KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Ǹjẹ́ O Sún Mọ́ Ọlọ́run?
“Téèyàn bá sún mọ́ Ọlọ́run, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀, ayé rẹ̀ á tòrò, á sì mọ̀ ọ́ lára pé Ọlọ́run fẹ́ òun fún ire.”—CHRISTOPHER, Ọ̀DỌ́KÙNRIN KAN TÓ Ń GBÉ NÍ GÁNÀ.
“Ọlọ́run rí ìdààmú ọkàn rẹ, á sì máa fìfẹ́ hàn sí ẹ ju bó o ṣe rò lọ.”—HÁNÀ, ỌMỌ ỌDÚN MẸ́TÀLÁ TÓ Ń GBÉ NÍ ALASKA, NÍLẸ̀ AMẸ́RÍKÀ.
“Kò sóhun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó sì ń dùn mọ́ni tó kéèyàn mọ̀ pé òun jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!”—GINA, OBÌNRIN ARÁ JÀMÁÍKÀ TÓ TI LÉ NÍ ẸNI OGÓJÌ ỌDÚN.
Christopher, Hánà àti Gina nìkan kọ́ ló ní irú èrò yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn, ó sì ka àwọn sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ṣé irú èrò tí ìwọ náà ní nìyẹn? Ṣé o gbà pé o sún mọ́ Ọlọ́run? Àbí wàá fẹ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? Ó ṣeé ṣe kó o máa rò ó pé: ‘Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún èèyàn lásánlàsàn bíi tèmi láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lèèyàn ṣe lè ṣe é?’
ÈÈYÀN LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Bíbélì fi dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ábúráhámù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí Ọlọ́run pè ní “ọ̀rẹ́ mi.” (Aísáyà 41:8) Ọlọ́run wá nawọ́ ìkésíni sí àwa náà nínú ìwé Jákọ́bù 4:8 pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Gbogbo èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ìrísí Ọlọ́run ò dàbí tàwa èèyàn torí ẹni àìrí ni. Báwo wá la ṣe lè “sún mọ́” Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀?
Ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká ronú nípa bí ẹni méjì ṣe máa ń di ọ̀rẹ́. Wọ́n á kọ́kọ́ mọ orúkọ ara wọn, wọ́n á sí máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Bí ọ̀rọ̀ wọn bá ṣe ń wọ̀, tí wọ́n sì tún ń ṣe aájò ara wọn, ni okùn ọ̀rẹ́ wọn á túbọ̀ máa lágbára, wọ́n á wá di kòríkòsùn. Bó ṣe máa ń rí náà nìyẹn tá a bá fẹ́ bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe lè rí bẹ́ẹ̀.