ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 11/15 ojú ìwé 22
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìwàláàyè Pípé Kì Í Màá Ṣe Àlá Lásán!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • “Báyìí Ni Ọlọ́run Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Wa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ohun Tí Jèhófà Ní Lọ́kàn Máa Ṣẹ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 11/15 ojú ìwé 22

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Jésù sọ fún àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé: “Kí ẹ jẹ́ pípé . . . bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.” Báwo làwọn èèyàn ṣe lè “jẹ́ pípé” lóde òní?—Mát. 5:48.

Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, àfi ká lóye bí wọ́n ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “pípé” àti “ìjẹ́pípé” nínú Bíbélì. Kì í ṣe gbogbo nǹkan tí Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ “pípé” ló rí bẹ́ẹ̀ láìkù síbì kan. Bíi ti Jèhófà kọ́ ṣá o, torí pé ó pé pérépéré láìkù síbì kan. Pípé ti àwa èèyàn àtàwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí kì í kọjá ibi tí agbára wa bá mọ. Àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tí Bíbélì túmọ̀ sí “pípé” sábà máa ń túmọ̀ sí “kún rẹ́rẹ́,” “dàgbà dénú,” tàbí “àìlálèébù” ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí aláṣẹ kan bá gbé kalẹ̀. Bá a bá ń sọ̀rọ̀, a sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà láti ṣàpèjúwe ohun tí kò dín kù sí ohun tá a retí. Àpẹẹrẹ kan lédè Yorùbá ni “orí pípé.”

Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà ní pípé ní ti pé wọ́n lè hùwà tó dáa, wọ́n lè jọ́sìn Ọlọ́run, ara wọn sì dá ṣáṣá. Wọ́n jẹ́ pípé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí Ẹlẹ́dàá wọn gbé kálẹ̀ fún wọn. Nítorí àìgbọràn, wọ́n kùnà láti dójú ìlà ohun tí Ọlọ́run fẹ́, nítorí náà, wọ́n pàdánù ìjẹ́pípé fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Nípa báyìí, ẹ̀ṣẹ̀, àìpé àti ikú tipasẹ̀ Ádámù kọjá sórí aráyé.—Róòmù 5:12.

Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe mú kó ṣe kedere nínú Ìwàásù Orí Òkè, àwọn èèyàn aláìpé pàápàá lè jẹ́ pípé dé ìwọ̀n tí agbára wọ́n mọ. Nínú àwíyé yẹn, ó gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ fún níní ìfẹ́ pípé tàbí ìfẹ́ kíkún rẹ́rẹ́. Èyí jẹ́ irú ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí aráyé. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mát. 5:44, 45) Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ń fi ìfẹ́ hàn nírú ọ̀nà yìí, a jẹ́ pé wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nìyẹn.

Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń sakun láti ní ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà gíga bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. À ń fẹ́ láti máa ṣèrànwọ́ fún onírúurú èèyàn tí ibi tí wọ́n ti wá, ẹ̀yà wọn àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Bíbélì. Ní òjìlénígba ilẹ̀ ó dín mẹ́rin [236], àwọn olùfìfẹ́hàn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lé ní mílíọ̀nù méje [7,000,000].

Jésù béèrè pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, èrè wo ni ẹ ní? Àwọn agbowó orí kò ha ń ṣe ohun kan náà bí? Bí ẹ bá sì kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni ẹ ń ṣe? Àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú kò ha ń ṣe ohun kan náà bí?” (Mát. 5:46, 47) Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe ojúsàájú sí àwọn èèyàn kan torí pé wọ́n kàwé tàbí nítorí ìlú tí wọ́n ti wá; kì í sì í ṣe àwọn tó bá lè san ohun kan pa dà fún wọn nìkan ni wọ́n máa ń fi ìfẹ́ hàn sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìní àtàwọn aláìsàn, àwọn ọmọdé àtàwọn àgbàlagbà. Ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, àwọn Kristẹni lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹni pípé débi tí agbára wọ́n mọ.

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ máa ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìjẹ́pípé tí Ádámù pàdánù? Bẹ́ẹ̀ ni, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, aráyé onígbọràn máa di pípé nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi, ní àkókò tí ‘Ọmọ Ọlọ́run máa fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.’—1 Jòh. 3:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́