ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 7/15 ojú ìwé 6-7
  • “Lọ Wẹ̀ Ní Odò Adágún Sílóámù”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Lọ Wẹ̀ Ní Odò Adágún Sílóámù”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Èèyàn Lè Ṣe Ohun Tó Dáa Lọ́jọ́ Sábáàtì?
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ṣíṣe Awọn Iṣẹ́ Rere ní Sabaati
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 7/15 ojú ìwé 6-7

“Lọ Wẹ̀ Ní Odò Adágún Sílóámù”

LẸ́YÌN tí Jésù ti fi amọ̀ tó fi itọ́ pò sójú afọ́jú kan, ó sọ fún un pé: “Lọ wẹ̀ ní odò adágún Sílóámù.” Ọkùnrin yẹn ṣe ohun tí Jésù ní kó ṣe, nígbà tó sì fi máa padà dé, “ó [ti] ń ríran.” (Jòhánù 9:6, 7) Ibo ni Adágún Sílóámù yìí wà? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìwádìí àwọn awalẹ̀pìtàn ti jẹ́ ká mọ ibi tó wà.

Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ti ṣèbẹ̀wò síbì kan tí wọ́n pè ní Adágún Sílóámù ní Jerúsálẹ́mù, torí wọ́n gbà pé òun gan-an ni adágún tí Jòhánù 9:7 ń sọ. Ibi tí ọ̀nà abẹ́lẹ̀, ìyẹn odò abẹ́lẹ̀ tí Hesekáyà gbẹ́ ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni parí sí ni adágún náà wà. Ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tá à ń sọ yìí gùn tó nǹkan bí ìdajì kìlómítà. Àmọ́, ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni ni wọ́n sọ pé adágún yẹn ti wà. Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ tí wọ́n ń pè ní Byzantine ni wọ́n gbẹ́ ẹ, èrò wọn sì ni pé ó ní láti jẹ́ pé ìparí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà ni adágún tí Ìhìn Rere Jòhánù sọ nípa rẹ̀ wà.

Àmọ́, lọ́dún 2004, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí adágún kan, wọ́n sì gbà pé òun gan-an ni Adágún Sílóámù tó wà nígbà ayé Jésù. Ó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mítà tí adágún tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí yìí fi jìnnà sí èyí tí wọ́n kọ́kọ́ pè ní Adágún Sílóámù. Báwo ni wọ́n ṣe wá a kàn? Àwọn aláṣẹ ìlú pinnu láti ṣàtúnṣe páìpù kan tómi ẹ̀gbin ń gba inú ẹ̀ kọjá, torí náà, àwọn òṣìṣẹ́ kó ẹ̀rọ ńlá ńlá wá láti wá ṣiṣẹ́ náà. Ọkùnrin awalẹ̀pìtàn kan tó ń ṣiṣẹ́ nítòsí ibẹ̀ ló wá wo bí wọ́n ṣe ń gbẹ́lẹ̀ náà tó sì rí i pé ohun kan tó dà bí ìpele méjì yọrí síta. Wọ́n dá iṣẹ́ náà dúró torí àtigbàṣẹ. Àwọn aláṣẹ ibẹ̀, ìyẹn Israeli Antiquities Authority sì fọwọ́ sí i pé kí wọ́n hú ohunkóhun tí wọ́n bá rí níbẹ̀, jáde. Ní báyìí, wọ́n ti hú igun méjì àti ẹ̀gbẹ́ kan adágún yẹn tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin mítà, ìyẹn igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ẹsẹ̀ bàtà jáde.

Wọ́n rí àwọn owó ẹyọ mélòó kan hú jáde, ẹ̀rí sì wà pé owó ẹyọ tí wọ́n ń ná ní nǹkan bí ọdún kejì, ìkẹta àti ìkẹrin táwọn Júù dìtẹ̀ sí ìjọba Róòmù ni. Láàárín ọdún 66 àti 70 Sànmánì Kristẹni ni ìdìtẹ̀ náà wáyé. Àwọn owó ẹyọ yẹn ló jẹ́ ẹ̀rí pé adágún yẹn ṣì wà títí dìgbà tí Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé: “Nítorí náà, wọ́n ti ní láti lo adágún yẹn títí dìgbà tí ìdìtẹ̀ náà dópin, kó tó di pé wọ́n pa á tì. Ibi tó rẹlẹ̀ jù lọ ní Jerúsálẹ́mù ni adágún yìí wà, kò sì sẹ́ni tó gbé àdúgbò ibẹ̀ títí dìgbà táwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ tí wọ́n ń pè ní Byzantine fi ṣí wá síbẹ̀. Lọ́dọọdún tójò bá ti rọ̀, ẹrẹ̀ máa ń wọ́ lọ sínú adágún náà. Ìgbà tó sì wá di pé àwọn ará Róòmù ṣẹ́gun ìlú náà, ẹnikẹ́ni ò tún kó ìdọ̀tí inú adágún náà mọ́. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí ẹrẹ̀ ti ń wọ́ lọ sínú rẹ̀, ojú ibi tó wà ò ṣeé dá mọ̀ mọ́ nítorí pé ó ti dí pátápátá. Àwọn awalẹ̀pìtàn ní láti gbẹ́lẹ̀ tó jìn tó mítà mẹ́ta, ìyẹn gíga odidi ilé kan, kí wọ́n tó kan ojú ibi tí Adágún Sílóámù wà.”

Kí nìdí táwọn ojúlówó akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi fẹ́ mọ ibi tí Adágún Sílóámù wà? Ìdí ni pé ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye bí Jerúsálẹ́mù táwọn ìwé Ìhìn Rere máa ń sábà sọ nípa rẹ̀ nínú ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣe rí gan-an.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Adágún Sílóámù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí

[Credit Line]

© 2003 BiblePlaces.com

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́