Má Ṣe Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ṣohun Tẹ́gbẹ́ Ń Ṣe Ní Ipa Lórí Àǹfààní Tí O Ní Láti Wàásù
1 Ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe máa ń nípa gidigidi lórí ẹni yálà sí rere tàbí sí búburú. Àwọn ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń nípa rere lórí wa, ìyẹn sì ń ru wá sókè láti ṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà tó jẹ́ ti Kristẹni. (Héb. 10:24) Ṣùgbọ́n, àwọn mẹ́ńbà tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé, àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn tí a jọ ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, àwọn aládùúgbò wa, àti àwọn ojúlùmọ̀ wa mìíràn lè fẹ́ fagbára mú wa láti máa ṣe àwọn nǹkan tó lòdì sí àwọn ìlànà Kristẹni. Wọ́n lè “bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà rere [wa] ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi.” (1 Pét. 3:16) Báwo la ṣe lè dúró lórí ìpinnu wa láti máa bá a nìṣó ní wíwàásù láìka ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe tí kò dára tí a lè bá pàdé sí?
2 Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé: Nígbà mìíràn, ọkọ tàbí baba tí kì í ṣe ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máà fẹ́ kí ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé kan ní ìlú Mẹ́síkò nìyẹn. Ìyàwó ọkùnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ méje wá sínú òtítọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ta kò wọ́n nítorí pé kò fẹ́ kí ìdílé rẹ̀ lọ máa wàásù kí wọ́n sì máa fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni láti ilé dé ilé. Ó ronú pé iṣẹ́ yẹn kò buyì kún wọn. Ṣùgbọ́n, ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ dúró lórí ìpinnu tí wọ́n ti ṣe pé Jèhófà làwọ́n máa sìn àti pé àwọn yóò máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé. Nígbà tó yá, ọkùnrin yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí rí ìjẹ́pàtàkì títẹ́wọ́gba ètò tí Ọlọ́run ṣe pé kí á máa wàásù, òun pẹ̀lú sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló gbà á kó tó tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ṣùgbọ́n ṣé yóò tẹ́wọ́ gbà á ká ní ìdílé rẹ̀ jáwọ́ nínú àǹfààní tí wọ́n ní láti wàásù?—Lúùkù 1:74; 1 Kọ́r. 7:16.
3 Àwọn Tí Ẹ Jọ Ń Ṣiṣẹ́: Àwọn kan lára àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lè máà fẹ́ràn bí o ṣe ń sapá láti jẹ́rìí fún wọn. Arábìnrin kan ṣàlàyé pé nígbà tí wọ́n dá ìjíròrò kan sílẹ̀ níbi iṣẹ́ nípa òpin ayé, ó ní wọ́n fòun ṣẹ̀sín nítorí pé òun sọ pé kí wọ́n ka Mátíù orí kẹrìnlélógún. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, obìnrin kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ fún un pé òun ti ka orí náà àti pé ó gbádùn mọ́ òun. Ni arábìnrin yẹn bá fún un ní ìwé kan, ó sì ṣètò láti máa bá obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Agogo méjì òru ni wọ́n tó parí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kẹta, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí wọ́n fi jáwọ́ nínú mímu tábà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣé èyí ì bá ṣẹlẹ̀ ká ní arábìnrin wa yìí kò sapá láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìrètí rẹ̀?
4 Àwọn Tí Ẹ Jọ Ń Lọ Ilé Ẹ̀kọ́: Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sábà máa ń kojú ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe ní ilé ẹ̀kọ́, wọ́n sì lè bẹ̀rù pé àwọn ọ̀dọ́ yòókù yóò fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn nítorí pé àwọn ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Kristẹni kan tó jẹ́ ọ̀dọ́langba ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ẹ̀rù máa ń bà mí láti jẹ́rìí fún ọ̀dọ́ bíi tèmi nítorí pé mi ò fẹ́ kí wọ́n fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.” Nítorí náà, kì í lo àǹfààní tó bá ní láti jẹ́rìí fún àwọn ojúgbà rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ àti ní òde ẹ̀rí. Báwo lo ṣe lè di ẹni tó lókun láti kojú ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe? Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, máa wá ojú rere rẹ̀. (Òwe 29:25) Má ṣe tijú lílo agbára tí o ní láti lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. (2 Tím. 2:15) Ọ̀dọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà, ó bẹ̀bẹ̀ pé kí ó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè fẹ́ láti máa bá àwọn tí àwọn jọ ń lọ ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà ní ilé ẹ̀kọ́, àbájáde rẹ̀ dára, kò sì pẹ́ tó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tó bá mọ̀ ló ń bá sọ̀rọ̀. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ èèyàn wọ̀nyẹn ń fẹ́ láti ní ìrètí nípa ọjọ́ ọ̀la, Jèhófà sì ń lò wá láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”
5 Àwọn Aládùúgbò Wa: A lè ní àwọn aládùúgbò tàbí àwọn ojúlùmọ̀ wa mìíràn tí wọ́n máa ń bínú sí wa nítorí irú ẹni tí a jẹ́ àti nítorí àwọn ohun tí a gbà gbọ́. Bí o bá ń bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń rò, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé wọ́n mọ òtítọ́ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun? Kí ni mo lè ṣe láti dé ọkàn-àyà wọn?’ Alábòójútó àyíká kan sọ pé àbájáde rere máa ń wà bí a bá jẹ́rìí ní ṣókí fún àwọn aládùúgbò wa ṣùgbọ́n tí a ń jẹ́rìí fún wọn déédéé. Fi taratara bẹ Jèhófà pé kí ó fún ọ ní okun àti ọgbọ́n tí o nílò láti lè máa bá a nìṣó láti máa wá àwọn aláìlábòsí ọkàn rí.—Fílí. 4:13.
6 Jíjuwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe tí kò dára lè dùn mọ́ àwọn alátakò wa, ṣùgbọ́n ṣe jíjuwọ́ sílẹ̀ lọ́nà yìí yóò ṣe wọ́n láǹfààní, ṣé yóò tilẹ̀ ṣe àwa pẹ̀lú láǹfààní? Àwọn ará ìlú Jésù ta kò ó. Kódà ó gbọ́ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé bí òun bá ṣe olóòótọ́ lójú ọ̀nà tí Ọlọ́run ti là sílẹ̀ fún òun, èyí nìkan lòun fi lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Nípa báyìí, Jésù “fara da irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ire ara wọn.” (Héb. 12:2, 3) Ohun kan náà la gbọ́dọ̀ ṣe. Pinnu láti lo àǹfààní tí o ní láti wàásù iṣẹ́ Ìjọba náà lọ́nà tó dára jù lọ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, “ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tím. 4:16.