Ẹ̀yin Èwe Ẹ Lè Múnú Àwọn Òbí Yín Dùn Tàbí Kẹ́ Ẹ Bà Wọ́n Nínú Jẹ́
ÀPỌ́SÍTÉLÌ JÒHÁNÙ tó ti di àgbàlagbà kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ni àwọn ọmọ tá a sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí, ó dájú pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jòhánù náà ló ṣe rí lára àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run. Báwọn òbí ṣe lè mú káyé ọmọ wọn dáa tàbí káyé ọmọ wọn bà jẹ́ ni àwọn ọmọ náà lè múnú àwọn òbí wọn dùn tàbí kí wọ́n ba àwọn òbí wọn nínú jẹ́.
Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì mọ̀ pé àwọn ọmọ lè múnú àwọn òbí wọn dùn gan-an tàbí kí wọ́n bà wọ́n nínú jẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ẹni tí ń mú kí baba yọ̀, arìndìn ọmọ sì ni ẹ̀dùn-ọkàn ìyá rẹ̀.” (Òwe 10:1) Nítorí náà, á dára káwọn èwe àtàwọn ọmọ tó ti ń dàgbà pàápàá ronú jinlẹ̀ pé ìwà àwọn lè nípa rere tàbí ipa búburú lórí bàbá àti ìyá wọn. Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ronú jinlẹ̀?
Ro gbogbo ìtọ́jú táwọn òbí rẹ tó bẹ̀rù Ọlọ́run fún ẹ bó o ti ń dàgbà! Kí wọ́n tó bí ọ rárá ni wọ́n ti ń ṣàníyàn nípa rẹ tí wọ́n sì ń gbàdúrà nípa rẹ. Lẹ́yìn tí wọ́n bí ọ tán, àwọn méjèèjì nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àǹfààní àgbàyanu pé àwọn jẹ́ òbí, èyí tó tún jẹ́ iṣẹ́ tí kò ṣeé fọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Ọmọ kékeré jòjòló kan tí ò lè dá nǹkan kan ṣe ti wà níkàáwọ́ wọn báyìí, wọn ò sì fọwọ́ kékeré mú iṣẹ́ yìí nítorí pé wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà.
Nítorí pé àwọn òbí rẹ jẹ́ Kristẹni tòótọ́, wọ́n ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì kí wọ́n lè rí ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé. Wọ́n tún lọ bá àwọn tó ti tọ́mọ rí pé kí wọ́n fún àwọn nímọ̀ràn. Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò yéé sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn fún Ọlọ́run nínú àdúrà. (Onídàájọ́ 13:8) Bó o ti ń dàgbà, àwọn òbí rẹ mọ àwọn ibi tó o dáa sí àtàwọn ibi tó o kù sí. (Jóòbù 1:5) Bó o ti ń di géńdé, bẹ́ẹ̀ làwọn ìṣòro tuntun ń yọjú. Ìgbà kan tiẹ̀ lè wà tó o yọwọ́kọ́wọ́ táwọn òbí rẹ sì tẹra mọ́ àdúrà gbígbà, tí wọ́n ń ka àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń ronú bí wọ́n ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa jọ́sìn Jèhófà, Baba rẹ ọ̀run.
Kò sígbà kan tí ọ̀rọ̀ rẹ kò jẹ bàbá rẹ àti ìyá rẹ lọ́kàn. Àní nígbà tó o ti dàgbà tán pàápàá, wọ́n ṣì ń ronú nípa ìlera rẹ, nípa bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ àti àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn òbí rẹ kò gbàgbé pé o lómìnira láti yan ohun tó bá wù ẹ́, wọn ò sì lè sọ pé báyìí ni ìgbésí ayé rẹ ṣe máa rí. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìwọ fúnra rẹ lo máa pinnu ohun tó o máa fi ayé rẹ ṣe.
Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí “kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́” ju pé kí wọ́n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ wọn “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́,” ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu láti sọ pé inú wọn á bà jẹ́ táwọn ọmọ wọn ò bá rìn nínú òtítọ́? Ká sòótọ́, ńṣe làwọn ọmọ tó ń ṣe ohun tí kò bójú mu ń ba àwọn òbí wọn nínú jẹ́. Sólómọ́nì sọ pé: “Arìndìn ọmọ jẹ́ ìbìnújẹ́ fún baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i.” (Òwe 17:25) Ìbànújẹ́ ńlá ló mà ń bá àwọn òbí o nígbà táwọn ọmọ wọn bá kẹ̀yìn sí ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́!
Ó dájú pé ìwà àti ìṣe rẹ ń nípa tó pọ̀ gan-an lórí ìdílé rẹ àtàwọn mìíràn tó o mọ̀. Ìwà rẹ lè múnú àwọn òbí rẹ dùn tàbí kó bà wọ́n nínú jẹ́. Bó o bá kẹ̀yìn sí Ọlọ́run àti ìlànà rẹ̀, inú àwọn òbí rẹ á bà jẹ́. Àmọ́, tó o bá ń ṣe dáadáa, inú wọn á dùn gan-an. Tó o bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tó o sì ń ṣègbọràn sí i, àwọn òbí rẹ yóò máa láyọ̀. Pinnu pé wàá múnú àwọn òbí rẹ dùn! Ẹ̀bùn wo ló dára ju èyí lọ tó o tún lè fún àwọn tó tọ́ ẹ dàgbà, tí wọ́n dáàbò bò ẹ́, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ?