ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w19 August ojú ìwé 26-28
  • Ìgbàgbọ́—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbàgbọ́—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NI ÌGBÀGBỌ́?
  • A GBỌ́DỌ̀ MỌYÌ ÒTÍTỌ́ KÁ TÓ LÈ NÍ ÌGBÀGBỌ́
  • OHUN TÓ MÚ KÍ DÁFÍDÌ NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ LÁGBÁRA
  • OHUN TÁÁ MÚ KÍ ÌGBÀGBỌ́ RẸ LÁGBÁRA
  • Ẹ NÍ ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ JÉSÙ
  • “Ẹ MÁA FÚN ARA YÍN LÓKUN LÁTINÚ ÌGBÀGBỌ́ MÍMỌ́ JÙ LỌ TÍ Ẹ NÍ”
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Lo Igbagbọ Ti A Gbekari Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣé Lóòótọ́ Lo Nígbàgbọ́ Nínú Ìhìn Rere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
w19 August ojú ìwé 26-28

Ìgbàgbọ́​—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára

  • ÌFẸ́

  • AYỌ̀

  • ÀLÀÁFÍÀ

  • SÙÚRÙ

  • INÚ RERE

  • ÌWÀ RERE

  • ÌGBÀGBỌ́

  • ÌWÀ TÚTÙ

  • ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU

ÌGBÀGBỌ́ máa ń jẹ́ ká lágbára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì ń wọ́nà bó ṣe máa pa wá nípa tẹ̀mí, àmọ́ ìgbàgbọ́ ń jẹ́ ká “lè paná gbogbo ọfà oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfé. 6:16) Tá a bá ní ìgbàgbọ́, àá lè borí àwọn ìṣòro tó dà bí òkè. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ.” (Mát. 17:20) Torí pé ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ kéèyàn di alágbára nípa tẹ̀mí, á dáa ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí: Kí ni ìgbàgbọ́? Báwo lohun tó wà lọ́kàn wa ṣe lè ní ipa lórí ìgbàgbọ́ wa? Báwo la ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára? Ta ló yẹ ká nígbàgbọ́ nínú rẹ̀?—Róòmù 4:3.

KÍ NI ÌGBÀGBỌ́?

Kéèyàn ní ìgbàgbọ́ kọjá ká kàn gbà pé òótọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì. Ó ṣe tán, “àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà [pé Ọlọ́run wà], jìnnìjìnnì sì bò wọ́n.” (Jém. 2:19) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ni ìgbàgbọ́?

Bí ayé ṣe rí téèyàn bá wò ó láti ojú ọ̀run

Bó ṣe dá wa lójú pé ojoojúmọ́ ni ilẹ̀ á máa ṣú táá sì máa mọ́, ó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ

Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé apá méjì ni ìgbàgbọ́ pín sí. Àkọ́kọ́, “ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí.” (Héb. 11:1a) Tó o bá ní ìgbàgbọ́, ó máa dá ẹ lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé ni gbogbo ohun tí Jèhófà sọ, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò sì ní lọ láìṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Bí ẹ bá lè ba májẹ̀mú mi nípa ọ̀sán àti májẹ̀mú mi nípa òru jẹ́, pé kí ọ̀sán àti òru má ṣe wà ní àkókò wọn nìkan ni májẹ̀mú tí mo bá Dáfídì ìránṣẹ́ mi dá tó lè bà jẹ́.” (Jer. 33:20, 21) Ṣé o ti ronú ẹ̀ rí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí oòrùn ò ní yọ mọ́, tó fi jẹ́ pé kò ní sí ọ̀sán àti òru mọ́? Rárá o, torí pé ojoojúmọ́ ni ilẹ̀ ń ṣú tí ilẹ̀ sì ń mọ́. Tó bá dá wa lójú pé bẹ́ẹ̀ lá máa rí lọ, ṣé kò wá yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run tó dá àwọn nǹkan yẹn máa mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ?—Àìsá. 55:10, 11; Mát. 5:18.

Ìkejì, ìgbàgbọ́ ni “ẹ̀rí tó dájú nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí.” Bíbélì sọ pé ìgbàgbọ́ ni “ẹ̀rí tó dájú” tàbí “ẹ̀rí tó ṣe kedere” nípa àwọn nǹkan tó wà lóòótọ́ bá ò tiẹ̀ rí wọn. (Héb. 11:1b; àlàyé ìsàlẹ̀) Ọ̀nà wo ló gbà rí bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àkàwé kan táá jẹ́ ká lóye kókó yìí. Ká sọ pé ọmọ kékeré kan bi ẹ́ pé, ‘Báwo lẹ ṣe mọ̀ pé lóòótọ́ ni atẹ́gùn wà?’ Òótọ́ ni pé o ò rí atẹ́gùn rí, síbẹ̀ wàá tọ́ka sí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn kedere pé atẹ́gùn wà. Bí àpẹẹrẹ, òun là ń mí sínú tá à ń mí síta, a sì máa ń rí i tó ń fẹ́ ewé sọ́tùn-ún sósì. Táwọn ẹ̀rí yẹn bá ṣe kedere sí ọmọ náà, á gbà pé atẹ́gùn wà bí ò tiẹ̀ rí i. Lọ́nà kan náà, àwọn ẹ̀rí tó dájú tó sì ṣe kedere ló ń mú ká nígbàgbọ́.—Róòmù 1:20.

A GBỌ́DỌ̀ MỌYÌ ÒTÍTỌ́ KÁ TÓ LÈ NÍ ÌGBÀGBỌ́

Kéèyàn tó lè ní ẹ̀rí táá mú kó nígbàgbọ́, ó ṣe pàtàkì kó ní “ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Ṣùgbọ́n ìmọ̀ nìkan ò tó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọkàn la fi ń ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 10:10) Kéèyàn nígbàgbọ́ kọjá kó kàn gba òtítọ́ gbọ́, ó tún ṣe pàtàkì kó mọyì rẹ̀. Ìgbà yẹn lèèyàn á tó lè lo ìgbàgbọ́, kó sì ṣe ohun tó bá ẹ̀kọ́ òtítọ́ mu. (Jém. 2:20) Àmọ́ téèyàn ò bá mọyì òtítọ́, kò ní fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ bó tiẹ̀ rí ẹ̀rí tó ṣe kedere. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa rin kinkin mọ́ èrò tiẹ̀ tàbí kó máa ṣàwáwí láti bo ìwàkiwà ẹ̀ mọ́lẹ̀. (2 Pét. 3:3, 4; Júùdù 18) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, kì í ṣe gbogbo àwọn tó rí iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run ló nígbàgbọ́. (Nọ́ń. 14:11; Jòh. 12:37) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ju irọ́ lọ ni ẹ̀mí mímọ́ máa ń mú kó nígbàgbọ́.—Gál. 5:22; 2 Tẹs. 2:10, 11.

OHUN TÓ MÚ KÍ DÁFÍDÌ NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ LÁGBÁRA

Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹni ìgbàgbọ́, ọ̀kan ni Ọba Dáfídì. (Héb. 11:32, 33) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ló nírú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Élíábù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Dáfídì fi hàn pé òun ò nígbàgbọ́ nígbà tó sọ̀rọ̀ sí Dáfídì torí pé Dáfídì ń béèrè nípa Gòláyátì. (1 Sám. 17:26-28) Ohun kan ni pé ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun àbímọ́ni, a ò sì lè jogún ẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa. Torí náà, àjọṣe tó dáa tí Dáfídì ní pẹ̀lú Ọlọ́run ló mú kó nígbàgbọ́.

Àkọsílẹ̀ inú Sáàmù 27 jẹ́ ká mọ ohun tó mú kí ìgbàgbọ́ Dáfídì lágbára tó bẹ́ẹ̀. (Ẹsẹ 1) Dáfídì máa ń ṣàṣàrò lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún un àti bí Jèhófà ṣe mú kó ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Ẹsẹ 2 àti 3) Bákan náà, ó mọyì ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn tòótọ́. (Ẹsẹ 4) Dáfídì máa ń jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ nínú àgọ́ ìjọsìn. (Ẹsẹ 6) Ó tún máa ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà. (Ẹsẹ 7 àti 8) Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì fẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà. (Ẹsẹ 11) Dáfídì gbà pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn ló fi béèrè pé: “Ibo ni mi ò bá wà, ká ní mi ò ní ìgbàgbọ́?”—Ẹsẹ 13.

OHUN TÁÁ MÚ KÍ ÌGBÀGBỌ́ RẸ LÁGBÁRA

Bó ṣe wà nínú Sáàmù 27, o lè nígbàgbọ́ bíi ti Dáfídì tó o bá fara wé e, tó o sì ń ṣe bíi tiẹ̀. Bá a ṣe sọ ṣáájú, ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní ìmọ̀ tó péye kéèyàn tó lè ní ìgbàgbọ́ tó jẹ́ apá kan èso tẹ̀mí. Torí náà, bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe ní ìgbàgbọ́ tó. (Sm. 1:2, 3) Máa wáyè láti ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tó ò ń kọ́. Bó o bá ṣe túbọ̀ ń ṣàṣàrò bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún ẹ. Bó o bá sì ṣe túbọ̀ ń mọyì Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa lo ìgbàgbọ́. Èyí á mú kó o máa pésẹ̀ sípàdé déédéé, wàá sì máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn míì. (Héb. 10:23-25) Bákan náà, à ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ tá a bá ń ‘gbàdúrà nígbà gbogbo, tá ò sì jẹ́ kó sú wa.’ (Lúùkù 18:1-8) Torí náà, “máa gbàdúrà nígbà gbogbo” sí Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé á “bójú tó” ẹ. (1 Tẹs. 5:17; 1 Pét. 5:7) Ìgbàgbọ́ á mú ká ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn á sì mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára.—Jém. 2:22.

Ẹ NÍ ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ JÉSÙ

Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú èmi náà.” (Jòh. 14:1) Torí náà, láfikún sí Jèhófà, ó yẹ ká tún nígbàgbọ́ nínú Jésù. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù? Ẹ jẹ́ ká sọ ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá (11) tó jẹ́ olóòótọ́

Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn nígbàgbọ́ nínú Jésù?

Àkọ́kọ́, gbà pé ìwọ gangan ni Jésù kú fún. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mò ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gál. 2:20) Tó o bá nígbàgbọ́ nínú Jésù, á dá ẹ lójú pé ìràpadà Jésù máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Yàtọ̀ síyẹn, ìràpadà ló ń jẹ́ kí Jèhófà máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ẹ́, òun ló jẹ́ kó o nírètí láti wà láàyè títí láé, òun ló sì jẹ́ kó o mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. (Róòmù 8:32, 38, 39; Éfé. 1:7) Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ kó o ronú pé o ò já mọ́ nǹkan kan, kò sì ní jẹ́ kó o ro ara rẹ pin.—2 Tẹs. 2:16, 17.

Ìkejì, túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o máa gbàdúrà sí i lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Lọ́lá ìràpadà náà, a lè gbàdúrà sí Jèhófà “ní fàlàlà, ká lè rí àánú gbà, ká sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó máa ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tó tọ́.” (Héb. 4:15, 16; 10:19-22) Tá a bá tẹra mọ́ àdúrà gbígbà, àá borí ìdẹwò tàbí ohunkóhun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀.—Lúùkù 22:40.

Ìkẹta, máa ṣègbọràn sí Jésù. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, àmọ́ ìbínú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòh. 3:36) Kíyè sí i pé àìgbọràn ni Jòhánù pè ní òdìkejì kéèyàn nígbàgbọ́. Torí náà, tó o bá ń ṣègbọràn sí Jésù, ìyẹn á fi hàn pé o nígbàgbọ́. O lè fi hàn pé ò ń ṣègbọràn sí Jésù tó o bá ń pa “òfin Kristi” mọ́, ìyẹn gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó pa láṣẹ. (Gál. 6:2) Tó o bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” a jẹ́ pé Jésù lò ń ṣègbọràn sí. (Mát. 24:45) Tó o bá ń ṣègbọràn sí Jésù, wàá di ìgbàgbọ́ rẹ mú bíná ń jó bí ìjì ń jà.—Lúùkù 6:47, 48.

“Ẹ MÁA FÚN ARA YÍN LÓKUN LÁTINÚ ÌGBÀGBỌ́ MÍMỌ́ JÙ LỌ TÍ Ẹ NÍ”

Ìgbà kan wà tí ọkùnrin kan bẹ Jésù pé: “Mo ní ìgbàgbọ́! Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!” (Máàkù 9:24) Òótọ́ ni pé ọkùnrin náà nígbàgbọ́ déwọ̀n àyè kan, àmọ́ ó kíyè sí i pé òun ṣì nílò ìgbàgbọ́ sí i. Bíi ti ọkùnrin yẹn, àwọn nǹkan kan máa ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa táá mú ká túbọ̀ nílò ìgbàgbọ́. Àmọ́ ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Bá a ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, a lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí torí pé á mú ká túbọ̀ mọyì Jèhófà. Ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára tá a bá ń pésẹ̀ sípàdé déédéé, tá à ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń gbàdúrà nígbà gbogbo. Tá a bá ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, àá rí ẹ̀bùn tó ju ẹ̀bùn lọ gbà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ máa fún ara yín lókun látinú ìgbàgbọ́ mímọ́ jù lọ tí ẹ ní . . . kí ẹ lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Júùdù 20, 21.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́