Iṣẹ́ Tó Lè Fún Abiyamọ Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn Jù Lọ
KÁRÍ ayé lónìí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ oṣù. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, iye àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ oṣù fẹ́rẹ̀ẹ́ tó iye àwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ oṣù. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn obìnrin máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lóko torí àtigbọ́ bùkátà ìdílé.
Ọ̀pọ̀ obìnrin ló wà tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń sáré àtirí owó ìgbọ́bùkátà ni wọ́n á tún máa wá bí wọ́n á ṣe bójú tó ìdílé wọn, ọrùn wọn sì ni iṣẹ́ ìtọ́jú ilé tún wà. Kì í ṣe pé àwọn obìnrin yìí ń sáré owó oúnjẹ, aṣọ àti ilé nìkan ni, àmọ́ àwọn náà ni yóò máa gbọ́ oúnjẹ, tí wọ́n á máa fọṣọ tí wọ́n á sì tún máa tọ́jú ilé.
Ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni ò mọ síbẹ̀ yẹn o, wọ́n tún ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Cristina tó jẹ́ ìyá àwọn ọmọbìnrin méjì sọ pé: “Ká sòótọ́, kò rọrùn láti máa ṣiṣẹ́ ká tún máa bójú tó ìdílé kí ọ̀kan má sì pa èkejì lára, àgàgà táwọn ọmọ rẹ bá ṣì kéré. Kò rọrùn láti bójú tó àwọn ọmọ bó ṣe yẹ kéèyàn bójú tó wọn.”
Kí ló ń fà á táwọn abiyamọ kan fi lọ ń ṣiṣẹ́ níta? Ìṣòro wo ni wọ́n ń dojú kọ? Ṣó tiẹ̀ pọn dandan fáwọn obìnrin pé kí wọ́n lọ máa ṣiṣẹ́ níta kí wọ́n tó lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn?
Ìdí Táwọn Abiyamọ Fi Ń Ṣiṣẹ́
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn obìnrin ló pọn dandan fún pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ oṣù. Àwọn kan ò ní ọkọ tó lè máa bá wọn gbé bùkátà. Àwọn tọkọtaya míì sì ti rí i pé owó tó ń wọlé fẹ́nì kan ò tó láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé wọn.
Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ló pọn dandan fún pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kí wọ́n tó lè rówó ná. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń ṣiṣẹ́ torí káwọn èèyàn lè máa kà wọ́n sí ẹni pàtàkì. Àwọn kan nínú wọn ń ṣiṣẹ́ torí kí wọ́n má bàa máa wojú ọkọ kí wọ́n tó lè náwó, àwọn míì sì ń wá owó tí wọ́n á fi máa jẹ̀gbádùn. Ọ̀pọ̀ ló ń ṣiṣẹ́ torí pé wọ́n mọṣẹ́ tí wọ́n kọ́ dunjú, wọ́n sì máa ń gbádùn iṣẹ́ ọ̀hún.
Ohun tó ń mú káwọn obìnrin míì fẹ́ ṣiṣẹ́ ni pé àwọn ẹgbẹ́ wọn ń ṣiṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwọn abiyamọ tó ń ṣiṣẹ́ níta máa ń ṣe wàhálà gan-an tó sì máa ń rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, síbẹ̀ tí wọ́n bá rí àwọn obìnrin tí kò ṣiṣẹ́ níta, ojú tí kò dáa ni wọ́n sábà máa fi ń wo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kódà wọ́n lè máa pẹ̀gàn wọn. Obìnrin kan sọ pé: “Kò rọrùn fún obìnrin láti máa ṣàlàyé fáwọn èèyàn pé òun ò níṣẹ́ míì lẹ́yìn pé òun jẹ́ ‘ìyàwó ilé.’ Báwọn kan nínú wọn á ṣe máa wò ẹ́ tàbí ọ̀nà tí wọ́n á gbà máa sọ̀rọ̀ á mú kó dà bíi pé ńṣe lò ń fi ìgbésí ayé ẹ ṣòfò.” Rebeca, ìyá ọmọbìnrin ọlọ́dún méjì kan sọ pé: “Lóòótọ́, àwọn èèyàn mọ̀ pé ó yẹ káwọn obìnrin máa tọ́jú àwọn ọmọ wọn, àmọ́ lójú tèmi ó dà bíi pé ojú ẹni yẹpẹrẹ ni wọ́n fi ń wo obìnrin tí kì í ṣiṣẹ́ níta.”
Irọ́ Ni Àbí Òótọ́?
Láwọn apá ibì kan láyé, obìnrin tí wọ́n kà sí “obìnrin àtàtà” lórí tẹlifíṣọ̀n, rédíò àti nínú àwọn ìwé ìròyìn máa ń jẹ́ obìnrin tó rọ́wọ́ mú lẹ́nu iṣẹ́ tó yàn láàyò, tó ń gbowó gọbọi, tó múra nigínnigín, tọ́kàn ẹ̀ sì balẹ̀ dẹ́dẹ́ẹ́dẹ́. Bákan náà, tírú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá tibi iṣẹ́ dé, ẹ̀mí ẹ̀ ṣì gbé e láti yanjú ìṣòro àwọn ọmọ ẹ̀, ó tún lè tọ́ ọkọ ẹ̀ sọ́nà níbi tó bá ti ṣàṣìṣe, wàhálà èyíkéyìí tó bá tún ṣẹlẹ̀ nínú ilé kò kọjá agbára rẹ̀. Ká sòótọ́, ṣàṣà ni obìnrin tó lè ṣe ohun tí ẹni tí wọ́n pè ní “obìnrin àtàtà” yìí ṣe.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ táwọn obìnrin máa ń rí jẹ́ èyí tí kì í pẹ́ sú èèyàn, owó tí wọ́n sì ń gbà nídìí irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í tó nǹkan. Nígbà tí wọ́n bá wọnú ẹ̀ tán ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń rí i pé iṣẹ́ àwọn kì í fún àwọn láyè láti lo gbogbo ẹ̀bùn táwọn ní. Ìwé kan tó ń jẹ́ Social Psychology ṣàlàyé pé: “Pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú láti jẹ́ kí obìnrin àti ọkùnrin ní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba, síbẹ̀ àwọn ọkùnrin ló ṣì ń rí iṣẹ́ gidi tó ń mówó wọlé ṣe jù. Torí náà, ìjákulẹ̀ lèyí jẹ́ fáwọn obìnrin tí wọ́n gbà pé irú iṣẹ́ táwọn bá ṣe ló máa jẹ́ káwọn èèyàn ka àwọn séèyàn pàtàkì.” Ìwé ìròyìn El País tó ń jáde lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Iye àwọn obìnrin tó ṣeé ṣe kí wàhálà iṣẹ́ di àárẹ̀ sí lára fi mẹ́ta pọ̀ ju iye àwọn ọkùnrin tírú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí lọ torí pé iṣẹ́ méjì làwọn obìnrin ń ṣe lóòjọ́. Tí wọ́n bá ti parí iṣẹ́ ti ìta, iṣẹ́ ilé tún wà níbẹ̀ tí wọ́n ń bọ̀ wá ṣe.”
Báwọn Ọkọ Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
A mọ̀ pé abiyamọ kan tó jẹ́ Kristẹni ló máa pinnu fúnra rẹ̀ bóyá ó yẹ kóun lọ máa ṣiṣẹ́ níta àbí kò yẹ. Ṣùgbọ́n, tó bá lọ́kọ, òun àtọkọ ẹ̀ ló jọ máa ṣèpinnu yẹn, wọ́n sì ti gbọ́dọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo ohun tó so mọ́ ọ̀ràn náà kí wọ́n tó ṣerú ìpinnu ọ̀hún.—Òwe 14:15.
Tó bá jẹ́ pé torí kí wọ́n lè rí owó tó tó láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé ni wọ́n ṣe pinnu pé káwọn méjèèjì lọ máa ṣiṣẹ́ owó ńkọ́? Nígbà náà, ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ fún irú ọkọ bẹ́ẹ̀ láti fi ọ̀rọ̀ ìṣítí tó wà nínú Bíbélì sọ́kàn, pé: “Kí ẹ̀yin ọkọ náà máa fi ọgbọ́n bá àwọn aya yín gbé. Ẹ máa bu ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lágbára tó yín. Ẹ rántí pé wọ́n jẹ́ alábapín ẹ̀bùn ìyè pẹ̀lu yín.” (1 Pétérù 3:7, Ìròhìn Ayọ̀) Bí ọkọ ṣe lè máa bọlá fún ìyàwó rẹ̀ ni pé kó máa kíyè sí ohun tí agbára rẹ̀ gbé àtohun tí ọkàn rẹ̀ lè gbé. Ní gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe, á máa bá ìyàwó ẹ̀ ṣe iṣẹ́ ilé. Bíi ti Jésù, ọkọ kan á fẹ́ máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan nínú ilé, kò ní kà wọ́n sí iṣẹ́ ìwọ̀sí. (Jòhánù 13:12-15) Kàkà bẹ́ẹ̀, á ka ṣíṣe irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ọ̀nà tó lè gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun tó jẹ́ òṣìṣẹ́kára. Ìyàwó rẹ̀ á mọrírì irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gan-an ni.—Éfésù 5:25, 28, 29.
Láìsí àní-àní, tó bá pọn dandan káwọn méjèèjì máa ṣiṣẹ́ níta, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ilé pẹ̀lú. Ìròyìn kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn ABC lórílẹ̀-èdè Sípéènì fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìwádìí tí àjọ kan tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìdílé, ìyẹn Institute of Family Matters, ṣe, ó sọ pé ohun tó fà á tí ìkọ̀sílẹ̀ fi pọ̀ nílẹ̀ Sípéènì ni “bó ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀sìn wọn kọ́ wọn tí wọn ò sì mọ ìyàtọ̀ láàárín ìwà tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ mọ́.” Àmọ́ ó tún mẹ́nu kan àpapọ̀ nǹkan méjì míì tó ń fà á, ìyẹn ni “báwọn obìnrin ṣe ń lọ ṣiṣẹ́ níta táwọn ọkùnrin kì í sì í bá wọn ṣe iṣẹ́ ilé.”
Ipa Pàtàkì Táwọn Ìyá Tó Jẹ́ Kristẹni Ń Kó
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá ni Jèhófà dìídì gbé iṣẹ́ kíkọ́ ọmọ lé lọ́wọ́, àwọn ìyá tó jẹ́ Kristẹni mọ̀ pé àwọn ní ipa pàtàkì kan láti kó, pàápàá nígbà tọ́mọ bá ṣì wà lọ́mọ ọwọ́. (Òwe 1:8; Éfésù 6:4) Nígbà tí Jèhófà ń sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbin Òfin òun sínú ọkàn àwọn ọmọ wọn, àti bàbá àti ìyá ló ń bá wí. Jèhófà mọ̀ pé ohun tóun ní kí wọ́n ṣe yìí á gba àkókò àti sùúrù, pàápàá nígbà tọ́mọ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́njú. Ìdí rèé tí Ọlọ́run fi sọ fáwọn òbí pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá wà nínú ilé, nígbà tí wọ́n bá wà lójú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá dìde.—Diutarónómì 6:4-7.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká rí ipa pàtàkì tó ń buyì kúnni táwọn ìyá ní láti máa kó nígbà tó pàṣẹ fáwọn ọmọ pé: “Má . . . ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 6:20) A mọ̀ pé obìnrin tó bá wà nílé ọkọ ní láti kọ́kọ́ fi tó ọkọ rẹ̀ létí kó tó gbé òfin kan kalẹ̀ fáwọn ọmọ nínú ilé. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣe fi hàn, àwọn ìyá lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣòfin. Àǹfààní ńláǹlà ló máa jẹ́ fọ́mọ tó bá gba ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ ilé tí ìyá rẹ̀ tó bẹ̀rù Ọlọ́run ń kọ́ ọ. (Òwe 6:21, 22) Teresa, obìnrin kan tó jẹ́ ìyá àwọn ọmọkùnrin kéékèèké méjì ṣàlàyé ìdí tí kò fi wá iṣẹ́ síta. Ó ní: “Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ fún mi ni títọ́ àwọn ọmọ mi dàgbà lọ́nà tí wọ́n á fi lè sin Ọlọ́run. Mo sì fẹ́ ṣe iṣẹ́ yìí débi tó lápẹẹrẹ.”
Àwọn Ìyá Tó Ṣohun Àrà Ọ̀tọ̀
Ọba kan wà ní Ísírẹ́lì tó ń jẹ́ Lémúẹ́lì, ó jàǹfààní púpọ̀ nínú ìsapá tí ìyá rẹ̀ ṣe lórí rẹ̀. “Iṣẹ́ wíwúwo” kan tí ìyá rẹ̀ jẹ́ fún un gẹ́gẹ́ “bí ìtọ́sọ́nà” wà lára Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. (Òwe 31:1; 2 Tímótì 3:16) Ohun tí ìyá ọba yìí sọ nípa béèyàn ṣe lè mọ aya tó dáńgájíá ṣì ń ran àwọn ọmọkùnrin lọ́wọ́ láti lè yan aya rere. Ìkìlọ̀ tó sì ṣe nípa ìṣekúṣe àti àmujù ọtí ṣì wúlò lónìí gẹ́gẹ́ bó ṣe wúlò nígbà tí wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀.—Òwe 31:3-5, 10-31.
Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kan sáárá sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Yùníìsì torí iṣẹ́ ribiribi tó ṣe lórí bó ṣe kọ́ Tímótì ọmọ rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé aláìgbàgbọ́ ni ọkọ obìnrin yìí, tó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òrìṣà Gíríìkì ló ń bọ, ó pọn dandan fún obìnrin yìí pé kó ran Tímótì ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti rí ìdí tó fi yẹ kó nígbàgbọ́ nínú “ìwé mímọ́.” Ìgbà wo ni Yùníìsì bẹ̀rẹ̀ sí í fi Ìwé Mímọ́ kọ́ Tímótì? Àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí sọ pé “láti ìgbà ọmọdé jòjòló,” ìyẹn látìgbà tí Tímótì ti wà lọ́mọ ọwọ́. (2 Tímótì 1:5; 3:14, 15) Ó ṣe kedere pé àpẹẹrẹ ìyá Tímótì àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ ọ ran Tímótì lọ́wọ́ débi tó fi di míṣọ́nnárì nígbà tó yá.—Fílípì 2:19-22.
Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyá kan tí wọ́n gba àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run lálejò, tí èyí sì jẹ́ káwọn ọmọ wọn lè sún mọ́ àwọn èèyàn gidi tí wọ́n lè fara wé nínú ìgbésí ayé wọn. Àpẹẹrẹ kan ni ti obìnrin ará Ṣúnémù kan tó sábà máa ń gba wòlíì Èlíṣà lálejò nínú ilé rẹ̀. Nígbà tí ọmọ rẹ̀ kú, Èlíṣà ló wá jí i dìde. (2 Ọba 4:8-10, 32-37) Tún wo àpẹẹrẹ Màríà tó jẹ́ ìyá Máàkù. Máàkù yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì. Ó ṣe kedere pé ó yọ̀ǹda ilé rẹ̀ tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní wá máa ṣèpàdé níbẹ̀. (Ìṣe 12:12) Ó dájú pé èyí fún Máàkù láǹfààní láti lè máa bá àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni míì rìn torí pé wọ́n máa ń wá sílé wọn déédéé.
Ó hàn gbangba pé inú Jèhófà dùn gidigidi sí iṣẹ́ àṣekára àwọn obìnrin olóòótọ́ tí wọ́n ń fi ìlànà rẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ó fẹ́ràn wọn nítorí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin àti pé ipa tí wọ́n ń kó nínú ilé ń mú kí ilé wọn jẹ́ ibi tí wọ́n ti ka ìjọsìn Ọlọ́run sí pàtàkì.—2 Sámúẹ́lì 22:26; Òwe 14:1.
Ohun Tó Lè Fún Obìnrin Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn Jù Lọ
Gẹ́gẹ́ báwọn àpẹẹrẹ tá a rí nínú Ìwé Mímọ́ yìí ṣe fi hàn, téèyàn bá pèsè ohun tí ìdílé ẹni nílò, tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run, tó sì ń ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n níbàlẹ̀ ọkàn, èrè ńlá nirú ẹni bẹ́ẹ̀ máa rí. Àmọ́ iṣẹ́ kékeré kọ́ ló gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dà bíi pé iṣẹ́ ilé obìnrin máa ń le ju iṣẹ́ tó lè máa ṣe ní ipò ńlá èyíkéyìí nílé iṣẹ́ kan lọ.
Lóòótọ́, lẹ́yìn tí obìnrin kan bá ti bá ọkọ rẹ̀ jíròrò, tóbìnrin náà sì pinnu láti dín àkókò tó fi ń ṣiṣẹ́ níta kù, ó lè gba pé kí wọ́n jẹ́ kí ìwọ̀nba àwọn ohun ìní tara tẹ́ àwọn lọ́rùn, ó sì lè gba pé kó fara da yẹ̀yẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn tí kò mọ̀dí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ èrè tó máa rí níbẹ̀ pọ̀ fíìfíì ju ohun tó ní láti fara dà lọ. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Paqui ní ọmọ mẹ́ta ó sì ní láti máa fi àkókò díẹ̀ ṣiṣẹ́ lóòjọ́. Ó ní: “Ó máa ń wù mí kí n wà nílé nígbà táwọn ọmọ mi bá dé láti ilé ìwé kí wọ́n lè rẹ́ni bá sọ̀rọ̀.” Àǹfààní wo lèyí ṣe àwọn ọmọ rẹ̀? Ó sọ pé: “Mo máa ń bá wọn ṣe iṣẹ́ ilé tí wọ́n fún wọn láti ilé ìwé, tí ìṣòro kan bá sì yọjú, kíá, mo ti bá wọn bójú tó o. Bá a ṣe máa ń wà pa pọ̀ lójoojúmọ́ mú ká lè jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa. Mo gbádùn àkókò tí mo máa ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ mi débi pé nígbà tí wọ́n fi iṣẹ́ kan lọ̀ mí tí màá máa ṣe látàárọ̀ ṣúlẹ̀, mo ní mi ò ṣe.”
Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni ló ti rí i pé táwọn bá lè dín àkókò táwọn fi ń ṣiṣẹ́ níta kù, gbogbo ìdílé àwọn ló máa jàǹfààní rẹ̀. Cristina tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí mo kúrò níbi iṣẹ́ tí mò ń ṣe, ó dà bíi pé ìṣòro wa dín kù nínú ilé. Mo wá ráyè láti máa bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀, ó sì wá ṣeé ṣe fún mi láti ran ọkọ́ mi lọ́wọ́ ní onírúurú ọ̀nà. Inú mi ń dùn bí mo ṣe ń kọ́ àwọn ọmọbìnrin mi tí mo sì ń rí i tí wọ́n gbẹ̀kọ́ tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú.” Ó sọ ohun kan tí kò lè gbàgbé láé. Ó ní: “Ọ̀dọ̀ àwọn abáni-tọ́jú-ọmọ ni àkọ́bí ọmọ mi tí kọ́ ìrìn, àmọ́ inú ilé lèmi fúnra mi ti kọ́ ọmọ mi kejì ní ìrìn. Ojú mi ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ọwọ́ mi báyìí ló sì ṣubú sí lọ́jọ́ tó kọ́kọ́ gbẹ́sẹ̀ rẹ̀ nílẹ̀. Inú mi dùn ayọ̀ mi sì kún lọ́jọ́ tá à ń wí yìí!”
Ohun míì tó tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni pé owó tí ìyá kan ń pàdánù látàrí pé kò ṣiṣẹ́ níta tàbí pé kò fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ lè má pọ̀ tó báwọn èèyàn ṣe rò. Cristina ṣàlàyé pé: “Owó abáni-tọ́jú ọmọ àtowó ọkọ̀ lèyí tó pọ̀ jù nínú owó oṣù mí ń bá lọ. Nígbà tá a fara balẹ̀ wo bí nǹkan ṣe rí, a rí i pé èyí tó ṣẹ́ kù lára owó tó ń wọlé fún mi kò tó nǹkan.”
Lẹ́yìn táwọn tọkọtaya kan ti fara balẹ̀ wo bí ipò wọn ṣe rí, wọ́n rí i pé àǹfààní tó wà nínú kí ìyàwó máa bójú tó ìdílé pé àwọn ju owó táwọn ì bá máa rí ká ní ó ń ṣiṣẹ́ níta lọ. Paul ọkọ Cristina sọ pé: “Inú mi dùn pé ìyàwó mi wà nílé láti máa tọ́jú àwọn ọmọ wá kéékèèké méjì. Nǹkan ò rọrùn rárá fáwa méjèèjì nígbà tí ìyàwó mi ṣì máa ń lọ ṣiṣẹ́ níta.” Ipa wo ni ìpinnu wọn yẹn ti ní lórí àwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì? Paul sọ pé: “Ọkàn wọn ti wá balẹ̀ sí i báyìí, àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́, ó tún dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ohun tí ì bá ti ní ipa búburú lórí wọn nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà.” Kí nìdí tí tọkọtaya yìí fi gbà pé, bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó, ó ṣe pàtàkì káwọn lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin àwọn? Paul dáhùn pé: “Táwa òbí ò bá gbin nǹkan tá a fẹ́ sọ́kàn àwọn ọmọ wa, àwọn ẹlòmíì á gbin nǹkan míì síbẹ̀.”
A ti wá rí i kedere pé ó yẹ kí gbogbo tọkọtaya ṣàyẹ̀wò ìdílé tiwọn fúnra wọn, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ sọ pé ìpinnu tẹ́lòmíì bá ṣe kò dára. (Róòmù 14:4; 1 Tẹsalóníkà 4:11) Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àǹfààní tí ìdílé máa rí tí ìyàwó kò bá gba iṣẹ́ tó máa gba àkókò tó pọ̀. Nígbà tí Teresa tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú ń ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tó rí lórí ọ̀ràn yìí, ó ní: “Kò sóhun tó lè fún èèyàn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó kéèyàn máa fi gbogbo àkókò tó bá ní tọ́jú àwọn ọmọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ kó sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.”—Sáàmù 127:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn ìyá tó jẹ́ Kristẹni ń kó ipa pàtàkì nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn