Wọ́n Láyọ̀ Láti Dúró De Jèhófà
ǸJẸ́ o ti jẹ èso tí kò pọ́n rí? Kò sí àní-àní pé bó ṣe rí lẹ́nu rẹ kò dára rárá. Ó máa ń gba àkókò kí èso tó pọ́n, ó sì dájú pé ó dára kéèyàn dúró kí èso pọ́n kó tó jẹ ẹ́. Àwọn ipò mìíràn tún wà tó jẹ́ pé ó dára gan-an kéèyàn ní sùúrù. Bíbélì sọ pé: “Ó dára kí ènìyàn dúró, àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, de ìgbàlà Jèhófà.” (Ìdárò 3:26; Títù 2:13) Àwọn ipò wo làwọn Kristẹni ti gbọ́dọ̀ dúró de Jèhófà? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú dídúró dè é?
Kí Ni Dídúró De Ọlọ́run Túmọ̀ Sí?
Àwa Kristẹni ń ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà a sì ń fi sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ À ń retí àtirí ìtura nígbà tó bá mú “ìparun [wá sórí] àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:7, 12) Ó wà lọ́kàn Jèhófà fúnra rẹ̀ láti pa gbogbo ohun tó jẹ́ ibi run, àmọ́ ìdí tí kò tíì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ó fẹ́ gba àwọn Kristẹni là lọ́nà tí yóò fògo fún orúkọ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ ní ìfẹ́ láti fi ìrunú rẹ̀ hàn gbangba, kí ó sì sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, . . . fi ọ̀pọ̀ ìpamọ́ra fàyè gba àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun, kí ó bàa lè sọ àwọn ọrọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú.” (Róòmù 9:22, 23) Bí Jèhófà ti ṣe nígbà ayé Nóà, ó mọ ìgbà tó yẹ láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là. (1 Pétérù 3:20) Nípa báyìí, dídúró de Ọlọ́run túmọ̀ sí pé ká dúró de àkókò tó ní lọ́kàn láti gbà wá là.
Bá a ti ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, inú wa lè bà jẹ́ nígbà míì tá a bá rí i tí ìwà àwọn èèyàn túbọ̀ ń burú sí i. Nírú àkókò yẹn, ó dára ká ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Míkà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run kọ sílẹ̀ pé: “Ẹni ìdúróṣinṣin ti ṣègbé kúrò lórí ilẹ̀ ayé, kò sì sí ẹni adúróṣánṣán nínú aráyé.” Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Míkà 7:2, 7) Kí ni “ẹ̀mí ìdúródeni” tó yẹ ká ní yìí? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, dídúró de nǹkan máa ń tánni ní sùúrù, báwo la ṣe lè láyọ̀ bá a ti ń dúró de Ọlọ́run?
Bá A Ṣe Lè Láyọ̀ Bá A Ti Ń Dúró De Jèhófà
A lè kọ́ bá a ṣe lè ní ẹ̀mí tó tọ́ látinú àpẹẹrẹ ti Jèhófà. Kò sígbà kan tí Jèhófà kò jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Ó láyọ̀ bó ti ń ní sùúrù, nítorí pé ó ń báṣẹ́ lọ láti mú ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé ṣẹ, ìyẹn ni láti mú kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ di ẹni pípé, bó ṣe fẹ́ kí èèyàn rí nígbà tó dá wọn níbẹ̀rẹ̀. (Róòmù 5:12; 6:23) Ó sì ń rí àwọn àbájáde tó ń múnú rẹ̀ dùn látinú iṣẹ́ rẹ̀. Ìdí ni pé, ọ̀pọ̀ yanturu èèyàn ló ń wá sínú ìjọsìn tóótọ́. Jésù sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” (Jòhánù 5:17) Ṣíṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíràn máa ń múni láyọ̀. (Ìṣe 20:35) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí pẹ̀lú àwọn Kristẹni tòótọ́ nìyẹn, wọn ò káwọ́ gbera bí wọ́n ti ń dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń bá iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nìṣó, káwọn èèyàn lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé.
Ó pẹ́ táwọn olóòótọ́ ti máa ń yin Ọlọ́run láìráhùn bí wọ́n ti ń dúró de ìgbà tí yóò gbà wọ́n là. Wo àpẹẹrẹ Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù. Ọba tó ń ṣàkóso lákòókò yẹn ṣenúnibíni sí Dáfídì, ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ finú tán ara wọn dà á, ọmọ òun fúnra rẹ̀ sì tún kẹ̀yìn sí i. Ní gbogbo àkókò tí Dáfídì fi wà nínú àwọn ìṣòro yìí, ǹjẹ́ ó láyọ̀ bó ti ń dúró de Jèhófà láti mú ìtura wá lákòókò tó tọ́ lójú rẹ̀? Sáàmù kọkànléláàádọ́rin, tó dájú pé Dáfídì ló kọ̀ ọ́, sọ pé: “Ní tèmi, èmi yóò máa dúró nígbà gbogbo, ṣe ni èmi yóò sì máa fi kún gbogbo ìyìn rẹ. Ẹnu mi yóò máa ròyìn òdodo rẹ lẹ́sẹẹsẹ, ìgbàlà rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 71:14, 15) Dípò kínú Dáfídì bà jẹ́ bó ti ń dúró de àkókò Jèhófà, ó láyọ̀, nítorí ńṣe ló ń yin Jèhófà tó sì ń ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìjọsìn tòótọ́.—Sáàmù 71:23.
Dídúró de Jèhófà kò dà bí ìgbà téèyàn ń dúró de bọ́ọ̀sì tí kò tètè dé, tí inú sì ń bíni. A lè fi wé bí àwọn òbí ṣe máa ń ní sùúrù tayọ̀tayọ̀ bí ọmọ wọn ti ń dàgbà dẹni tí wọ́n lè fi yangàn. Ní gbogbo ọdún tọ́mọ náà ń dàgbà yẹn, ọwọ́ wọn máa ń dí lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́, fífún un nítọ̀ọ́ni, àti bíbá a wí, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ torí kọ́mọ wọn lè jẹ́ ọmọ tó yàn tó yanjú. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwa tí à ń dúró de Jèhófà, ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run ń fún wa láyọ̀. Àwa náà sì fẹ́ láti rí ojú rere Ọlọ́run ká sì rí ìgbàlà níkẹyìn.
Ohun Tí Kò Ní Jẹ́ Ká Sọ̀rètí Nù
Dídúró de Jèhófà túmọ̀ sí pé ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ká sì máa sìn ín láìjáwọ́. Èyí lè ṣòro. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ló ń gbé láwọn ibi tó jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn máa ń fini ṣe yẹ̀yẹ́ téèyàn bá ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run. Àmọ́, ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́, tí wọn ò sọ̀rètí nù ní gbogbo àkókó tí wọ́n wà nígbèkùn fún àádọ́rin ọdún nílẹ̀ Bábílónì. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Kò sí àní-àní pé kíka ìwé Sáàmù mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Sáàmù kan tó ń fúnni níṣìírí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àárín àkókò yẹn ni wọ́n kọ ọ́, sọ pé: “Mo sì ti dúró de ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọkàn mi ti dúró de Jèhófà ju bí àwọn olùṣọ́ ti ń dúró de òwúrọ̀, tí wọ́n ń wọ̀nà fún òwúrọ̀. Kí Ísírẹ́lì máa bá a nìṣó ní dídúró de Jèhófà.”—Sáàmù 130:5-7.
Àwọn Júù tí wọn ò sọ̀rètí nù, tí wọ́n ń kà nípa ìrètí wọn tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, rí èrè nígbà táwọn ọ̀tá ṣẹ́gun ilẹ̀ Bábílónì níkẹyìn. Kíá ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù tó jẹ́ olóòótọ́ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò padà sí Jerúsálẹ́mù. Bíbélì sọ nípa àkókò náà pé: “Nígbà tí Jèhófà kó àwọn òǹdè Síónì jọ padà, . . . ẹnu wa kún fún ẹ̀rín.” (Sáàmù 126:1, 2) Àwọn Júù yẹn kò sọ̀rètí nù, ńṣe ni wọ́n ń bá a lọ láti máa ṣe ohun tó máa mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Wọn ò sì yéé kọrin láti yin Jèhófà.
Bíi tàwọn Júù yẹn, àwọn Kristẹni tòótọ́ tó ń dúró de Ọlọ́run ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” yìí ń sapá nígbà gbogbo láti rí i pé ìgbàgbọ́ àwọn ò kú. Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ń fún ara wọn níṣìírí, wọ́n sì ń yin Jèhófà nìṣó nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀.—Mátíù 24:3, 14.
A Ó Jàǹfààní Nínú Ìbáwí Tá A Bá Dúró De Jèhófà
Jeremáyà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run kọ̀wé pé: “Ó dára kí ènìyàn dúró, àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, de ìgbàlà Jèhófà.” (Ìdárò 3:26) Ohun tí Jeremáyà ń sọ ni pé, ó dára káwọn èèyàn Ọlọ́run wọ̀nyẹn má ṣe ṣàròyé nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá wọn wí nígbà tó gbà káwọn ọ̀tá pa Jerúsálẹ́mù run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n jàǹfààní látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, kí wọ́n máa ronú lórí ohun tí àìgbọràn wọn fà, kí ìyẹn sì mú kí wọ́n yí ìwà wọn padà.—Ìdárò 3:40, 42.
A lè fi ọ̀nà tí ìbáwí Jèhófà gbà ń ṣe wá láǹfààní wé bí èso ṣe máa ń gbó. Bíbélì sọ nípa ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé: “Fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Bí èso ṣe nílò àkókò láti pọ́n, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ń gba àkókò ká tó lè yí ọ̀nà tí à ń gbà ronú padà, èyí tó máa fi hàn pé a tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run ń pèsè. Bí àpẹẹrẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé a dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tí èyí sì mú káwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tá a ní nínú ìjọ bọ́ lọ́wọ́ wa, ìfẹ́ tá a ní láti dúró de Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì tàbí ká sọ pé a ò sin Ọlọ́run mọ́. Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Dáfídì tí Ọlọ́run mí sí lè fún wa níṣìírí. Ó sọ pé: “Wíwà lábẹ́ ìbínú [Ọlọ́run] jẹ́ fún ìṣẹ́jú kan, wíwà lábẹ́ ìfẹ́ rere rẹ̀ jẹ́ jálẹ̀ ìgbà ayé. Ẹkún sísun lè wá gba ibùwọ̀ ní alẹ́, ṣùgbọ́n igbe ìdùnnú ń bẹ ní òwúrọ̀.” (Sáàmù 30:5) Bá a bá kọ́ láti máa dúró de Ọlọ́run tá a sì ń fi ìmọ̀ràn tá à ń rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti látọ̀dọ̀ ètò rẹ̀ sílò, àkókò tá a máa ké “igbe ìdùnnú” yóò dé.
Ó Ń Gba Àkókò Kéèyàn Tó Di Ẹni Tẹ̀mí
Bó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ọ́ tàbí tí kò tíì pẹ́ tó o ṣèrìbọmi, ara rẹ lè ti wà lọ́nà láti ní àwọn iṣẹ́ tí wàá máa bójú tó nínú ìjọ Kristẹni. Àmọ́ ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè ní àwọn ànímọ́ tẹ̀mí téèyàn nílò láti lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, lo àǹfààní ìgbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ láti di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àkókò ọ̀dọ́ jẹ́ àkókò tó dára láti ka Bíbélì tán látòkèdélẹ̀, láti dẹni tó ní àwọn ànímọ́ tó yẹ Kristẹni, àti láti já fáfá nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Oníwàásù 12:1) Tó o bá fi hàn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé o lẹ́mìí ìdúródeni, àkókó tó dára lójú Jèhófà á dé tí wàá ní àwọn iṣẹ́ tí wàá máa bójú tó nínú ìjọ.
Iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tún gba sùúrù. Bí àgbẹ̀ ṣe ní láti máa bomi rin oko rẹ̀ títí tí Ọlọ́run á fi mú kóhun tó gbìn dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ló rí pẹ̀lú iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (1 Kọ́ríńtì 3:7; Jákọ́bù 5:7) Kéèyàn tó lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ kí wọ́n sì mọrírì Jèhófà nínú ọkàn wọn, ó máa ń gba kéèyàn máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún pàápàá. Dídúró de Jèhófà gba pé kéèyàn má ṣe jáwọ́ báwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ó bà tiẹ̀ tètè ṣiṣẹ́ lórí ohun tí à ń kọ́ wọn. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba ìmọrírì díẹ̀ ni wọ́n ní, ìyẹn lè jẹ́ àmì pé ẹ̀mí Jèhófà ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Bó o bá ní sùúrù, Jèhófà lè mú kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, èyí tí yóò múnú rẹ dùn jọjọ.—Mátíù 28:20.
Níní Ẹ̀mí Ìdúródeni Ń Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́
Wo ohun tí màmá àgbà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣe tó fi hàn pé níní ẹ̀mí ìdúródeni jẹ́ àmì ìfẹ́ àti ìfọkàntánni. Àgbègbè kan tó ń jẹ́ Andes tó jẹ́ aṣálẹ̀ ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù ló ń gbé. Òun àti arábìnrin kan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lábúlé wọn. Wo bí wọ́n á ti máa fojú sọ́nà tó láti rí i kí àwọn Kristẹni bíi tiwọn wá sọ́dọ̀ wọn. Nígbà kan, alábòójútó arìnrìn-àjò kan ń lọ sọ́dọ̀ wọn láti lọ bẹ̀ wọ́n wò fún ìgbà àkọ́kọ́, ó sì ṣìnà. Ó ní láti ṣẹ̀ṣẹ̀ padà sẹ́yìn, èyí sì mú kó fi bíi wákàtí díẹ̀ pẹ́ sígbà tó yẹ kó débẹ̀. Ọ̀gànjọ́ òru ló tó ó rí abúlé náà lọ́ọ̀ọ́kán. Ó yà á lẹ́nu nígbà tó rí ìná kan tó tàn, nítorí pé kò sí ìná mànàmáná lágbègbè náà. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó jàjà débi tí wọ́n ń gbà wọnú abúlé náà tó sì rí i pé inú àtùpà elépo tí màmá àgbà náà gbé sókè ni ìmọ́lẹ̀ náà ti wá! Ó dá màmá àgbà yìí lójú pé arákùnrin náà yóò wá, ó sì dúró dè é.
Irú ẹ̀mí sùúrù tí màmá àgbà yìí ní ló ń mú káwa náà máa fayọ̀ dúró de Jèhófà. Ó dá wa lójú pé yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bíi ti alábòójútó arìnrìn-àjò yẹn, àwa náà máa ń mọyì àwọn tó bá dúró dè wá tìfẹ́tìfẹ́. Abájọ tí kò fi yà wá lẹ́nu pé inú Ọlọ́run máa ń dùn sáwọn tó bá dúró dè é. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn . . . tí ń dúró de inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.”—Sáàmù 147:11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn tọ́wọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ yíyin Ọlọ́run máa ń láyọ̀ bí wọ́n ti ń dúró de Jèhófà