̀jinlẹ̀. Erasmus náà tẹ ìwé kan tó ní gbogbo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì jáde lọ́dún 1516.
b Ìwé Wessel Gansfort (1419-1489) àti Northern Humanism, ojú ìwé 9 àti 15.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
BÍ WESSEL ṢE LO ORÚKỌ ỌLỌ́RUN
Ọ̀nà tí Wessel gbà kọ orúkọ Ọlọ́run lọ́pọ̀ ibi tó ti fara hàn nínú ìwé rẹ̀ ni “Johavah.” Àmọ́ Wessel lo “Jèhófà” ní ibi méjì ó kéré tán. Nígbà tí òǹkọ̀wé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ H.A Oberman ń sọ̀rọ̀ nípa èrò tí Wessel ní, ohun tó sọ ni pé, Wessel lérò pé ká ní Thomas Aquinas àtàwọn mìíràn ti mọ èdè Hébérù dáadáa ni, “wọn ì bá mọ̀ pé orúkọ tí Ọlọ́run sọ fún Mósè pé òun ń jẹ́ kò túmọ̀ sí ‘Èmi ni ẹni tí èmi jẹ́,’ bí kò ṣe ‘Èmi yóò jẹ́ ẹni tí èmi yóò jẹ́.’”c Ọ̀nà tí Ìtumọ̀ Ayé Tuntun gbà túmọ̀ rẹ̀ dára gan-an, ó ní “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.”—Ẹ́kísódù 3:13, 14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Wessel Gansfort (1419-1489) and Northern Humanism, ojú ìwé 105.
[Credit Line]
Ìwé àfọwọ́kọ: Universiteitsbibliotheek, Utrecht
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Wessel sọ pé kò tọ̀nà láti máa gba owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí Póòpù Sixtus Kẹrin fọwọ́ sí