ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 9/15 ojú ìwé 16-20
  • Ìfẹ́ Kristi Ń Mú Ká Ní Ìfẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ Kristi Ń Mú Ká Ní Ìfẹ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Máa Hùwà Bíi Kristi Sáwọn Tó Hùwà Àìtọ́
  • Bá A Ṣe Lè Máa Lo Ìfẹ́ Bíi Kristi Lákòókò Òpin Yìí
  • Máa Hùwà Bíi Kristi Sáwọn Tó Ń Ṣàìsàn
  • Ẹ Máa Hùwà Bíi Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìrònú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìfẹ́—Ànímọ́ Kan Tó Ṣe Pàtàkì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Kí Ìfẹ́ Máa Gbé Yín Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 9/15 ojú ìwé 16-20

Ìfẹ́ Kristi Ń Mú Ká Ní Ìfẹ́

“Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé, ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.”—JÒH. 13:1.

1, 2. (a) Báwo ni ìfẹ́ Jésù ṣe ta yọ? (b) Kí làwọn ohun tá a máa gbé yẹ̀ wò nípa ìfẹ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

JÉSÙ fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ nípa ìfẹ́. Ohun gbogbo tó ṣe, látorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, ìwà rẹ̀, ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti ikú ìrúbọ tó kú fi ìfẹ́ tó ní hàn. Títí tí ìgbésí ayé Jésù fi parí lórí ilẹ̀ ayé, ó fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tó bá pàdé, ní pàtàkì jù lọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.

2 Àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó ta yọ tí Jésù fi lélẹ̀ yìí jẹ́ ìlànà pàtàkì táwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní láti máa tẹ̀ lé. Ó tún ń sún wa láti fi irú ìfẹ́ kan náà hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa àtàwọn èèyàn míì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàgbéyẹ̀wò ohun táwọn alàgbà lè rí kọ́ lára Jésù nípa bí wọ́n ṣe lè lo ìfẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀ràn ẹnì kan tó hùwà àìtọ́, kódà kó jẹ́ ìwà àìtọ́ tó burú jáì. A tún máa jíròrò bí ìfẹ́ Jésù ṣe lè mú káwọn Kristẹni ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí ìṣòro bá yọjú, nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ àti nígbà tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn.

3. Ojú wo ni Jésù fi wo Pétérù pẹ̀lú gbogbo àwọn àṣìṣe ńlá tó ṣe yẹn?

3 Lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù kú, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sẹ́ ẹ. (Máàkù 14:66-72) Àmọ́ nígbà tí Pétérù kọ́fẹ pa dà, bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jésù dárí jì í. Ó wá gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta kan lé Pétérù lọ́wọ́. (Lúùkù 22:32; Ìṣe 2:14; 8:14-17; 10:44, 45) Kí la rí kọ́ lára Jésù nínú bó ṣe hùwà sáwọn tó ṣàṣìṣe ńlá?

Ẹ Máa Hùwà Bíi Kristi Sáwọn Tó Hùwà Àìtọ́

4. Ipò wo ní pàtàkì jù lọ ló ti máa ń gba pé kéèyàn hùwà bíi Kristi?

4 Ọ̀pọ̀ ipò ló máa ń yọjú tó ti máa ń gba pé kéèyàn hùwà bíi Kristi, àmọ́ èyí tó lè bani nínú jẹ́ jù lọ ni ìgbà tẹ́nì kan bá hùwà àìtọ́ tó burú jáì, yálà nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ. Ó bani nínú jẹ́ pé bí ayé Sátánì yìí ṣe ń lọ sópin, ńṣe ni ẹ̀mí ayé túbọ̀ ń mú kí ìwà àwọn èèyàn burú sí i. Ìwà burúkú àti ẹ̀mí àìbìkítà tó kúnnú ayé yìí lè nípa lórí tàgbàtèwe, kó sì ṣàkóbá fún ìpinnu wọn láti máa rìn ní ọ̀nà tóóró. Ní ọ̀rúndún kìíní, ó di dandan kí wọ́n yọ àwọn kan kúrò nínú ìjọ Kristẹni, wọ́n sì bá àwọn míì wí. Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. (1 Kọ́r. 5:11-13; 1 Tím. 5:20) Síbẹ̀síbẹ̀, táwọn alàgbà tó bójú tó ọ̀ràn náà bá lo ìfẹ́ bíi ti Kristi, èyí lè nípa rere lórí oníwà àìtọ́ náà.

5. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi nínú bó ṣe hùwà sáwọn oníwà àìtọ́?

5 Bíi ti Jésù, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Jèhófà nígbà gbogbo. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn ní ìwà tútù, inú rere àti ìfẹ́ bíi ti Jèhófà. Tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tó fi hàn pé òun jẹ́ “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà” àti pé òun ní ìrora ọkàn nítorí àṣìṣe òun, ó lè má ṣòro fáwọn alàgbà láti “tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.” (Sm. 34:18; Gál. 6:1) Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe máa bójú tó ọ̀ràn ẹni tó kó agídí borí, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ hàn pé ó kábàámọ̀ ohun tó ṣe?

6. Kí lohun tó yẹ káwọn alàgbà yẹra fún tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀ràn ẹni tó hùwà àìtọ́, kí sì nìdí?

6 Inú lè fẹ́ bí àwọn alàgbà àtàwọn míì, tí oníwà àìtọ́ kan kò bá gba ìbáwí tí wọ́n fún un látinú Ìwé Mímọ́ tàbí tó ń di ẹ̀bi ohun tó ṣe ru àwọn ẹlòmíì. Torí pé wọ́n mọ ìpalára tí ẹni náà ti fà, wọ́n lè fẹ́ máa fi bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn bójú tó ọ̀ràn oníwà àìtọ́ náà. Àmọ́ ìbínú kì í bímọ rere, kò sì fi hàn pé èèyàn ní “èrò inú ti Kristi.” (1 Kọ́r. 2:16; ka Jákọ́bù 1:19, 20.) Jésù kìlọ̀ fáwọn kan nígbà ayé rẹ̀ láìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀, àmọ́ kò sígbà kankan tó sọ̀rọ̀ ìkórìíra tàbí nani lẹ́gba ọ̀rọ̀. (1 Pét. 2:23) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ran àwọn oníwà àìtọ́ lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Kódà, olórí ìdí tí Jésù fi wá sáyé ni láti “gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.”—1 Tím. 1:15.

7, 8. Kí ló yẹ káwọn alàgbà fi sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́?

7 Ipa wo ló yẹ kí àpẹẹrẹ Kristi ní lórí ìṣe wa sí ẹni tó bá di dandan kí ìjọ bá wí? Má gbàgbé pé ìlànà Ìwé Mímọ́ tó sọ pé kí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bójú tó ọ̀ràn àwọn tó hùwà àìtọ́ nínú ìjọ jẹ́ láti dáàbò bo agbo, kó sì tún mú kí oníwà àìtọ́ náà ronú pìwà dà. (2 Kọ́r. 2:6-8) Ó báni nínú jẹ́ pé àwọn kàn ò ronú pìwà dà, tó sì di dandan pé ká yọ wọ́n lẹ́gbẹ́. Àmọ́, ó dùn mọ́ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ ló pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sínú ìjọ rẹ̀. Táwọn alàgbà bá hùwà bíi Kristi, ó máa jẹ́ kó rọrùn fún àwọn oníwà àìtọ́ láti ṣàtúnṣe, kí wọ́n sì pa dà wá sínú ìjọ. Tó bá yá, irú àwọn bẹ́ẹ̀ lè ṣàìrántí gbogbo ìbáwí tí wọ́n fún wọn látinú Ìwé Mímọ́, àmọ́ wọn ò ní gbàgbé pé àwọn alàgbà fọ̀wọ̀ wọ àwọn, wọ́n sì fi ìfẹ́ bá àwọn lò.

8 Fún ìdí yìí, àwọn alàgbà ní láti máa fi èso tẹ̀mí hàn, ní pàtàkì jù lọ ìfẹ́ bíi ti Kristi, kódà nígbà tí ẹni tó hùwà àìtọ́ náà kò bá gba ìbáwí tí wọ́n fún un látinú Ìwé Mímọ́. (Gál. 5:22, 23) Wọn ò gbọ́dọ̀ kánjú lé oníwà àìtọ́ kan kúrò nínú ìjọ. Wọ́n ní láti fi hàn pé àwọn fẹ́ kẹ́ni tó ṣẹ̀ náà pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ irú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló máa ń ronú pìwà dà. Tí ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí bá wá ronú pìwà dà lọ́jọ́ iwájú, yóò lè fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún Jèhófà àti “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” tó mú kó rọrùn fún un láti pa da sínú ìjọ.—Éfé. 4:8, 11, 12.

Bá A Ṣe Lè Máa Lo Ìfẹ́ Bíi Kristi Lákòókò Òpin Yìí

9. Sọ àpẹẹrẹ ọ̀nà pàtó kan tí Jésù gbà fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.

9 Lúùkù ṣàkọsílẹ̀ ọ̀nà tó ta yọ kan tí Jésù gbà fi ìfẹ́ hàn. Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọ ogun Róòmù máa tó wá sàga ti ìlú Jerúsálẹ́mù tí ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé lórí, táwọn èèyàn ò sì ní lè sá lọ. Ó fìfẹ́ kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? Jésù fún wọn ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ó ní: “Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀; nítorí pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọjọ́ fún pípín ìdájọ́ òdodo jáde, kí gbogbo ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀ lè ní ìmúṣẹ.” (Lúùkù 21:20-22) Lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun Róòmù ti yí ìlú Jerúsálẹ́mù ká lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni, àwọn tó jẹ́ onígbọràn tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù.

10, 11. Tá a bá ń ronú lórí báwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, báwo ló ṣe máa múra wa sílẹ̀ de “ìpọ́njú ńlá”?

10 Nígbà táwọn Kristẹni ń sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n ní láti fi ìfẹ́ bíi ti Kristi hàn sí ara wọn, bí Kristi ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn náà. Wọ́n ní láti jọ máa pín ohun tí wọ́n bá ní láàárín ara wọn. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yẹn sọ ju ohun tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn lọ. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mát. 24:17, 18, 21) Àwa náà lè dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ìnira, kí “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ yẹn tó dé àti nígbà tó bá dé. Àmọ́ tá a bá ń hùwà bíi Kristi a óò kẹ́sẹ járí.

11 Nígbà yẹn, a máa ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, a ó máa lo ìfẹ́, a ó yàgò fún ìmọtara-ẹni-nìkan. Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn kan lórí kókó yìí, ó ní: “Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀ . . . Wàyí o, kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.”—Róòmù 15:2, 3, 5.

12. Irú ìfẹ́ wo ló yẹ ká ní báyìí, kì sì nìdí?

12 Pétérù tóun náà jàǹfààní ìfẹ́ Jésù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa ní “ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè,” kí wọ́n sì máa ṣe ‘ìgbọràn sí òtítọ́.’ Wọ́n ní láti “nífẹ̀ẹ́ ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.” (1 Pét. 1:22) Lóde òní, àwa náà gbọ́dọ̀ máa ní àwọn ànímọ́ Kristi yìí. Ńṣe ni ìṣòro tó dojú kọ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ ń peléke sí i. Kò yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wa gbọ́kàn lé ètò ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí nínú ayé ògbólógbòó yìí, bá a ṣe ń rí i kedere báyìí tí ọrọ̀ ajé àgbáyé ń dẹnu kọlẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 2:15-17.) Kàkà bẹ́ẹ̀, bí òpin ètò ayé burúkú yìí ṣe ń sún mọ́lé gan-an yìí, a ní láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ará wa, ká máa yan ojúlówó ọ̀rẹ́ nínú ìjọ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Pétérù náà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pét. 4:8.

13-15. Báwo làwọn ará kan ṣe fi ìfẹ́ bíi ti Kristi hàn lẹ́yìn tí àjálù ṣẹlẹ̀?

13 Karí ayé làwọn èèyàn ti mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ bíi ti Kristi hàn. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n dìde ìrànwọ́ nígbà tí ìjì àti ìjì líle ba àgbègbè kan jẹ́ lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2005. Àpẹẹrẹ Jésù sún àwọn èèyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ kan [20,000] láti yọ̀ǹda ara wọn, ọ̀pọ̀ ló fi ilé tó dára àti iṣẹ́ tó fọkàn ẹni balẹ̀ tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀ kí wọ́n lè ran àwọn ará tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́.

14 Lágbègbè kan, ìjì líle náà jà wọnú ìlú lọ, ibi tó jà dé sì fi nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà jìnnà sétíkun, ìgbì òkun ya wọ àárín ìlú, ó ga tó nǹkan bí òpó iná kan. Nígbà tí omi náà fi máa lọ sílẹ̀, ìdá mẹ́tà àwọn ilé gbígbé àtàwọn ilé míì tó wà lágbègbè yẹn ló bà jẹ́ pátápátá. Àwọn Ẹlẹ́rìí láti àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan yọ̀ǹda ara wọn, àwọn tó mọṣẹ́ dunjú wá, wọ́n mú irin iṣẹ́ àtàwọn ohun èlò ìkọ́lé wá lóríṣiríṣi, wọ́n sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yẹ ní ṣíṣe. Àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan tí wọ́n jẹ́ opó wà lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn. Àwọn obìnrin náà kó ohun ìní wọ́n sínú ọkọ̀ akẹ́rù, wọ́n sì rin ìrìn tó ju ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] kìlómítà láti lọ síbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà ṣì wà lágbègbè yẹn báyìí, ó ń ran ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ lọ́wọ́, ó sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà.

15 Ó ju ẹgbẹ̀rún márùn-un àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [5,600] ilé àwọn Ẹlẹ́rìí àti tàwọn ẹlòmíì tó wà lágbègbè yẹn tí wọ́n tún kọ́ tàbí tí wọ́n tún ṣe. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè yẹn nígbà táwọn ará fi irú ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí hàn sí wọn? Arábìnrin kan tí ilé rẹ̀ bà jẹ́ kó lọ sínú ilé alágbèérìn kan tí òrùlé rẹ̀ ń jò, tí sítóòfù ìdáná tó wà níbẹ̀ sì ti bà jẹ́. Àwọn ará kọ́ ilé míì tó mọ níwọ̀n tó sì dára fún un. Nígbà tó dúró níwájú ilé rèǹtèrente náà, ńṣe ló ń da omi lójú bó ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àtàwọn ará. Ní tàwọn Ẹlẹ́rìí kan tí ilé wọn bà jẹ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti bá wọn tún ilé wọn kọ́, ó ju ọdún kan lọ tí wọ́n fi gbé ilé tí wọ́n fi wọ́n sí. Kí nìdí? Ńṣe ni wọ́n yọ̀ǹda ilé wọn tuntun yìí, káwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà lè máa rí i lò. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ ìwà bíi Kristi lèyí jẹ́!

Máa Hùwà Bíi Kristi Sáwọn Tó Ń Ṣàìsàn

16, 17. Àwọn ọ̀nà wo la lè gba hùwà bíi Kristi sáwọn tó ń ṣàìsàn?

16 Ìwọ̀nba díẹ̀ nínú wa ni àjálù ńlá ti ṣẹlẹ̀ sí rí. Àmọ́, ó dájú pé gbogbo wa la máa ń ní ìṣòro àìsàn, bóyá kó jẹ́ àwa fúnra wa tàbí ẹnì kan nínú ìdílé wa. Ìwà tí Jésù hù sáwọn tó ń ṣàìsàn jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. Ìfẹ́ tó ní sí wọn mú kí àánú wọn ṣe é. Nígbà tí ogunlọ́gọ̀ gbé àwọn èèyàn wọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó “wo gbogbo àwọn tí nǹkan kò sàn fún sàn.”— Mát. 8:16; 14:14.

17 Lóde òní, àwọn Kristẹni kò lè wo àwọn aláìsàn sàn lọ́nà ìyanu, àmọ́ àwọn náà máa ń ṣàánú àwọn aláìsàn, bí Jésù ṣe máa ń ṣe. Lọ́nà wo? Ọ̀nà kan táwọn alàgbà ń gbà hùwà bíi Kristi ni pé wọ́n máa ń ṣètò láti ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń bójú tó ètò náà, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Mátíù 25:39, 40.a (Kà á.)

18. Báwo làwọn arábìnrin méjì ṣe fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí arábìnrin kan, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

18 Àmọ́ ṣá o, kò dìgbà téèyàn bá jẹ́ alàgbà kéèyàn tó lè ṣe ohun rere sáwọn èèyàn. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Charlene, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì [44] tó lárùn jẹjẹrẹ, tí wọ́n sì sọ fún un pé ọjọ́ mẹ́wàá ló kù tó máa lò tó fi máa kú. Arábìnrin méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Sharon àti Nicolette kíyè sí ohun tójú olùfọkànsìn tó jẹ́ ọkọ arábìnrin náà ń rí bó ṣe ń tọ́jú ìyàwó rẹ̀. Àwọn arábìnrin náà yọ̀ǹda gbogbo àkókò wọn láti tọ́jú Charlene níwọ̀nba àkókò tó kù fún un. Ọjọ́ mẹ́wàá tí wọ́n ní ó máa lò pàpà di ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, àmọ́ àwọn arábìnrin méjì yìí fi ìfẹ́ wọn hàn títí dé òpin. Sharon sọ pé: “Ó máa ń ṣòro gan-an téèyàn bá mọ̀ pé àìsàn tó ń ṣe ẹnì kan ló máa gbẹ̀mí ẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà fún wa lókun. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ará.” Ọkọ Charlene sọ pé: “Mi ò ní gbàgbé inú rere táwọn arábìnrin méjì yìí fi hàn sí mi lọ́nà pàtàkì àti bí wọ́n ṣe tì mí lẹ́yìn. Ọkàn mímọ́ àti èrò tó tọ́ tí wọ́n ní ló jẹ́ kí ìdánwò náà rọrùn fún Charlene aya mi ọ̀wọ́n, ó sì jẹ́ kí ara tu èmi náà. Títí láé ni n ó máa dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Bí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ara wọn tinútinú yìí ti fún ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà àti ìfẹ́ tí mo ní fún ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé lókun.”

19, 20. (a) Àwọn ìwà Kristi márùn-ún wo la ti gbé yẹ̀ wò? (b) Kí lo pinnu láti ṣe?

19 Nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ mẹ́tà yìí, a ti ṣàgbéyẹ̀wò márùn-un lára àwọn ìwà Jésù àti bá a ṣe lè máa ronú ká sì máa hùwà bíi tiẹ̀. Torí náà ẹ jẹ́ káwa náà jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà,” bíi Jésù. (Mát. 11:29) Ẹ jẹ́ ká máa sapá láti fi inú rere hàn sáwọn èèyàn, kódà nígbà tí àìpé àti kùdìẹ̀-kudiẹ wọn bá hàn gbangba. Ká sì máa fìgboyà ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà ní ká máa ṣe, kódà nígbà àdánwò.

20 Lákòótán, ẹ jẹ́ ká máa fi ìfẹ́ Kristi hàn sáwọn ará, bí Kristi fúnra rẹ̀ ṣe “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ló ń fi hàn pé ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá. (Jòh. 13:1, 34, 35) Àní sẹ́, “ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.” (Héb. 13:1) Má ṣe juwọ́ sílẹ̀! Máa lo ìgbésí ayé rẹ láti fi yin Jèhófà, kó o sì máa fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́! Jèhófà á sì bù kún ìsapá tó o ṣe tọkàntọkàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí náà: “Ṣe Jù Sísọ pé: ‘Ki Ara Yin Gbóná Ki Ẹ Sì Jẹun’” nínú Ilé-ìṣọ́nà October 15, 1986.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo làwọn alàgbà ṣe lè hùwà bíi Kristi sáwọn oníwà àìtọ́?

• Kí nìdí tí títẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Kristi fi ṣe pàtàkì gan-an lákòókò òpin yìí?

• Báwo la ṣe lè hùwà bíi Kristi sáwọn tó ń ṣàìsàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn alàgbà fẹ́ káwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Báwo làwọn Kristẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ṣe hùwà bíi Kristi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ẹni tó ń fi ìfẹ́ bíi ti Kristi hàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́