ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 6/1 ojú ìwé 12-13
  • Ṣé Ìdádọ̀dọ́ La Fi Ń Mọ̀ Pé Èèyàn Ti Di Ọkùnrin?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìdádọ̀dọ́ La Fi Ń Mọ̀ Pé Èèyàn Ti Di Ọkùnrin?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Tí Ọlọ́run Fi Wo Ìdádọ̀dọ́
  • Àwọn “Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdádọ̀dọ́” Wá Ńkọ́?
  • Kí Ló Ń Sọ Kristẹni Kan Di Ọkùnrin?
  • ‘Lẹ́yìn Tí Wọ́n Jiyàn Díẹ̀’
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Àti Òfin Mósè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 6/1 ojú ìwé 12-13

Ṣé Ìdádọ̀dọ́ La Fi Ń Mọ̀ Pé Èèyàn Ti Di Ọkùnrin?

LÁPÁ ibi púpọ̀ láyé, àwọn èèyàn máa ń dá dọ̀dọ́ fáwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọwọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ìlera. Láwọn apá ibòmíràn, àwọn ọkùnrin kì í dá dọ̀dọ́ rárá. Ní tàwọn kan sì rèé, irú bí àwọn Júù àtàwọn Mùsùlùmí, kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ ìlera nìkan ni wọ́n ṣe ń dádọ̀dọ́, ó tún ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.

Àmọ́ o, láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó láwọn nǹkan kan tí wọ́n máa ń ṣe tí wọ́n bá fẹ́ dádọ̀dọ́ fún ọmọkùnrin kan nígbà tó bá ti bàlágà. Wọ́n sábà máa ń mú ọmọkùnrin náà lọ síbì kan tí wọ́n ti ń kọ́ nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, níbi tí wọ́n á ti dádọ̀dọ́ rẹ̀, tá á sì wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ títí tí ojú abẹ náà á fi san. Láàárín àkókò yẹn, ó láwọn nǹkan kan ti ọmọkùnrin náà yóò máa ṣe, wọ́n á sì máa kọ́ ọ ní béèyàn ṣe ń di ọkùnrin. Ǹjẹ́ irú ìdádọ̀dọ́ yìí pọn dandan láti fi hàn pé ọmọ kan ti di ọkùnrin? Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò nípa ohun tó jẹ́ èrò Ọlọ́run lórí kókó yìí.—Òwe 3:5, 6.

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Wo Ìdádọ̀dọ́

Àwọn èèyàn kan láyé ọjọ́un, irú bí àwọn ará Íjíbítì, máa ń dá dọ̀dọ́, ìyẹn ni gígé awọ tó bo nǹkan ọmọkùnrin kúrò. Àmọ́ wọn ò bí Ábúráhámù sí àgbègbè tí wọ́n ti ń dá dọ̀dọ́. Àní sẹ́, èyí tó pọ̀ jù lọ nígbèésí ayé Ábúráhámù ló fi wà láìdádọ̀dọ́. Síbẹ̀, nígbà tí Ábúráhámù fi wà láìdádọ̀dọ́ yẹn, akínkanjú ọkùnrin ló jẹ́. Pẹ̀lú ìwọ̀nba àwọn ọkùnrin díẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó lépa àwọn ọba mẹ́rin àtàwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n mú Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ arákùnrin rẹ̀, ó sì ṣẹ́gun wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 14:8-16) Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlá lẹ́yìn náà, Ọlọ́run pàṣẹ fún Ábúráhámù pé kó dádọ̀dọ́ kó sì tún dá dọ̀dọ́ fún gbogbo àwọn aráalé rẹ̀. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pa àṣẹ yìí?

Ó dájú pé kì í ṣe káwọn èèyàn lè mọ̀ pé Ábúráhámù ti kúrò ní ọ̀dọ́mọkùnrin, pé ó ti di géńdé. Kódà, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ló jẹ́ lákòókò náà! (Jẹ́nẹ́sísì 17:1, 26, 27) Ọlọ́run sọ ìdí tóun fi pa àṣẹ yìí, ó ní: “Kí a sì dá adọ̀dọ́ yín, kí ó sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàárín èmi àti ẹ̀yin.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:11) Lára ohun tó wà nínú májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ni pé, nípasẹ̀ Ábúráhámù, àwọn àgbàyanu ìbùkún yóò tẹ “gbogbo ìdílé orí ilẹ̀” lọ́wọ́ níkẹyìn. (Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3) Nípa báyìí, lójú Ọlọ́run, ìdádọ̀dọ́ kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú dídi ọkùnrin. Ìdí tó fi ní káwọn èèyàn náà ṣe é ni láti fi hàn pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, tí Ọlọ́run fún ní àǹfààní kan, ìyẹn ni pé ó “fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run sí ìkáwọ́ wọn.”—Róòmù 3:1, 2.

Bí àkókò ti ń lọ, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi hàn pé àwọn ò kúnjú ìwọ̀n ipò pàtàkì tí Ọlọ́run fi wọ́n sí yìí nítorí pé wọn ò tẹ́wọ́ gba Jésù Kristi tó jẹ́ Irú-Ọmọ tòótọ́ fún Ábúráhámù. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run kọ̀ wọ́n sílẹ̀, jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni tó ń dádọ̀dọ́ kò sì nítumọ̀ kankan mọ́ lójú Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní rin kinkin mọ́ ọn pé Ọlọ́run ṣì fẹ́ káwọn Kristẹni máa dádọ̀dọ́. (Ìṣe 11:2, 3; 15:5) Èyí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán Títù láti “ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù” ní onírúurú ìjọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù nípa ọ̀kan nínú irú àwọn àbùkù bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ewèlè ènìyàn ni ó wà, àwọn asọ̀rọ̀ tí kò lérè, àti àwọn tí ń tan èrò inú jẹ, ní pàtàkì àwọn ènìyàn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ìdádọ̀dọ́. Ó pọndandan láti pa ẹnu àwọn wọ̀nyí mọ́, níwọ̀n bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá ti ń bá a nìṣó ní dídojú gbogbo àwọn agbo ilé pátá dé nípa kíkọ́ni ní àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n fi kọ́ni nítorí èrè àbòsí.”—Títù 1:5, 10, 11.

Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ṣì wúlò lóde òní. Ó dájú pé kò ní bá Ìwé Mímọ́ mu rárá kí Kristẹni tòótọ́ kan máa rọ ẹnì kan pé kó lọ dádọ̀dọ́ ọmọ rẹ̀. Dípò tí Kristẹni kan á fi jẹ́ “olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn,” kó kúkú fi irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ fáwọn òbí ọmọ náà láti ṣe. (1 Pétérù 4:15) Kò tán síbẹ̀ o, Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé nípa ìdádọ̀dọ́ tó bá Òfin Mósè mu pé: “A ha pe ọkùnrin èyíkéyìí nígbà tí ó ti dádọ̀dọ́? Kí ó má di aláìdádọ̀dọ́. A ha ti pe ọkùnrin èyíkéyìí nínú àìdádọ̀dọ́? Kí ó má ṣe dádọ̀dọ́. Ìdádọ̀dọ́ kò túmọ̀ sí nǹkan kan, àìdádọ̀dọ́ kò sì túmọ̀ sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú ipò yòówù tí a bá ti pe olúkúlùkù, kí ó dúró nínú rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 7:18-20.

Àwọn “Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdádọ̀dọ́” Wá Ńkọ́?

Báwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni bá wá pinnu láti dádọ̀dọ́ ọmọ wọn ọkùnrin ńkọ́? Ǹjẹ́ yóò bá Bíbélì mu láti rán àwọn ọmọ wọn lọ sáwọn ibi tí wọ́n ń pè ní ilé ẹ̀kọ́ ìdádọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀? Lílọ sírú àwọn ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ ju pé kí wọ́n kàn gé awọ tó bo nǹkan ọmọkùnrin kúrò lásán. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ lẹni tó lọ sílé ẹ̀kọ́ náà yóò fi máa gbé pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin àtàwọn olùkọ́ tí wọn kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n sì ń kọ́ láwọn ilé ìwé wọ̀nyí ló ta ko àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Ńṣe làwọn ewu tó wà nínú lílọ sírú àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọ̀nyí túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Lọ́dún 2003, ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ South African Medical Journal tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìṣègùn, kìlọ̀ pé: “A tún ti rí àwọn àbájáde tó bani lẹ́rù gan-an lọ́dún yìí, nítorí pé gbogbo àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ńláńlá níbi gbogbo láyé ló ń gbé ìròyìn àwọn ọmọ tó ń kú àtàwọn tí wọ́n dádọ̀dọ́ wọn nídàákúdàá. . . . Ní kúkúrú, ayédèrú ni ọ̀pọ̀ àwọn ibi tí wọ́n ń pè ní ‘ilé ẹ̀kọ́ ìdádọ̀dọ́’ lónìí, wọ́n sì lè gbẹ̀mí èèyàn.”

Yàtọ̀ sí àkóbá tí wọ́n lè ṣe fún ọ̀dọ́ kan nítorí àìdádọ́dọ́ rẹ̀ bó ti tọ́ àti bó ti yẹ, ewu tó tún ga jùyẹn lọ ni àkóbá tó máa ṣe fún àjọṣe àárín ọmọ náà àti Ọlọ́run. Àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn tó ń lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ wọ̀nyí àtàwọn ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú bíbá ẹ̀mí èṣù lò àti jíjọ́sìn àwọn baba ńlá tó ti kú. Bí àpẹẹrẹ, dípò kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àìkíyèsára àwọn tó ń dádọ̀dọ́ náà àti àyíká tó dọ̀tí ló ń fa àwọn jàǹbá tó máa ń ṣẹlẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn ni pé àwọn àjẹ́ tàbí àwọn baba ńlá tínú ń bí ló ń fa àwọn aburú yìí. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké, ó pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? . . . ‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’” (2 Kọ́ríńtì 6:14-17) Nítorí ìmọ̀ràn yìí, kò ní bójú mu rárá fáwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni láti rán àwọn ọmọ wọn ọkùnrin lọ sílé ẹ̀kọ́ ìdádọ̀dọ́.

Kí Ló Ń Sọ Kristẹni Kan Di Ọkùnrin?

Yálà Kristẹni kan tó jẹ́ ọkùnrin dádọ̀dọ́ tàbí kò dádọ̀dọ́, ìyẹn kọ́ ló ń fi hàn pé ó jẹ́ ọkùnrin. Ohun tó jẹ àwọn Kristẹni tòótọ́ lógún ni pé káwọn máa ṣe ohun tó dára lójú Ọlọ́run, kì í ṣe “láti ní ìrísí wíwuni nínú ẹran ara.”—Gálátíà 6:12.

Àmọ́ kí Kristẹni kan tó lè múnú Ọlọ́run dùn, ó gbọ́dọ̀ “dá adọ̀dọ́ ọkàn-àyà.” (Diutarónómì 10:16; 30:6; Mátíù 5:8) Ọ̀nà tí wọ́n sì ń gbà ṣe èyí kì í ṣe nípa fífí ọ̀bẹ gé nǹkan kan nínú ara wọn bíkòṣe nípa kíkọ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ẹ̀mí ìgbéraga sílẹ̀, irú bíi kéèyàn máa lérò pé òun sàn ju àwọn mìíràn nítorí pé òun dádọ̀dọ́. Nípa fífara da àdánwò àti nípa dídúró “gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,” Kristẹni kan á fi hàn pé òun ti di ọkùnrin, yálà ó dádọ̀dọ́ tàbí kò dádọ̀dọ́.—1 Kọ́ríńtì 16:13; Jákọ́bù 1:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́