ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/04 ojú ìwé 8
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Wàásù fún Àwọn Mọ̀lẹ́bí Wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Wàásù fún Àwọn Mọ̀lẹ́bí Wa?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìbátan Rẹ Ńkọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Bá A Ṣe Lè Mú Kí Àwọn Ìbátan Wa Tí Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí Nífẹ̀ẹ́ Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Àwọn Tó Ń Fetí Sí Ọ” Máa Rí Ìgbàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 12/04 ojú ìwé 8

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Wàásù fún Àwọn Mọ̀lẹ́bí Wa?

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká lo òye nígbà tá a bá ń wàásù fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa?

1 Láìsí àní-àní, inú wa á dùn gan-an tí àwa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa bá jọ ń sin Jèhófà tí gbogbo wa sì jọ dé inú ayé tuntun! Ṣùgbọ́n kí èyí tó lè ṣẹlẹ̀, a ní láti wàásù fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa. Àmọ́ o, tí a bá fẹ́ wàásù fún wọn lọ́nà tó máa tù wọ́n lára, ó ṣe pàtàkì pé ká lo òye. Alábòójútó àyíká kan sọ pé: “Àwọn tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n máa ń wàásù fún àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, tí wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ló sábà máa ń ṣàṣeyọrí jù lọ.” Báwo la ṣe lè ṣe èyí?

2. Báwo la ṣe lè lo ìfẹ́ tá a ní sí àwọn mọ̀lẹ́bí wa láti fi mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere?

2 Sọ Ohun Tó Máa Mú Kí Wọ́n Fẹ́ Gbọ́: Kó o tó bá àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ sọ̀rọ̀, ronú dáadáa lórí àwọn ohun tó o lè sọ tó máa mú kí wọ́n fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. (Òwe 15:28) Kí làwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa rẹ̀? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n ní? O lè fi àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé wa hàn wọ́n tàbí kó o mẹ́nu kan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ti kókó ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí gan-an lẹ́yìn. Bó bá jẹ́ pé ọ̀nà jíjìn làwọn mọ̀lẹ́bí rẹ ń gbé, o lè kọ lẹ́tà tàbí kó o lo tẹlifóònù láti fi wàásù fún wọn. Má sọ̀rọ̀ púpọ̀ jù, kàkà bẹ́ẹ̀ rọra máa gbin irúgbìn òtítọ́, kó o sì máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà kó bàa lè mú kí àwọn irúgbìn náà dàgbà sókè.—1 Kọ́r. 3:6.

3. Báwo ni ìfẹ́ táwọn mọ̀lẹ́bí wa ní sí wa ṣe lè fún wa láǹfààní láti wàásù fún wọn?

3 Lẹ́yìn tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọkùnrin kan, ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Lọ sí ilé lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ọ àti àánú tí ó ní sí ọ.” (Máàkù 5:19) Fojú inú wo bí ìròyìn ọkùnrin yìí ṣe máa wọ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ́kàn tó! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwàásù tìrẹ lè má wọ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ lọ́kàn bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ó dájú pé àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ máa ń fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìgbòkègbodò rẹ tàbí ohun táwọn ọmọ rẹ ń ṣe. Tí o bá sọ fún wọn nípa iṣẹ́ tó o ṣe ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àpéjọ àgbègbè tó o lọ, ìbẹ̀wò tó o ṣe sí Bẹ́tẹ́lì tàbí ohun ìdùnnú kan tó ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ, èyí lè fún ọ láǹfààní láti túbọ̀ bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀.

4. Àwọn ohun wo ni kò yẹ ká ṣe nígbà tá a bá ń wàásù fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa?

4 Máa Lo Òye: Nígbà tó o bá ń jẹ́rìí fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, má ṣe sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ jù lẹ́ẹ̀kan. Arákùnrin kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ní: “Mo kàn máa ń rọ̀jò àlàyé lé màmá mi lórí ni ṣáá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ni mo máa ń sọ, ọ̀pọ̀ ìgbà lèyí sì máa ń di àríyànjiyàn, pàápàá láàárín èmi àti bàbá mi.” Kódà bí mọ̀lẹ́bí kan bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì, ńṣe ló yẹ kó o rọra máa ṣàlàyé fún un, kó bàa lè fẹ́ láti mọ̀ sí i. (Òwe 25:7) Máa fi sùúrù, ọ̀wọ̀ àti inú rere bá a lò, gẹ́gẹ́ bó o ṣe máa ṣe tó o bá ń bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí.—Kól. 4:6.

5. Kí ló yẹ ká ṣe bí àwọn mọ̀lẹ́bí wa ò bá mọrírì gbogbo ìsapá wa láti wàásù fún wọn?

5 Lákòókò kan, àwọn mọ̀lẹ́bí Jésù rò pé orí rẹ̀ ti yí. (Máàkù 3:21) Àmọ́, nígbà tó yá, àwọn kan lára wọn di onígbàgbọ́. (Ìṣe 1:14) Bí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ ò bá tètè mọrírì gbogbo ìsapá rẹ láti wàásù fún wọn, má ṣe jẹ́ kó sú ọ. Ìṣesí àwọn mọ̀lẹ́bí wa àti bí ipò nǹkan ṣe rí fún wọn lè yí padà. Máa wá ọ̀nà tó o lè gbà sọ àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí fún wọn, èyí tó lè jẹ́ kí wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i. O lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè ayérayé, èyí á sì múnú rẹ dùn gan-an.—Mát. 7:13, 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́