ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 3/15 ojú ìwé 4-7
  • Ohun Tí Kristi Máa Ṣe Tó Bá Dé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Kristi Máa Ṣe Tó Bá Dé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Wọ́n Á Gbé Ìjọba Sílẹ̀ Lẹ́rọ̀?
  • Ìmúpadàbọ̀sípò Tó Máa Mú Ìbùkún Wá
  • “Ọlọ́run Ni Ìtẹ́ Rẹ Títí Láé”
  • Àǹfààní Tí Ìrètí Bíbọ̀ Kristi Ń Ṣe Fáwọn Èèyàn
  • Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe?
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìjọba Kan “Tí A Kì Yóò Run Láé”
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Àwọn Nǹkan Wo Ni Ọlọ́run Máa Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 3/15 ojú ìwé 4-7

Ohun Tí Kristi Máa Ṣe Tó Bá Dé

“ÌPAYÀ BÁ ÀWỌN ARÁÀLÚ SÃO PAULO.” Ọ̀rọ̀ yìí ni ìwé ìròyìn Veja fi ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Sao Paulo tó jẹ́ ìlú téèyàn pọ̀ sí jù tó sì lọ́rọ̀ jù lórílẹ̀-èdè Brazil. Àwọn adàlúrú ‘fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú gbogbo nǹkan dé’ ní odindi ọjọ́ mẹ́rin tí wọ́n fi da ìlú náà rú lóṣù May ọdún 2006. Nǹkan bí àádọ́jọ [150] èèyàn ló kú láàárín “ọjọ́ mẹ́rin tí wọ́n fi dàlú yẹn rú.” Lára wọn ni àwọn agbófinró, àwọn arúfin, àtàwọn aráàlú míì.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ibi gbogbo láyé ni wọ́n ti máa ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ìwà jàgídíjàgan àti ìwà ipá nínú ìròyìn. Ó dà bíi pé apá àwọn alákòóso pàápàá ò ká a. Ayé yìí ti wá di ibi tó túbọ̀ ń léwu sí i fọmọ èèyàn láti gbé. Ìròyìn burúkú tó gbayé kan yìí lè ti mú kí gbogbo nǹkan tojú sú ẹ. Àmọ́, àyípadà ò ní pẹ́ dé bá gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn.

Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí wọ́n sì máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Kristi Jésù ni Ọlọ́run fi ṣe Ọba Ìjọba náà. Ìjọba náà yóò mú gbogbo ìṣòro tó ń yọ ọmọ aráyé lẹ́nu kúrò láìku ẹyọ kan. Àmọ́ kí Ìjọba Ọlọ́run tó ṣe gbogbo ìyẹn, ìjọba èèyàn gbọ́dọ̀ kúrò kí Ìjọba Kristi nìkan sì máa ṣàkóso. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Kristi bá dé gan-an nìyẹn.

Ṣé Wọ́n Á Gbé Ìjọba Sílẹ̀ Lẹ́rọ̀?

Ǹjẹ́ àwọn aláṣẹ ayé á gbé ìjọba sílẹ̀ ní wọ́ọ́rọ́wọ́ pé kí Kristi nìkan máa ṣàkóso? Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan tó dáhùn ìbéèrè yẹn. Jòhánù sọ ohun tó rí, ó ní: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà náà [ìyẹn ètò ìṣèlú ayé] àti àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn tí wọ́n kóra jọpọ̀ láti bá [Jésù] ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.” (Ìṣípayá 19:19) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọba ayé nínú ogun yìí? Bíbélì sọ pé Jésù tí í ṣe Ọba tí Jèhófà fòróró yàn “yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn, bí ohun èlò amọ̀kòkò ni . . . yóò fọ́ wọn túútúú.” (Sáàmù 2:9) Jésù yóò pa ètò ìṣèlú ayé run. Ìjọba Ọlọ́run “yóò fọ́ ìjọba [èèyàn] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.

Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run? Bíbélì sọ pé “nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, [yóò] mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” (2 Tẹsalóníkà 1:7, 8) Òwe 2:22 sọ pé: “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”

Bíbélì sọ nípa bíbọ̀ Kristi pé: “Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà, gbogbo ojú ni yóò sì rí i.” (Ìṣípayá 1:7) Kì í ṣe pé àwọn èèyàn máa rí Jésù sójú o. Látìgbà tí Jésù ti lọ sọ́run ló ti di ẹ̀dá ẹ̀mí “tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́, ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.”—1 Tímótì 6:16.

Rírí tí Bíbélì sọ pé èèyàn yóò rí Jésù kò túmọ̀ sí pé Jésù máa para dà dèèyàn káwọn èèyàn tó ń gbé láyé tó lè rí i. Ńṣe ló dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Mósè, tó jẹ́ pé Jèhófà ò ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ wá sáyé káwọn èèyàn sì rí i kó tó fi Ìyọnu Mẹ́wàá kọ lu àwọn ará Íjíbítì. Síbẹ̀, ó dá àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn lójú hán-ún pé Jèhófà ló fa àwọn ìyọnu náà, èyí sì mú kí wọ́n gbà tipátipá pé Ọlọ́run lágbára. (Ẹ́kísódù 12:31) Bákan náà, nígbà tí Kristi bá bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìdájọ́ wá sórí àwọn olubi bí Ọlọ́run ṣe rán an, àwọn olubi yóò “rí i” tipátipá, ìyẹn ni pé wọ́n á róye pé Ọlọ́run ti ń lo Jésù láti ṣèdájọ́ wọn. Ohun tó sì máa jẹ́ káwọn ẹni ibi mọ èyí ni pé àwọn èèyàn Ọlọ́run á ti kìlọ̀ fún aráyé ṣáájú. Bẹ́ẹ̀ ni, “gbogbo ojú ni yóò sì rí [Jésù], gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò sì lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn nítorí rẹ̀.”—Ìṣípayá 1:7.

Kí ayé yìí tó lè padà wà ní àlàáfíà kí áásìkí sì wà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà níbẹ̀rẹ̀, ìparun gbọ́dọ̀ dé bá àwọn èèyàn búburú àtàwọn òǹrorò alákòóso. Kristi ni yóò pa wọ́n run. Lẹ́yìn náà, yóò gba àkóso ayé pátá, àwọn àyípadà tó pabanbarì yóò sì wáyé.

Ìmúpadàbọ̀sípò Tó Máa Mú Ìbùkún Wá

Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa “ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé.” (Ìṣe 3:21) Ara ìmúpadàbọ̀sípò yìí ni àwọn àyípadà tó máa wáyé lórí ilẹ̀ ayé nígbà ìjọba Kristi. Ọ̀kan lára àwọn wòlíì tí Ọlọ́run gbẹnu wọn sọ̀rọ̀ nípa “ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo” lórí ilẹ̀ ayé ni wòlíì Aísáyà tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù Kristi, tí í ṣe “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” yóò mú kí àlàáfíà padà wà nínú ayé. Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìjọba Kristi, ó ní: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.” (Aísáyà 9:6, 7) Jésù yóò kọ́ àwọn tó máa gbélé ayé nígbà yẹn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè máa gbé pa pọ̀ lálàáfíà. Àwọn tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀ ayé “yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìṣẹ́ àti ebi nígbà ìjọba Kristi? Aísáyà sọ pé: “Dájúdájú, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn ní òkè ńlá yìí, àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́, èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.” (Aísáyà 25:6) Onísáàmù kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) Kò tán síbẹ̀ o, Aísáyà sọ nípa àwọn tí yóò máa gbé láyé pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Aísáyà 65:21, 22.

Aísáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àìsàn àti ikú máa dópin. Ọlọ́run gbẹnu Aísáyà sọ pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 35:5, 6) Nígbà yẹn “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ọlọ́run “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.

Gbogbo àwọn òkú tó wà ní “nínú ibojì ìrántí” ńkọ́? (Jòhánù 5:28, 29) Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. . . . Wọn yóò dìde.” (Aísáyà 26:19) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn òkú yóò jíǹde!

“Ọlọ́run Ni Ìtẹ́ Rẹ Títí Láé”

Ó ti dájú pé nígbà tí Kristi bá dé, yóò sọ ayé di bó ṣe wà níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àní, ilé ayé yóò di Párádísè, ọ̀nà kan náà ni gbogbo èèyàn yóò sì gbà máa sin Ọlọ́run tòótọ́. Ṣé Jésù Kristi á lè mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, kó sì sọ ayé di ibi tó dára láti máa gbé?

Ìwọ ronú nípa ẹni tó fún Jésù ní àṣẹ àti agbára. Bíbélì sọ̀rọ̀ kan nípa Ọmọ, ìyẹn Jésù, ó ní: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ títí láé àti láéláé, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ sì jẹ́ ọ̀pá aládé ìdúróṣánṣán. Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin.” (Hébérù 1:8, 9) Jèhófà lẹni tó fi Jésù jọba, òun ló fún un ní àṣẹ. Ọlọ́run fúnra ẹ̀ ló ni ìjọba yẹn, òun ló sì gbé e lé Jésù lọ́wọ́. Fún ìdí yìí, kò sí ìṣòro tí Jésù ò ní lè yanjú.

Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18) Pétérù kìíní orí kẹta ẹsẹ kejìlélógún sọ pé: “A sì fi àwọn áńgẹ́lì àti àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sábẹ́ rẹ̀.” Kò sí alágbára tàbí aláṣẹ tó ń ta ko Jésù tó máa lè borí. Kò sóhun tó máa lè dí Jésù lọ́wọ́ kó má tú ìbùkún tí kò lópin sórí aráyé.

Àǹfààní Tí Ìrètí Bíbọ̀ Kristi Ń Ṣe Fáwọn Èèyàn

Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà, ó ní: “Láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti ìfaradà yín nítorí ìrètí yín nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa.” (1 Tẹsalóníkà 1:3) Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìrètí táwọn ará Tẹsalóníkà ní nínú Jésù Kristi ló jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìṣòtítọ́ tó ń méso jáde, òun ló sì jẹ́ kí wọ́n lè lẹ́mìí ìfaradà. Lára ohun tí wọ́n ń retí ni bíbọ̀ Kristi àti ìmúbọ̀sípò tí bíbọ̀ rẹ̀ máa mú kó ṣeé ṣe. Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ ò ní jẹ́ káwọn Kristẹni tòótọ́ sọ̀rètí nù nígbà tí wọ́n bá níṣòro tó le gan-an, ó sì lè jẹ́ kí wọ́n lè fara da ìṣòro ọ̀hún.

Àpẹẹrẹ kan ni ti arákùnrin kan tó ń jẹ́ Carlos tó ń gbé nílùú São Paulo lórílẹ̀-èdè Brazil. Lóṣù August ọdún 2003, Carlos mọ̀ pé òun ní àrùn jẹjẹrẹ. Látìgbà yẹn, ìgbà mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ fún un. Ìrora tí iṣẹ́ abẹ yìí ti fà pọ̀ gan-an, àkóbá tó sì ti ṣe fún un kì í ṣe kékeré. Síbẹ̀, ó ṣì máa ń fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń wàásù ní òpópónà níwájú ọsibítù ńlá kan, ó rí obìnrin kan tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ọkọ rẹ̀ ń gbàtọ́jú ní ọsibítù nítorí àìsàn kan tó le. Nǹkan tójú arákùnrin Carlos ti rí nítorí àrùn jẹjẹrẹ tó ní mú kó lè fún arábìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ níṣìírí, ó sì tún mú kó lè tù wọ́n nínú. Tọkọtaya náà sọ pé ọ̀rọ̀ tí Carlos bá àwọn sọ jẹ́ ìṣírí ńlá fún àwọn. Arákùnrin Carlos wá rí i pé òótọ́ lohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “[Ọlọ́run] ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa, kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.”—2 Kọ́ríńtì 1:4.

Kí ló ran Carlos lọ́wọ́ tó fi lè máa gba àwọn ẹlòmíràn níyànjú bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun alára ń ṣàìsàn? Ìrètí tó ní pé Kristi ń bọ̀ àti ìrètí tó ní nínú gbogbo nǹkan tí bíbọ̀ Kristi á mú kó ṣeé ṣe ni kò jẹ́ kó ṣíwọ́ “ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—Gálátíà 6:9.

Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Samuel tí wọ́n yìnbọn pa àbúrò rẹ̀ ọkùnrin níbi tí kò jìnnà tó òpó iná méjì sílé bàbá wọn. Ọta ìbọn mẹ́wàá ló wọ ara rẹ̀. Wákàtí mẹ́jọ ni òkú rẹ̀ fi wà lójú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀. Ẹ̀yìn táwọn ọlọ́pàá parí ìwádìí wọn láti mọ ẹni tó ṣiṣẹ́ ibi náà ni wọ́n tó gbé òkú rẹ̀ kúrò níbẹ̀. Samuel ò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn. Àmọ́, Samuel kò banú jẹ́ jù nítorí ó ní ìrètí pé Kristi máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò láyé àti pé ìjọba rẹ̀ tó jẹ́ ìjọba òdodo yóò mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún aráyé. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Samuel máa ń fojú inú wò ó pé òun àti àbúrò òun jọ ń yọ̀ mọ́ra nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 24:15.

Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe?

Tó o bá nígbàgbọ́ pé Kristi ń bọ̀ tó o sì nígbàgbọ́ nínú àwọn ohun tó máa ṣe nígbà tó bá dé, ìtùnú ńlá nìyẹn máa jẹ́ fún ọ. Ó dájú pé Jésù Kristi máa yanjú gbogbo nǹkan tó ń fa ìṣòro àti nǹkan burúkú bá ọmọ aráyé.

Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe láti lè wà lára àwọn tó máa gbádùn ìbùkún tí ìjọba Kristi máa rọ̀jò rẹ̀ sórí ọmọ aráyé? Bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà kan tí Jésù gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Rí i dájú pé o kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ̀ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe èyí. Jọ̀wọ́ kàn sí wọn tàbí kó o kọ lẹ́tà sí àwa tá a tẹ ìwé ìròyìn yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Nígbà tí Kristi bá dé, yóò sọ ayé di bó ṣe wà níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀

[Credit Line]

Àwòrán inú àpótí yàtọ̀ sí ọmọ àti kìnnìún: Rhino and Lion Park, Gauteng, South Africa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́