Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ń sọ̀rọ̀
“Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin [máa ń] ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin [Ọlọ́run] lọ́nà ti ẹ̀dá.”—RÓÒMÙ 2:14.
1, 2. (a) Kí làwọn èèyàn kan ti ṣe torí àtiṣàánú àwọn ẹlòmíràn? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo la rí nínú Ìwé Mímọ́ nípa báwọn èèyàn ṣe ṣàánú àwọn ẹlòmíràn?
WÁRÁPÁ gbé ọmọkùnrin ẹni ogún ọdún kan tó dúró sórí pèpéle lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n ti ń wọkọ̀ ojú irin tó máa ń gba abẹ́ ilẹ̀, ó sì ṣubú sójú irin tí ọkọ̀ náà máa ń gbà. Bí ọ̀gbẹ́ni kan tó dúró sí tòsí ibẹ̀ ṣe rí i báyìí, ó ju àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì lọ́wọ́ sílẹ̀, ó sì bẹ́ sójú irin náà. Ó wọ́ ọmọkùnrin tí wárápá gbé yẹn kúrò lójú irin ó sì gbé e sáàárín méjì ojú irin, ó wá ràgà bò ó kí ọkọ̀ ojú irin tó ń bá eré bọ̀ tó fẹ́ dúró máa bàa gorí ẹ̀. Àwọn kan lè pe ọkùnrin aláàánú yẹn ní akíkanjú o, àmọ́ ohun tóun fúnra rẹ̀ sọ ni pé: “Ó yẹ ká máa ṣohun tó tọ́. Inúure lèmi ń lò. Mi ò ṣe é torí kí ẹnikẹ́ni lè yìn mí.”
2 Ó ṣeé ṣe kó o mẹnì kan tó fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu torí pé ó fẹ́ ṣàánú ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ ló ṣerú ẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nítorí àtidáàbò bo àwọn àjèjì. Má sì gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àtàwọn èèyàn igba ó lé márùndínlọ́gọ́rin [275] tí wọ́n jọ wọ ọkọ̀ ojú omi tó rì ní erékùṣù Málítà nítòsí erékùṣù Sísílì. Àwọn tó ń gbé ní erékùṣù yẹn “fi àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá ènìyàn hàn sí” wọn. (Ìṣe 27:27–28:2) Ti ọmọbìnrin ará Ísírẹ́lì yẹn ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu, àmọ́ ó wá bó ṣe máa dára fún ọ̀kan lára àwọn ará Síríà tó kó o lẹ́rú. (2 Àwọn Ọba 5:1-4) Tún wá wo àpèjúwe kan tí Jésù sọ, tá a mọ̀ bí ẹní mowó, nípa aláàánú ará Samáríà. Àlùfáà kan àti ọmọ Léfì kan ti dé ọ̀dọ̀ ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ Júù tó ń kú lọ yẹn tí wọn ò ṣàánú ẹ̀, síbẹ̀ ará Samáríà kan sa gbogbo ipá rẹ̀ kó bàa lè ṣàánú ọkùnrin Júù yẹn. Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tí Jésù ti sọ àpèjúwe yẹn, ó ṣì wà lọ́kàn àwọn èèyàn oríṣiríṣi ẹ̀yà.—Lúùkù 10:29-37.
3, 4. Kí ni fífẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ gba ikú àwọn ẹlòmíì kú jẹ́ ká mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n?
3 Lóòótọ́, “àkókò lílekoko tó nira láti bá lò,” tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ya “òǹrorò” tí wọ́n sì jẹ́ “aláìní ìfẹ́ ohun rere” là ń gbé yìí. (2 Tímótì 3:1-3) Síbẹ̀, a ṣì ń ráwọn èèyàn tí wọ́n máa ń ṣe àwọn ẹlòmíì lóore. Ṣé àwa pàápàá lè sọ pé ẹnikẹ́ni ò tíì ṣe wá lóore rí? Ṣíṣe ọmọnìkejì lóore, kódà nígbà tó bá tiẹ̀ nira, wọ́pọ̀ débi pé àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé ẹni tó bá ń ṣoore jẹ́ ẹni tó ṣèèyàn.
4 Káàkiri gbogbo ìran àti onírúurú ẹ̀yà la ti ráwọn èèyàn tó máa ń fẹ́ ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn ẹlòmíì láìwo ti pé irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ lè kó wàhálà bá wọn. Èyí sì jẹ́ ká rí i pé kò sóòótọ́ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó fi kọ́ni pé ara ẹranko làwa èèyàn ti jáde wá. Dókítà Francis S. Collins, onímọ̀ nípa apilẹ̀ àbùdá, tó jẹ́ abẹnugan nínú ìwádìí tí ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe láti lóye apilẹ̀ àbùdá àwa èèyàn, sọ pé: “Àdìtú ló ṣì ń jẹ́ fáwọn onímọ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n pé a ṣì ń ráwọn èèyàn tí wọ́n ṣe tán láti gba ikú ẹlòmíì kú. . . . Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni pé apilẹ̀ àbùdá kan wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa tó jẹ́ onímọ-tara-ẹni-nìkan tí kì í sì í fẹ́ kú, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ, kí ló wá fà á tá a fi ń ráwọn tó fẹ́ gba ikú ẹlòmíì kú.” Dókítà Collins tún sọ pé: “Àwọn èèyàn kan máa ń fẹ̀mí ara wọn wewu láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí wọn ò bá tan tàbí tí nǹkan kan ò tiẹ̀ jọ dà wọ́n pọ̀. . . . Ó dà bíi pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀ ò lè ṣàlàyé ìdí tọ́rọ̀ fi rí báyìí.”
“Ohun Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ń Sọ”
5. Kí làwọn èèyàn máa ń sábà fẹ́ láti ṣe?
5 Dókítà Collins mẹ́nu ba nǹkan míì nípa báwọn èèyàn ṣe máa ń fẹ́ gba ikú ẹlòmíì kú, ó ní: “Ohun tí ẹ̀rí ọkàn ń sọ fún wa ni pé ká máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kódà tí kò bá sí ohun tá a máa rí gbà níbẹ̀.”a Bó ṣe mẹ́nu ba “ẹ̀rí ọkàn” yẹn mú ká rántí òkodoro ọ̀rọ̀ kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.”—Róòmù 2:14, 15.
6. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa jíhìn fún Ẹlẹ́dàá?
6 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó fi hàn pé àwa èèyàn máa jíhìn fún Ọlọ́run torí pé Ọlọ́run wà àti pé àwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣe kedere látinú ohun tá a rí. Bó ṣe wà “láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé” nìyẹn. (Róòmù 1:18-20; Sáàmù 19:1-4) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ka Ẹlẹ́dàá wọn sí, tí wọ́n sì ń jayé ìjẹkújẹ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé káwọn èèyàn mọ ohun tóun kà sí òdodo kí wọ́n sì ronú pìwà dà kúrò nínú ìwà búburú wọn. (Róòmù 1:22–2:6) Ní tàwọn Júù, kò sóhun tó ní kí wọ́n má mọ òdodo Ọlọ́run torí pé Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fún wọn ní Òfin rẹ̀. Àmọ́, ó yẹ káwọn tí kò ní “ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run” pàápàá gbà pé Ọlọ́run wà.—Róòmù 2:8-13; 3:2.
7, 8. (a) Ṣé òye ìwà tó tọ́ wà lọ́kàn àwọn èèyàn? Ṣàlàyé. (b) Kí sì nìyẹn fi hàn?
7 Ìdí pàtàkì kan tí gbogbo èèyàn fi gbọ́dọ̀ gbà pé Ọlọ́run wà kí wọ́n sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ yẹn máa hàn nínú ìṣe wọn ni pé kálukú ló mọ̀ nínú ara ẹ̀ bí ohun kan bá tọ́ tàbí bí kò bá tọ́. Mímọ̀ tá a mọ ohun tó bẹ́tọ̀ọ́ mu yàtọ̀ sóhun tí kò dáa fi hàn pé a ní ẹ̀rí ọkàn. Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Àwọn ọmọdé kan tò sórí ìlà níbi tí wọ́n ti fẹ́ gun jangirọ́fà. Ni ọmọ kan bá dédé lọ tò síwájú àwọn tó wà lórí ìlà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ tó wà níbẹ̀ sọ pé, ‘Ohun tó o ṣe yẹn ò dáa o!’ Wá bi ara rẹ pé, ‘Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé pàápàá máa fi hàn pé àwọn mọ ohun tó dáa yàtọ̀ sóhun tí kò dáa?’ Ohun tó fà á ni pé òye ìwà tó yẹ ọmọ èèyàn wà lọ́kàn wọn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá.” Kò sọ pé, “Tó bá ṣẹlẹ̀ pé,” bíi pé ohun tí kì í sábàá ṣẹlẹ̀ ló ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “nígbàkigbà,” tàbí “nígbà,” tó fi hàn pé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ló ń sọ nípa rẹ̀. Ìyẹn ni pé àwọn èèyàn máa ń “ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá,” tó fi hàn pé òye ìwà tó yẹ ọmọ èèyàn tí wọ́n ní máa ń mú kí wọ́n ṣohun tó bá òfin Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀ mu.
8 Ó hàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ pé ìwà ọmọlúwàbí yìí wà lọ́kàn àwọn èèyàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nílé ìwé gíga kan kọ̀wé pé nínú òfin àwọn ará Bábílónì, àwọn ará Íjíbítì, àwọn Gíríìkì àtàwọn tó tẹ ilẹ̀ Ọsirélíà dó, tó fi mọ́ àwọn Amẹríńdíà, “wọ́n dẹ́bi fún níni ọmọnìkejì lára, ìpànìyàn, àdàkàdekè àti ẹ̀tàn; ó sì wà nínú àwọn òfin náà pé a ní láti máa ṣohun tó dáa fáwọn arúgbó, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tí kò lágbára.” Dókítà Collins sì tún wá kọ̀wé pé: “Ó dà bíi pé kárí ayé làwọn èèyàn onírúurú ẹ̀yà ti ní èrò kan náà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́.” Ǹjẹ́ ìyẹn ò mú kóhun tó wà nínú Róòmù 2:14 wá sí ọ lọ́kàn?
Báwo Ni Ẹ̀rí Ọkàn Tìrẹ Ṣe Ń Siṣẹ́?
9. Kí ló ń jẹ́ ẹ̀rí ọkàn, báwo ló sì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o tó ṣe ohunkóhun?
9 Bíbélì fi hàn pé ohun tó ń jẹ́ kó o mọ̀ nínú ọkàn rẹ bóyá ohun tó o ṣe tọ́ tàbí kò tọ́ ló ń jẹ́ ẹ̀rí ọkàn. Ṣe ló dà bíi pé ohùn kan ń sọ̀rọ̀ nínú ọkàn rẹ tó ń jẹ́ kó o mọ̀ bóyá nǹkan tó o ṣe dára tàbí kò dára. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ohùn yìí tó wà nínú rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀rí-ọkàn mi ti ń jẹ́rìí pẹ̀lú mi nínú ẹ̀mí mímọ́.” (Róòmù 9:1) Bí àpẹẹrẹ, bó o ṣe ń rò ó bóyá nǹkan kan tó o fẹ́ ṣe dáa àbí kò dáa, ohùn yìí lè sọ fún ọ ṣáájú. Ẹ̀rí ọkàn rẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí ibi tí nǹkan tó o fẹ́ ṣe máa já sí, ó sì lè jẹ́ kó o mọ báá ṣe rí lára rẹ tó o bá ṣe nǹkan náà tán.
10. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn ṣe máa ń ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà?
10 Lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ẹ̀yìn tó o bá ti ṣe nǹkan náà tán ni ẹ̀rí ọkàn rẹ á tó fọhùn. Nígbà tí Dáfídì ń sá kiri kí Sọ́ọ̀lù Ọba má bàa rí i pa, Dáfídì láǹfààní láti hùwà kan tó dà bí àrífín sí ọba tí Ọlọ́run yàn, ó sì ṣe nǹkan ọ̀hún. Lẹ́yìn náà, “ọkàn-àyà Dáfídì ń gbún un ṣáá.” (1 Sámúẹ́lì 24:1-5; Sáàmù 32:3, 5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò rí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀rí ọkàn” nínú àkọsílẹ̀ yẹn, ohun tí ẹ̀rí ọkàn máa ń ṣe fún èèyàn ló ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì yẹn. Gbogbo wa náà ni ẹ̀rí ọkàn ti gbún báyẹn rí. Tó jẹ́ pé lẹ́yìn tá a ti ṣe ohun kan, ó wá dùn wá, ohun tá a ṣe yẹn sì bà wá nínú jẹ́. Ẹ̀rí ọkàn da àwọn kan tí kò san owó orí láàmú débi pé wọ́n padà lọ san owó ọ̀hún. Ẹ̀rí ọkàn àwọn míì ti tì wọ́n débi tí wọ́n fi lọ jẹ́wọ́ fún ọkọ tàbí aya wọn pé àwọn ti ṣe panṣágà. (Hébérù 13:4) Síbẹ̀, téèyàn bá ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ní kó ṣe, onítọ̀hún á ní ìtẹ́lọ́rùn ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀.
11. Kí nìdí tó fi léwu pé ká ‘gbà kí ẹ̀rí ọkàn wa máa darí wa síbi tó bá wù ú’? Ṣàlàyé.
11 Ṣé a kàn wá lè ‘gbà kí ẹ̀rí ọkàn wa máa darí wa síbi tó bá wù ú’? Ó kúkú máa ṣàǹfààní tá a bá ń gbọ́ nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn wa ń sọ fún wa, àmọ́ ó lè sọ nǹkan tó máa darí wa sígbó nígbà míì. Òótọ́ sì ni, ohùn “ẹni tí àwa jẹ́ ní inú” lè ṣì wá lọ́nà. (2 Kọ́ríńtì 4:16) Àpẹẹrẹ kan rèé. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Sítéfánù, tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi tọkàntọkàn, tó sì “kún fún oore ọ̀fẹ́ àti agbára.” Àwọn Júù kan ju Sítéfánù sí òde Jerúsálẹ́mù wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa. Sọ́ọ̀lù (tó wá padà di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù) dúró nítòsí àwọn tó pa Sítéfánù, ó sì “fọwọ́ sí ṣíṣìkàpa á.” Ó dà bíi pé ohun táwọn Júù yẹn ṣe dáa lójú ara wọn, torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò dà wọ́n láàmú. Ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn Sọ́ọ̀lù náà ò dá a lẹ́bi torí pé lẹ́yìn ìgbà yẹn, “ó ṣì ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa.” Ó ṣe kedere pé lákòókò yẹn, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò fọ ohùn tó dáa.—Ìṣe 6:8; 7:57–8:1; 9:1.
12. Kí ni ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó lè fà á tí ẹ̀rí ọkàn wa ò fi ní ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ?
12 Kí ló lè fà á tí ẹ̀rí ọkàn Sọ́ọ̀lù ò fi ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ o? Ara nǹkan tó lè fà á ni àwọn tó ń bá rìn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti bá ọkùnrin kan tó fohùn jọ bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀ rí lórí tẹlifóònù. Ohùn rẹ̀ lè rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ẹní bíni là á jọ, àmọ́ ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ló ń fara wé ọ̀nà tí bàbá ẹ̀ ń gbà sọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn Júù tí wọ́n kórìíra Jésù tí wọ́n sì ń ta ko ẹ̀kọ́ rẹ̀, tí Sọ́ọ̀lù ń bá ṣe wọléwọ̀de ló sọ Sọ́ọ̀lù dohun tó dà. (Jòhánù 11:47-50; 18:14; Ìṣe 5:27, 28, 33) Kókó ibẹ̀ nìyẹn o, nǹkan tá a lè bá lọ́wọ́ àwọn tí Sọ́ọ̀lù ń bá kẹ́gbẹ́ ni ohùn tó ń sọ̀rọ̀ lọ́kàn Sọ́ọ̀lù, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, ń sọ.
13. Báwo ni àyíká ibi téèyàn dàgbà sí ṣe lè mú kí ẹ̀rí ọkàn èèyàn má máa sọ ohun tó yẹ?
13 Nǹkan míì tó tún lè mú kí ẹ̀rí ọkàn wa má ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ ni ìwà táwọn èèyàn ń hù lágbègbè ibi tá à ń gbé. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí èdè tí wọ́n ń sọ ní àdúgbò tẹ́nì kan gbé dàgbà bá nípa lórí irú èdè tóun náà ń sọ. (Mátíù 26:73) Ó ní láti jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará Ásíríà ìgbàanì nìyẹn. Arógunyọ̀ ni wọ́n, àwọn ère tí wọ́n gbẹ́ fi bí wọ́n ṣe máa ń dá àwọn tí wọ́n bá kó lójú ogún lóró hàn. (Náhúmù 2:11, 12; 3:1) Bíbélì sọ pé àwọn ará Nínéfè ìgbà ayé Jónà “kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé kò yé wọn bí wọ́n ṣe lè mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ séyìí tí kò tọ́ lójú Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé tó bá jẹ́ pé Nínéfè lèèyàn ti dàgbà, àyíká ibẹ̀ yẹn kò ní jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn onítọ̀hún lè ṣiṣẹ́ dáadáa! (Jónà 3:4, 5; 4:11) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn téèyàn bá ń bá rìn lè kó tiwọn ran èèyàn débi tí ẹ̀rí ọkàn èèyàn ò fi ní máa fọhùn bó ṣe yẹ.
Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ẹ̀rí Ọkàn Wa Máa Ṣiṣẹ́ Dáadáa
14. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe fi nǹkan tí Jẹ́nẹ́sísì 1:27 ń sọ hàn?
14 Jèhófà fún Ádámù àti Éfà ní ẹ̀rí ọkàn, àwa náà sì jogún ẹ̀rí ọkàn látọ̀dọ̀ wọn. Jẹ́nẹ́sísì 1:27 sọ fún wa pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé irú ara tí Ọlọ́run ní làwa náà ní, ìdí ni pé ẹ̀mí ni Ọlọ́run, ẹlẹ́ran ara sì làwa. Bá a ṣe wà ní àwòrán Ọlọ́run ni pé a ní àwọn ànímọ́ rẹ̀ nínú wa, lára ẹ̀ sì ni pé a lè mọ ohun tó tọ́ torí pé a ní ẹ̀rí ọkàn tó ń ṣiṣẹ́. Jíjẹ́ tá a jẹ́ àwòrán Ọlọ́run yìí mú ká rí i pé nǹkan kan wà tá a lè ṣe láti mú kí nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn wa ń sọ túbọ̀ ṣeé tẹ̀ lé. Ìyẹn ni pé ká kọ́ púpọ̀ sí i nípa Ẹlẹ́dàá, ká sì túbọ̀ sún mọ́ ọn.
15. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà jàǹfààní látinú mímọ̀ tá a bá mọ Bàbá wa?
15 Bíbélì fi hàn pé Jèhófà ló dà bíi Bàbá fún gbogbo wa. (Aísáyà 64:8) Gbogbo Kristẹni olóòótọ́ ló lè máa pe Ọlọ́run ní Baba, yálà wọ́n nírètí àtilọ sọ́run tàbí ìrètí àtigbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9) Ó yẹ kó máa wù wá látọkànwá pé ká máa sún mọ́ Bàbá wa ṣáá ká sì máa lóye èrò àti ìlànà rẹ̀. (Jákọ́bù 4:8) Kò wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣe ni wọ́n dà bí àwọn Júù tí Jésù sọ nípa wọn pé: “Ẹ kò tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kankan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò tíì rí ìrísí rẹ̀; ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti dúró nínú yín.” (Jòhánù 5:37, 38) Lóòótọ́ la ò tíì gbọ́ ohùn Ọlọ́run gan-an rí o, àmọ́ a lè mọ èrò rẹ̀ nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyí á sì lè mú ká túbọ̀ jọ ọ́, a ó sì lè máa fojú tó fi ń wo nǹkan wò ó.
16. Kí ni àkọsílẹ̀ nípa Jósẹ́fù kọ́ wa lórí bó ṣe yẹ ká máa kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa ká sì máa fetí sóhun tó bá ń sọ fún wa?
16 Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù nílé Pọ́tífárì fi hàn bẹ́ẹ̀. Ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ kí Jósẹ́fù bá òun ṣèṣekúṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà ayé Jósẹ́fù kò sí ìwé inú Bíbélì kankan tó tíì wà lákọọ́lẹ̀, kò sì tíì sí Òfin Mẹ́wàá, síbẹ̀ Jósẹ́fù sọ pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” (Jẹ́nẹ́sísì 39:9) Kì í ṣe torí kó lè ṣohun tó máa dùn máwọn èèyàn ẹ̀ nínú ló ṣe dáhùn báyẹn; torí pé ọ̀nà àwọn èèyàn ẹ̀ jìn síbi tó wà. Ọlọ́run ló dìídì fẹ́ tẹ́ lọ́rùn. Jósẹ́fù mọ ìlànà Ọlọ́run lórí ìgbéyàwó, ó mọ̀ pé ọkọ kan, aya kan ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ àti pé àwọn méjèèjì ti di “ara kan.” Ó tún ṣeé ṣe kó ti gbọ́ pé ó dun Ábímélékì nígbà tó mọ̀ pé Rèbékà ti lọ́kọ àti pé kò ní dáa kóun sọ ọ́ di ìyàwó òun, kóun sì kó àwọn èèyàn òun sí wàhálà. Inú Jèhófà dùn sóhun tó ṣẹlẹ̀ lórí ọ̀ràn Ábímélékì àti Rèbékà, ìyẹn sì jẹ́ ká rí ojú tó fi ń wo panṣágà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àrọ́bá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí Jósẹ́fù bá nílẹ̀ ló jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ lè sọ ohun tó yẹ fún un, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ̀ láti ṣèṣekúṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24; 12:17-19; 20:1-18; 26:7-14.
17. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè túbọ̀ jọ Bàbá wa, kí nìdí tí àǹfààní tá a ní fi pọ̀ ju ti Jósẹ́fù lọ?
17 A mọ̀ pé, àwa láwọn àǹfààní tí Jósẹ́fù ò ní. A ní Bíbélì lódindi níbi tá a ti lè rí bí Bàbá wa ṣe ń ronú àti ojú tó fi ń wo nǹkan tó fi mọ́ ohun tó fọwọ́ sí àtohun tó kà léèwọ̀. Bá a bá ṣe fara wa fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tó, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe máa sún mọ́ Ọlọ́run tó tá a ó sì máa fìwà jọ ọ́ tó. Bá a bá ṣe ń ṣèyẹn, àwọn nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn wa ń sọ á túbọ̀ máa bá èrò Bàbá wa mu. Wọ́n á túbọ̀ máa bá fẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ mu.—Éfésù 5:1-5.
18. Láìka àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó ti ṣẹlẹ̀ sí wa sí, kí la lè ṣe tí ẹ̀rí ọkàn wa á fi túbọ̀ ṣeé tẹ̀ lé?
18 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àyíká wa ṣe lè fún ẹ̀rí ọkàn wa ńkọ́? Èrò àti ìṣe àwọn ìbátan wa àtàwọn tó wà láyìíká ibi tá à ń gbé lè ti ràn wá. Ìdí nìyẹn tí nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn ń sọ fún wa fi lè má ṣe kedere tàbí kí ẹ̀rí ọkàn máa sọ nǹkan tí kò dáa tó. Á wá máa sọ èdè ẹnu àwọn tó wà láyìíká wa. Lóòótọ́, a ò lè ṣe nǹkan kan lórí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa kọjá; àmọ́, a lè pinnu pé àwọn èèyàn tó máa jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa la ó máa bá rìn àti pé a ò ní fi ara wa sí àyíká tó máa kó bá ẹ̀rí ọkàn wa. Ohun pàtàkì kan tó yẹ ká ṣe ni pé ká máa wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ látọjọ́ tó ti pẹ́, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fìwà jọ Bàbá wọn. Tá a bá ń lọ sí ìpàdé ìjọ, tá à ń tètè débẹ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tá a sì ń dúró lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí, ó máa fún wa láǹfààní láti máa báwọn ará kẹ́gbẹ́. A ó lè máa kíyè sí bí ìrònú àti ìwà àwọn ará wa ṣe bá Bíbélì mu àti bí wọ́n ṣe ń fẹ́ láti máa tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn wọn tó ń sọ ohun tó bá ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan mu. Ohun tó máa yọrí sí nígbà tó bá yá ni pé a ó lè mú ẹ̀rí ọkàn tiwa alára bá àwọn ìlànà Bíbélì mu, èyí á sì mú ká túbọ̀ lé máa gbé àwòrán Ọlọ́run tá a jẹ́ yọ. Tá a bá mú kí ẹ̀rí ọkàn wa bá àwọn ìlànà Bàbá wa mu tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti lè máa tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn wa, àá sì lè máa gba ohun tó bá sọ.—Aísáyà 30:21.
19. Àwọn nǹkan wo ló tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò nípa ẹ̀rí ọkàn?
19 Síbẹ̀, ó ṣì ń ṣòro fáwọn kan láti máa tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá ń sọ fún wọn. Àpilẹ̀kọ tó kàn á jíròrò ọ̀ràn táwọn Kristẹni kan ti dojú kọ. Lẹ́yìn tá a bá ti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn yẹn, iṣẹ́ tí ẹ̀rí ọkàn ń ṣe á túbọ̀ ṣe kedere sí wa, a óò rí ìdí tí ẹ̀rí ọkàn wa fi lè sọ ohun tí kò bá ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíì mu, a óò sì rí bá a ṣe lè túbọ̀ máa tẹ̀ lé ohun tó bá sọ.—Hébérù 6:11, 12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bákan náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Owen Gingerich tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà nílé ìwé gíga Harvard University, kọ̀wé pé: “Ìbéèrè míì tún jẹ yọ nípa báwa èèyàn ṣe máa ń fẹ́ gba ikú ẹlòmíràn kú, èyí táwọn tó ṣèwádìí ìṣe àwọn ẹranko ò lè . . . rí ìdáhùn tó ṣe gúnmọ́ sí látinú ohun tí wọ́n ti kọ́. Ó lè jẹ́ pé ibòmíì ló yẹ ká fojú sí tá a bá fẹ́ rí ìdáhùn tó mọ́gbọ́n dání lórí ìyẹn. Ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run dá mọ́ àwa èèyàn, tó fi mọ́ ẹ̀rí ọkàn.”
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo onírúurú èèyàn tó ní àṣà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹ̀rí ọkàn wọn máa ń sọ fún wọn bí ohun kan bá tọ́ tàbí tí kò bá tọ́?
• Kí nìdí tá a fi ní láti ṣọ́ra ká má kàn máa jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa darí wa síbi tó bá wù ú?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà mú kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀rí ọkàn ń lu Dáfídì . . .
àmọ́ ẹ̀rí ọkàn Sọ́ọ̀lù ará Tásù ò dá a lẹ́bi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
A lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa