Mímú Kí Àwọn Èèyàn Mọrírì Fídíò The Bible—Mankind’s Oldest Modern Book
Àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí ń tẹnu mọ́ àwọn kókó tí o ti lè kíyè sí nígbà tí o ń wo fídíò yìí: (1) Àwọn kókó wo ló fi Bíbélì hàn yàtọ̀ pé kò ní ẹlẹgbẹ́? (2) Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ Bíbélì ti pẹ́, ó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní mu. (3) Báwo la ṣe lè ní ìdánilójú pé Bíbélì tòní kò tíì yí padà kúrò ní bí wọ́n ṣe kọ ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀? (4) Kí ni ohun kan tó ta yọ nínú ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì ìgbàanì, ìgbọ́kànlé wo lèyí sì mú kí o ní? (5) Àwọn ọ̀nà wo ni John Wycliffe, Johannes Gutenberg, William Tyndale, Mary Jones, àti Charles Taze Russell gbà kópa nínú mímú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàn ká gbogbo ayé? (6) Báwo ni ṣọ́ọ̀ṣì ṣe tako Bíbélì lọ́nà gbígbónájanjan, ṣùgbọ́n kí ló mú kí Bíbélì wà títí di ọjọ́ wa? (7) Báwo ni Bíbélì tí ètò àjọ Jèhófà ti túmọ̀ tí wọ́n sì ti mú jáde ṣe pọ̀ tó? (8) Báwo ni ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Bíbélì ti ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro tẹ́tẹ́ títa tó ti di bárakú (1 Tím. 6:9, 10), pípínyà nínú ìgbéyàwó àti àìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó (1 Kọ́r. 13:4, 5; Éfé. 5:28-33), àti jíjẹ́ kí ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì gba gbogbo ìgbésí ayé ẹni (Mát. 16:26)? (9) Ẹ̀rí wo ló wà pé fífi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò lè borí ìkórìíra tó wà nínú ayé lónìí láàárín orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àti ìran? (10) Àwọn ọ̀nà wo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú Bíbélì fi fún ọ ní ayọ̀ ńláǹlà? (11) Àwọn wo lo rò pé wọ́n máa jàǹfààní nínú fídíò yìí, báwo ni wàá sì ṣe sọ fún wọn nípa rẹ̀?