Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
“Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe rí.”—SÁÀMÙ 127:4.
1, 2. Báwo làwọn ọmọ ṣe dà bí “àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá”?
TAFÀTAFÀ kan fẹ́ ta ọfà lu ohun kan. Ó rọra fi ọfà sínú okùn ọrun, ó sì fà á tágbára tágbára. Kò ro ti agbára tó gbà láti fà á, ibi tó fẹ́ ta ọfà náà sí ló ń wò. Bó ṣe jù ú sílẹ̀ báyìí, ńṣe ló ń já lọ ṣòòròṣò! Ǹjẹ́ ọfà yìí á ba ohun tó ta á sí? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa pinnu bóyá á bà á àbí kò ní bà á. Lára ohun tó máa pinnu ni, bí ọwọ́ ẹni tó ta ọfà yẹn ṣe tọ́ tó, bí afẹ́fẹ́ á ṣe gbé ọfà náà sí àti bí ọfà yẹn fúnra ẹ̀ ṣe rí.
2 Sólómọ́nì Ọba fi àwọn ọmọ wé “àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá.” (Sáàmù 127:4) Wo bá a ṣe lè lo àpèjúwe yìí. Àkókò tí ọfà yẹn máa lò nínú ọrun tafàtafà yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Tó bá fẹ́ kó ba ohun tó fẹ́ ta á lù, ó gbọ́dọ̀ tètè jù ú sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìgbà díẹ̀ làwọn òbí ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkànwá. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn ọmọ ti dàgbà wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í filé sílẹ̀. (Mátíù 19:5) Ṣáwọn ọfà yẹn a lọ síbi táwọn òbí ta wọ́n sí, ìyẹn ni pé ṣáwọn ọmọ á máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nìṣó tí wọ́n á sì máa sìn ín lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kúrò lábẹ́ òbí wọn? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa pinnu bí ìdáhùn ṣe máa rí. Mẹ́ta nínú wọn ni bí òbí ṣe mọ ọmọ tọ́ sí, bí nǹkan ṣe rí nínú ilé tí wọ́n ti ń tọ́ àwọn ọmọ àti bí ọmọ kọ̀ọ̀kan, tá a lè fi wé ọfà, ṣe tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ àwọn òbí ẹ̀ tó. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan. Lákọ̀ọ́kọ́, a ó ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tó fi hàn pé òbí kan mọ ọmọ tọ́.
Àwọn Òbí Tó Mọ Ọmọ Tọ́ Máa Ń Fi Àpẹẹrẹ Tó Dáa Lélẹ̀
3. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe òbí bára mu?
3 Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn òbí torí pé ohun tó ń kọ́ni ló fi ń ṣèwà hù. (Jòhánù 13:15) Àmọ́, ó bẹnu àtẹ́ lu àwọn Farisí tí wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n ń sọ. (Mátíù 23:3) Táwọn òbí bá fẹ́ káwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn náà gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ. Tí ohun tí wọ́n ń sọ bá yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe, ọ̀rọ̀ wọn ò ní wúlò, ńṣe ló máa dà bí ọrun tí ò ní okùn.—1 Jòhánù 3:18.
4. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn òbí bi ara wọn, kí sì nìdí?
4 Kí nìdí tí àpẹẹrẹ àwọn òbí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Bó ṣe jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà lè kọ́ nípa Ọlọ́run tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ ṣe lè kọ́ nípa Jèhófà tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere àwọn òbí wọn. Ẹni tọ́mọdé bá sún mọ́ lè mú kó ya ọmọ dáadáa tàbí kó mú kí ‘ìwà rere rẹ̀ bà jẹ́.’ (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àwọn òbí ọmọ lọ́mọ máa ń sún mọ́ jù, àwọn náà ló sì máa nípa lórí rẹ̀ jù lọ, pàápàá nígbà tọ́mọ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́njú. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwọn òbí bi ara wọn pé: ‘Irú ọ̀rẹ́ wo ni mo jẹ́ fọ́mọ mi? Ṣé àpẹẹrẹ mi tọ́mọ mi ń rí á mú kó níwà rere? Àpẹẹrẹ wo ni mò ń fi lélẹ̀ lórí àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì bí àdúrà gbígbà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?’
Àwọn Òbí Tó Mọ Ọmọ Tọ́ Máa Ń Gbàdúrà Pẹ̀lú Àwọn Ọmọ Wọn
5. Kí làwọn ọmọ lè rí kọ́ nípa gbígbọ́ àdúrà àwọn òbí wọn?
5 Àwọn ọmọ yín lè rí ohun tó pọ̀ kọ́ nípa Jèhófà tí wọ́n bá ń gbọ́ àdúrà yín. Bí wọ́n bá ń gbọ́ tẹ́ ẹ̀ ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run kẹ́ ẹ tó jẹun tẹ́ ẹ sì ń gbàdúrà nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn á kọ́ wọn? Ó ṣeé ṣe kó yé wọn pé Jèhófà ló ń fún wa láwọn ohun tára wa ń fẹ́, ó sì yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti pé Jèhófà ló ń kọ́ wa láwọn òtítọ́ tá a mọ̀ látinú Bíbélì. Ẹ̀kọ́ iyebíye sì nìwọ̀nyí.—Jákọ́bù 1:17.
6. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí i pé Jèhófà ka ọ̀rọ̀ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sí?
6 Àmọ́, tẹ́ ẹ bá ń gbàdúrà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé láwọn àkókò míì yàtọ̀ sí àkókò oúnjẹ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tẹ́ ẹ sì ń fi ọ̀rọ̀ tó kan ẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín sínú àdúrà, ó dájú pé àwọn ọmọ yín á túbọ̀ rí ohun tó pọ̀ kọ́. Èyí á jẹ́ kẹ́ ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí i pé Jèhófà wà nínú ìdílé yín àti pé ọ̀rọ̀ yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ ẹ́ lọ́kàn gidigidi. (Éfésù 6:18; 1 Pétérù 5:6, 7) Bàbá kan sọ pé: “Látìgbà tá a ti bí ọmọbìnrin wa la ti máa ń gbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀. Bó ṣe ń dàgbà sí i, à ń gbàdúrà pé kó má ṣe bá àwọn èèyànkéèyàn rìn a sì máa ń gbàdúrà nípa àwọn ọ̀ràn míì tó kàn án. Títí dìgbà tó fi kúrò nílé tó lọ ilé ọkọ ẹ̀, ọjọ́ kan ò kọjá ká má gbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀.” Ṣé ẹ̀yin náà lè máa gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ yín lójoojúmọ́? Ṣé ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rẹ́ tó ń pèsè àwọn ohun tó ń gbé ẹ̀mí wọn ró, tó sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò láti sìn ín, tí kò sì fi ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn ṣeré?—Fílípì 4:6, 7.
7. Kí àdúrà àwọn òbí lórí àwọn ọmọ wọn bàa lè dá lórí ohun kan pàtó, kí ni wọ́n ní láti mọ̀?
7 Ó dájú pé kó o tó lè gbàdúrà nípa ohun tó kan ọmọ rẹ, o ní láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé ẹ̀. Ẹ kíyè sí ohun tí bàbá kan tó tọ́ ọmọbìnrin méjì dàgbà sọ, ó ní: “Ní òpin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, mo máa ń bi ara mi ní ìbéèrè méjì. Àwọn ìbéèrè ọ̀hún ni: ‘Àwọn ọ̀ràn wo ló gba àwọn ọmọ mi lọ́kàn lọ́sẹ̀ yìí? Àwọn nǹkan dáadáa wo ló sì ṣẹlẹ̀ sí wọn?’” Ẹ̀yin òbí, ṣé kò ní dáa kẹ́yin náà máa bi ara yín láwọn ìbéèrè yẹn, kẹ́ ẹ sì wá fi àwọn ọ̀ràn náà sínú àdúrà tẹ́ ẹ bá ń gbà pẹ̀lú àwọn ọmọ yín? Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ wọn ni pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà, tó jẹ́ Olùgbọ́ àdúrà. Ìyẹn nìkan kọ́, ẹ tún ń kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 65:2.
Àwọn Òbí Tó Mọ Ọmọ Tọ́ Máa Ń Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dáadáa
8. Kí nìdí táwọn òbí fi gbọ́dọ̀ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ wọn lára?
8 Báwo ni èrò tí òbí ní nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè pinnu bí ọmọ á ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó? Bí àárín àwọn méjì kan bá máa gún régé tí àjọṣe wọn ò sì ní bà jẹ́, àwọn méjèèjì ní láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì máa fetí sí ara wọn. Ọ̀nà kan tá a gbà ń fetí sí Jèhófà ni nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká máa lo àwọn ìwé tí “ẹrú olóòótọ́” ṣe. (Mátíù 24:45-47; Òwe 4:1, 2) Torí náà, táwọn òbí bá fẹ́ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà tí wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ títí láé, wọ́n ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.
9. Báwo lẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́?
9 Báwo la ṣe lè ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe yẹ? Nínú ọ̀ràn yìí pẹ̀lú, àpẹẹrẹ òbí ló ṣe pàtàkì jù. Ṣé àwọn ọmọ yín máa ń rí yín lemọ́lemọ́ tí ẹ̀ ń gbádùn Bíbélì kíkà tàbí ìdákẹ́kọ̀ọ́? Lóòótọ́, ọwọ́ rẹ lè dí torí bíbójútó àwọn ọmọ rẹ, o sì lè máa rò ó pé ibo ni wàá ti máa ráyè kàwé tàbí kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ bi ara rẹ pé, ‘Ṣé àwọn ọmọ mi máa ń rí mi lemọ́lemọ́ tí mo ń wo tẹlifíṣọ̀n?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣó o lè lo díẹ̀ nínú àkókò náà láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn lórí ọ̀ràn ìdákẹ́kọ̀ọ́?
10, 11. Kí nìdí táwọn òbí fi ní láti máa jíròrò Bíbélì déédéé nínú ìdílé wọn?
10 Ohun míì táwọn òbí lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa fetí sí Jèhófà ni pé kí wọ́n máa jíròrò Bíbélì déédéé nínú ìdílé wọn. (Aísáyà 30:21) Àmọ́ ṣá, àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Kí tún làwọn ọmọ fẹ́ fi ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ṣe táwọn òbí bá ti ń mú wọn lọ sí ìpàdé ìjọ ní gbogbo ìgbà?’ Ohun tí wọ́n fẹ́ fi ṣe pọ̀. Àwọn òbí ni Jèhófà dìídì gbé iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ọmọ wọn lé lọ́wọ́. (Òwe 1:8; Éfésù 6:4) Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ìdílé máa ń kọ́ àwọn ọmọ pé ìjọsìn kì í kàn-án ṣe ààtò kan lásán, èyí téèyàn ń ṣe ní gbangba nìkan, àmọ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn Jèhófà nínú ilé.—Diutarónómì 6:6-9.
11 Ìdí míì tún ni pé táwọn òbí bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é, á jẹ́ kí wọ́n lè mọ èrò àwọn ọmọ wọn lórí ọ̀ràn tó jẹ́ mọ́ ìjọsìn àti ìwà tó dára. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ bá ṣì kéré, àwọn òbí lè lo àwọn ìwé bíi Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.a Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ìpínrọ̀ tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ni wọ́n ti ní káwọn ọmọ máa sọ èrò wọn lórí kókó tí wọ́n jíròrò ní àkòrí yẹn. Báwọn òbí bá bá àwọn ọmọ wọn fèròwérò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé náà, wọ́n á lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lo agbára ìmòye wọn “láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.
12. Báwo làwọn òbí ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé bá ipò àwọn ọmọ wọn mu, kí lẹ sì ti rí i pé ó gbéṣẹ́ nínú ìdílé yín?
12 Báwọn ọmọ yín bá ṣe ń dàgbà sí i, ẹ máa mú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ipò wọn mu. Ẹ wo báwọn tọkọtaya kan ṣe ran àwọn ọ̀dọ́bìnrin wọn tí ò tíì pé ogún ọdún lọ́wọ́ láti ronú nígbà tí wọ́n láwọn fẹ́ lọ sí ibi ijó kan nílé ìwé wọn. Baálé ilé yẹn sọ pé: “A sọ fún àwọn ọmọ wa pé nígbà tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa, a máa ṣe eré kan. Èmi àtìyàwó mi á ṣe ọmọ nígbà táwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì á ṣe òbí. Èyí tó bá wù nínú àwọn méjèèjì lè ṣe Bàbá tàbí Màmá, ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣe ìwádìí nípa ijó jíjó ní ilé ìwé kí wọ́n sì tọ́ wa sọ́nà.” Báwo lọ̀ràn náà ṣe lọ? Bàbá náà sọ síwájú pé: “Ó yà wá lẹ́nu láti rí báwọn ọmọbìnrin wa ṣe lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ (nígbà tí wọ́n ṣe òbí) tí wọ́n sì ṣàlàyé fún (àwa tá a ṣe ọmọ) lórí ohun tí wọ́n rí tó bá Bíbélì mu tí kò fi yẹ kéèyàn lọ síbi ijó yẹn. Ohun tó tún wá yà wá lẹ́nu ni àwọn àbá tí wọ́n mú wá lórí ohun míì téèyàn lè ṣe dípò lílọ jó nílé ìwé. Èyí ràn wá lọ́wọ́ púpọ̀ láti mọ bí wọ́n ṣe ń ronú àti ohun tó wù wọ́n.” Lóòótọ́ o, kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó lè máa lọ déédéé kó sì lè ṣe ìdílé láǹfààní, ó gba pé ká máa ṣe é láìjáwọ́, ká sì máa ronú ohun tó lè ran ìdílé lọ́wọ́. Àmọ́ èrè tó wà níbẹ̀ pọ̀ jọjọ.—Òwe 23:15.
Ẹ Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Ilé
13, 14. (a) Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè mú kí àlàáfíà jọba nínú ilé? (b) Àǹfààní wo ló lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ tí òbí bá ń gbà pé òun ṣàṣìṣe?
13 Ara ohun tó tún lè mú kí ọfà lọ síbi tí tafàtafà ta á sí ni pé kó fara balẹ̀ kọjú ẹ̀ síbi tó fẹ́ ta á sí kó sì rọra jù ú sílẹ̀. Bọ́rọ̀ àwọn ọmọ ṣe rí náà nìyẹn, wọ́n á lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà táwọn òbí wọn bá mú kí àlàáfíà jọba nínú ilé. Jákọ́bù sọ pé: “Èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” (Jákọ́bù 3:18) Báwo làwọn òbí ṣe lè mú kí àlàáfíà jọba nínú ilé? Tọkọtaya ní láti mú kí àárín àwọn méjèèjì dán mọ́rán dáadáa. Ọkọ àti aya tó bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn ló máa rọrùn fún jù láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ní ìfẹ́ kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíì, títí kan Jèhófà. (Gálátíà 6:7; Éfésù 5:33) Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ máa ń jẹ́ kí àlàáfíà rídìí jókòó. Tí ọkọ àti aya bá ń gba àlàáfíà láyè láàárín ara wọn, á túbọ̀ rọrùn fún wọn láti bójú tó èdè àìyedè tó bá fẹ́ yọjú nínú ìdílé.
14 Àmọ́ ṣá, níwọ̀n bí kò ti sí ìgbéyàwó tí kò níṣòro, bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ìdílé tí kò níṣòro tiẹ̀. Nígbà míì, ẹ̀yin òbí lè ṣàìfi èso tẹ̀mí sílò nígbà tẹ́ ẹ bá ń bá àwọn ọmọ yín lò. (Gálátíà 5:22, 23) Nírú àkókò yẹn, kí ló yẹ kẹ́ ẹ ṣe? Ṣé táwọn òbí bá gbà pé àwọn ṣe àṣìṣe, ṣé ìyẹn ò ní jẹ́ káwọn ọmọ wọn bọ̀wọ̀ fún wọn bó ṣe yẹ ni? Ẹ jẹ́ ká fi ti Pọ́ọ̀lù ṣàpẹẹrẹ. Bíi bàbá nínú òtítọ́ ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. (1 Kọ́ríńtì 4:15) Síbẹ̀ náà, kò fi bò pé òun máa ń ṣàṣìṣe. (Róòmù 7:21-25) Àmọ́, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ yẹn mú kí ọ̀wọ̀ tá a ní fún un pọ̀ sí i dípò kó dín kù. Láìfi ti àwọn àṣìṣe tó ṣe pè, ọkàn Pọ́ọ̀lù balẹ̀ láti kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 11:1) Bẹ́yin náà bá ń gba àṣìṣe yín, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ yín máa gbójú fò ó.
15, 16. Kí nìdí táwọn òbí fi ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin, báwo ni wọ́n sì ṣe lè ṣe èyí?
15 Kí tún lẹ̀yin òbí lè ṣe láti rí i pé àlàáfíà jọba nínú ilé yín táwọn ọmọ yín á sì dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nígbà tí wọ́n bá dàgbà? Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòhánù 4:20, 21) Èyí fi hàn pé tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin, ńṣe lẹ̀ ń kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ó yẹ káwọn òbí bi ara wọn láwọn ìbéèrè yìí, ‘Ṣé ọ̀rọ̀ ìwúrí ló máa ń hàn jù nínú ohun tí mo máa ń sọ nípa ìjọ àbí àríwísí?’ Báwo lẹ ṣe lè mọ̀? Ẹ máa kíyè sí báwọn ọmọ yín ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ìpàdé àtàwọn ará ìjọ. Ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ rí i pé fèrè tẹ́ ẹ fun sáwọn ọmọ yín nínú ni wọ́n ń fun síta bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀.
16 Báwo wá làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará? Arákùnrin Peter, tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọkùnrin méjì, sọ pé: “Látìgbà táwọn ọmọkùnrin wa ti wà ní kéékèèké la ti máa ń pe àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn wá sílé wa. Wọ́n á wá bá wa jẹun wọ́n á sì lo àkókò díẹ̀ nílé wa, a sì máa ń gbádùn ẹ̀ gan-an ni. Báwọn ọmọ wa ṣe ń dàgbà, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni wọ́n ń bá rìn wọ́n sì ti wá rí i báyìí pé sísin Jèhófà ni ọ̀nà tó dáa láti gbà gbé ìgbé ayé ẹni.” Dennis, tóun náà bí ọmọbìnrin márùn-ún sọ pé, “A rọ àwọn ọmọbìnrin wa pé kí wọ́n máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ṣọ̀rẹ́ nínú ìjọ. Ní gbogbo ìgbà tó bá sì ṣeé ṣe, a máa ń gba àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtìyàwó wọn lálejò.” Ṣé ẹ̀yin náà lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti máa wo àwọn ará ìjọ bíi pé ara ìdílé yín ni wọ́n?—Máàkù 10:29, 30.
Ọmọ Ní Ojúṣe Tiẹ̀
17. Ìpinnu wo làwọn ọmọ ṣì ń bọ̀ wá ṣe bópẹ́bóyá?
17 Tún wo àpèjúwe tafàtafà yẹn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ọwọ́ tafàtafà yẹn lè tọ́ o, àmọ́ bóyá ni ọfà yẹn á ba ohun tó ta á sí tí ọfà yẹn bá tẹ̀ tàbí tó bá wọ́. A mọ̀ pé àwọn òbí á sa gbogbo ipa wọn láti tún èrò tí ò dáa tó wà lọ́kàn ọmọ ṣe, gẹ́gẹ́ bí tafàtafà kan á ṣe sapá láti na ọfà tó tẹ̀. Àmọ́ bópẹ́bóyá, àwọn ọmọ ló ṣì ń bọ̀ wá pinnu fúnra wọn bóyá wọ́n á gbà kí ayé yìí tẹ àwọn síbi táyé tẹ̀ sí tàbí wọ́n á jẹ́ kí Jèhófà mú ‘ipa ọ̀nà àwọn tọ́.’—Òwe 3:5, 6; Róòmù 12:2.
18. Ipa wo ni ìpinnu tọ́mọ kan bá ṣe lè ní lórí àwọn míì?
18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ pàtàkì tó wà lọ́rùn àwọn òbí ni pé kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” ọmọ kọ̀ọ̀kan fúnra rẹ̀ ló máa pinnu ohun tó máa yà tó bá dàgbà. (Éfésù 6:4) Torí náà, ẹ̀yin ọmọ, ó yẹ kẹ́ ẹ bi ara yín pé, ‘Ṣé màá gba ẹ̀kọ́ táwọn òbí mi ń kọ́ mi tìfẹ́tìfẹ́?’ Tó o bá gbẹ̀kọ́ yẹn, ọ̀nà táyé ẹ máa gbà dáa jù lọ lo fẹsẹ̀ lé yẹn. Wàá múnú àwọn òbí rẹ dùn gan-an. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, wàá mú ọkàn Jèhófà yọ̀.—Òwe 27:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo làwọn òbí ṣe lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
• Báwo làwọn òbí ṣe lè jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ilé?
• Ìpinnu wo làwọn ọmọ ní láti ṣe, báwo ni ìpinnu yẹn á sì ṣe kan àwọn ẹlòmíì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ṣé ẹ máa ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ yín lórí ọ̀rọ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Inú ilé tó bá tòrò layọ̀ ibẹ̀ máa ń pọ̀