Irú Ẹni Wo Ni Ọlọ́run?
Bá a bá ṣe ń mọ ìwà ẹnì kan sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa mọ ẹni náà, tí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ á sì máa dáa sí i. Lọ́nà kan náà, bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa mọ irú ẹni tó jẹ́, tí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ á sì máa dáa sí i. Nínú gbogbo àwọn ìwà àti ìṣe Ọlọ́run, mẹ́rin ló ta yọ, àwọn ni agbára, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́.
ỌLỌ́RUN LÁGBÁRA
“Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó! Agbára ńlácrẹ . . . lo fi dá ọ̀run àti ayé.” —JEREMÁYÀ 32:17.
Ọ̀pọ̀ nǹkan là ń rí nínú ìṣẹ̀dá tó jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run lágbára. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jáde síta nígbà tí oòrùn bá ràn, báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ? Ó dájú pé ńṣe ni oòrùn yẹn á máa rà ẹ́ lára. Ṣùgbọ́n tá a bá fẹ́ sọ bó ṣe jẹ́ ní pàtó, ẹ̀rí agbára Ọlọ́run lò ń rí lára ẹ yẹn. Báwo tiẹ̀ ni agbára oòrùn ṣe pọ̀ tó? Ìwádìí fi hàn pé inú oòrùn lọ́hùn-ún máa ń gbóná tó ìpele mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000,000) lórí òṣùwọ̀n Celsius. Ní ìṣẹ́jú àáyá kan, iná tó ń bù yẹ̀rì jáde látara oòrùn dà bí ìgbà tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù bọ́ǹbù runlérùnnà bá bú gbàù lẹ́ẹ̀kan náà!
Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kékeré ni oòrùn jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àìmọye mílíọ̀nù ìràwọ̀ míì tó kún inú ọ̀run lọ́hùn-ún. Ọ̀kan lára irú àwọn ìràwọ̀ bẹ́ẹ̀ lèyí tí wọ́n ń pè ní UY Scuti. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ìràwọ̀ yìí tóbi ju oòrùn lọ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ìgbà. Ìràwọ̀ UY Scuti tóbi débi pé ká sọ pé òun ló wà níbi tí oòrùn wà, ó máa gba gbogbo ayé yìí, á tiẹ̀ tún débi tí pílánẹ́ẹ̀tì Jupiter wà. Ó ṣeé ṣe kéyìí jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí wòlíì Jeremáyà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra ẹ̀ ló fi agbára ńlá ẹ̀ dá ọ̀run àtayé.
Báwo la ṣe ń jàǹfààní agbára Ọlọ́run? Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ló ń gbẹ́mìí wa ró. Lára wọn ni oòrùn àtàwọn ohun iyebíye míì tí Ọlọ́run dá sáyé. Ọlọ́run tún máa ń lo agbára ẹ̀ láti ṣe wá lóore lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Lọ́nà wo? Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó kàmàmà. Bíbélì sọ pé: “Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí, àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde.” (Mátíù 11:5) Lónìí ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ó ń fún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára,” ó tún sọ pé “àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà.” (Àìsáyà 40:29, 31) Ìyẹn ni pé Ọlọ́run lè fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ká lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ká sì lè fara dà á. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, tó sì ṣe tán láti fi agbára ẹ̀ tí kò láfiwé ràn ẹ́ lọ́wọ́.
ỌLỌ́GBỌ́N NI ỌLỌ́RUN
“Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe.”—SÁÀMÙ 104:24.
Bá a bá ṣe ń mọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, bẹ́ẹ̀ lẹnu á máa yà wá, tàá sì rí i pé ọgbọ́n Ọlọ́run ò láfiwé. Kódà, ẹ̀ka ìwádìí kan wà tí wọ́n ń pè ní biomimetics tàbí biomimicry. Nínú ẹ̀ka yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, wọ́n á sì lo ọgbọ́n tí wọ́n kọ́ lára wọn láti mú káwọn nǹkan tí wọ́n ṣe dáa sí i. Àwọn nǹkan yìí bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ohun èlò kéékèèké dórí àwọn nǹkan ńlá bí ọkọ̀ òfúrufú.
Ohun àgbàyanu gbáà ni ojú àwa èèyàn jẹ́ nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá
Ọ̀kan lára ibi tá a ti lè rí ọgbọ́n Ọlọ́run lọ́nà tó kàmàmà ni ara àwa èèyàn. Àpẹẹrẹ kan ni báwọn sẹ́ẹ̀lì kéékèèké ṣe máa ń di ọmọ inú oyún. Sẹ́ẹ̀lì kan ṣoṣo ló máa ń di ọmọ, á sì ní gbogbo ìsọfúnni tó máa wà nínú àpilẹ̀ àbùdá ọmọ náà. Sẹ́ẹ̀lì yìí á wá bẹ̀rẹ̀ sí í pín ara ẹ̀, á sì di ọ̀pọ̀ sẹ́ẹ̀lì míì tó jọra wọn. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn sẹ́ẹ̀lì náà á máa di oríṣiríṣi sẹ́ẹ̀lì tó yàtọ̀ síra, àwọn kan á di sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀jẹ̀, àwọn míì á di sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ àti sẹ́ẹ̀lì inú egungun. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí á para pọ̀ di ẹ̀yà ara, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́. Láàárín oṣù mẹ́sàn-án, sẹ́ẹ̀lì kékeré ọjọ́sí á ti di ọmọ làǹtì-lanti. Ẹ ò rí i bí èyí ṣe gbé ọgbọ́n Ọlọ́run yọ lọ́nà àrà. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé òótọ́ lohun tí òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Mo yìn ọ́ nítorí pé lọ́nà tó ń bani lẹ́rù ni o ṣẹ̀dá mi tìyanutìyanu.”—Sáàmù 139:14.
Báwo la ṣe ń jàǹfààní ọgbọ́n Ọlọ́run? Ẹlẹ́dàá wa mọ àwọn nǹkan tá a nílò ká lè láyọ̀. Ìmọ̀ àti òye rẹ̀ kò lópin, torí náà ó máa ń fún wa nímọ̀ràn ọgbọ́n látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó rọ̀ wá pé: “Ẹ máa . . . dárí ji ara yín fàlàlà.” (Kólósè 3:13) Ṣé ìmọ̀ràn yẹn bọ́gbọ́n mu? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìwádìí fi hàn pé téèyàn bá ń dárí jini, èèyàn á máa rórun sùn dáadáa, ó sì máa ń dín ẹ̀jẹ̀ ríru kù. Bákan náà, ó tún máa ń dín ìdààmú ọkàn àtàwọn àìsàn míì kù. Ọlọ́run dà bí ọ̀rẹ́ kan tó máa ń fúnni nímọ̀ràn ọgbọ́n nígbà gbogbo. (2 Tímótì 3:16, 17) Ṣó kò wù ẹ́ kó o nírú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀?
ỌLỌ́RUN JẸ́ ONÍDÀÁJỌ́ ÒDODO
“Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.”—SÁÀMÙ 37:28.
Gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó tọ́. Kódà, Bíbélì sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!” (Jóòbù 34:10) Àwọn ìdájọ́ Jèhófà tọ́, ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà fi sọ nípa Jèhófà pé: “Wàá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó tọ́.” (Sáàmù 67:4) Torí pé “Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn,” kò sẹ́ni tó lè tàn án jẹ. Ó lágbára láti mọ ohun tó jóòótọ́, kó sì ṣe ìdájọ́ tó yẹ. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bákan náà, Ọlọ́run ń rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú ayé, ó sì ṣèlérí pé láìpẹ́, òun máa pa àwọn ẹni burúkú run.—Òwe 2:22.
Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ò dà bí adájọ́ burúkú tí kò mọ̀ ju kó kàn máa fìyà jẹni. Ọlọ́run máa ń fàánú hàn sí wa nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Aláàánú ni Jèhófà, ó sì ń gba tẹni rò.” Kódà tí ẹni burúkú bá ronú pìwà dà, ó máa rí àánú Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ìyẹn kì í ṣe ìdájọ́ òdodo?—Sáàmù 103:8; 2 Pétérù 3:9.
Báwo ni ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣe ń ṣe wá láǹfààní ? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ìṣe 10:34, 35) À ń jàǹfààní ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run torí pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. A lè di ọ̀rẹ́ ẹ̀ láìka ẹ̀yà tá a ti wá, orílẹ̀-èdè tá a ti wá, bá a ṣe kàwé tó tàbí ipò wa láwùjọ.
Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àwa náà sì ń jàǹfààní ìyẹn láìka ẹ̀yà wa tàbí ipò wa láwùjọ sí
Torí pé Ọlọ́run fẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìdájọ́ òdodo ẹ̀, ó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ẹ̀rí ọkàn. Ìwé Mímọ́ sọ pé ẹ̀rí ọkàn dà bí òfin tá a ‘kọ sínú ọkàn wa,’ tó máa ‘jẹ́ wa lẹ́rìí’ bóyá ohun tá a ṣe dáa àbí ó burú. (Róòmù 2:15) Báwo lèyí ṣe ń ṣe wá láǹfààní? Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, ó lè kìlọ̀ fún wa ká má bàa ṣe ohun tó léwu tàbí ohun tí kò bófin mu. Tá a bá ṣàṣìṣe, ó lè mú ká ronú pìwà dà ká sì ṣe ohun tó tọ́. Bá a bá ṣe túbọ̀ ń lóye ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn!
ỌLỌ́RUN JẸ́ ÌFẸ́
“Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 JÒHÁNÙ 4:8.
Ọlọ́run máa ń lo agbára, ọgbọ́n àti ìdájọ́ òdodo. Àmọ́, Bíbélì ò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ agbára, ọgbọ́n tàbí ìdájọ́ òdodo. Ohun tó sọ ni pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọlọ́run lè lo agbára rẹ̀ láti ṣe ohun tó bá fẹ́, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n rẹ̀ ló sì ń darí àwọn nǹkan tó ń ṣe. Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ló ń mú kó ṣe nǹkan. Ìfẹ́ máa ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tí Jèhófà ò ní, ìfẹ́ ló mú kó dá àwa èèyàn sáyé, tó tún dá àwọn áńgẹ́lì sọ́run, tí gbogbo wa sì ń gbádùn ìfẹ́ àti ìkẹ́ rẹ̀ títí dòní. Ó dá ayé lọ́nà tó tura fáwa èèyàn láti gbé. Ó sì ń bá a lọ láti máa fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn ní ti pé “ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”—Mátíù 5:45.
Yàtọ̀ síyẹn, “Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jémíìsì 5:11) Ó máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó bá ń wá a tọkàntọkàn kí wọ́n lè sún mọ́ ọn. Ọlọ́run mọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Kódà, Bíbélì sọ pé “ó ń bójú tó [ẹ].”—1 Pétérù 5:7.
Báwo la ṣe ń jàǹfààní ìfẹ́ Ọlọ́run? A máa ń gbádùn bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rẹwà nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀, a máa ń láyọ̀ bá a ṣe ń wojú ọmọ jòjòló tó ń rẹ́rìn-ín, a sì máa ń mọyì ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó máa ń wà nínú ìdílé. Àwọn nǹkan yìí lè má pọn dandan ká tó lè wà láàyè, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń mú ká túbọ̀ gbádùn ayé wa.
Ọ̀nà míì tá a tún ń gbà jàǹfààní ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé a lè gbàdúrà sí i. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.” Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó fẹ́ ká máa béèrè ohunkóhun tá a bá fẹ́ lọ́wọ́ òun. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó ṣèlérí pé òun máa fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.”—Fílípì 4:6, 7.
Ṣé àwọn nǹkan tá a ti sọ nípa agbára Ọlọ́run, ọgbọ́n rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ ti wá jẹ́ kó o mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́? Kó o lè túbọ̀ mọyì Ọlọ́run, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kà nípa àwọn nǹkan tó ti gbé ṣe àtàwọn ohun tó ṣì máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú.
IRÚ ẸNI WO NI ỌLỌ́RUN? Jèhófà lágbára ju gbogbo alágbára lọ, òun ló gbọ́n jù lọ, ó sì tún jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Àmọ́, ohun tó fà wá mọ́ra jù nípa ẹ̀ ni pé ó jẹ́ ìfẹ́