Ogun Jíjà Àwọn Agẹṣinjagun Kan Tó Kàn Ọ́
1, 2. Báwo ni ìmúṣẹ ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 9:13-19 ṣe kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí?
1 “Áńgẹ́lì kẹfà . . . fun kàkàkí rẹ̀.” Lẹ́yìn èyí, “àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti agbo agẹṣinjagun” tí iye wọn jẹ́ “ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún” sán bí àrá. Èyí kì í ṣe ẹgbẹ́ ọmọ ogun lásánlàsàn kan. “Orí àwọn ẹṣin náà . . . dà bí orí kìnnìún.” Iná, èéfín àti imí ọjọ́ ń jáde wá láti ẹnu wọn, “ìrù wọn [sì] dà bí ejò.” Ìparun yán-án-yán-án ló máa ń jẹ́ àbájáde ogun jíjà àwọn agẹṣinjagun ìṣàpẹẹrẹ yìí. (Ìṣí. 9:13-19) Ǹjẹ́ o mọ bí ìmúṣẹ ìran kíkàmàmà tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe kàn ọ́?
2 Àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn àgùntàn mìíràn, ń fi ìṣọ̀kan sọ ìdájọ́ Ọlọ́run di mímọ̀. Àbájáde èyí ni pé wọ́n ń táṣìírí ipò òkú nípa tẹ̀mí tí Kirisẹ́ńdọ̀mù wà. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò apá méjì pàtàkì lára ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ náà, èyí tó ń fi ìdí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi múná dóko hàn.
3. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wo lo ti gbà láti máa sọ ìhìn Ọlọ́run lọ́nà tó múná dóko?
3 A Dá Wọn Lẹ́kọ̀ọ́, A sì Mú Wọn Gbára Dì Láti Sọ Ìhìn Ọlọ́run: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìpàdé ìjọ mìíràn ń mú kí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run dẹni tá a dá lẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ọlá àṣẹ sọ ìhìn Ọlọ́run. Ní àfarawé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń lọ láti wá àwọn ẹni yíyẹ kàn, nípa wíwàásù níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí àwọn èèyàn. (Mát. 10:11; Máàkù 1:16; Lúùkù 4:15; Ìṣe 20:18-20) Ọ̀nà tá à ń gbà wàásù tó bá Bíbélì mu yìí mà kúkú múná dóko o!
4. Ohun èlò wo ló wà níkàáwọ́ ọ̀pọ̀ àwọn akéde tó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe iṣẹ́ wọn?
4 Ọ̀kẹ́ àìmọye Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìròyìn làwa Ẹlẹ́rìí ti pín kiri láti fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún wa. A ti mú àwọn ìwé wọ̀nyí jáde ní èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó irínwó, oríṣiríṣi nǹkan làwọn ìwé yìí sì ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀nà tá a gbà kọ ọ̀rọ̀ inú wọn jẹ́ èyí tó lè fa onírúurú èèyàn mọ́ra. Ǹjẹ́ ò ń lo àwọn ìwé wọ̀nyí dáadáa?
5, 6. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn?
5 Ìtọ́sọ́nà àti Ìtìlẹyìn Ọlọ́run: Ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ náà tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ń ṣètìlẹyìn fún ìgbòkègbodò tí ogun jíjà àwọn agẹṣinjagun ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún. (Ìṣí. 9:13-15) Kì í ṣe ọgbọ́n tàbí agbára ẹ̀dá èèyàn ló ń jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tó kárí ayé yìí ṣeé ṣe, ẹ̀mí Ọlọ́run ni. (Sek. 4:6) Jèhófà ń lo àwọn áńgẹ́lì láti darí iṣẹ́ yìí. (Ìṣí. 14:6) Nípa bẹ́ẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú ìsapá àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jèhófà ń pèsè ìtìlẹyìn àtọ̀runwá láti fa àwọn ọlọ́kàn tútù sọ́dọ̀ rẹ̀.—Jòh. 6:45, 65.
6 Níwọ̀n bí a ti dá àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ti gbára dì láti sọ ìhìn Ọlọ́run, tí wọ́n tún ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìtọ́sọ́nà àwọn áńgẹ́lì, kò sóhun tó lè dá wọn dúró. Ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti ṣe ipa tiwa nínú ìmúṣẹ ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó ń wúni lórí yìí.