ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 11/1 ojú ìwé 3
  • Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogun
    Jí!—2017
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lẹ́yìn Tí Jésù Wá Sáyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Láyé Ìgbàanì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 11/1 ojú ìwé 3
Àwọn ọmọ ogun, ọkọ àwọn ológun, ọkọ òfuurufú tó ń ju bọ́ǹbù

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?

Tí wọ́n bá bi ẹ́ ní ìbéèrè yìí, kí ni wàá sọ? Ọ̀pọ̀ ronú pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun. Wọ́n sọ pé nínú Bíbélì, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ nígbà àtijọ́ pé kí wọ́n jagun. Àmọ́ àwọn míì sọ pé Jésù Ọmọ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Mátíù 5:​43, 44) Torí náà, wọ́n gbà pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun láyé àtijọ́, àmọ́ kò fẹ́ ká máa jagun mọ́ báyìí.

Kí lèrò tìẹ? Ṣé Ọlọ́run fẹ́ ká máa jagun? Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn wo ni Ọlọ́run máa ń tì lẹ́yìn nígbà ogun? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o ní èrò tó tọ̀nà nípa ogun. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá mọ̀ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun àti pé ẹ̀yìn àwọn tó o fẹ́ kó ṣẹ́gun ni Ọlọ́run wà, ọkàn rẹ máa balẹ̀ pé ẹ̀yin lẹ máa ṣẹ́gun. Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó bá jẹ́ pé ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá yín ni Ọlọ́run wà? Ó dájú pé ọ̀kan rẹ kò ní balẹ̀.

Ohun míì wà tó tún ṣe pàtàkì ju èyí lọ. Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ogun lè pinnu èrò tó o máa ní nípa Ọlọ́run. Tó o bá wà lára ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tí ogun ti fa àdánù ńlá fún, ó máa dáa kó o mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bíi: Ṣé arógunyọ̀ ni Ọlọ́run bí àwọn kan ṣe sọ? Ṣé inú rẹ̀ máa ń dùn sí ìyà tí ogun ń fà fún àwọn èèyàn? Ṣé ọ̀rọ̀ àwọn tí ogun ń hàn léèmọ̀ kò dun Ọlọ́run ni?

Ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò. Láfikún sí i, èrò Ọlọ́run nípa ogun láyé àtijọ́ kò tíì yí pa dà di báyìí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ lórí èrò Ọlọ́run nípa ogun láyé ìgbàanì àti lẹ́yìn tí Jésù wá sáyé. Ìyẹn máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá Ọlọ́run fẹ́ ká máa jagun lóde òní àti bóyá àwọn èèyàn á ṣì máa jagun lọ́jọ́ iwájú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́