ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/15 ojú ìwé 11-13
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ Sípàdé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ Sípàdé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi”
  • “Ẹ̀yin Tí Ń Ṣe Làálàá, Tí A sì Di Ẹrù Wọ̀ Lọ́rùn”
  • “Àjàgà Mi Jẹ́ Ti Inú Rere, Ẹrù Mi sì Fúyẹ́”
  • “Onínú Tútù àti Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-àyà Ni Èmi”
  • “Ẹ Ó sì Rí Ìtura fún Ọkàn Yín”
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń ṣamọ̀nà Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ṣé O Máa Ń Mú Kí Àwọn Ìpàdé Ìjọ Gbéni Ró?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/15 ojú ìwé 11-13

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ Sípàdé?

ỌKỌ obìnrin kan tó ń jẹ́ Christine dédé já a jù sílẹ̀ lẹ́yìn ogún ọdún tí wọ́n ti ṣègbéyàwó. Ó wá ku Christine nìkan láti tọ́ ọmọ mẹ́jọ, ìyẹn ọkùnrin méje, obìnrin kan. Èyí àgbà jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún, àbíkẹ́yìn sì jẹ́ ọmọ ọdún méje. Arábìnrin náà sọ pé: “Nísinsìnyí, èmi nìkan lá máa dá ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì-pàtàkì. Tí mo bá ro gbogbo ìyẹn, ó máa ń kà mí láyà, màá sì máa rò ó pé ì bá dáa kí n rẹ́ni táá máa ràn mí lọ́wọ́ táá sì máa tọ́ mi sọ́nà.” Ibo ló ti wá rí ìrànlọ́wọ́ tó ń fẹ́ yìí?

Arábìnrin Christine sọ pé: “Ìpàdé ìjọ ló ń gbé èmi àtàwọn ọmọ mi ró. Nígbà tá a bá wà nípàdé, àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fún wa níṣìírí, a sì tún máa ń gba ìtọ́sọ́nà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lílọ tá à ń lọ sípàdé déédéé ti ran ìdílé wa lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà tó ṣe pàtàkì.”

Onírúurú ìṣòro ni kálukú wa máa dojú kọ ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí. (2 Tímótì 3:1) Ó ṣeé ṣe kó o ti rí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí Christine ṣe rí i, pé ó ń gbé ìgbàgbọ́ ẹni ró, àti pé ó jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn rẹ sí Jèhófà. Ìpàdé márààrún tá à ń lọ lọ́sẹ̀ lè ti mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà jinlẹ̀ sí i, kó ti mú kí ìrètí tó o ní nípa ọjọ́ ọ̀la túbọ̀ dájú, kó sì ti máa fún ọ ní ìtọ́sọ́nà látinú Bíbélì tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe tó o bá níṣòro.

Àmọ́, àwọn kan wà tó jẹ́ pé ó nira fún láti máa lọ sípàdé déédéé. Ó máa ń rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu nígbà tó bá máa fi di ìrọ̀lẹ́, àtiwá múra lọ́nà tó bójú mu kí wọ́n sì lọ sípàdé á wá dìṣòro. Àwọn kan rí i pé iṣẹ́ táwọn ń ṣe ò fún àwọn láyè láti máa lọ sípàdé déédéé. Tí wọ́n bá ní káwọn máa lọ sí gbogbo ìpàdé, ó lè mú kí wọ́n dín owó iṣẹ́ wọn kù tàbí kí wọ́n dá wọn dúró lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn kan sì ń pa ìpàdé jẹ nítorí wọ́n gbà pé àwọn eré ìnàjú kan máa fún àwọn ní ìtura ju ìfararora inú ìpàdé ìjọ lọ.

Nítorí náà, kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa lọ sípàdé ìjọ? Kí la lè ṣe tí àwọn ìpàdé yìí á fi máa tù wá lára? Láti lè dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Jésù fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí àwọn èèyàn láti ṣe, èyí tó wà nínú Mátíù 11:28-30. Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi”

Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi.” Ọ̀nà kan tá a lè gbà wá sọ́dọ̀ Jésù ni pé ká máa lọ sípàdé déédéé. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa lọ sípàdé, nítorí Jésù tún sọ lẹ́yìn náà pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọpọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.”—Mátíù 18:20.

Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù fúnra rẹ̀ pe onírúurú èèyàn pé kí wọ́n wá máa tọ òun lẹ́yìn. Ó tipa báyìí fún wọn láǹfààní láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Lọ́gán ni àwọn kan lára àwọn tí Jésù pè di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mátíù 4:18-22) Àmọ́, àwọn míì jẹ́ kí àwọn nǹkan kan, irú bí àwọn nǹkan tara, dí wọn lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé Jésù. (Máàkù 10:21, 22; Lúùkù 9:57-62) Jésù wá fi àwọn tó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yin kọ́ ni ẹ yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni mo yàn yín.”—Jòhánù 15:16.

Lẹ́yìn tí Kristi kú tó sì jíǹde, kò sí lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́. Àmọ́ ó ṣì wà pẹ̀lú wọn ní ti pé ó ń darí ohun tí wọ́n ń ṣe, ó sì ń wo ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú ìtọ́ni òun. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí àádọ́rin ọdún lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fún ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré ní ìtọ́ni àti ìṣírí. Ohun tó sọ fún wọn fi hàn pé ó mọ ìkùdíẹ̀-káàtó olúkúlùkù àwọn tó wà nínú àwọn ìjọ náà àti ibi tí wọ́n dáa sí.—Ìṣípayá 2:1–3:22.

Títí di bá a ṣe ń wí yìí, Jésù kò fọ̀rọ̀ èyíkéyìí nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣeré rárá. Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20) Àkókò ìkẹyìn náà la wà yìí, nítorí náà, ó yẹ ká jẹ́ ìpè tí Jésù pè wá pé ká máa tọ òun lẹ́yìn. Lára ọ̀nà tá a sì lè gbà máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ni pé ká máa lọ sípàdé déédéé. Jésù fẹ́ ká máa fetí sí òun, ká sì dẹni “tí a . . . tipasẹ̀ rẹ̀ kọ́” nípa àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa ń gbọ́ nípàdé àtàwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì tó máa ń wáyé níbẹ̀ déédéé. (Éfésù 4:20, 21) Ǹjẹ́ ò ń jẹ́ ìpè tí Jésù pè wá pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi”?

“Ẹ̀yin Tí Ń Ṣe Làálàá, Tí A sì Di Ẹrù Wọ̀ Lọ́rùn”

Ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká máa lọ sípàdé ìjọ jẹ́ láti gba ìṣírí. (Hébérù 10:24, 25) Ọ̀pọ̀ lára wa ló “ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” ní onírúurú ọ̀nà. Ìṣòro, irú bí àìsàn, ti lè di ẹrù ńlá tó wọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Àmọ́ tó o bá dé ìpàdé ìjọ, níbi tá a ti jọ máa ń fúnra wa níṣìírí, wàá rí ìṣírí gbà níbẹ̀. (Róòmù 1:11, 12) Bí àpẹẹrẹ, wàá gbọ́ ìdáhùn tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun, wàá gbọ́ ọ̀rọ̀ tí yóò rán ọ létí ìrètí tí Bíbélì jẹ́ kó o ní, wàá sì tún rí ìgbàgbọ́ àwọn míì tí wọ́n ń fara da ìṣòro. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ kó o lè fara da ìṣòro rẹ, kò sì ní jẹ́ kó o ní èrò òdì nípa ìṣòro náà.

Wo ohun tí arábìnrin kan tí àìsàn líle kan ń ṣe sọ. Ó ní: “Àìsàn mi máa ń jẹ́ kí wọ́n dá mi dúró fúngbà díẹ̀ nílé ìwòsàn. Lẹ́yìn tí mo bá padà délé, àtilọ sípàdé kì í rọrùn, ṣùgbọ́n mi ò lè ṣàìlọ nítorí àǹfààní tí mò ń jẹ níbẹ̀. Ìfararora àti ìfẹ́ táwọn ará ń fi hàn sí mi máa ń fún mi láyọ̀, àwọn ẹ̀kọ́ àti ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà àti Jésù sì ń fúnni níbẹ̀ ń jẹ́ káyé mi nítumọ̀.”

“Àjàgà Mi Jẹ́ Ti Inú Rere, Ẹrù Mi sì Fúyẹ́”

Kíyè sí i pé nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá à ń gbé yẹ̀ wò yìí, Jésù sọ pé: “Kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.” Èèyàn máa ń di ọmọlẹ́yìn Jésù nígbà téèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, èèyàn sì máa ń gba àjàgà rẹ̀ nígbà tó bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run tó sì ṣe ìrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20) Tá a bá fẹ́ máa jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù nìṣó, ó ṣe pàtàkì pé ká máa kópa déédéé nínú ìpàdé ìjọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìpàdé ìjọ la ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ibẹ̀ la ti ń kọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, àti nípa ọ̀nà tó gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

Irú ẹrù wo ni Kristi fẹ́ ká rù? Ẹrù tóun alára rù ni, ìyẹn àǹfààní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jòhánù 4:34; 15:8) Ó gba ìsapá láti máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, àmọ́ ẹrù yìí ò wúwo jù fún wa. Ó lè dà bíi pé ó wúwo tá a bá fẹ́ dá a gbé. Ṣùgbọ́n tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tá a sì ń gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n ń sọ nípàdé ìjọ sọ́kàn, Ọlọ́run yóò fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Tá a bá ń múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé wọ̀nyí tá a sì ń kópa nínú wọn, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà yóò máa jinlẹ̀ sí i. Tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá sì jinlẹ̀ lọ́kàn wa, a ò ní ka àwọn òfin rẹ̀ sí “ẹrù ìnira.”—1 Jòhánù 5:3.

Àwọn èèyàn ní ìṣòro àtijẹ-àtimu, ìṣòro bí wọ́n á ṣe bójú tó àìsàn tó ń ṣe wọ́n àti bí wọ́n á ṣe máa yanjú aáwọ̀ àárín àwọn àtẹlòmíì. Àmọ́ tá a bá fẹ́ rójútùú àwọn ìṣòro wọ̀nyí, a ò gbọ́dọ̀ gbára lé ọgbọ́n èèyàn. Ìpàdé ìjọ ń ràn wá lọ́wọ́ láti “dẹ́kun ṣíṣàníyàn,” nítorí ó ń jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń pèsè àwọn ohun tá a nílò, ó sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè bójú tó àwọn ìṣòro wa. (Mátíù 6:25-33) Ní tòdodo, ìpàdé ìjọ jẹ́ ọ̀nà kan tí Ọlọ́run gbà ń fi ìfẹ́ tó ní sí wá hàn.

“Onínú Tútù àti Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-àyà Ni Èmi”

Ó jẹ́ àṣà Jésù láti máa lọ sí sínágọ́gù, níbi tí wọ́n ti máa ń jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nírú àkókò kan bẹ́ẹ̀ tí Jésù lọ sí sínágọ́gù, ó mú àkájọ ìwé Áísáyà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, ó rán mi jáde láti wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀, láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.” (Lúùkù 4:16, 18, 19) Ẹ ò rí i pé inú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ á dùn gan-an láti gbọ́ àlàyé tí Jésù ṣe nípa ọ̀rọ̀ yẹn. Ó ní: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ”!—Lúùkù 4:21.

Jésù, “olórí olùṣọ́ àgùntàn” tó jẹ́ onínú tútù, ṣì ń bójú tó àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa tẹ̀mí. (1 Pétérù 5:1-4) Lábẹ́ ìdarí Jésù, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń yan àwọn ọkùnrin sípò gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. (Mátíù 24:45-47; Títù 1:5-9) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń fi ìwà tútù “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run,” wọ́n sì ń fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa lílọ sípàdé ìjọ déédéé. O lè fi hàn pé o mọrírì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wọ̀nyí nípa lílọ sípàdé, níbi tí wàá ti lè fún àwọn míì níṣìírí nípa wíwá tó o wá sípàdé àti kíkópa nínú rẹ̀.—Ìṣe 15:30-33; 20:28; Éfésù 4:8, 11, 12.

“Ẹ Ó sì Rí Ìtura fún Ọkàn Yín”

Nígbà tó o bá lọ sípàdé, kí lo lè ṣe kí ìpàdé lè tù ọ́ lára? Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó sọ pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Ńṣe làwọn tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù máa ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n á ní kó ṣàlàyé àwọn àpèjúwe rẹ̀ fáwọn, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ní òye tó jinlẹ̀.—Mátíù 13:10-16.

Ọ̀nà kan tí ìwọ náà lè gbà ṣe bíi táwọn tí ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń pa wọ̀nyí ni pé kó o máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípàdé. (Mátíù 5:3, 6) Ohun kan tó máa jẹ́ kó o lè pọkàn pọ̀ nípàdé ni pé kó o máa fọkàn bá àlàyé tí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ń ṣe lọ. Máa bi ara rẹ làwọn ìbéèrè bíi: ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ọ̀rọ̀ tí mò ń gbọ́ yìí sílò? Ọ̀nà wo ni mo lè gbà lo ọ̀rọ̀ yìí láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́? Báwo ni mo ṣe lè ṣàlàyé kókó yìí?’ Yàtọ̀ síyẹn, máa wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí alásọyé bá ń kà láti fi ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn. Bó o bá ṣe ń fetí sílẹ̀ tó ni ìpàdé á ṣe tù ọ́ lára tó.

Lẹ́yìn ìpàdé, máa gbìyànjú láti bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbọ́. Máa ronú lórí àwọn kókó tí wọ́n sọ nípàdé, kó o sì ronú lórí bí wàá ṣe fi wọ́n sílò. Tó o bá ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì nípàdé lọ́nà tó ń gbéni ró, ìpàdé ọ̀hún á túbọ̀ tù ọ́ lára.

Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìdí tó ṣe pàtàkì ló wà tó fi yẹ ká máa lọ sípàdé ìjọ. A rọ̀ ọ́ pé kó o ronú lórí àwọn àǹfààní tá a ti jíròrò, kó o wá bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe ń jẹ́ ìpè Jésù, pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi”?’

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ǹjẹ́ àwọn nǹkan míì ń dí ọ lọ́wọ́ lílọ sípàdé?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́