ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 4/1 ojú ìwé 23
  • Ìgbà Tí Àwọn Arúgbó Yóò Pa Dà Di Ọ̀dọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Tí Àwọn Arúgbó Yóò Pa Dà Di Ọ̀dọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ọkùnrin Àwòfiṣàpẹẹrẹ Kan Tó Tẹ́wọ́ Gba Ìbáwí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jèhófà Wò Ó Sàn
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 4/1 ojú ìwé 23

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ìgbà Tí Àwọn Arúgbó Yóò Pa Dà Di Ọ̀dọ́

TA NI nínú wa ló fẹ́ràn ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ síni lọ́jọ́ ogbó, ìyẹn ara tó ń hun jọ, ojú tó ń ṣe bàìbàì, etí tí kò gbọ́ràn dáadáa àti ẹsẹ̀ tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ? O lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa láti gbádùn okun ìgbà ọ̀dọ́, nígbà tó bá tún yá tí a ó máa bẹ̀rù ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ síni lọ́jọ́ ogbó?’ Ìròyìn ayọ̀ kan ni pé, kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún wa nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi fi ìfẹ́ ṣèlérí láti gbà wá lọ́wọ́ ọjọ́ ogbó! Kíyè sí ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n sọ fún Jóòbù ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà ayé ọjọ́un, ọ̀rọ̀ náà wà nínú ìwé Jóòbù 33:24, 25.

Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ tí Jèhófà fẹ́ràn. Jóòbù kò kúkú mọ̀ pé Sátánì bẹnu àtẹ́ lu ìṣòtítọ́ òun lọ́dọ̀ Ọlọ́run, pé ohun tí òun rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run ló mú kí òun máa jọ́sìn rẹ̀. Nítorí pé Jèhófà fọkàn tán Jóòbù, tí ó sì tún mọ̀ pé òun lágbára láti mú ibi kúrò, ó gba Sátánì láyè láti dán Jóòbù wò. Nítorí náà, Sátánì “fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.” (Jóòbù 2:7) Ìdin bo ara Jóòbù, awọ ara rẹ̀ ń séèépá, ara rẹ̀ dúdú, ó sì ń ṣí kúrò. (Jóòbù 7:5; 30:17, 30) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ìrora rẹ̀? Síbẹ̀, Jóòbù jẹ́ olóòótọ́, ó ní: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5.

Àmọ́ ṣá o, Jóòbù ṣe àṣìṣe kan tó lágbára gan-an. Nígbà tó rò pé òun kò ní pẹ́ kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara rẹ̀ láre ju bó ṣe yẹ lọ, ó “polongo ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.” (Jóòbù 32:2) Élíhù tó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run bá Jóòbù wí. Àmọ́, Élíhù tún sọ ìròyìn ayọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún Jóòbù, ó ní: “Gbà á [Jóòbù] sílẹ̀ lọ́wọ́ sísọ̀kalẹ̀ sínú kòtò [ipò òkú]! Mo ti rí ìràpadà! Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.” (Jóòbù 33:24, 25) Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fọkàn Jóòbù balẹ̀ pé ìrètí ń bẹ. Kò ní máa jìyà títí tó fi máa kú. Bí Jóòbù bá ronú pìwà dà, inú Ọlọ́run á dùn láti tẹ́wọ́ gba ìràpadà nítorí rẹ̀, á sì dá a sílẹ̀ nínú àwọn àjálù tó dé bá a.a

Jóòbù fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìbáwí, ó sì ronú pìwà dà. (Jóòbù 42:6) Ó hàn gbangba pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìràpadà nítorí Jóòbù, ó jẹ́ kó bo ẹ̀ṣẹ̀ Jóòbù mọ́lẹ̀, èyí sì mú kí Ọlọ́run mú nǹkan bọ̀ sípò fún Jóòbù, kí ó sì san án lẹ́san. Jèhófà “bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.” (Jóòbù 42:12-17) Yàtọ̀ sí àwọn ìbùkún míì tí Jóòbù rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, fojú inú wo bí àìsàn burúkú tó ń ṣe Jóòbù ṣe pòórá, tí ara rẹ̀ sì wá “jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe”!

Ìgbà díẹ̀ ni ìràpadà tí Ọlọ́run gbà nínú ọ̀ràn Jóòbù ṣiṣẹ́ dà, nítorí pé aláìpé ṣì ni Jóòbù, nígbà tó sì yá, ó kú. Àmọ́ àwa ní ìràpadà kan tó dára ju ìyẹn lọ fíìfíì. Jèhófà fi ìfẹ́ pèsè Jésù, Ọmọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún wa. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà yìí ló nírètí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Nínú ayé tuntun tó ń bọ̀ yẹn, Ọlọ́run á gba àwọn olóòótọ́ lọ́wọ́ ọjọ́ ogbó. O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè wà láàyè nígbà táwọn tó ti darúgbó á rí i tí ara wọ́n máa “jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe.”

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún April:

◼ Jóòbù 16-37

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Ìràpadà” tá a lò níbí túmọ̀ sí “bò mọ́lẹ̀.” (Jóòbù 33:24) Nínú ọ̀ràn Jóòbù, ó ṣeé ṣe ki ìràpadà náà jẹ́ ẹran tó fi rúbọ, èyí tí Ọlọ́run á tẹ́wọ́ gbà kó lè bo ẹ̀ṣẹ̀ Jóòbù mọ́lẹ̀ tàbí kó ṣètùtù fún un.—Jóòbù 1:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́