Ẹ Di Ọ̀jáfáfá Nínú Bíbá Àwọn Èèyàn Fèrò Wérò
1. Àkọsílẹ̀ Bíbélì wo la fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbé yẹ̀ wò, kí sì nìdí?
1 Àpẹẹrẹ tó dára nípa bá a ṣe lè máa bá àwọn èèyàn fọ̀rọ̀ wérọ̀ ni ọ̀nà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wàásù nínú sínágọ́gù kan tó wà nílùú Písídíà ní Áńtíókù, bó ṣe wà nínú ìwé Ìṣe 13:16-41. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ro tirú èèyàn táwọn tó ń kọ́ jẹ́ àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú, mú kó sọ ìhìn rere náà lọ́nà tó yé wọn. Bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ yìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè fara wé e nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
2. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà bẹ̀rẹ̀ àwíyé rẹ̀?
2 Wá Ibi Térò Yín Ti Jọra: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà pàtàkì tí Jésù gbà mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ni àwíyé Pọ́ọ̀lù dá lé, síbẹ̀ orí kókó yẹn kọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bá àwọn Júù tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí ohun tó mọ̀ pé wọn ò lè jiyàn ẹ̀, ìyẹn ìtàn àwọn Júù. (Ìṣe 13:16-22) Bákan náà, a óò túbọ̀ máa dénú ọkàn àwọn èèyàn bá a bá ń wá ibi tí èrò tiwa àti tiwọn ti jọra. Ó lè jẹ́ pé ṣe la ní láti fọgbọ́n bi wọ́n láwọn ìbéèrè kan kí wọ́n lè sọ èrò wọn jáde, a ó sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n bá sọ ká bàa lè lóye ohun tó jẹ wọ́n lógún.
3. Kí ló mú kó nira fáwọn tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ láti gbà pé Jésù ni Mèsáyà?
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń jíròrò ìtàn àwọn Júù, ó rán àwọn tó ń fetí sí i létí ìlérí Ọlọ́run láti rán olùgbàlà kan tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n, ńṣe lọ̀pọ̀ Júù ń retí akọni ológun tó máa wá gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù tó ń jẹ gàba lé wọn lórí, kó sì gbé orílẹ̀-èdè Júù ga ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Ó dájú pé wọ́n mọ̀ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù kẹ̀yìn sí Jésù, wọ́n fà á lé àwọn aláṣẹ Róòmù lọ́wọ́, wọ́n sì fikú pa á. Ọgbọ́n wo ni Pọ́ọ̀lù máa wá ta sí i táwọn èèyàn yẹn á fi gbà pé Ẹni tí wọ́n pa yẹn gan-an ni Mèsáyà tó ń bọ̀?
4. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà fi òye yé àwọn Júù tó bá sọ̀rọ̀?
4 Mú Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Àwọn Tó Ò Ń Bá Sọ̀rọ̀ Mu: Nítorí pé Pọ́ọ̀lù mọ ọ̀nà táwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ gbà ń ronú, ló ṣe lè lo Ìwé Mímọ́ láti bá wọn fèrò wérò lórí àwọn nǹkan tí wọ́n gbà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àtọmọdọ́mọ Dáfídì ni Jésù òun sì ni Jòhánù Oníbatisí táwọn èèyàn mọ̀ sí wòlíì Ọlọ́run, sọ nípa rẹ̀. (Ìṣe 13:23-25) Pọ́ọ̀lù wá là á mọ́lẹ̀ pé ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó kọ Jésù tó sì pa á “mú àwọn ohun tí a sọ láti ẹnu àwọn Wòlíì ṣẹ.” (Ìṣe 13:26-28) Síwájú sí i, ó ṣàlàyé pé àwọn èèyàn rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde ó sì fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí àjíǹde Jésù mú ṣẹ hàn wọ́n.—Ìṣe 13:29-37.
5. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe yíwọ́ padà nígbà tó ń bá àwọn Gíríìkì sọ̀rọ̀? (b) Báwo la ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nígbà tá a bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
5 Lákòókò míì, nígbà tó ń bá àwọn Gíríìkì sọ̀rọ̀ ní Áréópágù nílùú Áténì, ọ̀nà míì ni Pọ́ọ̀lù bá yọ. (Ìṣe 17:22-31) Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn kan náà ló kọ́ wọn. Nígbà méjèèjì, ìyẹn ìgbà tó bá àwọn Júù sọ̀rọ̀ àtìgbà tó báwọn Gíríìkì fèrò wérò, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Ìṣe 13:42, 43; 17:34) Bákan náà lóde òní, ohun táwa náà ń kọ́ àwọn èèyàn á yé wọn bá a bá mọ ibi térò wa àti tiwọn ti jọra, tá a sì mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ látilẹ̀wá àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú.