Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Lépa Ohun Tó Máa Gbórúkọ Ọlọ́run Ga
“Máa kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.”—1 TÍMÓTÌ 4:7.
1, 2. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gbóríyìn fún Tímótì? (b) Báwo làwọn ọ̀dọ́ òde òní ṣe ń ‘kọ́ ara wọn pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n fojú sùn’?
“ÈMI kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. . . . Bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.” (Fílípì 2:20, 22) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló sọ ọ̀rọ̀ ìwúrí yìí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nílùú Fílípì. Ta ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Tímótì ni, ẹni tóun àti Pọ́ọ̀lù jọ máa ń rìnrìn àjò tó sì kéré sí Pọ́ọ̀lù lọ́jọ́ orí. Wo bí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí, tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Tímótì ó sì fọkàn tán an, yóò ti múnú Tímótì dùn tó!
2 Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọ̀dọ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run bíi Tímótì ti wúlò gan-an láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. (Sáàmù 110:3) Lóde òní, ètò Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú–ọ̀nà, míṣọ́nnárì, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ó tún yẹ ká gbóríyìn fáwọn tó ń fi tọkàntọkàn kópa nínú iṣẹ́ ìjọ tí wọ́n sì tún ń bójú tó àwọn nǹkan mìíràn tó yẹ ní ṣíṣe. Irú àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ń ní ojúlówó ayọ̀ téèyàn ń ní tó bá ń lépa àwọn ohun tó ń gbórúkọ Jèhófà, Baba wa ọ̀run, ga. Ká sòótọ́, ńṣe ni irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ń ‘kọ́ ara wọn pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n fojú sùn.’—1 Tímótì 4:7, 8.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Ìwọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, ǹjẹ́ o ní àwọn ohun kan pàtó tó ò ń lé tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga? Ibo lo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí gbà tí ọwọ́ rẹ á fi lè tẹ̀ wọ́n? Báwo lo ṣe lè yàgò fún ìfẹ́ ọrọ̀ tó gbayé kan? Àwọn ìbùkún wo ni wàá rí tó o bá lépa àwọn ohun tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí nípa gbígbé ìgbésí ayé Tímótì yẹ̀ wò àti iṣẹ́ tó ṣe.
Ìdílé Tí Tímótì Ti Wá
4. Ní ṣókí, sọ ohun tó o mọ̀ nípa bí Tímótì ṣe fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn Kristẹni.
4 Ìlú Lísírà tó jẹ́ ìlú kékeré kan ní ìpínlẹ̀ Gálátíà tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù ni Tímótì dàgbà sí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó wà ní ọ̀dọ́kùnrin ló mọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni, ìyẹn nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù nílùú Lísírà ní nǹkan bí ọdún 47 Sànmánì Kristẹni. Kò pẹ́ táwọn arákùnrin tó wà lágbègbè náà fi mọ Tímótì sẹ́ni tí ìwà rẹ̀ dára gan-an. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù padà wá sílùú Lísírà lọ́dún méjì lẹ́yìn náà tó sì gbọ́ nípa ìtẹ̀síwájú Tímótì, Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì bá òun lọ káwọn jọ máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. (Ìṣe 14:5-20; 16:1-3) Bí Tímótì ti túbọ̀ ń lóye nǹkan tẹ̀mí sí i, wọ́n fa àwọn iṣẹ́ pàtàkì lé e lọ́wọ́, títí kan fífún àwọn ará lókun, èyí kì í sì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni látinú ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílẹ̀ Róòmù, Tímótì ti di alàgbà nínú ìjọ tó wà nílùú Éfésù.
5. Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú 2 Tímótì 3:14, 15, ohun méjì wo ló ran Tímótì lọ́wọ́ láti lépa àwọn ohun tó gbórúkọ Ọlọ́run ga?
5 Ẹ̀rí fi hàn pé Tímótì pinnu láti lépa àwọn ohun tó ń gbé orúkọ Ọlọ́run ga. Àmọ́ kí ló ràn án lọ́wọ́ tó fi lè ṣe bẹ́ẹ̀? Nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ àwọn ohun méjì tó ran Tímótì lọ́wọ́. Ó ní: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́.” (2 Tímótì 3:14, 15) Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ìrànwọ́ táwọn Kristẹni mìíràn ṣe tó mú kí Tímótì ṣe irú ìpinnu tó ṣe yẹn.
Tímótì Jàǹfààní Látọ̀dọ̀ Àwọn Tó Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere
6. Irú ẹ̀kọ́ wo ni Tímótì gbà, kí ló sì ṣe nípa rẹ̀?
6 Inú ìdílé tí bàbá àti ìyá ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Tímótì ti dàgbà. Gíríìkì ni Bàbá rẹ̀, màmá rẹ̀ tó ń jẹ́ Yùníìsì àti ìyá ìyá rẹ̀ tó ń jẹ́ Lọ́ìsì sì jẹ́ Júù. (Ìṣe 16:1) Látìgbà tí Tímótì ti wà ní kékeré ni Yùníìsì àti Lọ́ìsì ti kọ́ ọ láwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Kò sí àní-àní pé wọ́n yí Tímótì lérò padà láti gba àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni gbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n di ẹlẹ́sìn Kristẹni. Ó dájú pé Tímótì jàǹfààní gan-an látinú ẹ̀kọ́ tí kò lẹ́gbẹ́ yìí. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo rántí ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú rẹ láìsí àgàbàgebè kankan, èyí tí ó kọ́kọ́ wà nínú ìyá rẹ àgbà Lọ́ìsì àti ìyá rẹ Yùníìsì, ṣùgbọ́n èyí tí mo ní ìgbọ́kànlé pé ó wà nínú rẹ pẹ̀lú.”—2 Tímótì 1:5.
7. Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní, ìrànlọ́wọ́ wo lèyí sì lè ṣe fún wọn?
7 Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ti jàǹfààní nítorí pé wọ́n ní àwọn òbí àtàwọn òbí àgbà tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run. Bíi ti Lọ́ìsì àti Yùníìsì, àwọn òbí wọ̀nyí mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti máa lépa àwọn ohun tó ń gbórúkọ Ọlọ́run ga. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Samira ṣì máa ń rántí ọ̀rọ̀ tóun àtàwọn òbí rẹ̀ jọ máa ń sọ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ó sọ pé: “Mọ́mì àti Dádì kọ́ mi láti máa wo àwọn nǹkan lọ́nà tí Jèhófà ń gbà wò wọ́n, wọ́n sì máa ń sọ pé kí n fi iṣẹ́ ìwàásù sí ipò àkọ́kọ́. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń fún mi níṣìírí pé kí n ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún.” Samira fi ohun táwọn òbí rẹ̀ sọ fún un sílò, ó sì ń gbádùn àǹfààní àkànṣe báyìí. Ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Bí àwọn òbí rẹ bá ń fún ọ níṣìírí pé kó o lépa àwọn ohun tó ń gbórúkọ Ọlọ́run ga, má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìmọ̀ràn wọn. Wọ́n fẹ́ káyé rẹ dára ni.—Òwe 1:5.
8. Báwo ni Tímótì ṣe jàǹfààní látinú bíbá àwọn Kristẹni tó lè fún un níṣìírí kẹ́gbẹ́?
8 Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o sún mọ́ àwọn tó lè fún ọ níṣìírí láàárín àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni. Tímótì dẹni táwọn alàgbà inú ìjọ rẹ̀ àtàwọn alàgbà ní Íkóníónì, tó wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà síbi tó ń gbé, mọ̀ dáadáa. (Ìṣe 16:1, 2) Òun àti Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ akínkanjú èèyàn di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. (Fílípì 3:14) Àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù fi hàn pé Tímótì máa ń gbàmọ̀ràn ó sì máa ń tètè fara wé àpẹẹrẹ àwọn tó nígbàgbọ́ gan-an. (1 Kọ́ríńtì 4:17; 1 Tímótì 4:6, 12-16) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìwọ ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi, ète mi, ìgbàgbọ́ mi, ìpamọ́ra mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi.” (2 Tímótì 3:10) Òótọ́ ni, Tímótì fara wé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù gan-an. Bíwọ náà bá sún mọ́ àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run gan-an nínú ìjọ, wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dẹni tó ní àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ò ń lépa.—2 Tímótì 2:20–22.
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ “Ìwé Mímọ́”
9. Yàtọ̀ sí bíbá àwọn tó ń ṣe dáadáa kẹ́gbẹ́, kí lo gbọ́dọ̀ ṣe kó o lè ‘kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun tó o fojú sùn’?
9 Ṣé bíbá àwọn èèyàn dáadáa kẹ́gbẹ́ nìkan ló máa jẹ́ kọ́wọ́ ẹni tẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí? Rárá o. Bíi ti Tímótì, o ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ “ìwé mímọ́” dáadáa. O lè má fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ rántí pé Tímótì ní láti máa ‘kọ́ ara rẹ̀ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun tó fojú sùn.’ Àwọn eléré ìdárayá máa ń dá ara wọn lẹ́kọ̀ọ́ kíkankíkan fún ọ̀pọ̀ oṣù kọ́wọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá. Bí ọ̀rọ̀ lílépa àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe rí náà nìyẹn, ó gba kéèyàn yááfì àwọn nǹkan kan kó sì máa sapá gan-an. O lè béèrè pé: ‘Ọ̀nà wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò gbà jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ àwọn ohun tí mò ń lé?’ Jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò.
10, 11. Kí nìdí tí Ìwé Mímọ́ fi máa jẹ́ kó wù ọ́ láti máa lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí? Sọ àpẹẹrẹ ti ẹnì kan.
10 Ọ̀nà kìíní, Ìwé Mímọ́ á jẹ́ kó wù ọ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Bíbélì fi àwọn ànímọ́ tí kò lẹ́gbẹ́ tí Baba wa ọ̀run ní hàn, ìfẹ́ tí kò lẹ́gbẹ́ tó fi hàn sí wa, àtàwọn ìbùkún ayérayé tó ń dúró de àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. (Ámósì 3:7; Jòhánù 3:16; Róòmù 15:4) Bí ìmọ̀ rẹ nípa Jèhófà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i, tá á sì túbọ̀ máa wù ọ́ láti ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún un.
11 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni ló sọ pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni olórí ohun tó ran àwọn lọ́wọ́ láti dẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni ni àwọn òbí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Adele, àmọ́ kò ní ohun tẹ̀mí kankan tó ń lé. Ó sọ pé: “Àwọn òbí mi ń mú mi lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ mi ò kì í dá kẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ni mi ò kì í tẹ́tí sílẹ̀ nípàdé.” Lẹ́yìn tí ẹ̀gbọ́n Adele tó jẹ́ obìnrin ṣèrìbọmi ni Adele ṣẹ̀ṣẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ dan-indan-in mú òtítọ́. Ó ní: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì mo sì kà á tán. Màá ka díẹ̀ lára rẹ̀, màá sì kọ nǹkan kan sílẹ̀ nípa ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kà náà. Gbogbo àwọn nǹkan tí mo kọ sílẹ̀ yẹn ṣì wà lọ́wọ́ mi. Láàárín ọdún kan, mo ka gbogbo Bíbélì tán. Èyí mú kí Adele fẹ́ láti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláàbọ̀ ara ni, ó ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà báyìí, ìyẹn àwọn tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù.
12, 13. (a) Àwọn ìyípadà wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti ṣe, báwo ló sì ṣe máa ṣe é? (b) Sọ díẹ̀ lára àwọn ọgbọ́n téèyàn lè múlò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
12 Ọ̀nà kejì, Bíbélì yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ nínú ìwà rẹ. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé “ìwé mímọ́” “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Bó o bá ń ronú nígbà gbogbo lórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o sì ń fi àwọn ìlànà inú Bíbélì ṣèwàhù, wàá fún ẹ̀mí Ọlọ́run láyè láti tún ìwà rẹ ṣe. Yóò jẹ́ kó o ní àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì, irú bí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìfaradà àti ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára, á sì tún jẹ́ kó o ní ojúlówó ìfẹ́ fáwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni. (1 Tímótì 4:15) Tímótì ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí, wọ́n sì mú kó wúlò gan-an fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn ìjọ tí Tímótì ti sìn.—Fílípì 2:20-22.
13 Ọ̀nà kẹta, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ ọgbọ́n téèyàn lè múlò. (Sáàmù 1:1-3; 19:7; 2 Tímótì 2:7; 3:15) Bíbélì yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni tó yẹ kó o fi ṣọ̀rẹ́, á jẹ́ kó o lè mọ eré ìnàjú tó bójú mu láti ṣe, á sì tún jẹ́ kó o lè ṣe àwọn ìpinnu mìíràn tó ṣòro láti ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2; Sáàmù 119:37; 1 Kọ́ríńtì 7:36) Ṣíṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nísinsìnyí ló máa jẹ́ kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn ohun tó ò ń lé.
“Ja Ìjà Àtàtà”
14. Kí nìdí tí kò fi rọrùn láti lépa àwọn ohun tó ń gbórúkọ Ọlọ́run ga?
14 Lílépa àwọn ohun tó ń gbé orúkọ Jèhófà ga ni ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ láti ṣe, àmọ́ kò rọrùn rárá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó bá kan ọ̀rọ̀ yíyan ohun tó o máa fi ayé rẹ ṣe, àwọn ẹbí, àwọn ojúgbà rẹ, àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n fẹ́ ọ fẹ́re lè máa gbà ọ́ nímọ̀ràn gan-an pé kó o lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga kó o lè ríṣẹ́ tó máa sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. Èrò wọn ni pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ń fúnni láyọ̀ òun ló sì ń fi hàn pé ayé ẹni dára. (Róòmù 12:2) Bíi ti Tímótì, ó di dandan kó o “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́” kó o lè “di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí,” èyí tí Jèhófà ṣèlérí fún ọ.—1 Tímótì 6:12; 2 Tímótì 3:12.
15. Àtakò wo ló ṣeé ṣe kí Tímótì ti rí?
15 Báwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ nínú ìdílé rẹ ò bá fara mọ́ ìpinnu rẹ, èyí lè jẹ́ àdánwò tó nira gan-an fún ọ. Àfàìmọ̀ kó má jẹ́ pé Tímótì pàápàá ní láti borí irú àtakò yìí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ti sọ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdílé “ọ̀mọ̀wé àti ìdílé ọlọ́rọ̀” ni Tímótì ti wá. Ó ṣeé ṣe kí bàbá Tímótì ti máa ronú pé Tímótì á kàwé gan-an á sì máa bá òwò ìdílé wọn lọ.a Ìwọ wo bí bàbá Tímótì ti máa ṣe nígbà tó mọ̀ pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó kún fún ewu tó sì jẹ́ pé àwọn tó ń ṣe é lè máà lówó lọ́wọ́ ni Tímótì yàn láti ṣe pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù!
16. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe kojú àtakò látọ̀dọ̀ òbí rẹ̀?
16 Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni ń dojú kọ irú ìṣòro yìí lónìí. Matthew, tó ń sìn ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sóun, ó ní: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, inú bàbá mi kò dùn rárá. Lójú rẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé mo fi ẹ̀kọ́ mi ‘ṣòfò’ nítorí pé mò ń ṣiṣẹ́ ìtọ́jú ilé kí n lè máa rówó gbọ́ bùkátà ara mi bí mo ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Bàbá mi máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, á máa sọ iye tí ì bá máa wọlé fún mi ká ní mo wáṣẹ́ gidi ṣe.” Báwo ni Matthew ṣe kojú àtakò yẹn? Ó ní: “Mi ò fi Bíbélì kíkà ṣeré rárá mo sì máa ń gbàdúrà gan-an, àgàgà láwọn ìgbà tó rọrùn fún mi láti fara ya.” Ọlọ́run bù kún ìpinnu Matthew. Àjọṣe àárín òun àti bàbá rẹ̀ gún padà nígbà tó yá. Matthew sì tún sún mọ́ Jèhófà sí i. Ó sọ pé: “Mo ti rí i pé Jèhófà kò jẹ́ kí ohun tí mo nílò wọ́n mi, ó fún mi níṣìírí, kò sì jẹ́ kí n ṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ì bá má tẹ̀ mí lọ́wọ́ ká ní mi ò lépa àwọn ohun tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga ni.”
Má Ṣe Mọ́kàn Kúrò Lórí Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Tó Ò Ń Lé
17. Láìmọ̀ọ́mọ̀, báwo làwọn kan ṣe lè máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún? (Mátíù 16:22)
17 Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ni yóò máa fọgbọ́n sọ pé kò pọn dandan kó o máa lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Àwọn kan lè béèrè pé ‘Kí ló dé tó o fẹ́ lọ máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?’ Wọ́n lè sọ fún ọ pé ‘O lè máa gbé irú ìgbésí ayé tí gbogbo èèyàn ń gbé síbẹ̀ náà kó o máa wàásù. Wá iṣẹ́ tó dára kó o rí towó ṣe.’ Èyí lè dà bí ìmọ̀ràn tó dára, àmọ́ bó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ṣé yóò fi hàn pé lóòótọ́ lò ń kọ́ ara rẹ pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ?
18, 19. (a) Báwo lo ṣe lè pa ọkàn rẹ pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ò ń lé? (b) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o múra tán láti yááfì nítorí ti Ìjọba Ọlọ́run.
18 Ó jọ pé àwọn Kristẹni kan ní irú èrò yìí nígbà ayé Tímótì. (1 Tímótì 6:17) Láti ran Tímótì lọ́wọ́ kó lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí, Pọ́ọ̀lù gbà á níyànjú pé: “Kò sí ènìyàn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí ń kó wọnú àwọn iṣẹ́ òwò ìgbésí ayé, kí ó bàa lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun.” (2 Tímótì 2:4) Ọmọ ogun tó wà lẹnu iṣẹ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohun táwọn tí kì í ṣe sójà ń lé pín ọkàn òun níyà. Ẹ̀mí rẹ̀ àti ẹ̀mí àwọn èèyàn tó kù sinmi lórí wíwà tó bá ń wà ní sẹpẹ́ láti ṣe ohun tí ọ̀gá rẹ̀ bá pa láṣẹ fún un. Níwọ̀n bó o ti jẹ́ ọmọ ogun Kristi, ìwọ náà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà. Má sì ṣe jẹ́ kí lílé àwọn nǹkan tara tí kò pọn dandan dí ọ lọ́wọ́ ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún, èyí tó jẹ́ iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là.—Mátíù 6:24; 1 Tímótì 4:16; 2 Tímótì 4:2, 5.
19 Dípò kó o máa lépa àtigbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, kọ́ láti lo ara rẹ fáwọn ẹlòmíràn. “Múra tán láti yááfì àwọn adùn ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun Kristi.” (2 Tímótì 2:3, The English Bible in Basic English) Nígbà tí Tímótì ń bá Pọ́ọ̀lù rìn, ó kọ́ béèyàn ṣe ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kódà nínú àwọn ipò tó nira gan-an pàápàá. (Fílípì 4:11, 12; 1 Tímótì 6:6-8) Ìwọ náà lè ṣe bíi tirẹ̀. Ǹjẹ́ o ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan nítorí ti Ìjọba Ọlọ́run?
Àwọn Ìbùkún Tí Wàá Rí Nísinsìnyí àti Lọ́jọ́ Iwájú
20, 21. (a) Sọ díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tí wàá rí tó o bá lépa ohun tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga. (b) Kí lo pinnu láti ṣe?
20 Nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni Tímótì àti Pọ́ọ̀lù fi jọ ṣiṣẹ́ pọ̀. Bí iṣẹ́ ìwàásù náà ti ń tẹ̀ síwájú tó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí gbogbo àríwá ilẹ̀ Mẹditaréníà, Tímótì fojú ara rẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀. Ìgbésí ayé rẹ̀ dùn bí oyin, ó sì lárinrin ju bí ì bá ṣe rí ká ní irú ìgbésí ayé tí gbogbo èèyàn ń gbé ló yàn láti gbé. Bíwọ náà bá lépa àwọn ohun tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga, wàá rí àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí kò ṣeé díye lé. Wàá sún mọ́ Jèhófà, àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ á nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọ́n á sì tún bọ̀wọ̀ fún ọ. Dípò ìbànújẹ́ àti ìnira téèyàn ń rí tó bá ń lépa ọrọ̀ ti ara, wàá ní ojúlówó ayọ̀ tó ń wá látinú lílo ara ẹni fáwọn ẹlòmíràn. Èyí tó ṣeyebíye jù lọ ni pé, wàá “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—1 Tímótì 6:9, 10, 17-19; Ìṣe 20:35.
21 A gbà ọ́ níyànjú pé kó o tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ara rẹ pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀. Sún mọ́ àwọn tó lè rán ọ́ lọ́wọ́ nínú ìjọ kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ò ń lé, kó o sì ní kí wọ́n tọ́ ọ sọ́nà. Rí i pé ò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Pinnu pé o ò ní jẹ́ kí ẹ̀mí ìfẹ́ ọrọ̀ tó gbayé kan yìí darí rẹ. Sì máa rántí nígbà gbogbo pé Ọlọ́run, ẹni tó “ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa,” ti ṣèlérí pé o lè ní ìbùkún rẹpẹtẹ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn bó o bá lépa àwọn nǹkan tó máa gbé orúkọ rẹ̀ ga.—1 Tímótì 6:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Gíríìkì ka ẹ̀kọ́ ìwé sóhun tó ṣe pàtàkì gan-an. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Plutarch tó gbé ayé lákòókò tí Tímótì gbé ayé kọ̀wé pé: “Kéèyàn gba ẹ̀kọ́ tó dára ni orísun gbogbo ohun rere. . . . Èyí ni mo gbà pé ó ń jẹ́ kéèyàn ní ìwà ọmọlúwàbí, òun ló sì ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀. . . . Gbogbo nǹkan tó kù kò já mọ́ nǹkan kan, wọn ò ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe ohun téèyàn ń kó lọ́kàn.”—Látinú ìwé Moralia I, “The Education of Children.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ibo làwọn ọ̀dọ́ ti lè rí àwọn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n á fi lè máa lépa àwọn ohun tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga?
• Kí nìdí tí kíkẹ̀ẹ́kọ́ Bíbélì tọkàntọkàn fi ṣe pàtàkì?
• Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè yàgò fún ìfẹ́ ọrọ̀ tó gbayé kan?
• Àwọn ìbùkún wo làwọn ọ̀dọ́ máa rí tí wọ́n bá lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn nǹkan tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga ni Tímótì lépa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn wo ló jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí wọ́n ran Tímótì lọ́wọ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Njẹ́ ò ń lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí?