ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/00 ojú ìwé 8
  • Ìpàdé Máa Ń Ṣe Àwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpàdé Máa Ń Ṣe Àwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Bí Àwọn Ìpàdé Ṣe Lè Fún Wa Ní Ìdùnnú Púpọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń ṣamọ̀nà Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 8/00 ojú ìwé 8

Ìpàdé Máa Ń Ṣe Àwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní

1 Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́langba sọ pé: “Nígbà mìíràn, mo máa ń ronú pé àwa ọ̀dọ́ ló ń kojú ìṣòro jù nínú ìgbésí ayé. Àwọn èèyàn tó ń ṣe àgbèrè, tí wọ́n ń joògùn yó, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀mùtí ló yí wa ká.” Ṣé bí ìwọ náà ṣe ronú nìyẹn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo rò pé ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbéjà ko àwọn ohun búburú tó lè nípa lórí rẹ yìí? O nílò ìgbàgbọ́, ìyẹn ìgbàgbọ́ tó lágbára pé ọ̀nà Jèhófà lọ̀nà tí ó tọ́, nítorí pé láìsí ìgbàgbọ́, “kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa.” (Héb. 11:6) Lílọ sí ìpàdé ìjọ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí àwọn ìdánilójú tí o ní àti ìpinnu tí o ṣe gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni láti yẹra fún ohun búburú túbọ̀ lágbára sí i.

2 Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Ìpàdé Lè Ṣe fún Ọ: Kí ló máa ń mú kí jíjẹ oúnjẹ aládùn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹni gbádùn mọ́ni? Ǹjẹ́ kì í ṣe ìgbà tí oúnjẹ tó ń ṣara lóore bá wà ni, tí ìbákẹ́gbẹ́ ọ̀hún lárinrin, tí kò sì sí gbúngbùngbún? Báyìí gan-an ni àwọn ìpàdé wa ṣe ń gbádùn mọ́ni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ lọ́nà ti ẹ̀mí.

3 Àwọn nǹkan tó ń gbéni ró la máa ń jíròrò ní ìpàdé, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé títí dórí kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń fani lọ́kàn mọ́ra. Àwọn ìtọ́ni tí yóò kọ́ ẹ bí o ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ kí o sì borí ìpèníjà tó bá dojú kọ ọ́ wà níbẹ̀. Kò tún síbi tóo ti lè rí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó dára bí irú èyí tóo lè rí ní àwọn ìpàdé, àyíká ipò tẹ̀mí tó sì wà níbẹ̀ máa ń gbádùn mọ́ni, ó sì ń dáàbò boni. (Sm. 133:1) Abájọ tí ọ̀dọ́ kan fi sọ pé: “Kò sí ọjọ́ tí mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí kì í mú mi káàárẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣe ni ìpàdé dà bíi pápá oko tútù nínú aṣálẹ̀, níbi tí mo ti máa ń gba okun láti lè la ọjọ́ kejì já ní ilé ẹ̀kọ́.” Ọ̀dọ́ mìíràn sọ pé: “Mo ti rí i pé kíkẹ́gbẹ́ dáadáa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ láti sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.”

4 Nípa fíforúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ìwọ yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí o ṣe lè kó ìsọfúnni jọ látinú Bíbélì, kí o sọ ọ́ di àsọyé, kí o sì fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ṣáà ronú ná nípa àǹfààní tó wà nínú gbígba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti fi òtítọ́ tí ń gbẹ̀mí là, tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni lọ́nà dídáńgájíá! Ibo tún ni àwọn ọ̀dọ́ ti lè rí irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó níye lórí bẹ́ẹ̀ gbà?

5 Bí A Ṣe Lè Jàǹfààní Dáadáa Nínú Ìpàdé: Láti jàǹfààní dáadáa nínú ìpàdé, nǹkan mẹ́ta wà tó ṣe pàtàkì. Àwọn ni, ìmúrasílẹ̀, kíkópa nínú ìpàdé, àti fífi àwọn ohun tí a kọ́ sílò.

6 Múra Sílẹ̀ fún Wọn: Máa wá àyè déédéé láti múra ìpàdé sílẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́, tàbí eré ìdárayá gba àkókò tó yẹ kí o lò ṣáájú nínú ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí a óò jíròrò ní ìpàdé kọ̀ọ̀kan. Yóò ṣèrànwọ́ báa bá ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó dáa fún ṣíṣe èyí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ máa bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run nìṣó. Lójúmọ́ kan, ìṣẹ́jú díẹ̀ ló ń gbà láti ka àwọn orí tí a yàn kí a sì ṣàṣàrò lórí wọn. Máa ya àkókò sọ́tọ̀ láti múra sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ó kéré tán, àwọn kan máa ń ṣe ìyẹn ní ọjọ́ kan tàbí méjì ṣáájú ọjọ́ ìpàdé wọ̀nyẹn. Bí ó bá ti ṣeé ṣe tó, tún múra àwọn apá tí a ṣètò fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

7 Kópa Nínú Wọn: Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, wọ́n rí i ní tẹ́ńpìlì, tó ń fetí sílẹ̀, tó ń béèrè ìbéèrè, tó sì ń dáhùn ìbéèrè. (Lúùkù 2:46, 47) Lọ́rọ̀ mìíràn, ó kópa dáadáa níbẹ̀. Wàá túbọ̀ jàǹfààní nínú àwọn ìpàdé nígbà tóo bá sapá láti kópa nínú wọn.—Òwe 15:23.

8 O gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ dáadáa sórí ohun tí a fi ń kọ́ni ní ìpàdé. Nígbà mìíràn, fífetí sí àsọyé máa ń ṣòro ju sísọ àsọyé lọ. Kí ló fà á? Ìdí ni pé ọkàn rẹ lè máa ro tibí ro tọ̀hún nígbà tí ẹlòmíràn bá ń sọ̀rọ̀. Báwo lo ṣe lè ṣẹ́pá èyí? Nípa kíkọ àkọsílẹ̀ ni. Kọ àwọn kókó pàtàkì tí wàá fẹ́ láti lò lẹ́yìn náà sílẹ̀. Kíkọ àkọsílẹ̀ yóò jẹ́ kí o lè pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Síwájú sí i, ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, kí o sì máa fojú bá wọn lọ bí olùbánisọ̀rọ̀ ti ń kà wọ́n.

9 Ní àfikún sí i, fi í ṣe góńgó rẹ láti máa kópa nínú gbogbo ìjíròrò tó ní ìbéèrè àti ìdáhùn ní ìpàdé. Kódà, wàá túbọ̀ jàǹfààní bí o bá ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí o fẹ́ sọ. Òwe 15:28 wí pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.”

10 Máa Fi Ohun Tí O Ń Kọ́ Ṣèwà Hù: Ìgbésẹ̀ tó kẹ́yìn ni pé kí o rí i dájú pé ohun tí o ń kọ́ ‘ń ṣiṣẹ́ nínú rẹ.’ (1 Tẹs. 2:13) Bí o ṣe ń fi àwọn kókó pàtàkì tí o ń kọ́ ní ìpàdé sílò, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run sí i. Yóò jẹ́ ẹni gidi sí ọ, wàá sì ní ayọ̀ ńláǹlà àti ìtẹ́lọ́rùn bí o ṣe “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́,” tí o ń sọ ọ́ di tìrẹ.—3 Jòh. 4.

11 Ẹ̀yin ọ̀dọ́ arákùnrin àti arábìnrin, bí ẹ ṣe ń múra ìpàdé sílẹ̀ déédéé, tí ẹ ń kópa nínú wọn, tí ẹ sì ń fi àwọn ohun tí ẹ ń kọ́ ṣèwà hù, ẹ óò máa gbádùn ìpàdé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Lọ́wọ́ kan náà, ẹ óò máa jàǹfààní nínú wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìyẹn á fún ìgbàgbọ́ yín lókun, àní gẹ́gẹ́ bí yóò ti fún ìpinnu yín lókun pẹ̀lú láti jẹ́ olóòótọ́ sí Baba yín ọ̀run, Jèhófà.—Sm. 145:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́