Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
Ọ̀MÙTÍ paraku ni bàbá Ian. Ìyà nǹkan kan kò jẹ Ian láti kékeré, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìfẹ́ bàbá sí ọmọ láàárín òun àti bàbá rẹ̀. Ian sọ pé: “Mi ò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn bàbá mi, pàápàá nítorí pé wọ́n ti máa ń mutí jù àti pé wọ́n máa ń fìyà jẹ màmá mi.” Bí Ian ṣe ń dàgbà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà. Ó ní: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, ‘Tí Ọlọ́run bá wà lóòótọ́, kí ló dé tó fi ń jẹ́ kí ìyà máa jẹ àwa èèyàn?’”
Kí ló ń jẹ́ káwọn èèyàn béèrè irú ìbéèrè yìí?
Béèyàn ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ níṣòro, ara èèyàn kì í gbà á tó bá rí i tí àwọn aláìṣẹ̀ ń jìyà. Àmọ́ tí o bá tún wá jẹ́ ẹni tójú rẹ̀ ti rí màbo bíi ti Ian tàbí ẹni tí èèyàn rẹ̀ ṣàìsàn tàbí ẹni tí èèyàn rẹ̀ kú, ó dájú pé wàá túbọ̀ fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí àwọn èèyàn máa jìyà.
Kí ni àwọn kan sọ nípa ìbéèrè yìí?
Àwọn kan gbà pé torí kí àwa èèyàn lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kí á sì jẹ́ olójú àánú ni Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. Àwọn míì sì gbà pé tí ẹnì kan bá ń jìyà, ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ wá sáyé ló ń jẹ.
Kí làwọn ìdáhùn yìí ń fi hàn?
Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé gbogbo bí aráyé ṣe ń jìyà kò kan Ọlọ́run, èyí ò sì jẹ́ kéèyàn lè fi gbogbo ọkàn fẹ́ràn rẹ̀. Àwọn ìdáhùn yìí tún ń sọ pé ìkà ni Ọlọ́run.
Kí ni Bíbélì fi kọ́ni?
Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe Ọlọ́run ló ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Ó ní: “Ki ẹnikẹni ti a danwo maṣe wi pe, ‘Lati ọwọ Ọlọrun ni a ti dán mi wò’; nitori a kò lè fi buburu dan Ọlọrun wò, oun naa ki i sì dán ẹnikẹni wò.” (Jákọ́bù 1:13, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kódà èrò tí àwọn èèyàn ní, pé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé, kò bá irú ẹni tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ mu rárá. Kí nìdí?
Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ìwà Ọlọ́run. (1 Jòhánù 4:8) Torí kí kókó yìí lè yé wa dáadáa, Bíbélì fi bí ọ̀rọ̀ wa ṣe ń rí lára Ọlọ́run wé ìfẹ́ tí abiyamọ máa ń ní sí ọmọ ọwọ́ rẹ̀. Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.” (Aísáyà 49:15) Ǹjẹ́ o rò pé abiyamọ onífẹ̀ẹ́ máa mọ̀ọ́mọ̀ ṣèkà sí ọmọ rẹ̀? Dípò kí òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa wá bí ọmọ rẹ̀ ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ìyà tó ń jẹ ẹ́. Bákàn náà, Ọlọ́run kì í fi ìyà jẹ àwọn aláìṣẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 18:25.
A gbà pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún o, ṣùgbọ́n ìyà ṣì ń jẹ àwọn aláìṣẹ̀ báyìí. O lè wá máa ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún tí kò sì sí ohun tí agbára rẹ̀ kò ká, kí ló dé tí kò fi kúkú mú gbogbo ohun tó ń fa ìjìyà kúrò pátápátá?’
Àwọn ìdí pàtàkì kan wà tí Ọlọ́run ṣì fi fàyè gba ìjìyà báyìí. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀kan lára rẹ̀: Àwọn èèyàn gan-an ló sábà máa ń fa ìyà tó ń jẹ àwọn ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fòòró ẹ̀mí àwọn míì àti àwọn tó ń fojú àwọn èèyàn gbolẹ̀ kò sì ṣe tán láti yí pa dà. Torí náà kí Ọlọ́run lè mú ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tó ń fa ìjìyà kúrò, ó máa pa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ run.
Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run kò fi tíì pa àwọn tó ń ṣe àìdáa run, ó ní: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Sùúrù tí Jèhófà Ọlọ́run ní yìí fi hàn pé ó jẹ́ aláàánú àti onífẹ̀ẹ́.
Ṣùgbọ́n láìpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run máa ṣe nǹkan kan sí ọ̀rọ̀ náà. Yóò “san ìpọ́njú pa dà fún àwọn tí ń pọ́n [ẹlòmíì] lójú.” Àwọn tó kàn ń fìyà jẹ ọmọnìkejì wọn yóò “fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.”—2 Tẹsalóníkà 1:6-9.
Ian tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí ìdáhùn tó tẹ́ ẹ lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ti ń béèrè nípa ìjìyà. Ẹ̀kọ́ tó wá rí kọ́ jẹ́ kó yí ojú tó fi ń wo ìgbésí ayé pa dà. Ka ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ lójú ìwé 13 nínú ìwé ìròyìn yìí.