Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Àwọn Ìpàdé Ìjọ
1 Tó bá jẹ́ pé Kristẹni ni ọ́, wàá fẹ́ káwọn ọmọ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì máa sìn ín, àti pé, nígbà tí àsìkò bá tó, kí wọ́n lè wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí wọ́n fi ìjọsìn Jèhófà ṣe ohun àkọ́múṣe nígbèésí ayé wọn? Àpẹẹrẹ tíwọ fúnra ẹ bá fi lélẹ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan. (Òwe 20:7) Nígbà tí arábìnrin kan ń sọ nípa ìyá rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, ó ní: “Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ sí pé à ń sọ, gbogbo ọjọ́ ìpàdé, lílọ ni.” Èyí sì ràn án lọ́wọ́ gan-an.
2 Ṣé ìdílé tìẹ náà mọyì ìdí tá a fi ń péjọ sí gbogbo ìpàdé? Ìtọ́ni tá à ń gbà láwọn ìpàdé wọ̀nyí ló máa ń fún wa lókun tá a fi ń bá a nìṣó láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, bákan náà sì ni ti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tá à ń jọlá rẹ̀ láàárín àwọn ará wa jẹ́ orísun ìṣírí tí ò lẹ́gbẹ́. (Aísá. 54:13; Róòmù 1:11, 12) Àmọ́, olórí ohun tá a tìtorí rẹ̀ ń ṣe ìpàdé bí kò ṣe ká lè máa kókìkí ìyìn Jèhófà láàárín “àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.” (Sm. 26:12) Ìpàdé àwa Kristẹni máa ń mú ká láǹfààní láti lè fi hàn bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó, ká sì sìn ín.
3 “Ẹ Máa Ṣọ́ra Lójú Méjèèjì”: Bá a bá gbà lóòótọ́ pé láti lè ṣe ìjọsìn mímọ́ la ṣe ń ṣe àwọn ìpàdé wa, a ó “máa ṣọ́ra lójú méjèèjì,” ìyẹn ni ò sì ní jẹ́ ká dẹni tó ti sọ́ ọ di àṣà láti máa sá ní ìpàdé nítorí àwọn ọ̀ràn tí kò ṣe pàtàkì. (Éfé. 5:15, 16; Héb. 10:24, 25) Nígbà tó o bá ń ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé rẹ, o lè bẹ̀rẹ̀ látorí yíya àwọn àkókò sọ́tọ̀ fún ìpàdé ìjọ. Lẹ́yìn náà, kíyè sára kó o má ṣe lo àkókò wọ̀nyẹn fáwọn nǹkan míì. Rí i dájú pé lílọ sípàdé lẹ fi ṣe ohun àkọ́kọ́ nínú ìdílé.
4 Ǹjẹ́ kì í wú wa lórí nígbà tá a bá kà nípa gudugudu táwọn ará wa ń ṣe láti borí ohun tí ì bá dí wọn lọ́wọ́ lílọ sí ìpàdé àtàwọn àpéjọ? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tìẹ lè máà nira tó bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe kíwọ náà ní ohun ìdíwọ́ kan. Sátánì ń mú kó túbọ̀ nira fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti máa sin Jèhófà. Síbẹ̀ jẹ́ kó dá ọ lójú pé, àwọn ọmọ rẹ ń wo bí ìdílé rẹ ṣe ń sapá láti dúró ti ìpinnu tí ìdílé tẹ́ ẹ ṣe láti lè máa lọ sí gbogbo ìpàdé. Ní ti gidi, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè fún wọn lẹ́bùn tẹ̀mí, èyí tí wọn ò ní gbàgbé láé.