ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/1 ojú ìwé 4-7
  • Àwọn Ìpinnu Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpinnu Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Bá Àwọn Èèyàn Lò
  • Ìpinnu Tá A Ṣe Nítorí Pé A Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
  • Ìpinnu Tá A Ṣe Nítorí Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
  • Bó O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Nígbà Ọ̀dọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ṣé Wọ́n Máa Sin Jèhófà Tí Wọ́n Bá Dàgbà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Lo Òmìnira Tá A ní Láti Sèpinnu?
    Jí!—2003
  • “Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/1 ojú ìwé 4-7

Àwọn Ìpinnu Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀

“KÁ NÍ mo mọ̀ ni, nǹkan míì ni ǹ bá ṣe!” Ìgbà mélòó lo ti sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn? Gbogbo wa la máa ń fẹ́ ṣèpinnu tá ò ní kábàámọ̀ rẹ̀, àgàgà tó bá jẹ́ ìpinnu tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìgbésí ayé wa. Báwo la ṣe lè ṣèpinnu tó máa mú wa láyọ̀?

Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká ní àwọn ìlànà tó ṣeé gbára lé. Ǹjẹ́ irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ wà? Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbà pé ó wà. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ìdá mẹ́ta nínú ìdá mẹ́rin àwọn ọmọ tó ku ọdún kan kí wọ́n jáde ilé ẹ̀kọ́ girama ló gbà pé kò sí ìlànà kankan tá a fi ń mọ̀ pé ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́. Wọ́n sì tún gbà pé, ọ̀rọ̀ nípa ìwà rere àti ìwà búburú sinmi lórí “ojú tí kálukú fi ń wo nǹkan àti àṣà ìbílẹ̀ kálukú.”

Àmọ́, ṣé ó bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ kéèyàn máa ronú pé irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù wulẹ̀ sinmi lórí ohun tí kálukú bá fẹ́ tàbí ohun tó jẹ́ èrò ọ̀pọ̀ èèyàn? Rárá o, kò bọ́gbọ́n mu. Táwọn èèyàn bá lómìnira láti máa ṣe ohunkóhun tó bá wù wọ́n, àbájáde rẹ̀ ò ní dáa rárá. Tá ló fẹ́ kóun máa gbé ìlú kan tí kò lófin, tí kò nílé ẹjọ́, tí kò sì ní ọlọ́pàá? Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe gbogbo ìgbà lohun tó bá dára lójú èèyàn máa ń tọ̀nà. A lè pinnu láti ṣe ohun kan tá a rò pé ó tọ̀nà, àmọ́ ká wá rí i nígbà tó yá pé ohun tá a ṣe yẹn kọ́ ló yẹ ká ṣe. Láìsí àní-àní, ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ látìgbà téèyàn ti wà lórí ilẹ̀ ayé fi hàn pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ibo wá la ti lè rí ìtọ́sọ́nà nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wa?

Ọ̀dọ́ tó jẹ́ alákòóso tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu, ó lọ sọ́dọ̀ Jésù. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i, nígbà tí Jésù ń dáhùn ìbéèrè ọ̀dọ́kùnrin náà, ó tọ́ka sí Òfin Ọlọ́run. Jésù gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo lèèyàn ti lè gba ìmọ̀ àti ọgbọ́n tó ga jù lọ àti pé òun ló mọ ohun tó lè ṣe ẹ̀dá láǹfààní jù lọ. Látàrí èyí, Jésù sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Ní ti tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lohun tá a lè gbára lé jù lọ tá a bá fẹ́ ìtọ́sọ́nà tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání nígbèésí ayé wa. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà díẹ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó jẹ́ pé tá a bá fi wọ́n sílò, ayọ̀ wa yóò túbọ̀ pọ̀ sí i.

Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Bá Àwọn Èèyàn Lò

Nínú Ìwàásù olókìkí tí Jésù ṣe lórí Òkè, ó kọ́ni ní ìlànà pàtàkì kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Ohun tó sọ rèé, ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.

Àwọn kan ti sọ gbólóhùn yìí lọ́nà mìíràn, wọ́n ní: “Ohunkóhun tí ẹ kò bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí yín, ẹ má ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú.” Ká lè mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìlànà pàtàkì tí Jésù fún wa yìí àti ọ̀nà mìíràn táwọn èèyàn gbà ń sọ ọ́, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àkàwé aláàánú ará Samáríà tí Jésù sọ. Àwọn ọlọ́ṣà lu ọkùnrin Júù kan débi pé díẹ̀ ló kù kó kú, wọ́n sì fi í sílẹ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà. Àlùfáà kan àti ọmọ Léfì kan rí i, àmọ́ ńṣe ni wọ́n gba ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọjá. A lè sọ pé ohun tí wọ́n ṣe yìí bá ọ̀nà mìíràn táwọn kan gbà ń sọ ọ̀rọ̀ Jésù yẹn mu, nítorí pé wọn ò ṣe ohunkóhun láti dá kún ìṣòro ọkùnrin náà. Àmọ́, ará Samáríà kan dúró, ó sì ran ọkùnrin yìí lọ́wọ́. Ó di ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e lọ síbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn aláìsàn. Ohun tó máa fẹ́ kéèyàn ṣe sóun gẹ́lẹ́ ló ṣe fún ọkùnrin náà. Ó tẹ̀ lé ìlànà pàtàkì yẹn, o sì ṣèpinnu tó dára.—Lúùkù 10:30-37.

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà tẹ̀ lé ìlànà yìí nínú ìwà wa táá sì yọrí sí ayọ̀. Ká sọ pé ìdílé kan ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sádùúgbò rẹ. O ò ṣe lọ sọ́dọ̀ wọn kó o lọ kí wọ́n káàbọ̀? O lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àdúgbò náà dáadáa, kó o ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá ní, kó o sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àwọn nǹkan mìíràn. Fífi ìfẹ́ hàn sáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sádùúgbò rẹ yìí á jẹ́ kí àjọṣe àárín yín dára gan-an. Inú rẹ yóò sì dùn pé ó ṣe ohun tó múnú Ọlọ́run dùn. Ǹjẹ́ ìyẹn kì í ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

Ìpinnu Tá A Ṣe Nítorí Pé A Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn

Yàtọ̀ sí ìlànà pàtàkì tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè yìí, Jésù tún fúnni ní ìtọ́sọ́nà mìíràn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Nígbà táwọn èèyàn béèrè èyí tó tóbi jù lọ nínú Òfin Mósè, Jésù fèsì pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́, àti àwọn Wòlíì.”—Mátíù 22:36-40.

Ní alẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù kú, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní “àṣẹ tuntun kan,” pé kí wọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Jòhánù 13:34) Kí nìdí tó fi sọ pé àṣẹ tuntun ni àṣẹ yẹn? Ṣebí ó ti kọ́kọ́ ṣàlàyé fún wọn pé nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣẹ méjì tí gbogbo Òfin so kọ́. Nínú Òfin Mósè, Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Àmọ́, Jésù wá ń pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ báyìí pé kí wọ́n ṣe jùyẹn lọ. Òru ọjọ́ yẹn náà ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun ò ní pẹ́ fi ẹ̀mí òun lélẹ̀ nítorí tiwọn. Ó wá sọ fún wọn pé: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:12, 13) Ní ti tòótọ́, àṣẹ tuntun ni àṣẹ yìí nítorí pé ó gba pé ká fi ọ̀ràn àwọn ẹlòmíì ṣáájú tiwa.

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fi irú ìfẹ́ yìí hàn, kó má ṣe jẹ́ pé tara wa nìkan la mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé nínú ilé tó ò ń gbé, o fẹ́ máa gbọ́ orin tó lọ sókè gan-an kí inú rẹ lè máa dùn, àmọ́ ariwo orin náà ń bí àwọn aládùúgbò rẹ nínú. Ṣé wàá fẹ́ láti dín ìgbádùn tiẹ̀ kù, kí ara lè tu àwọn aládùúgbò rẹ? Lédè mìíràn, ṣé wàá jẹ́ kí ohun tó máa ṣe àwọn aládùúgbò rẹ̀ láǹfààní ká ọ lára ju ohun tó o nífẹ̀ẹ́ sí?

Àpẹẹrẹ mìíràn rèé. Lọ́jọ́ kan tí òtútù mú gan-an nílẹ̀ Kánádà tí yìnyín sì ń já bọ́, méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé bàbá àgbàlagbà kan. Níbi tí wọ́n ti jọ ń fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀, bàbá náà sọ fún wọn pé àìsàn ọkàn tó máa ń yọ òun lẹ́nu kò jẹ́ kóun lè kó yìnyín tó wà níwájú ilé òun kúrò. Nǹkan bíi wákàtí kan lẹ́yìn ìyẹn ló ń gbọ́ ìró ṣọ́bìrì táwọn kan fi ń kó yìnyín náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì yẹn ti padà wá bá a kó yìnyín náà kúrò lójú ọ̀nà tó lọ síbi ilẹ̀kùn iwájú ilé rẹ̀. Bàbá yìí wá kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Kánádà, ó sọ pé: “Lónìí, mo fojú ara mi rí ohun tó ń jẹ́ ojúlówó ìfẹ́ Kristẹni. Ó wá jẹ́ kí n tún ní èrò mìíràn nípa ayé òde òní tí mo ti rò pé kò lè dáa mọ́, ó sì jẹ́ kí ọ̀wọ̀ tí mo ní fún iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe kárí ayé túbọ̀ pọ̀ sí i.” Ó dájú pé téèyàn bá ṣèrànwọ́, bó ti wú kí ìrànlọ́wọ́ náà kéré tó, ó lè nípa tó dáa gan-an lórí àwọn ẹlòmíì. Ẹ ò rí i pé ayọ̀ wà nínú kéèyàn máa lo ara rẹ̀ fáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́!

Ìpinnu Tá A Ṣe Nítorí Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

Kókó mìíràn tá a tún gbọ́dọ̀ ronú lé nígbà tá a bá ń ṣèpinnu ni ohun tí Jésù pè ní àṣẹ tó tóbi ju lọ, ìyẹn ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Jésù sọ̀rọ̀ yìí fáwọn Júù, tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa sin Ọlọ́run òun pẹ̀lú gbogbo ọkàn òun, kóun sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntara.—Diutarónómì 30:15, 16.

Bákan náà, ìpinnu tó o bá ṣe ló máa fi èrò tó o ní nípa Ọlọ́run hàn. Bí àpẹẹrẹ, bó o ṣe túbọ̀ ń gba ìmọ̀ sí i, tó o sì túbọ̀ ń mọrírì bí Bíbélì ṣe ń ṣeni láǹfààní tó, ìwọ náà ni láti ṣèpinnu. Ṣé wàá múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì ní i lọ́kàn pé ìwọ náà á di ọmọlẹ́yìn Jésù tó bá yá? Ó dájú pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fún ọ láyọ̀, nítorí pé Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.

A ò mọ̀ bóyá ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ alákòóso yẹn kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe. Ṣùgbọ́n, a mọ bí nǹkan ṣe rí lára àpọ́sítélì Pétérù lẹ́yìn tó ti tẹ̀ lé Jésù Kristi fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ní nǹkan bí ọdún 64 Sànmánì Kristẹni, tí Pétérù ti ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ó gba àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pétérù 1:14; 3:14) Ó hàn gbangba pé Pétérù ò kábàámọ̀ ìpinnu tó ti ṣe ní ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, ó sì gba àwọn ẹlòmíràn níyànjú pé káwọn náà má ṣe yí ìpinnu tí wọn ti ṣe padà.

Títẹ̀lé ìmọ̀ràn Pétérù túmọ̀ sí pé kéèyàn pinnu láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kéèyàn sì máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́. (Lúùkù 9:23; 1 Jòhánù 5:3) Èyí lè dà bí ohun tí kò rọrùn, àmọ́ Jésù ṣe ìlérí kan tó fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an, ó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.

Wo àpẹẹrẹ ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Arthur. Nígbà tí Arthur wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ta gòjé, ó sì ní i lọ́kàn pé ìyẹn lóun máa fi ṣiṣẹ́ ṣe. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ó ti dẹni tó lọ ń ta gòjé láwọn agbo ijó. Síbẹ̀ kò láyọ̀. Gbogbo ìgbà ni bàbá rẹ̀ máa ń béèrè ìbéèrè nípa ìdí tá a fi wà láyé, tó sì máa ń pe àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn wá sílé rẹ̀, síbẹ̀ ìdáhùn wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Nínú ìdílé wọn, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí àti ìdí tó fi fàyè gba ìwà ibi. Nígbà tó yá, bàbá Arthur bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọ̀rọ̀ wérọ̀. Ìjíròrò yẹn wọ bàbá Arthur lọ́kàn gan-an, ìyẹn sì mú kí gbogbo ìdílé náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, Arthur bẹ̀rẹ̀ sí í lóye Ìwé Mímọ́, ó sì wá mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, ó tún mọ ìdí tá a fi wà láyé. Arthur àtàwọn mẹ́ta mìíràn nínú ìdílé rẹ̀ wá ṣèpinnu kan tí wọn ò kábàámọ̀ rẹ̀. Ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó ní: “Inú mi dùn gan-an pé Jèhófà fún mi ní ìmọ̀ òtítọ́, ó sì ti yọ mí nínú ẹ̀mí ìdíje tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ń fi orin kíkọ ṣe iṣẹ́ ṣe. Kò sóhun táwọn èèyàn ò lè ṣe kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí.”

Arthur ṣì máa ń ta gòjé rẹ̀ láti dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lára yá, àmọ́ ìyẹn kọ́ ló ń fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Dípò ìyẹn, iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run ló gbájú mọ́. Ó ń sìn ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Dípò kó o dà bí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ alákòóso yẹn, ìwọ náà lè ṣèpinnu tó máa fún ọ láyọ̀ gan-an bíi ti Arthur àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn mìíràn, ìyẹn ni pé kó o dáhùn pípè tí Jésù ń pè ọ́ pé kó o wá di ọmọ ẹ̀yìn òun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìpinnu tó o bá ṣe lè mú àwọn ẹlòmíràn láyọ̀ gan-an

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé wàá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o sì di ọmọlẹ́yìn Jésù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́