“Kí Ni A Ó Jẹ?”
ÀWỌN èèyàn sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ àti ohun mímu lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù kọ́kọ́ ṣe ni sísọ omi di ọtí wáìnì, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì fi búrẹ́dì àti ẹja díẹ̀ bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. (Mátíù 16:7-10; Jòhánù 2:3-11) Yàtọ̀ sí pé Jésù máa ń jẹun pẹ̀lú àwọn òtòṣì, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé ó tún máa ń jẹun pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀. Kódà, àwọn ọ̀tá Jésù tiẹ̀ fẹ̀sùn kàn án pé alájẹkì àti ọ̀mùtípara ni. (Mátíù 11:18, 19) Ó dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n sọ nípa Jésù yìí kì í ṣòótọ́. Àmọ́, ó mọ̀ pé oúnjẹ àti ohun mímu ṣe pàtàkì fáwọn èèyàn, ìyẹn ló mú kó fọgbọ́n lo àwọn nǹkan yìí láti ṣàlàyé àwọn òtítọ́ nípa Ọlọ́run fún wọn.—Lúùkù 22:14-20; Jòhánù 6:35-40.
Irú oúnjẹ àti ohun mímu wo ló wọ́pọ̀ nígbà ayé Jésù? Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Ìsapá wo ni wọ́n sì máa ń ṣe kó tó di jíjẹ? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtàwọn ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.
Fún Wa Ní “Oúnjẹ Wa fún Ọjọ́ Òní”
Nígbà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n máa bẹ Ọlọ́run pé kó pèsè àwọn ohun kòṣeémáàní fún wọn, ìyẹn ni “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.” (Mátíù 6:11) Búrẹ́dì jẹ́ oúnjẹ tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn débi pé nínú èdè Hébérù àti Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà “jẹ oúnjẹ” túmọ̀ sí “jẹ búrẹ́dì.” Wọ́n máa ń fàwọn oúnjẹ oníhóró bí àlìkámà àti ọkà báálì ṣe búrẹ́dì, wọ́n tún máa ń lo ọkà oats, ọkà spelt àti ọkà bàbà, àwọn ọkà yìí ló sì pọ̀ jù nínú oúnjẹ táwọn Júù máa ń jẹ ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn olùṣèwádìí fojú díwọ̀n ẹ̀ pé ẹnì kan máa ń jẹ nǹkan bí ìwọ̀n igba [200] kìlógíráàmù àwọn oúnjẹ oníhóró yìí lọ́dún kan, èyí sì ń pèsè nǹkan bí ìlàjì èròjà afáralókun téèyàn nílò.
Wọ́n lè rí búrẹ́dì rà lọ́jà. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń ṣe búrẹ́dì fúnra wọn, èyí kì í sì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Ìwé Bread, Wine, Walls and Scrolls ṣàlàyé pé: “Torí pé ìyẹ̀fun lè bà jẹ́ tí wọ́n bá tọ́jú ẹ̀ fún àkókò gígùn, ojoojúmọ́ làwọn ìyàwó ilé máa ń fọwọ́ lọ̀ ọ́.” Báwo ló ṣe máa ń pẹ́ wọn tó? Ìwé yìí tún sọ pé: “Lẹ́yìn iṣẹ́ àṣelàágùn fún odindi wákàtí kan nídìí ọlọ ọlọ́wọ́, wọ́n máa rí ìyẹ̀fun tí kò tó kìlógíráàmù kan látinú hóró àlìkámà kìlógíráàmù kan. Àlìkámà tẹ́nì kan máa ń jẹ lóòjọ́ fẹ́ẹ̀ tó ìlàjì kìlógíráàmù, torí náà, láti pèsè oúnjẹ fún ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún tàbí mẹ́fà, ìyàwó ilé ní láti wà nídìí ọlọ fún odindi wákàtí mẹ́ta.”
Jẹ́ ká wá ronú nípa Màríà ìyá Jésù. Láfikún sáwọn iṣẹ́ míì tó máa ń ṣe nínú ilé, ó ní láti pèsè búrẹ́dì fún ọkọ rẹ̀, ọmọkùnrin márùn-ún àti ó kéré tán àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì. (Mátíù 13:55, 56) Kò sí àní-àní pé bíi tàwọn obìnrin Júù yòókù, Màríà ṣe iṣẹ́ takuntakun láti pèsè “oúnjẹ . . . fún ọjọ́ òní.”
“Ẹ Wá, Ẹ Jẹ Oúnjẹ Àárọ̀ Yín”
Láàárọ̀ ọjọ́ kan lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ti fi gbogbo òru wá ẹja, àmọ́ wọn ò rí ìkankan pa. Jésù wá pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ti rẹ̀ yìí pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ oúnjẹ àárọ̀ yín.” Lẹ́yìn náà ló wá fún wọn ní ẹja àti búrẹ́dì. (Jòhánù 21:9-13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibí yìí nìkan ni wọ́n ti tọ́ka sí oúnjẹ àárọ̀ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sábà máa ń fi búrẹ́dì, ẹ̀pà àti èso ólífì ṣe oúnjẹ àárọ̀ wọn.
Oúnjẹ ọ̀sán wá ńkọ́? Kí làwọn òṣìṣẹ́ sábà máa ń jẹ? Ìwé Life in Biblical Israel sọ pé: “Àwọn ìpápánu bíi búrẹ́dì, ọkà, èso ólífì àti èso ọ̀pọ̀tọ́ ni wọ́n máa ń jẹ lọ́sàn-án.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú àwọn ìpápánu yìí làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rà bọ̀ láti Síkárì nígbà tí wọ́n bá Jésù níbi tó ti ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kànga. “Nǹkan bí wákàtí kẹfà,” tàbí ọ̀sán ni, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ti “lọ sínú ìlú ńlá láti ra àwọn èlò oúnjẹ.”—Jòhánù 4:5-8.
Alẹ́ làwọn ìdílé máa ń wà pa pọ̀ láti jẹ oúnjẹ gidi. Ìwé Poverty and Charity in Roman Palestine, First Three Centuries C.E. sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ló máa ń jẹ búrẹ́dì tàbí àsáró tí wọ́n fi ọkà báálì ṣe àti onírúurú oúnjẹ oníhóró, àwọn míì sì máa ń jẹ àlìkámà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Wọ́n sábà máa ń fi iyọ̀ àti òróró tàbí àwọn èròjà tí wọ́n mú jáde látara igi ólífì sí i, wọ́n sì máa ń fi ọbẹ̀ tó láwọn èròjà tó ń mú oúnjẹ dùn tàbí ohun mímu eléso sí i lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.” Wọ́n tún lè fi mílíìkì, wàràkàṣì, ewébẹ̀ àti èso tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já tàbí èyí tó ti gbẹ sínú oúnjẹ náà. Oríṣi ewébẹ̀ tó tó nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ló wà nígbà yẹn, díẹ̀ lára ẹ̀ ni àlùbọ́sà, aáyù, èso radish, kárọ́ọ̀tì àti cabbage. Yàtọ̀ síyẹn, oríṣi èso tó lé ní mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni wọ́n ń gbìn lágbègbè náà, irú bí (1) èso ọ̀pọ̀tọ́, (2) èso déètì àti (3) pómégíránétì.
Ṣó o lè fojú inú wo àwọn kan lára àwọn èròjà yìí lórí tábìlì lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù ń jẹun pẹ̀lú Lásárù àtàwọn arábìnrin rẹ̀, Màtá àti Màríà? Tún wo bínú yàrá yẹn á ṣe máa ta sánsán lọ́jọ́ náà nígbà tí Màríà ń fi òróró tó jẹ́ “ojúlówó náádì” pa ẹsẹ̀ Jésù, ìtasánsán òróró olówó iyebíye yìí wá pa pọ̀ mọ́ ti oúnjẹ náà.—Jòhánù 12:1-3.
“Nígbà Tí Ìwọ Bá Se Àsè”
Lákòókò míì tí Jésù ń jẹun ní “ilé ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso àwọn Farisí,” ó kọ́ àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ó ní: “Nígbà tí ìwọ bá se àsè, ké sí àwọn òtòṣì, amúkùn-ún, arọ, afọ́jú; ìwọ yóò sì láyọ̀, nítorí tí wọn kò ní nǹkan kan láti fi san án padà fún ọ. Nítorí a ó san án padà fún ọ ní àjíǹde àwọn olódodo.” (Lúùkù 14:1-14) Tí Farisí yẹn bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù, irú oúnjẹ wo ni ì bá fún àwọn èèyàn lọ́jọ́ náà?
Ẹnì kan tó lówó lọ́wọ́ lè pèsè búrẹ́dì tó jojú ní gbèsè tí wọ́n ṣe lónírúurú ọ̀nà, tí wọ́n sì fi wáìnì, oyin, mílíìkì àtàwọn nǹkan amóúnjẹ-ta-sánsán sí lóríṣiríṣi fáwọn àlejò. Ó ṣeé ṣe kí bọ́tà àti wàràkàṣì náà wà lórí tábìlì. Kò sì sí àní-àní pé, ewé tàbí èso ólífì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já tàbí èyí tí wọ́n tọ́jú sílé máa wà níbẹ̀, títí kan òróró ólífì. Ìwé Food in Antiquity sọ pé: “Èèyàn kan máa ń jẹ tó ogún kìlógíráàmù òróró ólífì láàárín ọdún kan, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń fi ṣara lóge, wọ́n sì fi ń tanná.”
Bí Farisí yẹn bá ń gbé nítòsí òkun, ó ṣeé ṣe kóun àtàwọn àlejò ẹ̀ jẹ ẹja tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa. Torí ẹja tí wọ́n fi iyọ̀ tàbí àwọn èròjà tí kì í jẹ́ kí oúnjẹ tètè bà jẹ́ sí, làwọn tó ń gbé níbi tó jìn sókun sábà máa ń jẹ. Ó sì ṣeé ṣe kí ẹni tó gbàlejò tún gbé ẹran kalẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ ìtọ́jú tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fáwọn àlejò tó jẹ́ òtòṣì. Tórí ẹyin tí wọ́n ṣe lóríṣiríṣi ọ̀nà lóúnjẹ tó wọ́pọ̀. (Lúùkù 11:12) Ó ṣeé ṣe káwọn irúgbìn amóúnjẹ-ta-sánsán àtàwọn nǹkan amóúnjẹ-ta-sánsán bí efinrin, ewéko dílì, kúmínì àti hóró músítádì túbọ̀ mú kí oúnjẹ náà ta sánsán. (Mátíù 13:31; 23:23; Lúùkù 11:42) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jẹun gidi tán, ó ṣeé ṣe káwọn àlejò tún jẹ àlìkámà yíyan tí wọ́n fi álímọ́ńdì, oyin àtàwọn nǹkan amóúnjẹ-ta-sánsán sí.
Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fún àwọn tó wá síbi àsè kan ní èso àjàrà tuntun, èyí tó ti gbẹ tàbí èyí tí wọ́n ti sọ di ọtí wáìnì. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe wáìnì ni wọ́n ti ṣàwárí nílẹ̀ Palẹ́sìnì, èyí sì fi hàn pé ọ̀pọ̀ ló máa ń mu wáìnì. Níbì kan nílùú Gíbéónì, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn ihò mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta tí wọ́n ń tọ́jú wáìnì sí, ihò náà sì lè gbà tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] gálọ́ọ̀nù wáìnì.
“Ẹ Má Ṣàníyàn Láé”
Bó o ṣe ń ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, máa kíyè sí iye ìgbà tí Jésù mẹ́nu kan oúnjẹ tàbí ohun mímu nínú àwọn àpèjúwe tó ṣe tàbí nínú ọ̀nà tó gbà kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan lákòókò tó ń jẹun. Ó dájú pé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń jẹ, wọ́n sì máa ń mu, pàápàá nígbà tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn, àmọ́ èyí kọ́ ni wọ́n fi ṣe nǹkan àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn.
Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ ìdí tí wọ́n fi ní láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó bá dọ̀rọ̀ oúnjẹ àti ohun mímu nígbà tó sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” (Mátíù 6:31, 32) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi ìmọ̀ràn yìí sílò, Ọlọ́run sì bójú tó àìní wọn. (2 Kọ́ríńtì 9:8) Òótọ́ ni pé oúnjẹ tó ò ń jẹ lè yàtọ̀ sí tàwọn tó gbáyé ní ọ̀rúndún kìíní. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run á bójú tó ẹ tó o bá fi ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ sí àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ.—Mátíù 6:33, 34.