ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 3/15 ojú ìwé 24-28
  • Ẹ Wà Ní Ìmúratán!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Wà Ní Ìmúratán!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Wà Ní Ìmúratán Bíi Ti Nóà
  • Nóà àti Ìdílé Rẹ̀ Wà Ní Ìmúratán
  • Mósè Wà Lójúfò
  • Ẹ Wà Lójúfò!
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ohun Tó Mú Kí Nóà Rójú Rere Ọlọ́run—Ìdí Tó Fi Kàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 3/15 ojú ìwé 24-28

Ẹ Wà Ní Ìmúratán!

“Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—MÁT. 24:44.

1, 2. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wo la lè fi wé bí ẹkùn ṣe máa ń gbéjà koni? (b) Ọ̀nà wo ni ìgbéjàkò tó ń bọ̀ gbà kàn ẹ́?

LÁTI ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ẹnì kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé ó máa ń bá ẹranko ṣeré ti máa ń dá àwùjọ àwọn òǹwòran lára yá nígbà tó bá ń bá àwọn ẹkùn ilẹ̀ Bengal tó ti fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣeré, àwọn ẹkùn náà kì í sì í pa á lára. Ó sọ pé: “Bí ẹranko kan bá mojú rẹ, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹ̀bùn tó rẹwà jù lọ lágbàáyé lé ẹ lọ́wọ́.” Àmọ́ ní October 3, ọdún 2003, òkété bórù mọ́ ọ̀gbẹ́ni yìí lọ́wọ́. Láìsí ìdí kan gúnmọ́, ọ̀kan lára àwọn ẹkùn náà, tó ní àwọ̀ funfun tó sì wúwo tó àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́ta àtààbọ̀, gbéjà ko ọkùnrin náà. Kò ronú pé ẹkùn náà lè gbéjà ko òun, torí náà ó bá a lójijì.

2 Ó gbàfiyèsí pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbéjàkoni látọ̀dọ̀ “ẹranko ẹhànnà” kan, ó sì yẹ ká wà ní ìmúrasílẹ̀. (Ka Ìṣípayá 17:15-18.) Ta ni “ẹranko ẹhànnà” náà? Ta ló sì máa gbéjà kò? Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà dúró fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, “ìwo mẹ́wàá” náà sì dúró fún gbogbo agbára òṣèlú pátá. Wọ́n máa gbéjà ko Bábílónì Ńlá tó dà bí aṣẹ́wó, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, wọ́n á sì pa á run ní ìpa ìkà. Ìgbéjàkò yìí máa bá ọ̀pọ̀ èèyàn lójijì torí pé ọjọ́ pẹ́ tí ẹranko ẹhànnà náà àti Bábílónì ńlá ti ń bá ara wọn ṣọ̀rẹ́. Ìgbà wo ni ìgbéjàkò yìí máa wáyé? A kò mọ ọjọ́ àti wákàtí tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé. (Mát. 24:36) Ohun tí a mọ̀ ni pé ó máa jẹ́ ní wákàtí tí a kò retí, àkókò tó ṣẹ́ kù kí àtakò náà wáyé sì ti dín kù. (Mát. 24:44; 1 Kọ́r. 7:29) Ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká wà ní ìmúratán nípa tẹ̀mí kó lè jẹ́ pé nígbà tí ìgbéjàkò náà bá ṣẹlẹ̀ tí Kristi sì wá gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ, ó máa jẹ́ Olùdáǹdè wa! (Lúùkù 21:28) Ká bàa lè wà ní ìmúratán, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ tí àwọn náà wà ní ìmúratán tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run. Ṣé a máa fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ti gidi yìí sọ́kàn?

Ẹ Wà Ní Ìmúratán Bíi Ti Nóà

3. Àwọn ipò wo ló mú kó nira fún Nóà láti fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan kò fara rọ nígbà tí Nóà wà lórí ilẹ̀ ayé, Nóà fi hàn pé òun múra tán láti rí ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run. Ìwọ ronú nípa bí nǹkan ṣe ní láti nira fún Nóà tó nígbà tí àwọn áńgẹ́lì tó di ọlọ̀tẹ̀ gbé ara ẹ̀dá èèyàn wọ̀ tí wọ́n wá gbé pẹ̀lú àwọn obìnrin rírẹwà tí wọ́n sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn! Ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ yìí mú kí wọ́n bí àwọn àràmàǹdà ọmọ, ‘àwọn alágbára ńlá’ tí wọ́n ń lo agbára wọn tó ju ti ẹ̀dá lọ láti dúnkookò mọ́ àwọn èèyàn. (Jẹ́n. 6:4) Ronú nípa ìwà ipá tí àwọn òmìrán wọ̀nyí dá sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń mú ayé nira fáwọn èèyàn níbikíbi tí wọ́n bá lọ. Nítorí èyí, ìwà ibi gbilẹ̀, èrò inú àwọn èèyàn jẹ́ kìkì ibi, ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń hù sì wá gogò sí i. Nígbà náà ni Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run pa àṣẹ kan tó fi hàn pé ó ti pinnu láti pa àwọn èèyàn tó ń gbé nínú ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yẹn run.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:3, 5, 11, 12.a

4, 5. Báwo ni ipò àwọn nǹkan ní àkókò tá à ń gbé yìí ṣe rí bíi ti ọjọ́ Nóà?

4 Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí ní ọjọ́ Nóà ló ṣe máa rí ní àkókò tá à ń gbé yìí. (Mát. 24:37) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀mí búburú náà ń pitú ọwọ́ wọn ní àkókò tá à ń gbé yìí. (Ìṣí. 12:7-9, 12) Àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí èṣù yìí gbé ara ẹ̀dá èèyàn wọ̀ ní ọjọ́ Nóà. Wọn kò lè gbé ara ẹ̀dá èèyàn wọ̀ mọ́ báyìí, àmọ́ wọ́n ń sapá láti máa darí tàgbà tèwe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kò lè rí àwọn áńgẹ́lì búburú yìí, inú wọn máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí i tí àwọn tó ṣeé ṣe fún wọn láti sọ dìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ń hu ìwà ibi tí wọ́n sì ń fi ìwà ìbàjẹ́ ṣayọ̀.—Éfé. 6:11, 12.

5 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe Èṣù ní “apànìyàn” ó sì sọ pé ó ní “ọ̀nà àtimú ikú wá.” (Jòh. 8:44; Héb. 2:14) Ó ní ibi tí agbára rẹ̀ mọ bó bá di pé kó pa èèyàn ní tààràtà, àmọ́ ó lè mú káwọn èèyàn ṣe ohun tó máa mú kí ìyà jẹ wọ́n kí wọ́n sì kú. Ó máa ń mú káwọn èèyàn hùwà ẹ̀tàn. Ó máa ń gbin èròkerò sí àwọn èèyàn lọ́kàn kí wọ́n lè kórìíra àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n sì pa wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọmọ méjìlélógóje [142] tí wọ́n bá bí nílẹ̀ Amẹ́ríkà, àwọn tó ń hùwà ipá máa ń pa ọ̀kan nínú wọn. Níbi tí pípa èèyàn ní ìpakúpa gbilẹ̀ dé yìí, ǹjẹ́ o rò pé Jèhófà kò ní kíyè sí i bó ti ṣe nígbà ayé Nóà? Ṣé ó máa kùnà láti wá nǹkan ṣe sí i?

6, 7. Báwo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run?

6 Nígbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run, ó sọ fún Nóà pé òun máa mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé láti pa gbogbo ẹran ara run. (Jẹ́n. 6:13, 17) Jèhófà fún Nóà ní ìtọ́ni pé kó kan ọkọ̀ áàkì kan tó dà bí àpótí ńlá. Nóà àti ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í kan ọkọ̀ náà. Kí ló mú kí wọ́n ṣègbọràn kí wọ́n sì fi hàn pé àwọn ti wà ní ìmúratán de ìdájọ́ Ọlọ́run?

7 Ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run mú kí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe. (Jẹ́n. 6:22; Héb. 11:7) Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, Nóà pọkàn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kò sì lọ́wọ́ sí ìwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ń hù nígbà yẹn. (Jẹ́n. 6:9) Ó mọ̀ pé ìdílé òun kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìwà ipá àti ìwà àìgbọràn táwọn èèyàn tó yí wọn ká ń hù. Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ọ̀ràn ìgbésí ayé ojoojúmọ́ gbà wọ́n lọ́kàn. Ọlọ́run gbé iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́, ó sì ṣe pàtàkì pé kí ìdílé Nóà lódindi pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ náà.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:14, 18.

Nóà àti Ìdílé Rẹ̀ Wà Ní Ìmúratán

8. Kí ló fi hàn pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ fi ìfọkànsìn Ọlọ́run ṣèwà hù?

8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Nóà tó jẹ́ olórí ìdílé, síbẹ̀ olùjọ́sìn Jèhófà ni ìyàwó Nóà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ náà. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì jẹ́rìí sí èyí. Ó sọ pé bí Nóà bá gbé láyé lákòókò Ìsíkíẹ́lì ni, òdodo Nóà kò ní gba àwọn ọmọ rẹ̀ là. Ìdí ni pé wọ́n ti dàgbà tó láti pinnu yálà láti ṣègbọràn tàbí kí wọ́n ṣàìgbọràn. Torí náà, ńṣe ni olúkúlùkù wọn fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Ìsík. 14:19, 20) Ìdílé Nóà fara mọ́ ìtọ́ni tó fún wọn, wọ́n ní ìgbàgbọ́ bíi tirẹ̀, wọn ò sì jẹ́ kí ohun táwọn míì ń ṣe dí wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́.

9. Àwọn wo la lè rí tọ́ka sí lónìí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ bíi ti Nóà?

9 Lónìí, ó máa ń fún wa níṣìírí gan-an láti rí àwọn olórí ìdílé tí wọ́n jẹ́ apá kan ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé, tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà! Wọ́n mọ̀ pé ojúṣe àwọn ju pé káwọn pèsè oúnjẹ, aṣọ, ibùgbé àti ẹ̀kọ́ ìwé fún ìdílé àwọn. Wọ́n tún gbọ́dọ̀ bójú tó wọn nípa tẹ̀mí. Kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn ń múra sílẹ̀ de ohun tí Jèhófà máa tó ṣe.

10, 11. (a) Láìsí àníàní, báwo ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde áàkì ṣe máa rí lára Nóà àti ìdílé rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló dára pé ká bi ara wa?

10 Ó ṣeé ṣe kí Nóà, ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ ti fi nǹkan bí àádọ́ta [50] ọdún ṣiṣẹ́ kíkan ọkọ̀ áàkì náà. Wọ́n ti ní láti máa wọnú ọkọ̀ áàkì náà kí wọ́n sì máa jáde nínú rẹ̀ ní àìmọye ìgbà nígbà tí wọ́n ń kàn án lọ́wọ́. Wọ́n dí àwọn àlàfo tí omi lè gbà wọnú ọkọ̀ náà, wọ́n kó oúnjẹ sínú rẹ̀, wọ́n sì kó àwọn ẹranko sínú rẹ̀. Fojú inú yàwòrán ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Níkẹyìn, ọjọ́ tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ náà dé. Ó jẹ́ ọjọ́ kẹtàdínlógún nínú oṣù kejì ọdún 2370 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọjọ́ yẹn ni gbogbo wọn wọnú ọkọ̀ náà. Lẹ́yìn tí wọ́n wọnú rẹ̀ tán, Jèhófà ti ilẹ̀kùn ọkọ̀ náà, òjò sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Kì í wulẹ̀ ṣe ìkún omi kékeré kan là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ o. Àwọn ibú omi tàbí omi òkun tí Ọlọ́run sọ lọ́jọ̀ sójú sánmà ló ya, ọ̀yamùúmùú òjò sì bẹ̀rẹ̀ sí í dà yàà sórí áàkì náà. (Jẹ́n. 7:11, 16) Àwọn tó wà lóde áàkì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kú, àmọ́ mìmì kan kò mi àwọn tó wà nínú áàkì náà. Báwo ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà ṣe máa rí lára Nóà àti ìdílé rẹ̀? Ó dájú pé ńṣe ni wọ́n máa kún fún ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Kò sì sí iyè méjì pé wọ́n á tún máa ronú pé, ‘A mà láyọ̀ gan-an o pé a bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn tá a sì wà ní ìmúratán!’ (Jẹ́n. 6:9) Ṣé ìwọ náà ń wo ara rẹ pé o ti la Amágẹ́dọ́nì já tí ọkàn rẹ sì kún fún ìmọrírì bíi ti Nóà?

11 Kò sí ohun tó lè dí Olódùmarè lọ́wọ́ tí kò fi ní mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan Sátánì. Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ó dá mi lójú pé, bó ti wù kó kéré mọ, èyíkéyìí lára àwọn ìlérí Ọlọ́run kò ní lọ láìní ìmúṣẹ àti pé gbogbo wọn ló máa ní ìmúṣẹ bí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run?’ Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ náà gbọ́dọ̀ fi hàn pé o wà ní ìmúratán nípa fífi “ọjọ́ Jèhófà” tí ń yára bọ̀ kánkán náà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.—2 Pét. 3:12.

Mósè Wà Lójúfò

12. Kí ni ì bá ti mú kó ṣòro fún Mósè láti pọkàn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

12 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ míì yẹ̀ wò. Bá a bá fi ojú èèyàn wò ó, ńṣe ló dà bíi pé Mósè bá ara rẹ̀ ní ipò kan tó lè mú kó ní àǹfààní títayọ lọ́lá ní ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì. Torí pé ọmọbìnrin Fáráò gbà á ṣọmọ, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn máa gbé e gẹ̀gẹ̀, kó máa jẹ́ oúnjẹ tó dára jù lọ, kó máa wọ aṣọ tó dára jù lọ, kó sì máa gbé ní àyíká tó túni lára jù lọ. Ó gba ẹ̀kọ́ ìwé tó jíire. (Ka Ìṣe 7:20-22.) Ó sì ṣeé ṣe kó wà nípò tó máa mú kó jogún ohun ìní rẹpẹtẹ.

13. Báwo ni Mósè ṣe pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlérí Ọlọ́run?

13 Ó ti ní láti jẹ́ pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí Mósè fún un ló ràn án lọ́wọ́ láti fi òye mọ̀ pé ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́ láti máa jọ́sìn ère bíi tàwọn ará Íjíbítì. (Ẹ́kís. 32:8) Ètò ẹ̀kọ́ àwọn ará Íjíbítì àti yaágbó-yaájù ọrọ̀ tó wà ní ààfin ọba kò mú kí Mósè pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Ó ti ní láti ronú jinlẹ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá rẹ̀ kó sì wù ú láti wà ní ìmúratán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó ṣe tán, Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà . . . Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù, ni ó rán mi sí yín.”—Ka Ẹ́kísódù 3:15-17.

14. Kí ló dán ìgbàgbọ́ àti ìgboyà Mósè wò?

14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ère tó ń ṣàpẹẹrẹ àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí àwọn ará Íjíbítì kò já mọ́ nǹkan kan lójú Mósè, ó mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wà ní tòótọ́. Ó gbé ìgbé ayé rẹ̀ bí ẹni tó ń rí “Ẹni tí a kò lè rí.” Mósè ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, ṣùgbọ́n kò mọ ìgbà tó máa jẹ́. (Héb. 11:24, 25, 27) Bó ṣe jẹ́ ẹ lógún pé kí Ọlọ́run dá àwọn Hébérù nídè yìí fara hàn nínú bó ṣe gbèjà ẹrú kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí ẹnì kan ń lù ú. (Ẹ́kís. 2:11, 12) Àmọ́, kò tíì tó àkókò tí Jèhófà fẹ́ kí Mósè ṣojú fún òun, torí náà ó ní láti lọ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá ní ilẹ̀ jíjìnnà réré. Kò sí iyè méjì pé ó ṣòro fún un láti fi àyíká tó ti ń gbádùn ara rẹ̀ ní ààfin ọba ilẹ̀ Íjíbítì sílẹ̀ láti lọ máa gbé nínú aginjù. Síbẹ̀, Mósè fi hàn pé òun wà ní ìmúratán torí pé ó máa ń wà lójúfò láti fi gbogbo ìtọ́ni tí Jèhófà bá fún un sílò. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run lè lò ó láti mú ìtura bá àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́yìn tó ti lo ogójì ọdún ní ilẹ̀ Mídíánì. Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè pé kó pa dà sí ilẹ̀ Íjíbítì, ó ṣègbọràn ó sì pa dà síbẹ̀. Àkókò ti tó wàyí fún Mósè láti jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an kó sì ṣe iṣẹ́ náà ní ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ kó gbà ṣe é. (Ẹ́kís. 3:2, 7, 8, 10) Ní ilẹ̀ Íjíbítì, Mósè tó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn,” nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà kó tó lè fara hàn níwájú Fáráò. (Núm. 12:3) Ó fara hàn níwájú Fáráò ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, torí pé léraléra ló ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Jèhófà fi ń mú ìyọnu wá sórí ilẹ̀ náà, kò sì mọ iye ìgbà tóun tún máa pààrà ọ̀dọ̀ Fáráò.

15. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdílọ́wọ́ díẹ̀ wà, kí ló mú kí Mósè ṣì wà lójúfò láti tẹ́wọ́ gba àwọn àǹfààní táá mú kó lè yin Baba rẹ̀ ọ̀run?

15 Láàárín ogójì [40] ọdún tó tẹ̀ lé e, láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Mósè dojú kọ ọ̀pọ̀ ìjákulẹ̀. Síbẹ̀, kò gbójú fo àwọn àǹfààní tó ní láti yin Jèhófà tọkàntọkàn, ó sì fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ní ìṣírí láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Diu. 31:1-8) Kí nìdí? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ju orúkọ tiẹ̀ lọ. (Ẹ́kís. 32:10-13; Núm. 14:11-16) Láìka ìjákulẹ̀ tàbí ìdílọ́wọ́ sí, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti kọ́wọ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan ló mọ́gbọ́n dání jù, ló tọ̀nà jù, tó sì san ju ọ̀nà èyíkéyìí mìíràn lọ. (Aísá. 55:8-11; Jer. 10:23) Ṣé ojú tí ìwọ náà fi ń wò ó nìyẹn?

Ẹ Wà Lójúfò!

16, 17. Kí nìdí tí Máàkù 13:35-37 fi ní ìtumọ̀ tó ṣe pàtàkì gan-an fún ẹ?

16 “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.” (Máàkù 13:33) Èyí ni ìkìlọ̀ tí Jésù fún wa nígbà tó ń jíròrò àmì tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà ní ìparí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù fi kádìí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pàtàkì tí Máàkù ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀, yálà nígbà tí alẹ́ ti lẹ́ tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru tàbí ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀; kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí ó bá dé lójijì, òun kò ní bá yín lójú oorun. Ṣùgbọ́n ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Máàkù 13:35-37.

17 Ọ̀rọ̀ tí ń múni ronú jinlẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù yìí. Ó mẹ́nu kan ìgbà ìṣọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní òru. Ó máa nira gan-an láti wà lójúfò nígbà ìṣọ́ tó kẹ́yìn, torí pé ó jẹ́ láti nǹkan bí aago mẹ́ta òru títí di àfẹ̀mọ́jú. Àwọn tó mọ̀ nípa ọgbọ́n ogun jíjà ka àkókò yìí sí ìgbà tó dára jù lọ láti gbéjà ko ọ̀tá, torí pé ìgbà yẹn ló máa ń rọrùn jù lọ láti ká wọn mọ́ ojú “oorun.” Bákan náà, ní báyìí tí aráyé ń sùn fọnfọn nípa tẹ̀mí, ó gba ìsapá gidigidi fún wa láti wà lójúfò. Ǹjẹ́ à ń ṣiyè méjì lọ́nà èyíkéyìí pé ó yẹ ká “wà lójúfò” ká sì “máa wọ̀nà” de òpin àti ìdáǹdè tá a sọ tẹ́lẹ̀ náà?

18. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ wo la ní?

18 Ọ̀gbẹ́ni tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí kò kú nígbà tí ẹkùn ilẹ̀ Bengal tó fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbéjà kò ó. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mú kó dájú gbangba pé kò sí èyíkéyìí nínú ẹ̀sìn èké tàbí gbogbo apá tó kù nínú ètò búburú yìí tó máa la òpin tó ń bọ̀ já. (Ìṣí. 18:4-8) Ǹjẹ́ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run, lọ́mọdé lágbà, rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká bàa lè wà ní ìmúratán de ọjọ́ Jèhófà bí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ti ṣe. Òótọ́ ni pé à ń gbé nínú ayé tí àwọn èèyàn kò ti fi ọ̀wọ̀ hàn fún Ọlọ́run, tí àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn èké, àwọn onígbàgbọ́ Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀ àti àwọn aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọ́run ti ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu wọn tàbùkù sí Ẹlẹ́dàá. Ṣùgbọ́n kò yẹ ká jẹ́ kí ìyẹn nípa lórí wa. Ẹ jẹ́ ká fi àwọn àpẹẹrẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò sọ́kàn, ká sì wà lójúfò kí àǹfààní èyíkéyìí láti gbèjà Jèhófà ká sì máa fi ìyìn fún un gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run àwọn ọlọ́run,” àní “Ọlọ́run títóbi, alágbára ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù,” má sì ṣe bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.—Diu. 10:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ti “ọgọ́fà ọdún” tí Bíbélì mẹ́nu kàn nínú Jẹ́nẹ́sísì 6:3, wo Ilé Ìṣọ́, December 15, 2010, ojú ìwé 30.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi yẹ kí Nóà fi àjọṣe ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́?

• Àwọn ọ̀nà pàtàkì wo ni àkókò wa gbà jọ ti ìgbà Nóà?

• Láìka ìjákulẹ̀ sí, kí ló mú kí Mósè pa ọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí àwọn ìlérí Jèhófà?

• Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo ló mú kó o máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Nóà àti ìdílé rẹ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn ìlérí Ọlọ́run tó dájú pé wọ́n máa nímùúṣẹ mú kí Mósè wà lójúfò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́