Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
◼ Àwọn Erékùṣù Marshall: Ní February wọ́n ní àròpọ̀ 203 akéde—ìbísí ìpín mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lèyí fi lé sí iye ti February ọdún tó kọjá!
◼ Norway: Ní February 1999, àwọn olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà fi ìpín méjìléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lé sí ti oṣù February 1998; àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé fi ìpín mẹ́sàn-án lé; ìpadàbẹ̀wò fi ìpín mẹ́rin lé; ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì fi ìpín mẹ́fà lé. Wọ́n tún fi àwọn ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ púpọ̀ sí i sóde.
◼ Romania: Ìbísí tó jọjú dé bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń darí, pẹ̀lú góńgó tuntun 37,502 iye àwọn akéde tí ń bẹ ní pápá ní oṣù February.