ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 3/15 ojú ìwé 8-12
  • Ẹ̀mí Ọlọ́run Ni Kó O Gbà, Má Ṣe Gba Ẹ̀mí Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀mí Ọlọ́run Ni Kó O Gbà, Má Ṣe Gba Ẹ̀mí Ayé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Ẹ̀mí Ayé Fi Gbilẹ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
  • Ṣé Ẹ̀mí Ayé Ń Nípa Lórí Rẹ?
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Jésù
  • A Lè Ṣẹ́gun Ayé
  • Má Ṣe Fàyè Gba “Ẹ̀mí Ayé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìwọ Ha Ń Gbéjàko Ẹ̀mí Ayé Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí Kó O Sì Mú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Rẹ Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 3/15 ojú ìwé 8-12

Ẹ̀mí Ọlọ́run Ni Kó O Gbà, Má Ṣe Gba Ẹ̀mí Ayé

“Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí àwa bàa lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.” —1 KỌ́R. 2:12.

1, 2. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ gbà wà lójú ogun? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

OJÚ ogun làwa Kristẹni tòótọ́ wà! Ọ̀tá tá à ń bá jà lágbára, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni, kì í sá fún ogun. Ohun ìjà ogun tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lágbára débi pé ó ti lò ó láti fi ṣọṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń gbé láyé. Àmọ́, kò yẹ ká ronú pé a kò lè sa ipá kankan tàbí pé a kò lè borí rẹ̀. (Aísá. 41:10) A ní ohun ààbò tí ohun ọṣẹ́ kankan kò lè ràn tí kò sì ṣeé borí.

2 Kì í ṣe ogun nípa tara là ń jà bí kò ṣe ogun nípa tẹ̀mí. Sátánì Èṣù ni ọ̀tá wa, ọ̀kan lára ohun ìjà tó ń lò jù lọ ni “ẹ̀mí ayé.” (1 Kọ́r. 2:12) Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ohun ààbò pàtàkì tá a lè fi kojú àwọn àtakò rẹ̀. Ká bàa lè borí nínú ogun yìí kí ohunkóhun má sì ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó pọn dandan ká béèrè fún ẹ̀mí Ọlọ́run ká sì máa fi èso ẹ̀mí rẹ̀ ṣèwà hù nínú ìgbésí ayé wa. (Gál. 5:22, 23) Kí tilẹ̀ ni ẹ̀mí ayé, báwo ló sì ṣe di ohun tó ń nípa lórí aráyé tó bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ẹ̀mí ayé ti bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí wa? Kí la sì lè rí kọ́ lára Jésù nípa bá a ṣe lè gba ẹ̀mí Ọlọ́run, ká má sì fàyè gba ẹ̀mí ayé?

Kí Nìdí Tí Ẹ̀mí Ayé Fi Gbilẹ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?

3. Kí ni ẹ̀mí ayé?

3 Ọ̀dọ̀ Sátánì tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé” ni ẹ̀mí ayé ti bẹ̀rẹ̀, ẹ̀mí ayé yìí sì máa ń ta ko ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Jòh. 12:31; 14:30; 1 Jòh. 5:19) Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn tó gbòde kan, ó sì ń darí àwọn èèyàn láti hùwà. Ó sì tún jẹ́ agbára tó ń darí àwùjọ ẹ̀dá èèyàn láti ṣe àwọn nǹkan tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti ète rẹ̀.

4, 5. Báwo ni ẹ̀mí tí Sátánì ń gbé lárugẹ yìí ṣe gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?

4 Báwo ni ẹ̀mí tí Sátánì ń gbé lárugẹ yìí ṣe gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, Sátánì tan Éfà jẹ nínú ọgbà Édẹ́nì. Ó mú kó gbà pé ayé rẹ̀ á sunwọ̀n sí i bí kò bá fi ti Ọlọ́run ṣe. (Jẹ́n. 3:13) Òpùrọ́ mà ni Sátánì o! (Jòh. 8:44) Obìnrin yìí kan náà ló tún lò láti sọ Ádámù di aláìṣòótọ́ sí Jèhófà. Torí pé Ádámù yàn láti ṣàìgbọràn, ó sọ gbogbo aráyé di ẹlẹ́ṣẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún ẹ̀mí àìgbọràn tí Sátánì ń lò láti máa nípa lórí gbogbo èèyàn.—Ka Éfésù 2:1-3.

5 Sátánì tún nípa lórí ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì, àwọn ló sì di ẹ̀mí èṣù. (Ìṣí. 12:3, 4) Kí Ìkún-omi ọjọ́ Nóà tó wáyé ni àwọn áńgẹ́lì náà ti di ọlọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn áńgẹ́lì yẹn gbà pé nǹkan á sàn fún àwọn bí àwọn bá fi ipò àwọn sílẹ̀ lọ́run tí àwọn sì wá sáyé láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àwọn lọ́rùn. (Júúdà 6) Lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyẹn pa dà sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí, Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí í lò wọ́n láti máa “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣí 12:9) Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí èṣù ń darí aráyé.—2 Kọ́r. 4:4.

Ṣé Ẹ̀mí Ayé Ń Nípa Lórí Rẹ?

6. Ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni ẹ̀mí ayé lè gbà ràn wá?

6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé Sátánì ló ń darí ayé, àmọ́ kò sí ìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ fi ní láti sọ pé àwọn kò mọ àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 2:11) Ohun kan tó dájú ni pé ẹ̀mí ayé kò lè nípa lórí wa àyàfi tá a bá fàyè gbà á. Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ohun mẹ́rin tó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí wa tàbí ẹ̀mí ayé.

7. Kí ni ọ̀nà kan tí Sátánì ń gbà láti sọ wá di àjèjì sí Jèhófà?

7 Kí ni irú eré ìnàjú tí mo yàn ń sọ nípa mi? (Ka Jákọ́bù 3:14-18.) Sátánì ń gbìyànjú láti sọ wá di àjèjì sí Ọlọ́run nípa mímú ká nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá. Èṣù mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá. (Sm. 11:5) Torí náà, Sátánì ń gbìyànjú láti mú kí ọkàn àwọn èèyàn máa fà sí àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara nípa lílo àwọn ìwé, fíìmù, orin àtàwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà tí díẹ̀ lára wọn máa ń mú kó dà bíi pé àwọn tó ń gbá géèmù náà ń lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe ní tààràtà tí wọ́n sì ń hùwà òǹrorò. Sátánì ò kọ̀ tá a bá fi apá kan ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ ohun rere, tiẹ̀ ni pé ká ṣáà ti fi apá tó kù nífẹ̀ẹ́ ohun búburú tó ń gbé lárugẹ.—Sm. 97:10.

8, 9. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa nípa eré ìnàjú?

8 Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń mú káwọn tó bá rí i gbà jẹ́ ẹni tó mọ́ níwà, ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti ẹni tó kún fún àánú. Ó máa dára ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ eré ìnàjú tí mo yàn ń mú kí n ní àwọn ànímọ́ tí ń gbéni ró?’ Ọgbọ́n tó ti òkè wá “kì í ṣe àgàbàgebè.” Àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí kì í wàásù fáwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n máa hùwà mímọ́ kí wọ́n sì máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn, síbẹ̀ kí àwọn fúnra wọn máa fi wíwo ìwà ẹhànnà àti ìṣekúṣe dára yá nínú kọ̀rọ̀ yàrá wọn.

9 Jèhófà ń retí pé ká fún òun ní ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe. Àmọ́, ìjọsìn kan ṣoṣo péré ti tẹ́ Sátánì lọ́rùn. Irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ ló sì ní kí Jésù fún òun. (Lúùkù 4:7, 8) A lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ irú eré ìnàjú tí mo yàn á mú kó ṣeé ṣe fún mi láti fún Ọlọ́run ní ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe? Ǹjẹ́ irú eré ìnàjú tí mo yàn á mú kó túbọ̀ nira fún mi láti má ṣe fàyè gba ẹ̀mí ayé, àbí ńṣe ló máa mú kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti kọ̀ ọ́? Ǹjẹ́ ó yẹ kí n ṣe ìyípadà èyíkéyìí bí mo bá fẹ́ yan eré ìnàjú lọ́jọ́ iwájú?’

10, 11. (a) Irú ìwà wo ni ẹ̀mí ayé ń gbé lárugẹ nípa àwọn ohun ìní tara? (b) Irú ìwà wo ni Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí gbà wá níyànjú pé ká máa hù?

10 Kí ni ìṣarasíhùwà mi nípa àwọn ohun ìní tara? (Ka Lúùkù 18:24-30.) Ẹ̀mí ayé ń gbé “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” lárugẹ nípa mímú kí ìwọra àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì gba àwọn èèyàn lọ́kàn. (1 Jòh. 2:16) Ó ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn pinnu láti di ọlọ́rọ̀. (1 Tím. 6:9, 10) Ẹ̀mí yẹn máa jẹ́ ká gbà pé kíkó ohun ìní jọ rẹpẹtẹ ló máa mú ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀. (Òwe 18:11) Àmọ́, tí ìfẹ́ tá a ní fún owó bá borí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run, a ti jẹ́ kí Sátánì borí wa nìyẹn o. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìgbádùn tí owó lè fún mi ló kù tí mò ń gbájú mọ́?’

11 Lọ́nà tó yàtọ̀ sí èyí, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí gbà wá níyànjú pé ká ní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa owó, ká sì máa ṣiṣẹ́ kára ká bàa lè pèsè àwọn ohun tara tó jẹ́ kòṣeémánìí fún ara wa àti ìdílé wa. (1 Tím. 5:8) Ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń ran àwọn tó bá rí i gbà lọ́wọ́ láti máa fara wé ìwà ọ̀làwọ́ Jèhófà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fúnni ni, wọn kì í wá bí wọ́n ṣe máa gba tọwọ́ ẹlòmíì. Àwọn èèyàn ṣeyebíye lójú wọn gidigidi ju àwọn nǹkan tara lọ, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ ṣàjọpín ohun tí agbára wọ́n bá gbé pẹ̀lú àwọn míì. (Òwe 3:27, 28) Wọn kò sì jẹ́ kí ìlépa owó gba ìjọsìn Ọlọ́run mọ́ àwọn lọ́wọ́.

12, 13. Níwọ̀n bí ẹ̀mí Ọlọ́run ti yàtọ̀ sí ẹ̀mí ayé, báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè nípa rere lórí wa?

12 Irú ẹ̀mí wo ló ń darí ọ̀nà tí mo gbà ń hùwà? (Ka Kólósè 3:8-10, 13.) Ńṣe ni ẹ̀mí ayé máa ń gbé iṣẹ́ ti ara lárugẹ. (Gál. 5:19-21) Torí náà, ẹ̀mí tó ń darí wa kì í tètè fara hàn nígbà tí àwọn nǹkan bá ń lọ déédéé, àmọ́ ó dìgbà tí nǹkan ò bá lọ bó ṣe yẹ, irú bíi kí arákùnrin tàbí arábìnrin kan má kà wá sí, kó mú wa bínú tàbí kó tiẹ̀ ṣẹ̀ wá pàápàá. Ní àfikún sí ìyẹn, irú ẹ̀mí tó ń darí wa lè fara hàn nínú ọ̀nà tí à ń gbà bá àwọn alábàágbé wa lò. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu ká ṣe àyẹ̀wò ara wa. Bi ara rẹ pé, ‘Ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, ǹjẹ́ mo ti túbọ̀ fìwà jọ Kristi àbí mo ti jó àjórẹ̀yìn tí mo sì ń sọ̀rọ̀ tí kò bójú mu tàbí hu àwọn ìwà kan tí kò dára?’

13 Ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀,” ká sì fi “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ ara wa láṣọ. Ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn ká sì jẹ́ onínúure. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ la ṣẹ ara wa, ó máa rọrùn fún wa láti dárí ji ara wa fàlàlà. Bá a bá rí ẹnì kan tó ṣe ohun tá a kà sí èyí tí kò tọ́, a kò ní gbà kí ìyẹn yọrí sí “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.” Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa sapá láti fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” hàn.—Éfé. 4:31, 32.

14. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé fi ń wo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

14 Ǹjẹ́ mò ń fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà tó yẹ ká máa hù, ṣé mo sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà náà? (Ka Òwe 3:5, 6.) Ẹ̀mí ayé kì í jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ láti ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn tí ẹ̀mí yìí ń darí kì í fiyè sí apá tí wọ́n rò pé kò rọrùn fún àwọn láti tẹ̀ lé nínú Bíbélì, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yàn láti fara mọ́ ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àti ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí àwọn èèyàn. (2 Tím. 4:3, 4) Àwọn kan ò tiẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí rárá. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ máa ń kọminú pé bóyá ni Bíbélì wúlò tó sì ṣeé gbára lé, wọ́n á sì wá di ọlọgbọ́n lójú ara wọn. Wọ́n ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ìlànà ṣíṣe kedere tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nípa panṣágà, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti ìkọ̀sílẹ̀. Wọ́n ń kọ́ni pé “ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.” (Aísá. 5:20) Ṣé ẹ̀mí yìí ti nípa lórí wa? Bí ìṣòro bá dojú kọ wá, ṣé ọgbọ́n èèyàn àti èrò tiwa là ń gbára lé? Àbí ńṣe là ń sapá láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì?

15. Dípò ká gbára lé ọgbọ́n ti ara wa, kí ló yẹ ká ṣe?

15 Ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń mú ká fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì. Bíi ti onísáàmù, à ń wo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi fìtílà fún ẹsẹ̀ wa àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa. (Sm. 119:105) Dípò ká gbára lé ọgbọ́n tiwa, à ń gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run torí ó dá wa lójú pé ó máa jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó dára àti ohun tó burú. A ti kọ́ láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ká sì tún nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run.—Sm. 119:97.

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Jésù

16. Kí la lè ṣe ká bàa lè ní “èrò inú ti Kristi”?

16 Ká tó lè rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà, àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ ní “èrò inú ti Kristi.” (1 Kọ́r. 2:16) Ká tó lè ní “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní,” ó gba pé ká mọ bó ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Róòmù 15:5; 1 Pét. 2:21) Jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀nà díẹ̀ tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.

17, 18. (a) Kí la rí kọ́ lára Jésù nípa àdúrà gbígbà? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa “bá a nìṣó ní bíbéèrè”?

17 Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí rẹ̀. Kí Jésù tó dojú kọ àdánwò, ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ ran òun lọ́wọ́. (Lúùkù 22:40, 41) Ó pọn dandan kí àwa náà béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Torí pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́, gbogbo àwọn tó bá béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ pé ó máa fún àwọn, ló máa ń fún ní ẹ̀mí náà lọ́fẹ̀ẹ́. (Lúùkù 11:13) Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín. Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà, àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún.”—Mát. 7:7, 8.

18 Bó o bá ń bẹ Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́, má ṣe tètè dẹ́kun láti máa béèrè fún un. Ó lè gba pé kí àdúrà wa túbọ̀ ṣe lemọ́lemọ́ ká sì máa fi kún àkókò tá a fi ń gbàdúrà. Nígbà míì, Jèhófà máa ń jẹ́ kí àwọn tó ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ fi hàn bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ wọ́n lógún tó, ó sì tún máa ń fẹ́ mọ bí ìgbàgbọ́ wọn ṣe jẹ́ ojúlówó tó, kó tó dáhùn àwọn àdúrà wọn.a

19. Kí ni Jésù máa ń ṣe nígbà gbogbo, kí sì nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

19 Máa ṣègbọràn sí Jèhófà nínú ohun gbogbo. Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń ṣe àwọn nǹkan tó dùn mọ́ Bàbá rẹ̀ nínú. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan, ọ̀nà tí Jésù fẹ́ láti gbà bójú tó ọ̀ràn kan yàtọ̀ sí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ fún un. Síbẹ̀, ìgbọ́kànlé tó ní nínú Bàbá rẹ̀ mú kó sọ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Wá bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run kódà nígbà tí kò bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?’ Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run ká bàa lè máa wà láàyè. A gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí i nínú ohun gbogbo torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ní Orísun ìwàláàyè wa, òun náà ló sì ń gbé ìwàláàyè wa ró. (Sm. 95:6, 7) Kò sí ohun tá a lè fi rọ́pò ìgbọràn. A kò lè rí ojú rere Ọlọ́run àfi tá a bá ń ṣègbọràn sí i.

20. Kí ló jẹ Jésù lógún jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, báwo la sì ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

20 Mọ Bíbélì dáadáa. Nígbà tí Sátánì ta ko Jésù lójúkojú kó lè dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò, Jésù kojú àtakò náà nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 4:1-13) Nígbà tí Jésù ń dá àwọn alátakò rẹ̀ lóhùn, ó lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ rẹ̀. (Mát. 15:3-6) Ohun tó jẹ Jésù lógún jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ni bó ṣe máa mọ òfin Ọlọ́run àti bó ṣe máa mú un ṣẹ. (Mát. 5:17) Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń gbé ìgbàgbọ́ ẹni ró bọ́ ọkàn wa. (Fílí. 4:8, 9) Ó lè ṣòro fún àwọn kan lára wa láti wá àkókò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Àmọ́, dípò ká wá àkókò, ó lè jẹ́ pé ńṣe la máa ṣètò àkókò.—Éfé. 5:15-17.

21. Ìṣètò wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa ká sì máa fi í sílò?

21 “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àkókò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nípa ṣíṣètò fún Ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́. (Mát. 24:45) Ǹjẹ́ ò ń fi ìṣètò yìí sílò lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu? Nígbà tó o bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ǹjẹ́ o lè máa fi ọgbọ́n ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Jésù fi kọ́ni lórí kókó ẹ̀kọ́ tó o bá nífẹ̀ẹ́ sí kó o bàa lè ní èrò inú ti Kristi? O lè lo ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index láti wá àwọn ìsọfúnni tó kún fún ẹ̀kọ́ nípa kókó tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún 2008 sí ọdún 2010, ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde ti gbé àwọn àpilẹ̀kọ́ méjìlá jáde tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Ohun Tá A Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù.” O lè fẹ́ láti lo àwọn àpilẹ̀kọ yìí fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Láti ọdún 2006 wá ni ìwé ìròyìn Jí! ti ń gbé àpilẹ̀kọ́ náà, “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?” jáde. A ṣètò àpilẹ̀kọ náà kó o lè lò ó láti mú kí òye tó o ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbòòrò kó sì tún jinlẹ̀ sí i. O ò ṣe máa fi ìsọfúnni látinú irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ kún Ìjọsìn Ìdílé rẹ láti ìgbà dé ìgbà?

A Lè Ṣẹ́gun Ayé

22, 23. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè ṣẹ́gun ayé?

22 Kí ẹ̀mí Ọlọ́run lè máa darí wa, a kò gbọ́dọ̀ fàyè gba ẹ̀mí ayé. Dídènà ẹ̀mí ayé kì í ṣe ohun tó rọrùn. Nígbà mìíràn, ó gba kéèyàn jà fitafita, kéèyàn sì ja ìjà líle. (Júúdà 3) Àmọ́ a lè borí nínú ìjà náà! Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—Jòh. 16:33.

23 Àwa pẹ̀lú lè ṣẹ́gun ayé bí a kò bá fàyè gba ẹ̀mí rẹ̀ tá a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè gba ẹ̀mí Ọlọ́run. Ní tòótọ́, “bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?” (Róòmù 8:31) Bá a bá gba ẹ̀mí Ọlọ́run tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Bíbélì, a máa rí ìtẹ́lọ́rùn, àlàáfíà àti ayọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tó sún mọ́lé sì máa túbọ̀ dá wa lójú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo ojú ìwé 170 sí 173 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí ẹ̀mí ayé fi gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?

• Àwọn ìbéèrè mẹ́rin wo ló yẹ ká bi ara wa?

• Àwọn ohun mẹ́ta wo la rí kọ́ lára Jésù nípa bá a ṣe lè rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Báwo ni àwọn áńgẹ́lì kan ṣe di ẹ̀mí èṣù?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Sátánì ń lo ẹ̀mí ayé láti darí àwọn èèyàn, àmọ́ a lè já ara wa gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́