Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ?
Ṣé o máa ń ronú nípa bí ọjọ́ ọ̀la ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe máa rí? Bíbélì sọ pé:
“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí máa jẹ́ kó o mọ àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé àti àwa èèyàn, á tún jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe láti jàǹfààní nínú rẹ̀.