Ǹjẹ́ o ‘Ní Ọrọ̀ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run’?
“Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—LÚÙKÙ 12:21.
1, 2. (a) Kí ni nǹkan táwọn èèyàn máa ń tìtorí rẹ̀ fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn? (b) Ìṣòro àti ewu wo ló dojú kọ àwọn Kristẹni?
WÍWÁ ÌṢÚRA KIRI kì í wulẹ̀ ṣe eré ọmọdé lásán. Ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe ní ti gidi ni, wọ́n sì ti ń ṣe é tipẹ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Bí àpẹẹrẹ, Góòlù tí wọ́n ń wà láwọn orílẹ̀-èdè bíi Ọsirélíà, Gúúsù Áfíríkà, Kánádà, àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn múra tán láti fi ilé wọn àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn sílẹ̀ láti wá ọrọ̀ lọ sáwọn ilẹ̀ tí wọn ò dé rí, táwọn èèyàn ibẹ̀ ò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àlejò. Àní, ọ̀pọ̀ èèyàn ò kọ̀ láti fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn kí ọwọ́ wọn lè tẹ ọrọ̀ tọ́kàn wọ́n ń fẹ́.
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í lọ káàkiri láti wá ìṣúra, síbẹ̀ wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ àṣekára gan-an kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn. Ìyẹn ò sì rọrùn lákòókò òpin tá a wà yìí, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti àkókò, ó sì nira gan-an. Ó rọrùn láti máa wá àtijẹ àtimu kiri, kéèyàn sì máa ronú aṣọ tó máa wọ̀ àti ilé tó máa gbé débi pé yóò pa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tì tàbí kó tiẹ̀ gbàgbé wọn pátápátá. (Róòmù 14:17) Jésù sọ àkàwé kan tó gbé ohun táwọn èèyàn sábà máa ń ṣe yìí yọ dáadáa. Àkàwé náà wà nínú Lúùkù 12:16-21.
3. Ní ṣókí, sọ àkàwé Jésù tó wà nínú Lúùkù 12:16-21.
3 Àkàwé Jésù yìí wáyé lákòókò tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra fún ojúkòkòrò, èyí tá a jíròrò lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Lẹ́yìn tí Jésù kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ojúkòkòrò, ó wá sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí rẹ̀ tó kún fún ọ̀pọ̀ ohun rere tó ní. Àmọ́, tó wó wọn palẹ̀, tó sì kọ́ àwọn tó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kó bàa lè túbọ̀ kó àwọn ohun rere púpọ̀ pa mọ́ sí i. Bó ṣe ń ronú pé kóun wá fọkàn balẹ̀ kóun sì máa gbádùn ayé òun ni Ọlọ́run sọ fún un pé ikú rẹ̀ ti dé, gbogbo ohun rere tí ọkùnrin náà ti kó jọ yóò sì di ti ẹlòmíràn. Jésù wá fi gbólóhùn tó kẹ́yìn yìí kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:21) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àkàwé yìí? Báwo la ṣe lè fi ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa?
Ọkùnrin Kan Tó Ní Ìṣòro
4. Irú èèyàn wo la lè sọ pé ọkùnrin inú àkàwé Jésù yẹn jẹ́?
4 Àkàwé tí Jésù sọ yìí kò ṣàjèjì sáwọn èèyàn. A kíyè sí i pé ohun tí Jésù kàn fi bẹ̀rẹ̀ ìtàn náà ni pé: “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan mú èso jáde dáadáa.” Jésù ò sọ pé ọ̀nà èrú tàbí ọ̀nà tó lòdì sófin ni ọkùnrin náà gbà kó ọrọ̀ rẹ̀ jọ. Lédè mìíràn, Jésù ò sọ pé èèyàn burúkú lọkùnrin náà. Kódà, ohun tí Jésù sọ fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ọkùnrin inú àkàwé yìí ti ṣiṣẹ́ àṣekára. Ó kéré tán, a lè rí i pé ọkùnrin náà jẹ́ ẹni tó múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú tó sì kó àwọn nǹkan pa mọ́, bóyá kí ìyà má bàá jẹ àwọn ará ilé rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá fojú èèyàn wò ó, akínkanjú ọkùnrin tí kì í fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ojúṣe rẹ̀ la máa pè é.
5. Ìṣòro wo ni ọkùnrin inú àkàwé Jésù ní?
5 Bó ti wù kó rí, Jésù pe ọkùnrin inú àkàwé náà ní ọlọ́rọ̀, tó fi hàn pé ó jẹ́ ẹnì kan tó ti ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ní ìṣòro kan. Ohun tí ilẹ̀ rẹ̀ mú jáde pọ̀ gan-an ju ohun tó retí, ó pọ̀ gan-an ju ohun tóun fúnra rẹ̀ nílò lọ tàbí ohun tó lè bójú tó. Kí ló yẹ kó ṣe?
6. Àwọn ìpinnu wo ni ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti ṣe lóde òní?
6 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní ló ń bára wọn nínú irú ipò tó fara jọ èyí tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn bára rẹ̀. Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọn, wọ́n máa ń jẹ́ akínkanjú, wọn kì í sì í fi iṣẹ́ wọn ṣeré. (Kólósè 3:22, 23) Yálà wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún èèyàn ni ò tàbí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ara wọn, wọ́n sábà máa ń ṣe dáadáa, kódà wọ́n máa ń tayọ nínú ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé wọn ga lẹ́nu iṣẹ́ wọn tàbí tí wọ́n bá fẹ́ fún wọn láǹfààní tuntun èyíkéyìí, ó máa ń di dandan kí wọ́n ṣèpinnu. Ṣé káwọn tẹ́wọ́ gba àǹfààní tí wọ́n fẹ́ fún wọn yìí ni kówó lè túbọ̀ wọlé? Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ló máa ń ṣe dáadáa gan-an nílé ìwé. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n lè fẹ́ fún wọn ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ kí wọ́n lè lọ kàwé láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó lórúkọ. Ṣé ó yẹ kí wọ́n kàn ṣe bíi tàwọn èèyàn mìíràn kí wọ́n sì fára mọ́ ohun tí wọ́n fi lọ̀ wọ́n yìí?
7. Kí ni ọkùnrin inú àkàwé Jésù ṣe nípa ìṣòro tó ní?
7 Ẹ jẹ́ ká padà sórí àkàwé Jésù yẹn wàyí. Kí ni ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ṣe nígbà tí ilẹ̀ rẹ̀ mú ohun tó pọ̀ yanturu jáde débi pé kò ríbi kó àwọn ohun tó kórè náà sí? Ó pinnu láti wó àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí rẹ̀ lulẹ̀ kó sì kọ́ àwọn tó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ kó lè ríbi kó gbogbo ọkà àtàwọn ohun rere rẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù sí. Ìpinnu tó ṣe yẹn fi í lọ́kàn balẹ̀ gan-an ó sì fún un láyọ̀ débi pé ó ń sọ nínú ara rẹ̀ pé: “Èmi yóò sọ fún ọkàn mi pé: ‘Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.’”—Lúùkù 12:19.
Kí Nìdí Tí Ọkùnrin Náà Fi Jẹ́ “Aláìlọ́gbọ́n-Nínú”?
8. Ohun pàtàkì wo ni ọkùnrin inú àkàwé Jésù yìí gbójú fò dá?
8 Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ ọ́, ohun tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà pinnu láti ṣe yìí kò fún un ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó rò pé òun máa ní. Ó lè dà bíi pé ohun tó fẹ́ ṣe yìí bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ o, àmọ́ kò fi ohun pàtàkì kan kún un, ìyẹn ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Tara rẹ̀ nìkan ló ń rò, ó ń ronú bóun á ṣe fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, tóun á máa jẹ́, tóun á máa mu, tóun á sì máa gbádùn ara òun. Ó ti gbà pé níwọ̀n bóun ti ní “ọ̀pọ̀ ohun rere,” òun á tún wà láàyè fún “ọ̀pọ̀ ọdún.” Àmọ́, ó mà ṣe o, ibi tó fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Bí Jésù ṣe sọ níṣàájú gẹ́ẹ́ lọ̀rọ̀ ọkùnrin náà rí, ó sọ pé “nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Òru ọjọ́ yẹn gan-an ni gbogbo ohun tí ọkùnrin náà tìtorí rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ wá sópin lójijì, nítorí pé Ọlọ́run sọ fún un pé: “Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?”—Lúùkù 12:20.
9. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pe ọkùnrin inú àkàwé náà ní aláìlọ́gbọ́n-nínú?
9 Ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ ká kọ́ nínú àkàwé yìí gan-an lọ̀rọ̀ wá kàn báyìí. Ọlọ́run pe ọkùnrin náà ní aláìlọ́gbọ́n-nínú. Ìwé atúmọ̀ èdè Exegetical Dictionary of the New Testament ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n lò yẹn “sábà máa ń tọ́ka sí ẹni tí kò lóye.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà fi hàn pé nínú àkàwé yìí, Ọlọ́run ń lo ọ̀rọ̀ náà láti jẹ́ ká rí i pé “asán lórí asán ni báwọn ọlọ́rọ̀ ṣe máa ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ ọ̀la.” Ọ̀rọ̀ náà ò tọ́ka sí ẹnì kan tí kò ní làákàyè, àmọ́ ó ń tọ́ka sí “ẹni tó kọ̀ láti gbà pé Ọlọ́run ló yẹ kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé.” Bí Jésù ṣe ṣàpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn jẹ́ ká rántí ohun tó wá sọ fáwọn Kristẹni ìjọ Laodíkíà, tó wà ní Éṣíà Kékeré ní ọ̀rúndún kìíní. Ó ní: “Ìwọ wí pé: ‘Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo sì ti kó ọrọ̀ jọ, èmi kò sì nílò ohunkóhun rárá,’ ṣùgbọ́n o kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.”—Ìṣípayá 3:17.
10. Kí nìdí tí níní “ọ̀pọ̀ ohun rere” kò fi ń ṣe ẹ̀rí pé èèyàn máa wà láàyè fún “ọ̀pọ̀ ọdún”?
10 Á dára ká fi ẹ̀kọ́ inú àkàwé yìí sọ́kàn. Ṣé àwa náà ò dà bí ọkùnrin inú àkàwé yìí, ìyẹn ni pé ká ṣiṣẹ́ àṣekára láti rí i dájú pé a ní “ọ̀pọ̀ ohun rere” síbẹ̀ ká kùnà láti ṣe ohun tó máa jẹ́ ká nírètí àtiwà láàyè fún “ọ̀pọ̀ ọdún”? (Jòhánù 3:16; 17:3) Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí ó níye lórí kì yóò ṣàǹfààní rárá ní ọjọ́ ìbínú kíkan,” àti pé “ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀—òun fúnra rẹ̀ yóò ṣubú.” (Òwe 11:4, 28) Nítorí náà, Jésù wá fi ọ̀rọ̀ ìṣílétí tó kẹ́yìn yìí kún àkàwé náà, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:21.
11. Kí nìdí to fi jẹ́ pé asán lórí asán ni kéèyàn gbé ìrètí rẹ̀ ka ohun ìní, kó sì rò pé òun ló máa jẹ́ kóun nífọ̀kànbalẹ̀?
11 Nígbà tí Jésù sọ pé “bẹ́ẹ̀ náà ni ó máa ń rí,” ohun tó ń sọ ni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àkàwé yẹn ni yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn tó gbé gbogbo ìgbésí ayé wọn, ìyẹn ìrètí wọn, karí kìkì ohun ìní, tí wọ́n sì gbà pé òun ló máa fáwọn nífọ̀kànbalẹ̀. Kì í ṣe ‘títo ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara ẹni’ ni ẹ̀bi ọkùnrin náà ṣùgbọ́n pé ó kùnà láti ní “ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù fúnni ní ìkìlọ̀ kan tó jọ ìyẹn nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé: ‘Lónìí tàbí lọ́la a ó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú ńlá yìí, a ó sì lo ọdún kan níbẹ̀, a ó sì kó wọnú iṣẹ́ òwò, a ó sì jèrè,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.” Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? “Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí [wọ́n] sọ pé: ‘Bí Jèhófà bá fẹ́, àwa yóò wà láàyè, a ó sì ṣe èyí tàbí èyíinì pẹ̀lú.’” (Jákọ́bù 4:13-15) Bó ti wù kéèyàn lọ́rọ̀ tó tàbí bó ti wù káwọn ohun ìní rẹ̀ pọ̀ tó, asán lórí asán ni gbogbo rẹ̀ yóò já sí, àfi tó bá ni ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kí ló wá túmọ̀ sí láti ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
Béèyàn Ṣe Lè Ní Ọrọ̀ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
12. Kí lohun tá a ó máa ṣe tí yóò jẹ́ ká lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
12 Nínú ọ̀rọ̀ Jésù, kéèyàn ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sí títo ìṣúra ti ayé jọ fún ara ẹni, tàbí kíkó ọrọ̀ jọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí Jésù ń sọ ni pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ pé kíkó ọrọ̀ jọ tàbí bá a ṣe máa gbádùn ohun tá a ní ló máa jẹ wá lọ́kàn jù nígbèésí ayé wa. Dípò ìyẹn, a gbọ́dọ̀ lo àwọn ohun ìní wa lọ́nà tó máa jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ dára sí i. Ó dájú pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú ká lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí? Nítorí pé yóò fún wa láǹfààní láti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.
13. Báwo ni ìbùkún Jèhófà ṣe máa “ń sọni di ọlọ́rọ̀”?
13 Nígbà tí Jèhófà bá bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, ohun tó dára jù lọ ló máa ń fún wọn. (Jákọ́bù 1:17) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ tí wọ́n máa tẹ̀dó sí, ó jẹ́ “ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ilẹ̀ Íjíbítì náà nìyẹn, síbẹ̀ ilẹ̀ tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yàtọ̀ ní ọnà kan pàtàkì. Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń bójú tó” ni. Ohun tó ń sọ ni pé wọ́n á ní aásìkí nítorí pé Jèhófà yóò máa bójú tó wọn. Ní gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, wọ́n rí ìbùkún rẹ̀ gbà, wọ́n sì gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà kan tí gbogbo èèyàn rí i pé ó dáa gan-an ju ti gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká lọ. Dájúdájú, ìbùkún Jèhófà ló máa “ń sọni di ọlọ́rọ̀”!—Númérì 16:13; Diutarónómì 4:5-8; 11:8-15.
14. Kí lohun táwọn tó lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run ń gbádùn?
14 Gbólóhùn náà “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” tún túmọ̀ sí “ní ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run” (Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) tàbí “ní ọrọ̀ lójú Ọlọ́run.” (Bíbélì The New Testament in Modern English, látọwọ́ J. B. Phillips) Ohun tó jẹ àwọn ọlọ́rọ̀ lógún ni báwọn ṣe máa gbayì lójú àwọn èèyàn. Èyí sì máa ń hàn nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn. Wọ́n máa ń ṣe àṣehàn, èyí tí Bíbélì pè ní “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:16) Àmọ́, àwọn tó lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run máa ń rí ojú rere Ọlọ́run àti inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ gbà lọ́pọ̀ yanturu, wọ́n sì máa ń ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀. Ó dájú pé wíwà tí wọ́n wà nípò tó dára lójú Ọlọ́run yìí ń jẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ju èyí tí ọrọ̀ èyíkéyìí lè fúnni lọ. (Aísáyà 40:11) Ìbéèrè tó wá yẹ ká bi ara wa ni pé, kí ló yẹ ká ṣe ká bàa lè ní ọrọ̀ lójú Ọlọ́run?
Béèyàn Ṣe Lè Ní Ọrọ̀ Lójú Ọlọ́run
15. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè di ọlọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
15 Nínú àkàwé Jésù yẹn, ọkùnrin náà wéwèé ohun tó fẹ́ ṣe, ó sì ṣiṣẹ́ àṣekára kó bàa lè kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀, Ọlọ́run sì pè é ní aláìlọ́gbọ́n-nínú. Nítorí náà, tá a bá fẹ́ ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ sapá láti ṣiṣẹ́ àṣekára ká sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó níláárí tó sì ṣe pàtàkì gan-an lójú Ọlọ́run. Àṣẹ tí Jésù pa pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn” wà lára iṣẹ́ tá à ń wí yìí. (Mátíù 28:19) Tá ò bá lo àkókò wa, agbára wa, àti ẹ̀bùn tá a ní sórí wíwá nǹkan tí ara wa, ṣùgbọ́n tá a bá ń lò wọ́n fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá fowó dókòwò. Àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ sì ti rí èrè tó pọ̀ gan-an gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí ìsàlẹ̀ yìí ṣe fi hàn.—Òwe 19:17.
16, 17. Àwọn ìrírí wo lo lè sọ láti jẹ́ ká mọ ọ̀nà téèyàn lè gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ kó lè di ọlọ́rọ̀ lójú Ọlọ́run?
16 Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó jẹ́ Kristẹni lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà. Kọ̀ǹpútà ló máa ń tún ṣe nílé iṣẹ́ kan, wọ́n sì ń san owó tó pọ̀ gan-an fún un. Àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àkókò rẹ̀ ni iṣẹ́ náà ń gbà, ó sì wá rí i pé òun ò sún mọ́ Ọlọ́run tó bó ṣe yẹ. Níkẹyìn, dípò kó máa wá bọ́wọ́ òun á ṣe máa ròkè sí i lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀hún, ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó wá lọ ń ṣe áásìkiriìmù, ó sì ń tà á lójú pópó kó lè túbọ̀ ráyè gbájú mọ́ ìjọsìn rẹ̀ àti ojúṣe rẹ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ fi ṣe yẹ̀yẹ́, àmọ́ báwo ni nǹkan ṣe wá rí fún un? Ó ní: “Ní ti gidi, owó tí mo wá ń rí pọ̀ ju ti ìgbà tí mò ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ kọ̀ǹpútà yẹn. Iṣẹ́ yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ láyọ̀ nítorí pé gbogbo másùnmáwo àti ìdààmú ọkàn tí mo máa ń ní níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ yẹn kò sí mọ́. Ní pàtàkì jù lọ, mo ti wá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà dáadáa báyìí.” Ìyípadà tí Kristẹni yìí ṣe mú kó ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, ó sì ti ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ báyìí. Láìsí àní-àní, ìbùkún Jèhófà máa “ń sọni di ọlọ́rọ̀.”
17 Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti obìnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé kan tí ẹ̀kọ́ ìwé ti jẹ́ wọ́n lógún gan-an. Ó lọ sí yunifásítì lórílẹ̀-èdè Faransé, ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti nílẹ̀ Switzerland. Èyí máa fún un láǹfààní láti ríṣẹ́ tó máa sọ ọ́ dọlọ́rọ̀. Nígbà tó sì yá, ó sọ pé: “Mo rí towó ṣe gan-an, àwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fún mi, wọ́n sì máa ń kà mí sẹ́ni iyì, àmọ́ nínú mi lọ́hùn-ún, ńṣe ni mo dà bí àgbá òfìfo, inú mi ò dùn rárá.” Lẹ́yìn náà ló wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ó ní: “Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, bó ṣe ń wù mí láti múnú Jèhófà dùn àti láti dá díẹ̀ padà lára ohun tó ti fún mi ràn mí lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, ìyẹn ni pé kí n fi gbogbo àkókò mi sìn ín.” Ó kọ̀wé fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣèrìbọmi láìpẹ́ sí àkókò yẹn. Láti ogún ọdún sẹ́yìn ló ti ń fi tayọ̀tayọ̀ sin Jèhófà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Ó ní: “Àwọn kan rò pé mo ti fi ẹ̀bùn tí mo ní tàfàlà, àmọ́ wọ́n rí i pé mo láyọ̀, ìlànà tí mò ń tẹ̀ lé nígbèésí ayé mi sì wù wọ́n gan-an. Ojoojúmọ́ ni mò ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kí n lè rí ojú rere rẹ̀.”
18. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ọ̀nà wo la lè gbà ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
18 Sọ́ọ̀lù, tó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní iṣẹ́ kan tó lè sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. Síbẹ̀, ohun tó kọ nígbà tó yá ni pé: “Ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi.” (Fílípì 3:7, 8) Lójú Pọ́ọ̀lù, ọrọ̀ tó ní nípasẹ̀ Kristi ga ju ohunkóhun tí iṣẹ́ ayé lè fún un lọ. Bákan náà, tá a bá jáwọ́ nínú mo fẹ́ dogún, mo fẹ́ dọgbọ̀n, tá a sì ń gbé ìgbésí ayé ìfọkànsin Ọlọ́run, àwa náà lè gbádùn ìgbésí ayé tó lọ́rọ̀ lójú Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ìṣòro wo ni ọkùnrin inú àkàwé Jésù ní?
• Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pe ọkùnrin inú àkàwé náà ní aláìlọ́gbọ́n-nínú?
• Kí ló túmọ̀ sí láti ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
• Báwo la ṣe lè dẹni tó lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ní aláìlọ́gbọ́n-nínú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Báwo làwọn àǹfààní tá a ní láti tẹ̀ síwájú nínú ayé ṣe lè jẹ́ ìṣòro fún wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
“Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un”