ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 12/15 ojú ìwé 11-15
  • Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Máa Fara Hàn Kedere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Máa Fara Hàn Kedere
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Ànímọ́ Tẹ̀mí Ṣe Ń Fara Hàn
  • Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ
  • Ó Yẹ Ká Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ìwà Mímọ́ àti Ìṣesí
  • Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́ Ṣe Pàtàkì
  • Sapá Láti Mú Kí Ìlọsíwájú Rẹ Máa Fara Hàn Kedere
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Jẹ́ Kí Ìtẹ̀síwájú Yín Fara Hàn Kedere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Tímótì—“Ojúlówó Ọmọ Nínú Ìgbàgbọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Ọmọ Mi Olùfẹ́ Ọ̀wọ́n àti Olùṣòtítọ́ Nínú Olúwa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Fara Hàn Kedere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 12/15 ojú ìwé 11-15

Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Máa Fara Hàn Kedere

“Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 TÍM. 4:15.

1, 2. Kí la mọ̀ nípa ìgbésí ayé Tímótì nígbà tó wà lọ́mọdé àti ìyípadà tó dé bá a nígbà tó wà ní nǹkan bí ọmọ ogún ọdún?

ÀGBÈGBÈ Gálátíà ní ilẹ̀ ọba Róòmù ìgbàanì ni Tímótì dàgbà sí. Orílẹ̀-èdè Tọ́kì ni àgbègbè náà wà báyìí. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, wọ́n dá ìjọ mélòó kan sílẹ̀ ní ibẹ̀. Nígbà tó yá, Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ pẹ̀lú ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ di Kristẹni, wọ́n wà nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà ní àgbègbè yẹn, wọ́n sì ń ṣe déédéé. (2 Tím. 1:5; 3:14, 15) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ Kristẹni kan, ó dájú pé Tímótì ń gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀ níbí tó dàgbà sí yẹn. Àmọ́, ìyípadà kan tí kò rò tẹ́lẹ̀ dé bá a.

2 Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè yẹn lẹ́ẹ̀kejì ló bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí Tímótì. Ní àkókò yẹn, ó ṣeé ṣe kí Tímótì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí kó lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún. Nígbà ìbẹ̀wò Pọ́ọ̀lù, ó kíyè sí i pé àwọn ará “ròyìn [Tímótì] dáadáa,” ó ṣeé ṣé kó jẹ́ pé ìlú Lísírà ni Pọ́ọ̀lù wà nígbà yẹn. (Ìṣe 16:2) Tímótì á ti fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun bíi tàwọn àgbàlagbà. Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ darí Pọ́ọ̀lù àti ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà láti gbé ọwọ́ lé Tímótì, tí wọ́n sì yà á sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ àkànṣe nínú ìjọ.—1 Tím. 4:14; 2 Tím. 1:6.

3. Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn àrà ọ̀tọ̀ wo ni Tímótì rí gbà?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nawọ́ àǹfààní kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí Tímótì, ó ní kó jẹ́ káwọn jọ máa rin ìrìn àjò! (Ìṣe 16:3) Èyí á mà ya Tímótì lẹ́nu o, inú rẹ̀ yóò sì dùn gan-an! Ọ̀pọ̀ ọdún ni yóò fi máa bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò, yóò sì tún máa bá àwọn míì rìnrìn àjò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, táwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin á sì máa fi onírúurú iṣẹ́ rán an. Pọ́ọ̀lù àti Tímótì jọ ń ṣiṣẹ́ arìnrìn-àjò, ipa kékeré sì kọ́ ni iṣẹ́ wọn ń kó nínú gbígbé àwọn ará ró nípa tẹ̀mí. (Ka Ìṣe 16:4, 5.) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ìgbà yẹn ló rí i pé Tímótì ti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tóun àti Pọ́ọ̀lù ti jọ ń ṣiṣẹ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Fílípì pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí [Tímótì] tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. . . . Ẹ̀yin mọ ẹ̀rí tí ó fúnni nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.”—Fílí. 2:20-22.

4. (a) Iṣẹ́ bàǹtàbanta wo ni Pọ́ọ̀lù gbé lé Tímótì lọ́wọ́? (b) Ìbéèrè wo la lè béèrè nípa ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Tímótì 4:15?

4 Láàárín àsìkò tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Fílípì, ó tún gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta kan lé Tímótì lọ́wọ́, ó ní kó yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Tím. 3:1; 5:22) Ó ṣe kedere pé Tímótì ti di alábòójútó tó ṣeé fọkàn tán nígbà yẹn. Síbẹ̀ nínú lẹ́tà yẹn, Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé kó jẹ́ ‘kí ìlọsíwájú rẹ̀ fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.’ (1 Tím. 4:15) Ṣebí Tímótì ti tẹ̀ síwájú débi tó lápẹẹrẹ, kí wá ni ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú lẹ́tà yẹn túmọ̀ sí, àǹfààní wo la sì lè rí nínú ìmọ̀ràn yẹn?

Bí Àwọn Ànímọ́ Tẹ̀mí Ṣe Ń Fara Hàn

5, 6. Ewu wo ló dojú kọ ìjọ Éfésù, báwo ni Tímótì ṣe lè dáàbò bo ìjọ náà?

5 Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú 1 Tímótì 4:15 àtàwọn tó wà lẹ́yìn rẹ̀. (Ka 1 Tímótì 4:11-16.) Ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, ó ti rìnrìn àjò lọ sí Makedóníà, àmọ́ ó ní kí Tímótì dúró sílùú Éfésù. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn kan nínú ìjọ yẹn ń dá ìyapa sílẹ̀ nítorí wọ́n mú ẹ̀kọ́ èké wọlé. Tímótì ní láti dáàbò bo ìjọ náà kó lè wà ní mímọ́. Báwo ló ṣe máa ṣe èyí? Lọ́nà kan, ó ní láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ará láti máa tẹ̀ lé.

6 Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Di àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.” Ó fi kún un pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tím. 4:12, 15) Ìlọsíwájú tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí kì í ṣe nípa ipò tí Tímótì wà, kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ tẹ̀mí. Irú ìlọsíwájú yìí ló yẹ kí gbogbo Kristẹni fẹ́ láti ní.

7. Kí ni gbogbo ẹni tó wà nínú ìjọ ní láti máa ṣe?

7 Bó ṣe rí nígbà ayé Tímótì náà ló ṣe rí lónìí, oríṣiríṣi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lèèyàn lè ní nínú ìjọ. Àwọn kan ń sìn bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn míì ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bákan náà, àwọn kan jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn kan ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míì sì jẹ́ míṣọ́nnárì. Àwọn alàgbà máa ń ní oríṣiríṣi iṣẹ́ tó jẹ mọ́ kíkọ́ni, bíi ní àwọn àpéjọ wa. Àmọ́, gbogbo Kristẹni, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́mọdé lágbà ló ní àǹfààní láti mú kí ìlọsíwájú wọn tẹ̀mí máa fara hàn kedere. (Mát. 5:16) Bíi ti Tímótì, àní àwọn Kristẹni tó ní àkànṣe ojúṣe nínú ìjọ pàápàá ní láti máa mú kí ìlọsíwájú wọn fara hàn fún gbogbo èèyàn.

Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ

8. Ipa wo ni ọ̀rọ̀ ẹnu wa ń ní lórí ìjọsìn wa?

8 Ọ̀kan lára apá ibi tó ti yẹ kí Tímótì jẹ́ àpẹẹrẹ ni ọ̀rọ̀ sísọ. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìlọsíwájú wa fara hàn kedere lápá ibẹ̀ yẹn? Ọ̀rọ̀ ẹnu wa ń sọ púpọ̀ nípa wa. Jésù sọ gbólóhùn kan tó kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn, ó ní: “Nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Jákọ́bù àbúrò Jésù náà sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè ní lórí ìjọsìn wa, ó sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”—Ják. 1:26.

9. Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa gbà jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ?

9 Ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè jẹ́ káwọn ará ìjọ mọ ibi tá a ti tẹ̀ síwájú dé nípa tẹ̀mí. Torí náà, dípò tá a ó fi máa sọ̀rọ̀ tó buni kù, ọ̀rọ̀ burúkú, tá ó máa ṣe àríwísí, tàbí ká sọ̀rọ̀ tó máa dun àwọn èèyàn, àwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró, ọ̀rọ̀ ìtùnú, àti ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí. (Òwe 12:18; Éfé. 4:29; 1 Tím. 6:3-5, 20) Bá a ṣe ń fẹ́ láti máa sọ fáwọn èèyàn pé ìlànà gíga ti Ọlọ́run ló dára jù àti pé ìlànà rẹ̀ la fẹ́ máa tẹ̀ lé, ó ń fi hàn pé olùfọkànsìn Ọlọ́run ni wá. (Róòmù 1:15, 16) Ó dájú pé àwọn ọlọ́kàn rere máa rí bá a ṣe ń lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún wa, wọ́n sì lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wa.—Fílí. 4:8, 9.

Ó Yẹ Ká Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ìwà Mímọ́ àti Ìṣesí

10. Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ tí kò ní àgàbàgebè fi ṣe pàtàkì fún ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí?

10 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tí Kristẹni kan ń sọ nìkan ló ń fi hàn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Téèyàn bá ń sọ ohun tó dáa jáde lẹ́nu àmọ́ tí kì í hùwà tó dáa, alágàbàgebè ni. Pọ́ọ̀lù mọ ìwà àgàbàgebè àwọn Farisí dáadáa ó sì mọ ohun búburú tí ìwà wọn yẹn ń fà. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tó sọ fún Tímótì pé kó ṣọ́ra fún irú ìwà àgàbàgebè bẹ́ẹ̀. (1 Tím. 1:5; 4:1, 2) Àmọ́ èyí kò fi hàn pé alágàbàgebè ni Tímótì o. Nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ pé: “Mo rántí ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú rẹ láìsí àgàbàgebè kankan.” (2 Tím. 1:5) Síbẹ̀, Tímótì ní láti jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé ojúlówó Kristẹni lòun. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìwà.

11. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì nípa lílépa ọrọ̀?

11 Nínú lẹ́tà méjèèjì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó gbà á níyànjú lórí àwọn ọ̀ràn mélòó kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ní kí Tímótì má máa lépa ọrọ̀. Ó sọ fún un pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tím. 6:10) Tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀, ó jẹ́ àmì pé onítọ̀hún ti ń jó rẹ̀yìn nípa tẹ̀mí. Àmọ́ àwọn Kristẹni tó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ni àwọn tó jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tara díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti ní “ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ.”—1 Tím. 6:6-8; Fílí. 4:11-13.

12. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìlọsíwájú wa máa fara hàn kedere nínú ìgbé ayé wa?

12 Pọ́ọ̀lù tún sọ fún Tímótì pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn arábìnrin máa “fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” (1 Tím. 2:9) Tí àwọn obìnrin bá wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìmúra àti ìwọṣọ wọn àti nínú àwọn ọ̀ràn míì nínú ìgbésí ayé wọn, tí èrò inú wọn sì yè kooro, àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n ń fi lélẹ̀. (1 Tím. 3:11) Ìlànà yìí kan àwọn arákùnrin pẹ̀lú. Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn alábòójútó ní láti jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, tí ó wà létòletò.” (1 Tím. 3:2) Tá a bá ń jẹ́ kí àwọn ànímọ́ yìí yọ nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́, ìlọsíwájú wa yóò máa fara hàn kedere sí gbogbo èèyàn.

13. Bíi ti Tímótì, báwo la ṣe lè jẹ́ àpẹẹrẹ nínú ìwà mímọ́?

13 Pọ́ọ̀lù tún rọ Tímótì pé kó jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìwà mímọ́. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí, ó ní apá ibì kan tó fẹ́ kí Tímótì kíyè sí, ìyẹn ni ti ìhùwàsí rẹ̀ sáwọn obìnrin. Kò fẹ́ kí ọ̀nà tí Tímótì ń gbà hùwà sí àwọn obìnrin mú ẹ̀gàn kankan lọ́wọ́. Ó ní kí Tímótì máa ṣe “àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.” (1 Tím. 4:12; 5:2) Ìṣekúṣe tẹ́nì kan ṣe láṣìírí pàápàá kò pa mọ́ lójú Ọlọ́run, ó sì dájú pé àwọn èèyàn pẹ̀lú ṣì máa mọ̀ nípa rẹ̀ bó pẹ́ bó yá. Bákan náà, ìwà rere tí Kristẹni kan ń hù kò lè pa mọ́. (1 Tím. 5:24, 25) Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló láǹfààní láti mú kí ìlọsíwájú wọn máa fara hàn nínú ìwà mímọ́ àti ìṣesí wọn.

Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́ Ṣe Pàtàkì

14. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn kedere pé àwa Kristẹni tòótọ́ ní láti nífẹ̀ẹ́ láàárín ara wa?

14 Ìfẹ́ ṣe kókó láàárín àwa Kristẹni tòótọ́. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:35) Báwo la ṣe lè fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa ‘fara dà á fún ara wa nínú ìfẹ́,’ ká máa ‘fi inú rere àti ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ darí ji ara wa,’ ká sì máa kó àwọn ará wa mọ́ra. (Éfé. 4:2, 32; Héb. 13:1, 2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 12:10.

15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo Kristẹni ní ìfẹ́, pàápàá àwọn alábòójútó?

15 Tó bá jẹ́ pé ìwà òǹrorò tàbí ìwà ọ̀dájú ni Tímótì ń hù sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni, ìyẹn ì bá ti ba gbogbo iṣẹ́ rere tó ṣe gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àti alábòójútó jẹ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:1-3.) Àmọ́, ó dájú pé bí Tímótì ṣe ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sáwọn ará, tó ń kó wọn mọ́ra, tó sì tún ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere nítorí wọn, ńṣe nìyẹn ń fi hàn pé ó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi dìídì sọ fún Tímótì nínú lẹ́tà tó kọ sí i pé kó tún jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìfẹ́.

16. Kí nìdí tí Tímótì fi ní láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára?

16 Tímótì rí ohun tó dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò láwọn ìgbà tó fi wà ní Éfésù. Àwọn kan ń kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ kan tó ta ko òtítọ́ táwọn Kristẹni gbà gbọ́. Àwọn míì sì wà tí wọ́n ń tan àwọn “ìtàn èké” kálẹ̀ tàbí tí wọ́n ń ṣèwádìí nípa àwọn èrò kan tí kò ṣàǹfààní kankan fún ipò tẹ̀mí ìjọ. (Ka 1 Tímótì 1:3, 4.) Pọ́ọ̀lù sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ “ń wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, láìlóye ohunkóhun, ṣùgbọ́n [wọ́n] jẹ́ olókùnrùn ní èrò orí lórí bíbéèrè ìbéèrè àti fífa ọ̀rọ̀.” (1 Tím. 6:3, 4) Ǹjẹ́ Tímótì jẹ́ fàyè gba àwọn èrò eléwu tó ti ń yọ́ wọnú ìjọ yẹn nínú ọkàn rẹ̀? Rárá o, torí pé Pọ́ọ̀lù ti rọ̀ ọ́ pé kó “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́” kó sì “yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’” (1 Tím. 6:12, 20, 21) Kò sí àní-àní pé Tímótì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Pọ́ọ̀lù fún un yẹn.—1 Kọ́r. 10:12.

17. Kí ló lè dán ìgbàgbọ́ wa wò lóde òní?

17 Pọ́ọ̀lù wá sọ fún Tímótì pé “ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò, àwọn kan yóò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.” (1 Tím. 4:1) Gbogbo àwa ará ìjọ, títí kan àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ, la ní láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, kó sì dúró digbí bíi ti Tímótì. Tá a bá dúró lórí ẹsẹ̀ wa, tá ò sì fàyè gba èrò àwọn apẹ̀yìndà, ìlọsíwájú wa yóò máa fara hàn kedere, a ó sì jẹ́ àpẹẹrẹ nínú ìgbàgbọ́.

Sapá Láti Mú Kí Ìlọsíwájú Rẹ Máa Fara Hàn Kedere

18, 19. (a) Báwo lo ṣe lè mú kí ìlọsíwájú rẹ máa fara hàn fún gbogbo èèyàn? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ìrísí, ẹ̀bùn àbínibí tàbí béèyàn ṣe gbajúmọ̀ tó ló ń fi hàn bí Kristẹni kan ṣe tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí tó. Kì í sì í ṣe dandan kó jẹ́ béèyàn ṣe pẹ́ tó nínú ètò Ọlọ́run ló máa pinnu rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń fi ìlọsíwájú wa nípa tẹ̀mí hàn kedere ni bá a ṣe ń ṣègbọràn sí Jèhófà ní ọ̀rọ̀, ní èrò àti ní ìṣe. (Róòmù 16:19) A ní láti máa tẹ̀ lé àṣẹ náà pé ká máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, ká sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì, ká fi ara wa fún un pátápátá kí ìlọsíwájú wa lè máa fara hàn kedere fún gbogbo èèyàn.

19 Ànímọ́ míì tí yóò máa hàn lára wa tá a bá ń tẹ̀ síwájú tá a sì ń dàgbà nípa tẹ̀mí ni ìdùnnú, èyí tó wà nínú èso ti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Gál. 5:22, 23) Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò bá a ṣe lè ní ayọ̀ tí ayọ̀ wa kò sì ní bà jẹ́ lákòókò ìdààmú.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa wa?

• Báwo ni ìlọsíwájú wa yóò ṣe hàn nínú ìwà mímọ́ àti ìṣesí wa?

• Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni jẹ́ àpẹẹrẹ nínú ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun bíi tàwọn àgbàlagbà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ṣé ìlọsíwájú rẹ ń fara hàn kedere fún gbogbo èèyàn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́