Jèhófà Ń Ran Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé E Lọ́wọ́
1 Ọ̀pọ̀ rò pé èèyàn gbọ́dọ̀ ní owó, agbára àti ẹ̀bùn àbínibí kó tó lè ṣàṣeyọrí. (Sm. 12:4; 33:16, 17; 49:6) Àmọ́ o, Bíbélì fi àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e lọ́kàn balẹ̀ nípa sísọ pé “òun ni ìrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.” (Sm. 115:11) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tó yẹ ká gbà máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
2 Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: A gbọ́dọ̀ gbára lé Ọlọ́run nígbàkigbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ tàbí nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Wo àpẹẹrẹ Jésù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni, kò gbára lé ọgbọ́n tàbí òye tirẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ Baba rẹ̀ ọ̀run ló gbẹ́kẹ̀ lé láìkù síbì kan. (Jòh. 12:49; 14:10) Láìsí àní-àní, ó yẹ kí àwa pẹ̀lú túbọ̀ gbára lé baba wa ọ̀run! (Òwe 3:5–7) Àyàfi pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nìkan làwọn ìsapá wa tó lè bọlá fún un tí yóò sì ṣàwọn èèyàn láǹfààní.—Sm. 127:1, 2.
3 Bí a bá ń gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jèhófà àti ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó fi hàn pé a gbára lé e. (Sm. 105:4; Lúùkù 11:13) Síwájú sí i, bá a bá ń gbé ohun tá à ń kọ́ àwọn èèyàn ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyí á fi hàn pé a gbọ́kàn lé Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lágbára láti wọ àwọn èèyàn lọ́kàn kó sì yí ìgbésí ayé wọn padà. (Héb. 4:12) Bá a bá ń “ṣe ìránṣẹ́ bí ẹni tí ó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè,” èyí á fi ògo fún Jèhófà.—1 Pét. 4:11.
4 Nígbà Tá A Bá Ń Kojú Ìṣòro: Bákan náà, ó yẹ ká máa wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nígbà tá a bá ń dojú kọ ìṣòro. (Sm. 46:1) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá wa níbi iṣẹ́ lè máà fẹ́ fún wa láyè láti lọ sí àpéjọ tàbí kí ìṣòro wà nínú ìdílé wa. A lè fi hàn pé a gbára lé Jèhófà nígbà tá a bá ń fi tọkàntara rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i, tá a sì ń fi ìtọ́sọ́nà tó ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ sílò. (Sm. 62:8; 119:143, 173) Nípa ṣíṣe báyìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń rí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ gbà nínú ìgbésí ayé wọn.—Sm. 37:5; 118:13, 16.
5 Jèhófà fúnra rẹ̀ fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ìbùkún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí Jèhófà di ìgbọ́kànlé rẹ̀.” (Jer. 17:7) Ẹ jẹ́ ká máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe!—Sm. 146:5.