ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 1/1 ojú ìwé 18
  • ‘Ó Tu Jèhófà Lójú’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ó Tu Jèhófà Lójú’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Jèhófà Dárí Jì ẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí Ló Ń Fi Hàn Pé Ẹnì Kan Ti Ronú Pìwà Dà Tọkàntọkàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ṣé O Ti Sìn Nígbà Kan Rí? Ǹjẹ́ O Tún Lè Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 1/1 ojú ìwé 18

Sún Mọ́ Ọlọ́run

‘Ó Tu Jèhófà Lójú’

ỌKÙNRIN kan tó yà kúrò nínú ọ̀nà Ọlọ́run tí wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò kì í ṣe ẹni tó yẹ mọ́.” Nígbà tó fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, ẹ̀rù ń bà á pé Ọlọ́run kò ní dárí ji òun. Àmọ́ ohun tó wà nínú ìwé 2 Kíróníkà 33:1-17 nípa Mánásè fi ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà yìí lọ́kàn balẹ̀ pé ìrètí ń bẹ. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o kì í ṣe ẹni tó yẹ mọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó o ti dá sẹ́yìn, àpẹẹrẹ Mánásè lè tù ẹ́ nínú.

Nínú ilé tí wọ́n ti bẹ̀rù Ọlọ́run ni wọ́n ti tọ́ Mánásè dàgbà. Hesekáyà bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba ilẹ̀ Júdà tó tayọ jù lọ. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi iṣẹ́ ìyanu mú kí ẹ̀mí bàbá Mánásè gùn sí i ni wọ́n bí Mánásè. (2 Àwọn Ọba 20:1-11) Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn àánú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Hesekáyà ka ọmọ rẹ̀ yìí sí, ó sì dájú pé, ó sapá láti gbin ìfẹ́ fún ìjọsìn tòótọ́ sọ́kàn rẹ̀. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ọmọ àwọn òbí tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run kì í sábà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn òbí wọn. Bí ọ̀rọ̀ Mánásè ṣe rí nìyẹn.

Mánásè kò ju ọmọ ọdún méjìlá lọ nígbà tí bàbá rẹ̀ kú. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé, ńṣe ló “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” (Ẹsẹ̀ 1, 2) Ṣé àwọn agbani-nímọ̀ràn tí kò bọ̀wọ̀ fún ìjọsìn tòótọ́ ló ṣàkóbá fún ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí ni? Bíbélì kò sọ. Ohun tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ ni pé, Mánásè di abọ̀rìṣà paraku àti òǹrorò ẹ̀dá. Ó ṣe pẹpẹ fún àwọn ọlọ́run èké, ó fi ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ, ó lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò, ó sì gbé ère gbígbẹ́ sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Mánásè olórí kunkun kọ ìkìlọ̀ léraléra látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ pé iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ló jẹ́ kí wọ́n bí Mánásè.—Ẹsẹ 3-10.

Níkẹyìn, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de Mánásè lọ sí Bábílónì. Nígbà tí Mánásè wà ní ìgbèkùn, ó ronú lórí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀. Ṣé ó ti wá rí i pé, àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí tí kò lè ṣe nǹkan kan, èyí tí òun ń jọ́sìn kò lè dáàbò bo òun? Ṣé ó ronú lórí àwọn nǹkan tí bàbá rẹ̀ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run kọ́ ọ nígbà tó wà lọ́mọdé? Èyí ó wù tí ì báà jẹ́, Mánásè ronú pìwà dà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ó tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú, ó sì ń bá a nìṣó ní rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi . . . Ó sì ń gbàdúrà sí I ṣáá.” (Ẹsẹ 12, 13) Àmọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run lè dárí ji ọkùnrin tó dá irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì bẹ́ẹ̀?

Bí Mánásè ṣe ronú pìwà dà látọkàn wá mú kí Jèhófà yọ́nú sí i. Ọlọ́run gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tó bẹ̀ pé kó ṣàánú òun, “ó sì mú un padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀.” (Ẹsẹ 13) Mánásè ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe láti fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà, ó mú ìbọ̀rìṣà kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ń rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé “kí wọ́n máa sin Jèhófà.”—Ẹsẹ 15-17.

Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Ọlọ́run kò lè dárí jì ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó o ti dá sẹ́yìn, jẹ́ kí àpẹẹrẹ Mánásè tù ọ́ nínú. Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ara Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. (Róòmù 15:4) Ó hàn kedere pé, Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan dá ló ṣe pàtàkì lójú Jèhófà, bí kò ṣe ipò ọkàn ẹlẹ́ṣẹ̀ náà. Ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó gbàdúrà pẹ̀lú ọkàn ìrònúpìwàdà, tó jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tó sì pinnu láti máa ṣe ohun tó tọ́ lè ‘tu Jèhófà lójú,’ bí Mánásè tí ṣe.—Aísáyà 1:18; 55:6, 7.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún January:

◼ 2 Kíróníkà 29-36–Ẹ́sírà 1-10

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́