ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 8/1 ojú ìwé 26
  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọlọ́kàn Tútù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọlọ́kàn Tútù
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Kọrin sí Jèhófà”!
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Mósè Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Númérì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Jẹ́ Ọlọ́kàn Tútù Kó O Lè Múnú Jèhófà Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 8/1 ojú ìwé 26

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọlọ́kàn Tútù

Númérì 12:1-15

ÌGBÉRAGA, owú, lílépa ipò ọlá. Àwọn ànímọ́ yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ń fẹ́ láti jẹ́ òléwájú nínú ayé. Àmọ́ ṣáwọn ànímọ́ bí irú èyí lè mú ká sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run? Rárá o, ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ni pé káwọn olùjọsìn rẹ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Númérì orí 12 fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Inú aginjù Sínáì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà yẹn, lẹ́yìn tí Jèhófà gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní Íjíbítì.

Míríámù àti Áárónì, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè, “bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lòdì sí” àbúrò wọn. (Ẹsẹ 1) Dípò kí wọ́n bá Mósè sọ̀rọ̀, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ lòdì sí i, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ń rojọ́ Mósè láìdáa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Torí pé Míríámù ni ẹsẹ Bíbélì yẹn kọ́kọ́ dárúkọ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni òléwájú nínú ọ̀tẹ̀ yẹn. Ìdí àkọ́kọ́ tí wọ́n fi fẹ̀sùn kan Mósè ni pé obìnrin ará Kúṣì ló fẹ́. Ṣé kì í ṣe pé Míríámù ń jowú pé àwọn èèyàn á máa fún obìnrin tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì yìí ní àfiyèsí ju òun lọ?

Wọ́n tún ń ráhùn torí àwọn nǹkan míì. Míríámù àti Áárónì ń sọ pé: “Ṣé kìkì nípasẹ̀ Mósè nìkan ṣoṣo ni Jèhófà ti gbà sọ̀rọ̀ ni? Kò ha ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwa pẹ̀lú bí?” (Ẹsẹ 2) Ṣé torí wọ́n ń fẹ́ wà ní ipò àṣẹ tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí wọ́n sì ń fẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún wọn ni wọ́n ṣe ń ráhùn lóòótọ́?

Ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Mósè ò fúnra ẹ̀ fèsì ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yẹn. Ó jọ pé ṣe ló fi sùúrù fara dà á. Sùúrù tó fi dá wọn lóhùn yẹn túbọ̀ fìdí ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ múlẹ̀ pé ó “jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn” tó wà lórí ilẹ̀ ayé.a (Ẹsẹ 3) Kò sídìí tí Mósè fi ní láti máa gbèjà ara rẹ̀. Jèhófà ń fetí sí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì gbèjà Mósè.

Jèhófà wo ìráhùn táwọn èèyàn wọ̀nyẹn ṣe bíi pé òun gan-an ni wọ́n ń ráhùn sí. Ó ṣe tán, òun ló yan Mósè. Kí Ọlọ́run lè pa àwọn tó ń ráhùn wọ̀nyẹn lẹ́nu mọ́, ó rán wọn létí pé àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ lòun ní pẹ̀lú Mósè, ó ní: “Ẹnu ko ẹnu ni mo ń bá a sọ̀rọ̀.” Jèhófà wá bi Míríámù àti Áárónì pé: “Kí wá ni ìdí tí ẹ kò fi bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ lòdì sí . . . Mósè?” (Ẹsẹ 8) Bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ lòdì sí Mósè yìí fi hàn pé Ọlọ́run ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ lòdì sí ní ti gidi. Ó dájú pé wọ́n máa rí ìbínú Ọlọ́run nítorí ìwà àìlọ́wọ̀ tó burú jáì tí wọ́n hù yìí.

Jèhófà fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lu Míríámù torí òun ni eku ẹdá tó dá wàhálà sílẹ̀. Lójú ẹsẹ̀ ni Áárónì bẹ Mósè pé kó bá àwọn gbàdúrà sí Jèhófà nítorí Míríámù. Fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, Mósè, tí wọ́n sọ̀rọ̀ lòdì sí, ló wá wà nípò báyìí láti bá Míríámù bẹ̀bẹ̀! Torí pé Mósè jẹ́ ọlọ́kàn tútù, ó ṣohun táwọn èèyàn náà bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe. Ó fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà nítorí ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ìyẹn sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tó máa sọ̀rọ̀ nínú ìtàn yìí. Míríámù rí ìwòsàn, àmọ́ ó ṣì ní láti fara da ìtìjú gbígbé lẹ́yìn òde ibùdó fún ọjọ́ méje nítorí àrùn.

Ìtàn yìí jẹ́ ká lè fòye mọ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí àtàwọn èyí tó kórìíra. Tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa ká lè mú ẹ̀mí ìgbéraga, owú àti lílépa ipò ọlá kúrò lọ́kàn wa. Àwọn ọlọ́kàn tútù ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́. Ó ṣèlérí pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11; Jákọ́bù 4:6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Téèyàn bá jẹ́ ọlọ́kàn tútù, ó máa ń jẹ́ kó rọrùn fún un láti máa fi sùúrù fara da ìwà ìrẹ́jẹ láìronú pé òún máa gbẹ̀san.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́