ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 2/1 ojú ìwé 7-9
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣàyẹ̀wò Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣàyẹ̀wò Bíbélì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN ÌTÀN INÚ BÍBÉLÌ JÓÒÓTỌ́ DÉLẸ̀DÉLẸ̀
  • BÍBÉLÌ JẸ́ ÌWÉ ÀTIJỌ́ TÓ ṢÌ WÚLÒ LÓDE ÒNÍ
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Káwọn Ojúgbà Mi Má Bàa Ba Ìwà Mi Jẹ́?
    Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
  • “Mú Ipa Ọ̀nà Ẹsẹ̀ Rẹ Jọ̀lọ̀” Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Áńgẹ́lì Jèhófà Dó Yí Àwọn Tí ó Bẹ̀rù Rẹ̀ Ká”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ǹjẹ́ Òtítọ́ Ń So Èso Nínú Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 2/1 ojú ìwé 7-9
Ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Àbáyọ̀mí ń bá ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Kúnlé sọ̀rọ̀

ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣàyẹ̀wò Bíbélì?

Ìjíròrò tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Àbáyọ̀mí pàdé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Kúnlé.

ÀWỌN ÌTÀN INÚ BÍBÉLÌ JÓÒÓTỌ́ DÉLẸ̀DÉLẸ̀

Kúnlé: Mi ò rò pé a ní ọ̀rọ̀ púpọ̀ tá a lè jọ sọ torí pé mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.

Àbáyọ̀mí: Kò burú tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ nìyẹn. Àbáyọ̀mí lorúkọ mi, ìwọ ńkọ́?

Kúnlé: Kúnlé.

Àbáyọ̀mí: Inú mi dùn láti pàdé ẹ lónìí, Kúnlé, ṣé àlàáfíà ni?

Kúnlé: A dúpẹ́.

Àbáyọ̀mí: Má bínú o, mo kàn fẹ́ bi ẹ́ pé ṣé o fẹ́ràn ìsìn tẹ́lẹ̀?

Kúnlé: Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ àtìgbà tí mo ti wọ yunifásítì ni mi ò ti ráyè ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn mọ́.

Àbáyọ̀mí: Un ùn. Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ ni yunifásítì?

Kúnlé: Ẹ̀kọ́ nípa àjọṣe ẹ̀dá, ìyẹn social studies àti ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ni mo ṣe. Mo nífẹ̀ẹ́ si ìtàn gan-an torí pé ó sọ nípa ìrìn-àjò ẹ̀dá láyé.

Àbáyọ̀mí: Òótọ́ lo sọ, ìtàn máa ń dùn lóòótọ́. Àmọ́, o jẹ́ mọ̀ pé Bíbélì jẹ́ ìwé ìtàn tí o sọ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.

Kúnlé: Ẹ̀n-ẹ́n. Mo mọ̀ pé ìwé tó dáa ni Bíbélì, àmọ́ mi ò mọ̀ pé ìwé ìtàn ni.

Àbáyọ̀mí: Inú mi dùn pé o máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ. Jọ̀ọ́ fún mi ní ìṣẹ́jú díẹ̀ kí n fi méjì nínú àwọn ìtàn tó jóòótọ́ tá a lè rí nínú Bíbélì hàn ẹ́.

Kúnlé: Ó dáa. Àmọ́ mi ò ní Bíbélì o.

Àbáyọ̀mí: Kò burú, màá fi hàn ẹ́ nínú tọwọ́ mi. Àkọ́kọ́ wà nínú ìwé 1 Kíróníkà orí 29, ẹsẹ 26 àti 27. Ó kà pé: “Ní ti Dáfídì ọmọkùnrin Jésè, ó jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì; àwọn ọjọ́ tí ó sì fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì ọdún. Ní Hébúrónì, ó jọba fún ọdún méje, ní Jerúsálẹ́mù, ó jọba fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.”

Kúnlé: Báwo wá nìyẹn ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ ìtàn tó jóòótọ́?

Àbáyọ̀mí: Nígbà kan rí, àwọn alárìíwísí sọ pé kò sẹ́ni tó ń jẹ́ Dáfídì Ọba nínú ìtàn.

Kúnlé: Á-à-á, kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀?

Òkúta àtijọ́ kan tí wọ́n kọ “Ilé Dáfídì” sí lára

Àbáyọ̀mí: Ìdí ni pé, wọn ò rí ẹ̀rí mìíràn yàtọ̀ sí Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Dáfídì Ọba. Àmọ́ ní ọdún 1993, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí òkúta kan tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́, tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan sí lára tó túmọ̀ sí “Ilé Dáfídì.”

Kúnlé: Ẹ̀n ẹ́n, ó ga o.

Àbáyọ̀mí: Ẹlòmíì tí wọ́n tún ṣàríwísí rẹ̀ ni Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà nígbà ayé rẹ̀. Bíbélì mẹ́nu kàn án nínú ìwé Lúùkù orí 3, ẹsẹ 1. Ǹjẹ́ o rí orúkọ rẹ̀ níbẹ̀?

Kúnlé: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: “Nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì.”

Òkúta àtijọ́ kan tí wọ́n kọ orúkọ Pọ́ńtíù Pílátù sí

Àbáyọ̀mí: O ṣeun. Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ọ̀mọ̀wé fi ṣe lámèyítọ́ nípa bóyá ẹni tó ń jẹ Pọ́ńtíù Pílátù wà lóòótọ́. Àmọ́, ní nǹkan bí àádọ́ta [50] ọdún sẹ́yìn, wọ́n ṣàwárí òkúta kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn tí wọ́n kọ orúkọ Pọ́ńtíù Pílátù sí lára gàdàgbà.

Kúnlé: Ó ga o. Mi ò tiẹ̀ bá àwọn nǹkan yìí pàdé rí.

Àbáyọ̀mí: Inú mi dùn pé mo láǹfààní láti sọ ọ́ fún ẹ.

Kúnlé: Kí n sòótọ́ kan fún ẹ, mo mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì dùn-ún kà, àmọ́ mi ò rò pé ó wúlò fún wa mọ́. Bíbélì lè sọ nípa àwọn ìtàn tó jóòótọ́ o, àmọ́ mi ò rò pé ẹ̀kọ́ kankan wà tá a lè rí kọ́ nínú rẹ̀ lónìí.

BÍBÉLÌ JẸ́ ÌWÉ ÀTIJỌ́ TÓ ṢÌ WÚLÒ LÓDE ÒNÍ

Àbáyọ̀mí: Ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló rò pé Bíbélì ò wúlò mọ́ lónìí. Àmọ́ èmi ṣì gbà pé ó wúlò. Ìdí ni pé, àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì náà ló ṣe pàtàkì sí wa lónìí. Bí àpẹẹrẹ, látayébáyé ni àwa èèyàn ti nílò oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. Bákan náà, ó máa ń wu àwa èèyàn láti ní ọ̀rẹ́ tá a lè máa bá sọ̀rọ̀ ká sì ní ìdílé aláyọ̀. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Kúnlé: Bẹ́ẹ̀ ni.

Àbáyọ̀mí: O jẹ́ mọ̀ pé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ lórí àwọn kókó yìí. Ńṣe ló dà bí ìwé àtijọ́ kan tó ṣì wúlò lóde òní.

Kúnlé: Kí lo ní lọ́kàn?

Àbáyọ̀mí: Ohun tí mo ní lọ́kàn ni pé, Bíbélì ní àwọn ìlànà tó wúlò lónìí gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wúlò láyé ìgbà tí wọ́n kọ ọ́.

Bíbélì ní àwọn ìlànà tó wúlò lónìí gan-an gẹ́gẹ́ bó ṣe wúlò láyé ìgbà tí wọ́n kọ ọ́

Kúnlé: Ó dáa, láwọn apá ibo ló ti wúlò?

Àbáyọ̀mí: Àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ tó bá kan ọ̀rọ̀ owó tàbí bí ìdílé ṣe lè láyọ̀ tàbí béèyàn ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi. Ńṣe ló máa ń tọ́ni sọ́nà kéèyàn lè ṣàṣeyọrí. Jẹ́ n bi ẹ́ ní ìbéèrè kan, láyé tá a wà yìí, ṣé ó rọrùn kéèyàn jẹ́ ọkọ rere àti baálé ilé tó dáńgájíá?

Kúnlé: Áà, kò rọrùn o. Ó ti tọ́dún kan témi náà ti ṣègbéyàwó, mo sì lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn fún tọkọtaya láti fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀.

Àbáyọ̀mí: Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ lo sọ yẹn. Síbẹ̀, Bíbélì fún wa láwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, wo ìlànà tó wà nínú ìwé Éfésù orí 5 ẹsẹ 22, 23 àti 28. Jọ̀ọ́ bá mi kà á.

Kúnlé: Kò burú, ó kà pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ, bí òun ti jẹ́ olùgbàlà ara yìí.” Ẹsẹ 28 kà pé: “Lọ́nà yìí, ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.”

Àbáyọ̀mí: O ṣeun. Bí tọkọtìyàwó bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ǹjẹ́ ìdílé wọn ò ní láyọ̀?

Kúnlé: Ayọ̀ á wà lóòótọ́. Àmọ́, ó dùn ún sọ, ṣùgbọ́n kò rọrùn ṣe.

Àbáyọ̀mí: Òótọ́ lo sọ torí kò sí adára-má-kù-síbì-kan. Ẹsẹ Bíbélì míì tiẹ̀ gbà wá nímọ̀ràn pé ká jẹ́ ẹni tó ń fòye báni lò.a Kí àjọgbé ẹni méjì tó lè wọ̀, àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa gbà fún ara wọn. Bíbélì ti ran èmi àtìyàwó mi lọ́wọ́ lórí kókó yìí.

Kúnlé: O ríyẹn sọ ṣá.

Àbáyọ̀mí: Ṣó o rí i, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìkànnì kan tó o ti lè rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ìdílé. Jẹ́ kí n kàn fi díẹ̀ nínú ohun tó wà nínú rẹ̀ hàn ẹ́.

Kúnlé: Ó dáa. Àmọ́, ẹ má jẹ́ kó pẹ́ o.

Àbáyọ̀mí: Kò burú. Àdírẹ́sì ìkànnì yẹn ni www.jw.org/yo. Wo bí ojúde ìkànnì yẹn ṣe rí.

Ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Àbáyọ̀mí ń fi ìkànnì jw.org han ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Kúnlé

Kúnlé: Àwọn àwòrán yìí mà fani mọ́ra o.

Àbáyọ̀mí: Àwòrán bá a ṣe ń wàásù kárí ayé nìyẹn. Ibi à ń lọ lá dé yìí. Lábẹ́ akọ́lé tá a pè ní “Ìrànlọ́wọ́ fún Tọkọtaya àti Àwọn Òbí,” wà á rí àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí onírúurú ohun tó lè dé bá ìdílé kan. Èwo ló wù ẹ́ láti kà nínú gbogbo rẹ̀?

Kúnlé: Eléyìí tó sọ pé, “Bá A Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Tó Bá Jẹ Yọ.” Mo fẹ́ mọ bí mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀!

Àbáyọ̀mí: Àpilẹ̀kọ yìí sọ ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà yanjú ìṣòro nínú ìdílé. Jọ̀ọ́ bá mi ka ìpínrọ̀ yìí.

Kúnlé: Ó kà pé: “Tí tọkọtaya bá jẹ́ ara kan lóòótọ́, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ló dà bí ẹ̀jẹ̀ tí ara nílò. Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ló sì dà bí ọkàn àti ẹ̀dọ̀ tí ẹ̀jẹ̀ máa ń ṣàn gba inú wọn. Torí náà, ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ṣe pàtàkì láti lè jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó mọ́yán lórí wà nínú ìdílé.” Un-ùn, mo gbádùn àlàyé tó wà níbí.

Àbáyọ̀mí: O ṣeun bó o ṣe ka ibẹ̀ yẹn. Ẹsẹ Bíbélì kan wà níbi tó o kà yẹn, tẹ̀ ẹ́ kó o lè ka ohun tó wà níbẹ̀.

Kúnlé: Mo ti ri. Éfésù 5:33. Ó kà pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”

Àbáyọ̀mí: Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yẹn tẹnu mọ́ kí ẹni kọ̀ọ̀kan máa fún ẹni kejì ni ohun tó fẹ́?

Kúnlé: Bíi ti báwo?

Àbáyọ̀mí: Ṣó o mọ̀ pé àwa ọkùnrin máa ń fẹ́ káwọn ìyàwó wa bọ̀wọ̀ fún wa. Bákan náà làwọn obìnrin ṣe máa ń fẹ́ káwa ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Kúnlé: Òótọ́ lo sọ.

Àbáyọ̀mí: Bí ọkọ bá ń fìfẹ́ hàn sí ìyàwó rẹ̀, ǹjẹ́ inú ìyàwó yẹn ò ní dùn láti máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀?

Kúnlé: Inú rẹ̀ á dùn. Ún-ùn ìmọ̀ràn yìí gbéṣẹ́ lóòótọ́.

Àbáyọ̀mí: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ ẹsẹ Bíbélì tá a kà yìí láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn, ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀ wúlò fún àwọn tọkọtaya torí pé tí wọ́n bá tẹ̀ lé e, ìdílé wọn á túbọ̀ láyọ̀. Bí àpèjúwe inú ìpínrọ̀ tá a kà lẹ́ẹ̀kan, ìmọ̀ràn Bíbélì máa mú kí “ọkàn àti ẹ̀dọ̀” inú ìgbéyàwó kan ṣiṣẹ́ dáadáa.

Kúnlé: Ó ga o, mi ò mọ̀ pé ẹ̀kọ́ kún inú Bíbélì báyìí!

Àbáyọ̀mí: Inú mi dùn láti gbọ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́nu ẹ, Kúnlé. Ó wù mí kí èmi àti ẹ tún wáyè sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ míì lórí àkòrí kan tó sọ pé “Ìgbésẹ̀ Mẹ́rin Tẹ́ Ẹ Lè Gbé Láti Yanjú Ìṣòro,” èyí tó wà lábẹ́ àkòrí tá a jọ kà lórí Ìkànnì wa.b

Kúnlé: Ó dáa. Èmi àti ìyàwó mi la jọ máa kà á.

Ṣé àwọn ẹ̀kọ Bíbélì kan máa ń ṣe ìwọ náà ní kàyéfì? Ǹjẹ́ ó fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ àti bí ìjọsìn wa ṣe rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́tìkọ̀ láti bi ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa rẹ̀. Inú onítọ̀hùn á dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.

a Wo Éfésù 5:17.

b Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo orí 14 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́